Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Tó Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
“Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè”—JÒHÁNÙ 14:6.
1, 2. Kí ni Jésù fi ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun wé, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì àkàwé rẹ̀?
NÍNÚ Ìwàásù rẹ̀ olókìkí tó ṣe lórí Òkè, Jésù fi ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun wé ọ̀nà kan tó ní ẹnubodè téèyàn lè gbà wọ̀ ọ́. Ṣàkíyèsí pé Jésù tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀nà ìyè yìí kò rọrùn, ó sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”—Mátíù 7:13, 14.
2 Ǹjẹ́ o mọ ìjẹ́pàtàkì àkàwé yìí? Ǹjẹ́ kò ha fi hàn pé ọ̀nà kan ṣoṣo ló lọ sí ìyè àti pé a ní láti kíyè sára gidigidi bí a kò bá fẹ́ ṣáko kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, èwo wá ni ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun?
Ipa Tí Jésù Kristi Kó
3, 4. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi ipa tí Jésù ń kó nínú ìgbàlà wa hàn? (b) Nígbà wo ni Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣí i payá pé aráyé lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun?
3 Ó ṣe kedere pé, Jésù ní ipa pàtàkì tí yóò kó nípa ọ̀nà yẹn, gẹ́gẹ́ bí Pétérù àpọ́sítélì rẹ̀ ti kéde pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run [lẹ́yìn orúkọ Jésù] tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù polongo pé: “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Jésù fúnra rẹ̀ fi hàn pé òun ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, ó polongo pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6.
4 Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí a tẹ́wọ́ gba ipa tí Jésù ń kó nínú mímú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò fínnífínní lórí ipa tó ń kó. Lẹ́yìn tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé aráyé tún lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun? Gbàrà tí Ádámù ti ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ náà ni. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò bí a ṣe kọ́kọ́ sàsọtẹ́lẹ̀ nípa pípèsè Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà aráyé.
Irú-Ọmọ Táa Ṣèlérí
5. Báwo ni a ṣe lè mọ ejò náà tó tan Éfà jẹ?
5 Lédè àpèjúwe, Jèhófà Ọlọ́run sọ ẹni tí Olùgbàlà táa ṣèlérí náà yóò jẹ́. Ó ṣe èyí nígbà tó kéde ìdájọ́ lórí “ejò” náà tó bá Éfà sọ̀rọ̀, tó tún dán an wò láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nípa mímú kí obìnrin náà jẹ èso igi tí a kà léèwọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Àmọ́ ṣá o, ejo yìí kì í ṣe ejò gidi. Ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan báyìí ni, ẹni tí Bíbélì pè ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” (Ìṣípayá 12:9) Sátánì lo ẹranko lásánlàsàn yìí gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ láti tan Éfà jẹ. Nípa báyìí, nígbà tó ń kéde ìdájọ́ lórí Sátánì, Ọlọ́run wí fún un pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun [ìyẹn irú-ọmọ obìnrin náà] yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
6, 7. (a) Ta ni obìnrin tó mú “irú-ọmọ” náà jáde? (b) Ta ni Irú-Ọmọ náà táa ṣèlérí, kí ló sì ṣe?
6 Ta ni “obìnrin” yìí tí Sátánì ń bá ṣọ̀tá, tàbí tó kórìíra? Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ẹni tí “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” jẹ́ nínú ìwé Ìṣípayá orí kejìlá, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe sọ ẹni tí obìnrin tí Sátánì kórìíra náà jẹ́. Kíyè sí i ní ẹsẹ ìkíní tí ó sọ pé “a fi oòrùn ṣe” obìnrin náà “ní ọ̀ṣọ́, òṣùpá sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá sì ń bẹ ní orí rẹ̀.” Obìnrin yìí dúró fún ètò àjọ Ọlọ́run ti àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ tó wà lókè ọ̀run, “ọmọkùnrin” tí obìnrin náà bí sì dúró fún Ìjọba Ọlọ́run, tí Jésù Kristi ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba.—Ìṣípayá 12:1-5, The Jerusalem Bible.
7 Nítorí náà, ta ni “irú-ọmọ” náà, tàbí ọmọ, obìnrin náà, tí a mẹ́nu kàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ẹni táa sọ pé yóò fọ́ “orí” Sátánì, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ pa á lápatán? Onítọ̀hún ni ẹni tí Ọlọ́run rán wá látọ̀run, ẹni tó mú kí wúńdíá kan bí lọ́nà ìyanu, bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ni ọkùnrin náà. (Mátíù 1:18-23; Jòhánù 6:38) Orí kejìlá inú ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹni táa jí dìde yìí, tí ń ṣàkóso látọ̀run, àní Irú-Ọmọ yìí, ìyẹn Jésù Kristi, ni yóò ṣáájú nínú ṣíṣẹ́gun Sátánì, gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 12:10 sì ti sọ, òun ni yóò gbé “ìjọba Ọlọ́run wa àti ọlá àṣẹ Kristi rẹ̀” kalẹ̀.
8. (a) Ohun tuntun wo ni Ọlọ́run pèsè ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀? (b) Àwọn wo ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọba tuntun ti Ọlọ́run?
8 Ìjọba tó wà lọ́wọ́ Jésù Kristi yìí tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tuntun kan tí Ọlọ́run pèsè ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí ẹ̀dá ènìyàn máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì, ojú ẹsẹ̀ ni Jèhófà gbégbèésẹ̀ láti lo Ìjọba tuntun yìí láti mú gbogbo aburú tí ìwà ibi ti mú wá kúrò. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ ká mọ̀ pé òun nìkan kọ́ ni yóò dá ṣàkóso nínú ìjọba táà ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. (Lúùkù 22:28-30) A óò yan àwọn mìíràn láti inú aráyé, àwọn wọ̀nyí yóò sì dara pọ̀ mọ́ ọn ní ọ̀run láti ṣàkóso, nípa báyìí, wọn yóò di apá kejì nínú irú-ọmọ obìnrin náà. (Gálátíà 3:16, 29) Nínú Bíbélì a pe iye àwọn tí yóò bá Jésù ṣàkóso yìí ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, láti inú ìran ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a sì ti mú gbogbo wọn.—Ìṣípayá 14:1-3.
9. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí Jésù fara hàn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn? (b) Báwo ni Jésù ṣe pa iṣẹ́ Èṣù run?
9 Ṣùgbọ́n, kó tó di pé Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso, ó ṣe pàtàkì pé kí apá àkọ́kọ́ nínú irú ọmọ náà, ìyẹn ni Jésù Kristi, fara hàn lóri ilẹ̀ ayé. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run ti yàn án gẹ́gẹ́ bí Ẹni tí yóò “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú [tàbí tí yóò pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run].” (1 Jòhánù 3:8) Lára àwọn iṣẹ́ Sátánì ni sísún Ádámù láti dẹ́ṣẹ̀, èyí tó mú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù. (Róòmù 5:12) Jésù pa iṣẹ́ Èṣù run nípa fífi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. Nípa báyìí, ó pèsè ìpìlẹ̀ kan fún títú aráyé sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 20:28; Róòmù 3:24; Éfésù 1:7.
Ohun Tí Ìràpadà Mú Kó Ṣeé Ṣe
10. Ọ̀nà wo ni Jésù àti Ádámù gbà jọra?
10 Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé látọ̀run la ti tàtaré ìwàláàyè Jésù sínú ọlẹ̀ obìnrin náà, a bí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kò kó àbààwọ́n bá. Ó lágbára láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Bákan náà, a dá Ádámù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé tí ó ní ìrètí gbígbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Ohun tí àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí fi jọra ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “‘Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè ọkàn.’ Ádámù ìkẹyìn [Jésù Kristi] di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè. Ọkùnrin àkọ́kọ́ jẹ́ láti inú ilẹ̀, ekuru ni a sì fi dá a; ọkùnrin kejì jẹ́ láti ọ̀run.”—1 Kọ́ríńtì 15:45, 47.
11. (a) Ipa wo ni Ádámù àti Jésù ní lórí ìran ènìyàn? (b) Ojú wo ló yẹ ká fi wo ẹbọ Jésù?
11 Ohun tí àwọn méjèèjì yìí fi jọra—àwọn ọkùnrin pípé méjì tó tí ì gbé ayé rí—ni ọ̀rọ̀ Bíbélì tẹnu mọ́ pé Jésù “fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 2:6) Ta ni Jésù bá ṣe rẹ́gí? Họ́wù, Ádámù ni, nígbà tó ṣì jẹ́ ènìyàn pípé! Ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù àkọ́kọ́ dá yọrí sí jíjẹ̀bi tí gbogbo ìdílé ènìyàn jẹ̀bi ikú. Ìrúbọ “Ádámù ìkẹyìn” pèsè ìpìlẹ̀ fún ìdáǹdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí a bàa lè wà láàyè títí láé. Ẹbọ Jésù mà ṣeyebíye o! Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́, pẹ̀lú fàdákà tàbí wúrà, ni a fi dá yín nídè.” Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù ṣàlàyé pé: “Ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí, àní ti Kristi.”—1 Pétérù 1:18, 19.
12. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí a óò gbà mú ẹ̀bi ikú tí a dá wa kúrò?
12 Bíbélì ṣe àpèjúwe tó gún régé nípa ọ̀nà tí a óò gbà mú ẹ̀bi ikú tí a ti dá ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kúrò, nípa sísọ pé: “Nípasẹ̀ àṣemáṣe kan [tí Ádámù ṣe] ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan [ọ̀nà ìwà títọ́ Jésù látòkè délẹ̀, tó wá yọrí sí ikú rẹ̀] ìyọrísí náà fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan [Ádámù] ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Jésù], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.”—Róòmù 5:18, 19.
Ìfojúsọ́nà Ológo
13. Èé ṣe tí ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ nípa wíwàláàyè títí láé?
13 Ìpèsè Ọlọ́run yìí mà mú wa láyọ̀ o! Ǹjẹ́ inú ẹ ò dùn láti mọ̀ pé a ti pèsè Olùgbàlà kan? Nínú ìwádìí kan tí ìwé ìròyìn kan ṣe nínú ìlú ńlá pàtàkì kan ní Amẹ́ríkà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé, “Ǹjẹ́ ìrètí wíwà láàyè títí láé wù ẹ́?” Ó yani lẹ́nu pé ìpín tí ó lé ní mẹ́tàdínláàádọ́rin ló dáhùn pé, “Rárá.” Èé ṣe tí wọ́n fi sọ pé àwọn kò fẹ́ wà láàyè títí láé? Lọ́nà tó ṣe kedere, ó jẹ́ nítorí pé ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé kún fún ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ẹnì kan wí pé: “Kò dùn mọ́ mi nínú láti ronú nípa bí màá ṣe rí bí mo bá di ẹni igba ọdún.”
14. Èé ṣe tí wíwà láàyè títí láé fi lè jẹ́ ìgbádùn kẹlẹlẹ?
14 Síbẹ̀, kì í ṣe ayé kan tí àwọn èèyàn á ti máa ṣàìsàn, tí wọ́n á ti darúgbó, tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ mìíràn á ti ṣẹlẹ̀ sí wọn ni Bíbélì ń sọ. Rárá o, nítorí gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ tí Sátánì ń dá sílẹ̀ ni Jésù yóò mú kúrò. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, Ìjọba Ọlọ́run “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo” ìjọba aninilára tó wà nínú ayé yìí. (Dáníẹ́lì 2:44) Ní àkókò yẹn, ní ìdáhùn sí àdúrà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, “ìfẹ́” Ọlọ́run “la óò máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.” (Mátíù 6:9, 10, Today’s English Version) Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, lẹ́yìn tí a bá ti mú ìwà ibi kúrò ní ilẹ̀ ayé, àǹfààní ìràpadà Jésù yóò dé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tó tóótun ni a óò dá ìlera tó jí pépé padà fún!
15, 16. Irú ipò wo ni yóò wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run?
15 Àwọn èèyàn tí wọ́n bá ń gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí yóò nímùúṣẹ sí lára pé: “Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.” (Jóòbù 33:25) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn yóò ní ìmúṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:5, 6.
16 Tilẹ̀ rò ó wò ná: Láìka ọjọ́ orí wa sí nígbà yẹn, yálà a jẹ́ ẹni ọgọ́rin ọdún, tàbí ẹni ẹgbẹ̀rin ọdún, tàbi jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá, yọ̀yọ̀yọ̀ lara wa yóò máa dán. Yóò rí bí Bíbélì ti ṣèlérí pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Nígbà yẹn, a óò tún mú ìlérí yìí ṣẹ pé: [Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3, 4.
17. Kí la lè retí pé kí àwọn èèyàn ṣe nínú ìjọba Ọlọ́run?
17 Nínú ayé tuntun yẹn, yóò ṣeé ṣe fún wa láti lo ọpọlọ wa àgbàyanu lọ́nà tí Ẹlẹ́dàá gbà fẹ́ kí a lò ó nígbà tí ó dá a láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí kò lópin. Họ́wù, fojú inú wo àwọn ohun àgbàyanu tí a lè ṣe yọrí! Ṣe bí inú ilé àkójọ ohun àmúṣọrọ̀ tó wà nínú ilẹ̀ ayé ni àwọn èèyàn aláìpé pàápàá ti mú gbogbo ohun tí a lè fojú rí jáde—fóònù àgbékiri, makirofóònù, aago, ẹ̀rọ àfipeni, kọ̀ǹpútà, bàlúù, bẹ́ẹ̀ ni, mélòó la fẹ́ kà. Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí wọ́n mú jáde láti inú àwọn nǹkan tí wọ́n mú wá láti ọ̀nà jíjìn réré nínú àgbáálá ayé. Pẹ̀lú ìyè àìlópin tó wà níwájú wa, àwọn ohun tí a óò lè fọwọ́ ara wa ṣe nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ kò ní lópin!—Aísáyà 65:21-25.
18. Èé ṣe tí ìwàláàyè kò fi ní súni nínú ayé tuntun?
18 Ìgbésí ayé kò ní súni. Nísinsìnyí pàápàá, ọ̀nà ọ̀fun wa máa ń dá tòótòó fún oúnjẹ mìíràn tí a ó jẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti jẹ oúnjẹ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà. Nínú ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn, a óò gbádùn oúnjẹ dídọ́ṣọ̀ ti Párádísè orí ilẹ̀ ayé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. (Aísáyà 25:6) Títí ayé fáàbàdà ni inú wa yóò máa dùn láti máa bójú tó àwọn ẹranko rẹpẹtẹ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí a óò sì máa gbádùn wíwo wíwọ̀ oòrùn rẹ̀ tó jẹ́ àrímálèlọ, àwọn òkè rẹ̀, odò rẹ̀, àti àfonífojì rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ àwòpadàsẹ́yìn. Lóòótọ́, ìgbésí ayé kò lè súni nínú ayé tuntun Ọlọ́run!—Sáàmù 145:16.
Ṣíṣe Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè
19. Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé àwọn nǹkan kan wà tí a ń béèrè láti lè rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà?
19 O ha lè máa retí pé wàá rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú Párádísè láìjẹ́ pé o sapá rárá? Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n mu pé Ọlọ́run yóò béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ? Ó bọ́gbọ́n mu mọ̀nà. Ní ti gidi, Ọlọ́run kì í kàn án ju ẹ̀bùn náà sí wa ṣáá. Ó máa ń nawọ́ rẹ̀ sí wa, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún un, kí ọwọ́ wa tó lè tẹ̀ ẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń béèrè ìsapá. O lè béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ ara rẹ, èyí tí ọlọ́rọ̀, ọ̀dọ́ olùṣàkóso náà béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?” Tàbí kẹ̀, ó lè béèrè ìbéèrè náà lọ́nà tí onítúbú ará Fílípì náà gbà béèrè lọ́wọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Kí ni kí n ṣe láti rí ìgbàlà?”—Mátíù 19:16; Ìṣe 16:30.
20. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tí a ń béèrè láti lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà?
20 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ lájorí ohun tí a ń béèrè nígbà tó sọ nínú àdúrà sí baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kò ha bọ́gbọ́n mu pé kí a gba ìmọ̀ Jèhófà sínú, ẹni tó mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe, kí a sì ní ìmọ̀ ẹni náà tó kú fún wa, ìyẹn ni Jésù Kristi? Síbẹ̀, ohun tí a ń béèrè ju wíwulẹ̀ gba irú ìmọ̀ yẹn sínú.
21. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ń ṣe ohun tí lílo ìgbàgbọ́ ń béèrè?
21 Bíbélì tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Lẹ́yìn náà ó fi kún un pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè, ṣùgbọ́n ìrunú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòhánù 3:36) O lè fi hàn pé o ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ nípa yíyí ìgbésí ayé rẹ padà àti nípa mímú kí ìgbésí ayé rẹ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. O gbọ́dọ̀ yọwọ́ nínú gbogbo àìdáa tóo ti ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. O gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pétérù pa láṣẹ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.”—Ìṣe 3:19.
22. Kí ni àwọn ohun tí a ó ṣe tí yóò fi hàn pé a ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù?
22 Ǹjẹ́ kí a má ṣe gbàgbé láé pé lílo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nìkan ló lè mú kí a gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 6:40; 14:6) A ń fi hàn pé a ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nípa ‘títẹ̀lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’ (1 Pétérù 2:21) Kí ni ṣíṣe ìyẹn ní nínú? Ó dáa, nínú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run, Jésù kéde pé: “Wò ó! Mo dé . . . láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Hébérù 10:7) Ó ṣe pàtàkì pé kí a fara wé Jésù nípa gbígbà láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti yíya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Lẹ́yìn èyí, o ní láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ yẹn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi; Jésù pẹ̀lú jẹ́ kí a batisí òun. (Lúùkù 3:21, 22) Gbígbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu látòkè délẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Lọ́nà wo? Tóò, ìfẹ́ sún Jésù láti fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. Kò ha yẹ kí ìyẹn sún wa láti mú kí a dáhùn padà nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kó sún wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, èyí tó mú kó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Kristi fi ìwàláàyè rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run; àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣe bákan náà, a kò gbọ́dọ̀ fi ìwàláàyè wa ṣe ohun tó wù wá mọ́.
23. (a) Kí ni a óò fi àwọn tó gba ìyè kún? (b) Kí là ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni?
23 Kò pin síbẹ̀ yẹn o. Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a batisí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn, Bíbélì sọ pé “a sì fi kún wọn.” Àwọn wo ni a fi wọ́n kún? Lúùkù ṣàlàyé pé: “Wọ́n sì ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì àti ṣíṣe àjọpín pẹ̀lú ara wọn.” (Ìṣe 2:41, 42) Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n pàdé pọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti ìfararora, a sì tipa bẹ́ẹ̀ fi wọ́n kún ìjọ Kristẹni, tàbí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di apá kan rẹ̀. Àwọn Kristẹni ìjímìjí máa ń wá sípàdé déédéé fún ìtọ́ni nípa tẹ̀mí. (Hébérù 10:25) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe èyí, wọn yóò sì fẹ́ láti fún ẹ níṣìírí láti máa bá wọn wá sí àwọn ìpàdé wọ̀nyí.
24. Kí ni “ìyè tòótọ́,” báwo ni ọwọ́ wa yóò ṣe tẹ̀ ẹ́, ọ̀nà wo sì ni yóò gbà tẹ̀ ẹ́?
24 Ní báyìí, àrààdọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ló ń rin ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè. Rírìn ní ọ̀nà híhá yìí gba ìsapá gidigidi o! (Mátíù 7:13, 14) Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn nínú ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ ọlọ́yàyà rẹ̀: “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́.” Jíja ìjà yìí ni a nílò tí a bá fẹ́ “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:12, 19) Ìgbésí ayé yẹn kì í ṣe irú ti ìsinsìnyí tó kún fún ìrora, híhàhílo àti ìjìyà tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù mú wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ìgbésí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, èyí tí ọwọ́ wa yóò tẹ̀ láìpẹ́ nígbà tí a bá lo ẹbọ ìràpadà Kristi fún gbogbo àwọn tó nìfẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti mú ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí kúrò. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa yan ìyè—“ìyè tòótọ́”—ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun ológo ti Ọlọ́run.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
◻ Ta ni ejò, ta ni obìnrin náà, ta sì ni irú-ọmọ tí a sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15?
◻ Báwo ni Jésù ṣe bá Ádámù mu, kí sì ni ìràpadà mú kí ó ṣeé ṣe?
◻ Kí ni o lè máa fojú sọ́nà fún, tí yóò mú kí o gbádùn ayé tuntun Ọlọ́run?
◻ Kí ni àwọn ohun tí a ní láti ṣe kí a tó lè wà láàyè nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Fún tèwe tàgbà, Jésù nìkan ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, àwọn arúgbó yóò máa ta kébékébé bí ọ̀dọ́