Ṣọ́ra fún Àwọn Olùkọ́ Èké!
“Àwọn olùkọ́ èké yóò . . . wà pẹ̀lú láàárín yín.”—PÉTÉRÙ KEJÌ 2:1.
1. Kí ni Júúdà ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti kọ̀wé nípa rẹ̀, èé sì ti ṣe tí ó fi yí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà?
Ẹ WO bí èyí ti múni gbọ̀n rìrì tó! Àwọn olùkọ́ èké nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní! (Mátíù 7:15; Ìṣe 20:29, 30) Júúdà, iyèkan Jésù, mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yí. Ó sọ pé òun ti fẹ́ kọ lẹ́tà sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun “nípa ìgbàlà tí gbogbo [wa] jọ dì mú,” ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé pé: “Mo rí i pé ó pọn dandan láti kọ̀wé sí yín láti gbà yín níyànjú láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” Èé ṣe tí Júúdà fi yí kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà? Ó sọ pé, nítorí pé “àwọn ènìyàn kan báyìí ti yọ́ wọlé [sínú ìjọ] . . . tí wọ́n ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.”—Júúdà 3, 4.
2. Èé ṣe tí Pétérù Kejì, orí 2 àti Júúdà fi fara jọra gan-an?
2 Ó ṣe kedere pé, kò pẹ́ tí Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì ni Júúdà kọ tirẹ̀. Kò sí iyè méjì pé Júúdà ti ka lẹ́tà yí dáradára. Dájúdájú, ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó bá ti Pétérù mu nínú lẹ́tà ìyànjú lílágbára tí ó kọ. Nítorí náà, bí a ṣe ń ṣàyẹ̀wò Pétérù Kejì orí 2, a óò rí bí ó ṣe bá lẹ́tà Júúdà mu tó.
Àbájáde Ẹ̀kọ́ Èké
3. Kí ní ti ṣẹlẹ̀ rí tí Pétérù sọ pé yóò tún ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i?
3 Lẹ́yìn tí Pétérù rọ àwọn ará rẹ̀ láti fiyè sí àsọtẹ̀lẹ́, ó sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn wòlíì èké wáá wà pẹ̀lú [ní Ísírẹ́lì ìgbàanì], gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ èké yóò ti wà pẹ̀lú láàárín yín.” (Pétérù Kejì 1:14–2:1) Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìgbàanì rí àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ gbà, ṣùgbọ́n wọ́n tún ní láti bá ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì èké tí ń sọni dìbàjẹ́ wọ̀jà. (Jeremáyà 6:13, 14; 28:1-3, 15) Jeremáyà kọ̀wé pé: “Èmi ti rí ìríra lára àwọn wòlíì Jerúsálẹ́mù, wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì rìn nínú èké.”—Jeremáyà 23:14.
4. Èé ṣe tí ìparun fi tọ́ sí àwọn olùkọ́ èké?
4 Ní ṣíṣàpèjúwe itú tí àwọn olùkọ́ èké yóò pa nínú ìjọ Kristẹni, Pétérù sọ pé: “Àwọn wọ̀nyí gan-an ni yóò yọ́ mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé wá, wọn yóò sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú olúwa [Jésù Kristi] tí ó rà wọ́n pàápàá, wọn yóò mú ìparun yíyára kánkán wá sórí ara wọn.” (Pétérù Kejì 2:1; Júúdà 4) Kirisẹ́ńdọ̀mù, bí a ṣe mọ̀ ọ́n lónìí, ni àbájáde ìkẹyìn ti irú ẹ̀ya ìsìn ti ọ̀rúndún kìíní. Pétérù fi ìdí tí ìparun fi tọ́ sí àwọn olùkọ́ èké hàn: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò tẹ̀ lé àwọn ìṣe ìwà àìníjàánu wọn, ní tìtorí àwọn wọ̀nyí ọ̀nà òtítọ́ yóò sì di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Pétérù Kejì 2:2.
5. Kí ni àwọn olùkọ́ èké jẹ̀bi rẹ̀?
5 Ronú nípa èyí! Nítorí ipa tí àwọn olùkọ́ èké ń ní, ọ̀pọ̀ nínú ìjọ yóò lọ́wọ́ nínú ìwà àìníjàánu. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “ìwà àìníjàánu” túmọ̀ sí ìwàkiwà, àìlèṣàkóso-ara-ẹni, ìwà tí kò bójú mu, ìṣekúṣe, ìwà àìnítìjú. Pétérù sọ níṣàájú pé àwọn Kristẹni ti “yè bọ́ kúrò nínú ìdíbàjẹ́ tí ó wà nínú ayé nípasẹ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” (Pétérù Kejì 1:4) Ṣùgbọ́n àwọn kan yóò pa dà sínú ìwà ìbàjẹ́ yẹn, àwọn olùkọ́ èké nínú ìjọ ni yóò sì ni ẹ̀bi tí ó pọ̀ jù! Nípa báyìí, ọ̀nà òtítọ́ kò ní ní orúkọ rere mọ́. Ẹ wo bí èyí ti bani nínú jẹ́ tó! Dájúdájú, ọ̀ràn kan tí ó yẹ kí gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí fiyè sí dáradára nìyí. Kò yẹ kí a gbàgbé láé pé, nípa ìwà wa, a lè mú ìyìn tàbí ẹ̀gàn wá sórí Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀.—Òwe 27:11; Róòmù 2:24.
Mímú Àwọn Ẹ̀kọ́ Èké Wọlé
6. Kí ní ń sún àwọn olùkọ́ èké, báwo sì ni wọ́n ṣe ń wá ọ̀nà láti jẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́?
6 Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, a óò ṣàkíyèsí bí àwọn olùkọ́ èké ṣe ń mú ìrònú wọn tí ń sọni dìbàjẹ́ wọlé. Pétérù kọ́kọ́ sọ pé wọ́n ń yọ́ ọ ṣe, tàbí wọ́n ń ṣe é lọ́nà tí kò tètè hàn síta, tí a kò lè tètè fura sí. Ó fi kún un pé: “Pẹ̀lú ojúkòkòrò wọn yóò fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà.” Ìfẹ́ ọkàn tí ó kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan ní ń sún àwọn olùkọ́ èké, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe tẹnu mọ́ ọn nínú Bíbélì ìtúmọ̀ The Jerusalem Bible pé: “Wọn yóò hára gàgà láti fi àwọn ọ̀rọ̀ wọn tí ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣeni lọ́ṣẹ́ rà yín.” Bákan náà, ìtúmọ̀ ti James Moffatt sọ níhìn-ín pé: “Nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn, wọn yóò fi ìjiyàn ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ wọn kó yín nífà.” (Pétérù Kejì 2:1, 3) Ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn olùkọ́ èké lè dùn létí ẹnì kan tí kò wà lójúfò nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n wọ́n ń fọgbọ́n gbé àwọn ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ láti “ra” àwọn ènìyàn, ní títàn wọ́n jẹ sínú mímú ète onímọ̀tara-ẹni-nìkan ti àwọn ẹlẹ́tàn náà ṣẹ.
7. Àbá èrò orí wo ni ó gbajúmọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní?
7 Kò sí iyè méjì pé, ẹ̀mí ìrònú ayé ti ó gbòde nígbà náà lọ́hùn-ún nípa lórí àwọn olùkọ́ èké ní ọ̀rúndún kìíní. Ní àkókò tí Pétérù ń kọ̀wé rẹ̀, àbá èrò orí kan tí a ń pè ní Ìmọ̀ Awo ti ń gbajúmọ̀. Àwọn onímọ̀ awo gbà gbọ́ pé gbogbo ohun tí a lè fojú rí jẹ́ ohun búburú, pé kìkì ohun tí a kò lè fojú rí nìkan ni ohun rere. Nípa báyìí, àwọn kan lára wọ́n sọ pé ohun tí ènìyàn kan fi ara rẹ̀ ṣe kò ṣe pàtàkì. Nígbà tí ó yá, wọ́n jiyàn pé, ènìyàn kò ní ní ara yìí mọ́. Nítorí náà, wọ́n parí èrò pé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara—títí kan ìbálòpọ̀—kò ṣe pàtàkì. Ó ṣe kedere pé, irú àwọn ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni.
8, 9. (a) Èrò òdì wo ni ó nípa lórí àwọn Kristẹni ìjímìjí kan? (b) Gẹ́gẹ́ bí Júúdà ti sọ, kí ni àwọn kan nínú ìjọ ń ṣe?
8 Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bíbélì sọ pé “àwọn kàn wà nínú Ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n lọ́ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ oore ọ̀fẹ́,” tàbí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí po.” (Éfésù 1:5-7) Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ìjiyàn àwọn kan lọ báyìí pé: “Ẹ ha sọ pé [inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí] Ọlọ́run pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ bí? . . . Ẹ jẹ́ kí a máa dẹ́sẹ̀ lọ nígbà náà, nítorí pé [inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí] Ọlọ́run lè pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ní tòótọ́, bí a bá ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ náà ni [inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí] Ọlọ́run yóò ṣe láǹfààní láti ṣiṣẹ́ tó.” Ìwọ ha ti gbọ́ ìrònú òdì tí ó burú tó èyí bí?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ta ko èrò òdì nípa àánú Ọlọ́run nígbà tí ó béèrè pé: “Àwa yóò ha máa bá a lọ nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lè di púpọ̀ gidigidi bí?” Ó tún béèrè pé: “Àwa yóò ha dá ẹ̀ṣẹ̀ kan nítorí a kò sí lábẹ́ òfin bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?” Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan ní ṣàkó pé: “Kí èyíinì má ṣe ṣẹlẹ̀ láé!” (Róòmù 6:1, 2, 15) Ó ṣe kedere pé, gẹ́gẹ́ bí Júúdà ti sọ, àwọn kan “ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.” Ṣùgbọ́n, Pétérù sọ pé ‘ìparun kò tòògbé’ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀.—Júúdà 4; Pétérù Kejì 2:3.
Àwọn Àpẹẹrẹ Ìkìlọ̀
10, 11. Àwọn àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ mẹ́ta wo ni Pétérù fúnni?
10 Láti tẹnu mọ́ ọn pé Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ lòdì sí àwọn tí ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà àìtọ́, Pétérù pèsè àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ mẹ́ta láti inú Ìwé Mímọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyà jẹ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ṣẹ̀.” Àwọn wọ̀nyí ni Júúdà sọ pé wọn “kò . . . dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu tì” ní ọ̀run. Wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n sì gbé ẹran ara wọ̀ láti baà lè ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn. Láti jẹ wọ́n níyà fún ìwà tí kò bójú mu, tí kò sì bá ìwà ẹ̀dá mu tí wọ́n hù, a jù wọ́n sínú “Tátárọ́sì,” tàbí gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Júúdà ti sọ, a fi wọ́n “pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.”—Pétérù Kejì 2:4; Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:1-3.
11 Lẹ́yìn èyí, Pétérù tọ́ka sí àwọn ènìyàn ọjọ́ Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 7:17-24) Ó sọ pé ní ọjọ́ Nóà, Ọlọ́run “kò . . . fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyà jẹ ayé ìgbàanì, . . . nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Níkẹyìn, Pétérù kọ̀wé pé Ọlọ́run “fi àpẹẹrẹ àwòṣe kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀” nípa “sísọ àwọn ìlú ńlá Sódómù àti Gòmórà di eérú.” Júúdà fúnni ní àfikún ìsọfúnni pé àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn “ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá.” (Pétérù Kejì 2:5, 6; Júúdà 7) Kì í ṣe pé àwọn ọkùnrin ní ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu pẹ̀lú àwọn obìnrin nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún ń ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ẹran ara àwọn ọkùnrin mìíràn, wọ́n tilẹ̀ lè ti ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ẹran ara àwọn ẹranko ẹhànnà pàápàá.—Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5; Léfítíkù 18:22-25.
12. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ, báwo ni a ṣe ń san èrè fún ìwà òdodo?
12 Síbẹ̀, ní àkókò kan náà, Pétérù sọ pé Jèhófà jẹ́ olùsẹ̀san fún àwọn tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ sìn ín tòótọ́tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe “pa Nóà, oníwàásù òdodo, mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn” nígbà tí Ó mú Àkúnya wá. Ó tún sọ nípa bí Jèhófà ṣe dá “Lọ́ọ̀tì olódodo” nídè nígbà ti Sódómù, ó dórí èrò náà pé: “Jèhófà mọ bí a ti í dá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfọkànsin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.”—Pétérù Kejì 2:5, 7-9.
Àwọn Ìwà Tí Ó Yẹ fún Ìjìyà
13. Àwọn wo ní pàtàkì ni a ti fi pa mọ́ dé ọjọ́ ìdájọ́, àwọn àlá wo sì ni ó ṣe kedere pé wọ́n fi ń kẹ́ra wọn bà jẹ́?
13 Pétérù tọ́ka sí àwọn tí a fi pa mọ́ ní pàtàkì fún ìdájọ́ Ọlọ́run, ìyẹn ni, “àwọn wọnnì tí ń tọ ẹran ara lẹ́yìn pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin tí wọ́n sì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò olúwa.” A fẹ́rẹ̀ẹ́ lè nímọ̀lára ìbínú Pétérù nígbà tí ó sọ pé: “Wọ́n jẹ́ aṣàyàgbàǹgbà, aṣetinú-ẹni, wọn kì í wárìrì níwájú àwọn ẹni ògo ṣùgbọ́n wọn a máa sọ̀rọ̀ tèébútèébú.” Júúdà kọ̀wé pé “àwọn ènìyàn wọ̀nyí . . . ní fífi àwọn àlá kẹ́ra bàjẹ́, ń sọ ẹran ara di ẹlẹ́gbin . . . wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú.” (Pétérù Kejì 2:10; Júúdà 8) Àwọn àlá wọn lè ní fífọkànyàwòrán híhùwà ìbálòpọ̀ oníwà àìmọ́ nínú, tí ń mú wọn túbọ̀ lépa títẹ́ ìwà àìmọ́ ti ìbálòpọ̀ lọ́rùn. Ṣùgbọ́n, lọ́nà wo ni wọ́n fi ń “fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò olúwa,” tí wọ́n sì fi ń sọ̀rọ̀ “àwọn ẹni ògo tèébútèébú”?
14. Lọ́nà wo ni àwọn olùkọ́ èké fi “ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò olúwa,” tí wọ́n sì fi ń sọ̀rọ̀ “àwọn ẹni ògo tèébútèébú”?
14 Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti pé wọ́n ń gan ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Àwọn Kristẹni alàgbà ń ṣojú fún Jèhófà Ọlọ́run ológo àti Ọmọkùnrin rẹ̀, látàrí èyí, wọ́n ní ògo kan tí a fi dá wọn lọ́lá. Lóòótọ́, wọ́n ń ṣàṣìṣe, gẹ́gẹ́ bí Pétérù fúnra rẹ̀ ti ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ rọ àwọn mẹ́ńbà ìjọ láti wà ní ìtẹríba sí àwọn ẹni ògo wọ̀nyẹn. (Hébérù 13:17) Àwọn ìkù-díẹ̀-káàtó wọn kì í ṣe nǹkan tí a lè máa tìtorí rẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tèébútèébú. Pétérù sọ pé àwọn áńgẹ́lì kì í “mú ẹ̀sùn wá lòdì sí [àwọn olùkọ́ èké] ní àwọn èdè ìsọ̀rọ̀ èébú,” bí ó tilẹ̀ tọ́ sí wọn gidigidi. Pétérù ń bá a nìṣó pé: “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹran tí kì í ronú tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá fún mímú àti píparun, nínú àwọn ohun tí wọ́n ti jẹ́ aláìmọ̀kan tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú, yóò tilẹ̀ jìyà ìparun.”—Pétérù Kejì 2:10-13.
“Bí Wọ́n Ti Ń Jẹ Àsè . . . Pẹ̀lú Yín”
15. Ọgbọ́n wo ni àwọn olùkọ́ èké ń dá, ibo sì ni wọ́n ti ń lépa ẹ̀tàn wọn?
15 Bí àwọn oníwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí tilẹ̀ “ka ìgbésí ayé fàájì ní ìgbà ọ̀sán sí adùn,” tí wọ́n sì “jẹ́ èérí àti àbààwọ́n,” wọ́n tún jẹ́ alárèékérekè. Wọ́n máa ń “yọ́” hùwà, ní lílo “àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀,” gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ ṣáájú. (Pétérù Kejì 2:1, 3, 13) Nípa báyìí, wọ́n lè má pe ìgbìdánwò àwọn alàgbà láti gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù Ọlọ́run lárugẹ nìjá ní tààràtà, wọ́n sì lè má lépa ìtẹ́lọ́rùn ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tiwọn fúnra wọn ní gbangba. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pétérù sọ pé wọ́n ń kẹ́ra bà jẹ́ “pẹ̀lú inú dídùn aláìníjàánu nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ wọn bí wọ́n ti ń jẹ àsè pa pọ̀ pẹ̀lú yín.” Júúdà sì kọ̀wé pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn àpáta tí wọ́n fara sin lábẹ́ omi nínú àwọn àsè ìfẹ́ yín.” (Júúdà 12) Bẹ́ẹ̀ ni, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn àpáta gbágungbàgun ìsàlẹ̀ odò ti lè fa abẹ́ ọkọ̀ ojú omi ya, tí ó sì lè mú kí àwọn atukọ̀ tí kò wà lójúfò rì, àwọn olùkọ́ èké ń ba àwọn tí kò wà lójúfò jẹ́, àwọn tí wọ́n fi ìfẹ́ àgàbàgebè hàn sí nígbà “àwọn àsè ìfẹ́.”
16. (a) Kí ni “àwọn àsè ìfẹ́,” ní àwọn ibi jíjọra wo ni àwọn oníwà pálapàla lè gbà ṣọṣẹ́ lónìí? (b) Àwọn wo ni àwọn olùkọ́ èkè máa ń darí ọkàn wọn sí, nítorí náà, kí ni ó yẹ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe?
16 Ó ṣe kedere pé “àwọn àsè ìfẹ́” wọ̀nyí jẹ́ ayẹyẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà nígbà tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní bá kóra jọ láti gbádùn oúnjẹ àti ìfararora. Bákan náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí máa ń kóra jọ ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, bóyá níbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu ìgbéyàwò, nígbà ìjáde fàájì, tàbí nígbà ìfararora ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Báwo ni àwọn oníwà ìbàjẹ́ ṣe lè lo irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti tanni jẹ? Pétérù kọ̀wé pé: “Wọ́n ní àwọn ojú tí ó kún fún panṣágà . . . , wọ́n sì ń ré àwọn ọkàn tí kò dúró sójú kan lọ.” Wọ́n darí “ọkàn àyà” wọn “tí a fi ojúkòkòrò kọ́” sí àwọn tí kò dúró sójú kan nípa tẹ̀mí tí wọ́n ti kùnà láti sọ òtítọ́ di tiwọn pátápátá. Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Pétérù jẹ́ ìkìlọ̀ fún ọ, kí o sì wà lójúfò! Gbéjà ko ìrọni èyíkéyìí láti hùwà àìmọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ẹwà tàbí ìrísí fífanimọ́ra tí ẹnì kan tí ń fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́ ní tàn ọ́ jẹ!—Pétérù Kejì 2:14.
“Ipa Ọ̀nà Báláámù”
17. Kí ni “ipa ọ̀nà Báláámù,” báwo sì ni ó ṣe nípa lórí 24,000 àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
17 Ó ti ṣe díẹ̀ tí àwọn “ọmọ ègún” wọ̀nyí ti mọ òtítọ́. Wọ́n ṣì lè fara hàn bí ẹni tí ó gbó ṣáṣá nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n Pétérù sọ pé: “Ní pípa ipa ọ̀nà títọ́ tì, a ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ti tẹ̀lé ipa ọ̀nà Báláámù, ọmọkùnrin Béórì, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ èrè ẹ̀san ìwà àìtọ́.” (Pétérù Kejì 2:14, 15) Ipa ọ̀nà tí wòlíì Báláámù tọ̀ jẹ́ láti gbani nímọ̀ràn lórí bí a ṣe lè tanni sínú ìwà pálapàla nítorí èrè ti ara rẹ̀. Ó sọ fún Bálákì Ọba Móábù pé Ọlọ́run yóò fi Ísírẹ́lì bú bí a bá lè fa ọkàn àwọn ènìyàn náà mọ́ra láti ṣe panṣágà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn obìnrin Móábù sún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀, 24,000 sì kú nítorí ìwà pálapàla wọn.—Númérì 25:1-9; 31:15, 16; Ìṣípayá 2:14.
18. Báwo ni Báláámù ṣe tẹpẹlẹ mọ́ ọ̀ràn náà tó, kí sì ni àbájáde rẹ̀ ń tọ́ka sí fún àwọn olùkọ́ èké?
18 Pétérù sọ pé a ṣèdíwọ́ fún Báláámù nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀, síbẹ̀ Báláámù “nífẹ̀ẹ́ èrè ẹ̀san ìwà àìtọ́” tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí ìyẹn ṣẹlẹ̀ pàápàá, kò dẹ́kun títọ “ipa ọ̀nà wèrè” rẹ̀. (Pétérù Kejì 2:15, 16) Èyí mà burú jáì o! Ègbé ni fún ẹnikẹ́ni tí ó bá dà bíi Báláámù, tí ń gbìyànjú láti ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jẹ́ ní dídán wọn wò láti hùwà pálapàla! Báláámù kú nítorí ìwà burúkú rẹ̀, àpẹẹrẹ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n bá tẹ̀ lé ipa ọ̀nà rẹ̀.—Númérì 31:8.
Àwọn Ọ̀nà Ẹ̀tàn Elèṣù Wọn
19, 20. (a) Kí ni a fi àwọn tí ó dà bíi Báláámù wé, èé sì ti ṣe? (b) Àwọn wo ni wọ́n ń ré lọ, lọ́nà wo sì ni? (d) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn ọ̀nà ẹ̀tàn wọn jẹ́ ti elèṣù, báwo sì ni a ṣe lè dáàbò bo ara wa àti àwọn ẹlòmíràn kúrò lọ́wọ́ wọn?
19 Ní ṣíṣàpèjúwe àwọn ẹni bíi Báláámù, Pétérù kọ̀wé pé: “Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ojúsun [tàbí, kànga] tí kò ní omi, àti ìkùukùu [tàbí, awọ sánmà] tí ìjì líle nípá ń gbá kiri.” Fún ẹnì kan tí ń rìnrìn àjò nínú aṣálẹ̀, tí òǹgbẹ sì ń gbẹ, kànga tí kò ní omi lè túmọ̀ sí ikú. Abájọ tí “a . . . fi ìdúdú òkùnkùn pa mọ́ de” àwọn tí wọn jọ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀! Pétérù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Wọn a máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà kàǹkà tí kò ní èrè, àti nípa àwọn ìfẹ́ ọkàn ẹran ara àti nípa àwọn àṣà ìhùwà tí kò níjàánu wọ́n ń ré àwọn wọnnì lọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yè bọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń mú ara wọn hùwà nínú ìṣìnà.” Pétérù sọ pé, wọ́n ń tan àwọn tí kò nírìírí jẹ nípa ‘ṣíṣèlérí òmìnira fún wọn,’ nígbà tí “àwọn fúnra wọ́n wà gẹ́gẹ́ bí ẹrú ìdíbàjẹ́.”—Pétérù Kejì 2:17-19; Gálátíà 5:13.
20 Àwọn ọ̀nà ẹ̀tàn àwọn olùkọ́ oníwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti elèṣù. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé: ‘Ọlọ́run mọ̀ pé aláìlera ni wá, pé a sì lè tètè ní ìfẹ́ onígbòónára. Nítorí náà bí a bá kẹ́ra wa bà jẹ́, tí a sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn, Ọlọ́run yóò ṣojú àánú sí wa. Bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun yóò dárí jì wá gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nígbà tí a kọ́kọ́ wá sínú òtítọ́.’ Rántí pé Èṣù lo irú ohun tí ó fara jọ èyí fún Éfà, ní ṣíṣèlérí fún un pé ó lè dẹ́ṣẹ̀ láìjìyà rárá. Nínú ọ̀ràn Éfà, ó sọ pé dídẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run yóò mú kí ó lóye, kí ó sì lómìnira. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a bá irú oníwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ pàdé, tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, ojúṣe wa ni láti dáàbò bo ara wa àti àwọn ẹlòmíràn nípa fífi ẹjọ́ ẹni náà sun àwọn tí a fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ Kristẹni.—Léfítíkù 5:1.
Ìmọ̀ Pípéye Dáàbò Bò Wọ́n
21-23. (a) Kí ni àbájáde kíkùnà láti lo ìmọ̀ pípéye? (b) Ìṣòro mìíràn wo ni Pétérù jíròrò tí a óò gbé yẹ̀ wò tẹ̀ lé e?
21 Pétérù mú apá yìí nínú lẹ́tà rẹ̀ wá sí ìparí nípa ṣíṣàpèjúwe àbájáde kíkùnà láti lo ìmọ̀ tí ó sọ níṣàájú pé ó ṣe kókó fún “ìyè àti ìfọkànsin Ọlọ́run.” (Pétérù Kejì 1:2, 3, 8) Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ó bá jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n ti yè bọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀gbin ayé nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà, wọ́n tún kó wọnú àwọn nǹkan wọ̀nyí gan-an tí a sì ṣẹ́pá wọn, àwọn ipò ìgbẹ̀yìn ti burú fún wọn ju ti àkọ́kọ́.” (Pétérù Kejì 2:20) Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ohun bíbáni nínú jẹ́ tó! Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ Pétérù ti tìtorí ìtẹ́lọ́rùn ìbálòpọ̀ àkókò ráńpẹ́ gbé ìrètí ṣíṣeyebíye nípa ìyè àìleèkú ní ọ̀run jù nù.
22 Nítorí náà, Pétérù sọ pé: “Ì bá ti sàn fún wọn kí wọ́n má ti mọ ipa ọ̀nà òdodo lọ́nà pípéye ju pé lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n lọ́nà pípéye kí wọn yí pa dà kúrò nínú àṣẹ mímọ́ tí a fi lé wọn lọ́wọ́. Àsọjáde òwe tòótọ́ náà ti ṣẹlẹ̀ sí wọn: ‘Ajá ti pa dà sínú èébì ara rẹ̀, àti abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ sínú yíyígbiri nínú ẹrẹ̀.’”—Pétérù Kejì 2:21, 22; Òwe 26:11.
23 Ó hàn gbangba pé ìṣòro mìíràn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fara jọ èyí tí ń nípa lórí àwọn kan lónìí. Nígbà náà lọ́hùn-ún, ó hàn gbangba pé àwọn kan ń ṣàròyé nípa wíwàníhìn-ín Kristi tí a ti ṣèlérí tí ó dà bíi pé kò ní dé mọ́. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò bí Pétérù ṣe bójú tó ọ̀ràn yí.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ mẹ́ta wo ni Pétérù tọ́ka sí?
◻ Báwo ni àwọn olùkọ́ èké ṣe “ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ipò olúwa”?
◻ Kí ni ipa ọ̀nà Báláámù, báwo sì ni àwọn tí ń tọ̀ ọ́ ṣe lè gbìyànjú láti sún àwọn ẹlòmíràn dẹ́ṣẹ̀?
◻ Kí ni àbájáde kíkùnà láti lo ìmọ̀ pípéye?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Báláámù jẹ́ àpẹẹrẹ ìkìlọ̀