-
Àjíǹde Dájú!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | December
-
-
15. Àwọn wo ló wà lára “gbogbo” àwọn tí Ọlọ́run ‘máa sọ di ààyè’?
15 Kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 15:22) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní Kọ́ríńtì tí wọ́n máa jíǹde sí ọ̀run ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí. A sọ àwọn Kristẹni yẹn ‘di mímọ́ nínú Kristi Jésù, a sì pè wọ́n láti jẹ́ ẹni mímọ́.’ Ó tún mẹ́nu kan “àwọn tó ti sun oorun ikú nínú Kristi.” (1 Kọ́r. 1:2; 15:18; 2 Kọ́r. 5:17) Nínú lẹ́tà míì tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ, ó sọ pé àwọn tó “wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà kú” máa “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ lọ́nà tó gbà jíǹde.” (Róòmù 6:3-5) Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì lọ sọ́run. Ohun kan náà ni Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo àwọn tó wà “nínú Kristi,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.
-
-
Àjíǹde Dájú!Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020 | December
-
-
17. Ìgbà wo ni àwọn tó wà “nínú Kristi” máa gba èrè wọn ní ọ̀run?
17 Ọlọ́run ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn tó wà “nínú Kristi” sí ọ̀run nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Kọ́ríńtì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ iwájú nìyẹn máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Kálukú wà ní àyè rẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín.” (1 Kọ́r. 15:23; 1 Tẹs. 4:15, 16) Ìgbà wíwà níhìn-ín Kristi la wà báyìí. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ti kú máa ní láti dúró dìgbà wíwà níhìn-ín rẹ̀ kí wọ́n tó lè gba èrè wọn ti ọ̀run kí wọ́n sì “wà níṣọ̀kan pẹ̀lú [Jésù] lọ́nà tó gbà jíǹde.”
-