A Mọyì Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Tí Ọlọ́run Ń Fi Hàn sí Wa
‘Gbogbo wa ti gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.’—JÒH. 1:16.
1, 2. (a) Sọ àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin kan tó ní ọgbà àjàrà. (b) Báwo ni ìtàn yìí ṣe jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọ̀làwọ́ àtẹni tó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn?
ỌKÙNRIN kan tó ní ọgbà àjàrà lọ sí ọjà láti wá àwọn lébìrà tàbí àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ṣiṣẹ́ lóko rẹ̀. Òun àtàwọn ọkùnrin tó rí jọ ṣàdéhùn iye tí wọ́n máa gbà, àwọn òṣìṣẹ́ náà sì lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́, ọkùnrin náà ṣì nílò àwọn òṣìṣẹ́ sí i, torí náà jálẹ̀ ọjọ́ náà ló fi ń pààrà ọjà láti wá àwọn òṣìṣẹ́, ó sì ń bá àwọn tó rí ṣàdéhùn iye tí wọ́n máa gbà, títí kan àwọn tó gbà síṣẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí iṣẹ́ parí, ọkùnrin náà pe àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jọ, ó sì fún wọn ní iye tó bá wọn ṣàdéhùn, ó wá bọ́ sí pé iye kan náà ló fún gbogbo wọn, látorí àwọn tó ti ń fara ṣiṣẹ́ látàárọ̀ àtàwọn tí kò ṣe ju wákàtí kan lọ. Nígbà táwọn tó ti wà lóko látàárọ̀ gbọ́ pé iye kan náà ló fún wọn, ṣe ni wọ́n fárígá. Ọkùnrin náà wá bi wọ́n pé: ‘Ṣebí iye tá a jọ ṣàdéhùn ni mo fún yín, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fún àwọn tó bá mi ṣiṣẹ́ ni iye tó wù mí ni? Kí ló dé tí ẹ̀ ń jowú torí pé mò ń ṣoore fáwọn èèyàn?’—Mát. 20:1-15.
2 Àkàwé tí Jésù ṣe yìí rán wa létí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tí Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.”[1] (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:1.) Ó jọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tí kò ṣe ju wákàtí kan ò lẹ́tọ̀ọ́ àtigba iye kan náà pẹ̀lú àwọn tó kù, àmọ́ ọkùnrin àgbẹ̀ náà pinnu láti ṣe wọ́n lóore. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” táwọn Bíbélì kan pè ní “oore ọ̀fẹ́,” ó sọ pé: “Ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí gan-an ni ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ tá a fún ẹnì kan láìjẹ́ pé ó ṣiṣẹ́ fún un, ohun tí kò tọ́ sí i rárá.”
Ẹ̀BÙN Ọ̀FẸ́ TÍ JÈHÓFÀ FÚN WA
3, 4. Kí nìdí tí Jèhófà fi fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí aráyé? Ọ̀nà wo ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
3 Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Éfé. 3:7) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń fúnni ní “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” yìí, báwo ló sì ṣe ń fúnni? Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí Jèhófà ní ká máa ṣe là ń ṣe lọ́nà tó pé pérépéré, a jẹ́ pé a lẹ́tọ̀ọ́ sí inú rere tó fi hàn sí wa. Àmọ́, kò sí bá a ṣe mọ̀ ọ́n rìn tó tí orí wa kò ní mì. Ìyẹn bá ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Sólómọ́nì Ọba sọ mu, pé: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníw. 7:20) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,” àti pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 3:23; 6:23a) Ó ṣe kedere pé ikú ló tọ́ sọ́mọ aráyé.
4 Àmọ́ Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ aráyé ní ti pé ó ṣe inú rere sí wa lọ́nà tó ga lọ́lá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Ẹ̀bùn tó ga jù lọ tó fún wa ni “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” tó rán wá sáyé pé kó wá kú fún wa. (Jòh. 3:16) Torí náà, Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé Ọlọ́run ‘fi ògo àti ọlá dé e ládé nítorí tí ó kú, kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.’ (Héb. 2:9) Lóòótọ́, “ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23b.
5, 6. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá jẹ́ káwọn nǹkan yìí máa darí wa (a) ẹ̀ṣẹ̀ (b) inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?
5 Báwo làwa èèyàn ṣe kó sínú àjàgà ẹ̀ṣẹ̀ tá a sì ń kú? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Nípa àṣemáṣe ọkùnrin kan [ìyẹn Ádámù] ni ikú ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” lé àtọmọdọ́mọ Ádámù lórí. (Róòmù 5:12, 14, 17) Àmọ́, inú wa dùn pé a lè pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa darí wa. Tá a bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà láá máa darí wa. Lọ́nà wo? “Ní ibi tí ẹ̀ṣẹ̀ bá ti di púpọ̀ gidigidi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí túbọ̀ di púpọ̀ gidigidi sí i. Fún ète wo? Pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú ikú, bákan náà pẹ̀lú kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nípasẹ̀ òdodo pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú nípasẹ̀ Jésù Kristi.”—Róòmù 5:20, 21.
6 Lóòótọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni wá, síbẹ̀ ìyẹn ò ní ká wá máa mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a lè bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀gá lórí yín, níwọ̀n bí ẹ kò ti sí lábẹ́ òfin bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.” (Róòmù 6:14) Torí náà, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí là ń jẹ́ kó máa darí wa. Àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe wá? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . fún wa ní ìtọ́ni láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:11, 12.
ỌLỌ́RUN FI INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ HÀN “NÍ ONÍRÚURÚ Ọ̀NÀ”
7, 8. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn ní “onírúurú ọ̀nà”? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
7 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pét. 4:10) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé kò sí irú àdánwò tó lè dé bá wa láyé yìí tí Jèhófà ò ní ràn wá lọ́wọ́ láti kojú. (1 Pét. 1:6) Irú àdánwò tí ì báà jẹ́, Ọlọ́run máa fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa, àá sì lè fara dà á.
8 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Gbogbo wa ti gbà láti inú ẹ̀kún rẹ̀, àní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.” (Jòh. 1:16) Torí pé onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà fi inú rere hàn, ọ̀pọ̀ ìbùkún làwa èèyàn rẹ̀ ń gbádùn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún náà?
9. Àǹfààní wo là ń rí torí pé Jèhófà ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore?
9 Ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ló ń mú kí Jèhófà dárí jì wá. Àmọ́ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, ká sì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kápá ẹran ara tó máa ń mú wa dẹ́ṣẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 1:8, 9.) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àánú rẹ̀, ká sì máa yìn ín lógo. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn ẹni àmì òróró bíi tiẹ̀, ó sọ pé: ‘[Jèhófà] dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ òkùnkùn, ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọ rẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́, nípasẹ̀ ẹni tí a gba ìtúsílẹ̀ wa nípa ìràpadà, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.’ (Kól. 1:13, 14) Torí pé Jèhófà ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ṣe ni òjò ìbùkún míì ń rọ̀ yàà lé wa lórí.
10. Kí ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ń mú ká gbádùn?
10 Àárín àwa àti Jèhófà gún régé. Inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, torí bẹ́ẹ̀ àtinú oyún ni ẹ̀ṣẹ̀ ti sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀.” (Róòmù 5:10) Ikú Ọmọ rẹ̀ yìí ló mú kí àárín àwa àti Jèhófà pa dà gún régé. Pọ́ọ̀lù so ọ̀rọ̀ náà mọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, ó sọ pé: “Nísinsìnyí tí a ti polongo wa [ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ arákùnrin Kristi] ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí a máa gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi, ẹni tí àwa pẹ̀lú tipasẹ̀ rẹ̀ rí ọ̀nà ìwọlé wa nípa ìgbàgbọ́ sínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí nínú èyí tí àwa dúró nísinsìnyí.” (Róòmù 5:1, 2) Ẹ ò rí i pé ìbùkún yẹn ga!
11. Kí làwọn ẹni àmì òróró ń ṣe kí àwọn “àgùntàn mìíràn” lè di olódodo?
11 A sọ wá di olódodo. Torí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wa sí, a kì í ṣe olódodo. Àmọ́ wòlíì Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé tó bá di àkókó òpin, “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró máa “mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.” (Ka Dáníẹ́lì 12:3.) Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ sì rí torí pé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù táwọn ẹni àmì òróró ń ṣe àti bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ti mú kí Jèhófà máa fojú olódodo wo ẹgbàágbèje àwọn “àgùntàn mìíràn.” (Jòh. 10:16) Àmọ́ o, kì í ṣe mímọ́ ṣe wọn, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ló mú kí èyí ṣeé ṣe. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘A ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ [Ọlọ́run] nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.’—Róòmù 3:23, 24.
12. Báwo ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ṣe kan àdúrà?
12 A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà ní sí wa mú kó fún wa láǹfààní pé ká wá síwájú ìtẹ́ rẹ̀, ká sì gbàdúrà sí i. Kódà, Pọ́ọ̀lù pe ìtẹ́ Jèhófà ní “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” ó sì rọ̀ wá pé ká sún mọ́ ọn “pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.” (Héb. 4:16a) Ọlá Jésù ni Jèhófà fi fún wa láǹfààní yìí. Bíbélì sọ nípa Jésù pé, “nípasẹ̀ ẹni tí àwa ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ yìí àti ọ̀nà ìwọlé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.” (Éfé. 3:12) Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó ga lọ́lá gbáà ni pé a lè gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà!
13. Báwo ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tí ó tọ́”?
13 À ń rí ìrànwọ́ gbà lásìkò. Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé ká tọ Jèhófà lọ, ká sì bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà, “kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” (Héb. 4:16b) Nígbàkigbà tá a bá níṣòro tàbí tá a ní ìdààmú ọkàn, a lè ké pe Jèhófà pé kó ṣàánú wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ojú rere Ọlọ́run, síbẹ̀ ó ń gbọ́ àdúrà wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ará wa, “kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’”—Héb. 13:6.
14. Báwo ni inú rere Jèhófà ṣe ń tù wá nínú?
14 À ń rí ohun tó ń tù wá nínú. Ìbùkún ńlá míì tí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà ń mú wá ni ìtùnú tá a máa ń ní nígbà tọ́kàn wa bá dàrú. (Sm. 51:17) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà nílùú Tẹsalóníkà tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí, ó sọ pé: “Kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in.” (2 Tẹs. 2:16, 17) Ẹ wo bó ṣe tuni lára tó pé a ní Bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń gba tiwa rò torí pé inú rere rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n.
15. Ìrètí wo la ní lọ́lá inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?
15 A nírètí àtiwà láàyè títí láé. Torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, tí wọ́n bá fi dídàá wa, a ò lè ṣe ọ̀nà àbáyọ fúnra wa. (Ka Sáàmù 49:7, 8.) Àmọ́ Jèhófà ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa, ìrètí àgbàyanu sì ni. Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èyí ni ìfẹ́ Baba mi, pé gbogbo ẹni tí ó rí Ọmọ tí ó sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:40) Kò sí àní-àní pé ẹ̀bùn ni ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì jẹ́ ká rí i pé ohun ribiribi ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù mọyì kókó yìí gan-an, ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí ń mú ìgbàlà wá fún gbogbo onírúurú ènìyàn ni a ti fi hàn kedere.”—Títù 2:11.
MÁ ṢE ṢI INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ ỌLỌ́RUN LÒ
16. Báwo làwọn Kristẹni ayé ọjọ́un ṣe ṣi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lò?
16 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń gbádùn torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, síbẹ̀ kò yẹ ká máa ronú pé Ọlọ́run ò ní bínú tá a bá ń hu ìwàkiwà. Àwọn Kristẹni kan wà láyé ọjọ́un tí wọ́n fẹ́ “sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” (Júúdà 4) Àwọn Kristẹni aláìṣòótọ́ yẹn gbà pé àwọn lè máa dẹ́ṣẹ̀ torí pé aláàánú ni Jèhófà, á sì dárí ji àwọn. Ohun tó wá burú ńbẹ̀ ni pé wọ́n ń tan àwọn ará míì sínú ìwà àìnítìjú wọn. Lónìí, ńṣe lẹni tó bá ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lò.—Héb. 10:29.
17. Ìmọ̀ràn tó sojú abẹ níkòó wo ni Pétérù fún wa?
17 Sátánì ti mú káwọn kan lára àwa Kristẹni òde òní máa ronú pé àwọn lè máa dẹ́ṣẹ̀ báwọn ṣe fẹ́ torí pé àánú Ọlọ́run pọ̀. Òótọ́ ni pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà, síbẹ̀ ó retí pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí àwọn ohun tó máa ń mú ká dẹ́ṣẹ̀. Pétérù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí a má bàa mú yín lọ pẹ̀lú wọn nípa ìṣìnà àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.”—2 Pét. 3:17, 18.
OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE TORÍ PÉ A RÍ INÚ RERE ÀÌLẸ́TỌ̀Ọ́SÍ GBÀ
18. Kí ló yẹ ká ṣe torí pé Jèhófà ń fi inú rere hàn sí wa?
18 A mọyì bí Jèhófà ṣe ń fi inú rere hàn sí wa. Torí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa lo ẹ̀bùn tá a ní láti bọlá fún Ọlọ́run ká sì lò ó láti ṣe àwọn míì láǹfààní. Ọ̀nà wo la lè gbà lo ẹ̀bùn wa? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà náà, níwọ̀n bí àwa ti ní àwọn ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún wa, ì báà ṣe . . . iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan, ẹ jẹ́ kí a wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí; tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó wà lẹ́nu kíkọ́ni rẹ̀; tàbí ẹni tí ń gbani níyànjú, kí ó wà lẹ́nu ìgbani-níyànjú rẹ̀; . . . ẹni tí ń fi àánú hàn, kí ó máa fi ọ̀yàyà ṣe é.” (Róòmù 12:6-8) Bí Jèhófà ṣe ń fi inú rere hàn sí wa mú ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kọ́wọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká máa gba àwọn ará wa níyànjú, ká sì máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá.
19. Iṣẹ́ pàtàkì wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
19 A mà dúpẹ́ o pé à ń rọ́wọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára wa lójoojúmọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” (Ìṣe 20:24) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò nípa iṣẹ́ pàtàkì tá a ní yìí àti bá a ṣe lè ṣe é.
^ [1] (ìpínrọ̀ 2) Wo ọ̀rọ̀ náà “Undeserved kindness” nínú àfikún tá a pè ní “Glossary of Bible Terms” nínú Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013.