Ẹ Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí Kẹ́ ẹ Lè Jogún Ìyè Àti Àlàáfíà
“Rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.”—RÓÒMÙ 8:4.
1, 2. (a) Ewu wo ló wà nínú kéèyàn má pọkàn pọ̀ bó bá ń wakọ̀? (b) Ewu wo ló wà nínú kéèyàn fàyè gba ìpínyà ọkàn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?
ALÁBÒÓJÚTÓ ètò ọkọ̀ ìrìnnà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó túbọ̀ ń wọ́pọ̀ sí i pé káwọn èèyàn máa wakọ̀ láì pọkàn pọ̀, ó sì dà bíi pé ńṣe ló ń burú sí i lọ́dọọdún.” Fóònù alágbèéká wà lára ohun tó máa ń mú kí ọkàn àwọn awakọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin pínyà kúrò nínú ohun tó yẹ kí wọ́n gbájú mọ́, ìyẹn ni wíwakọ̀. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé awakọ̀ tó ń lo fóònù lọ́wọ́ ti fi ọkọ̀ gbá àwọn rí tàbí kó fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ọkọ̀ gbá àwọn. Ó lè dà bí ohun tó rọrùn pé kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan míì nígbà tó ń wakọ̀, àmọ́ ibi tó máa ń yọrí sí kì í dáa.
2 Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ nínú àjọse wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bó ṣe jẹ́ pé bí ọkàn awakọ̀ kan bá pínyà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kò ní kíyè sí àwọn àmì tó fi hàn pé ewu ń bẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó fàyè gba ìpínyà ọkàn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ṣe lè tètè kó sínú ìṣòro. Bá a bá fàyè gba ohun táá máa mú ká ṣe ségesège nínú ìjọsìn wa àtàwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ìyẹn lè mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wá rì. (1 Tím. 1:18, 19) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù nípa ewu yìí nígbà tó sọ fún wọn pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú, ṣùgbọ́n gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.” (Róòmù 8:6) Kí ni ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn túmọ̀ sí? Kí la lè ṣe ká má bàa máa ‘gbé èrò inú wa ka ẹran ara’ ká sì lè máa ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí’?
Wọn “Kò Ní Ìdálẹ́bi Kankan”
3, 4. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí ẹran ara rẹ̀ ṣe ń bá èrò inú rẹ̀ jagun? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká fún ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù láfiyèsí?
3 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ fún wọn nípa bí ẹran ara òun ṣe ń bá èrò inú òun jagun. (Ka Róòmù 7:21-23.) Pọ́ọ̀lù kò sọ ọ̀rọ̀ yìí kó lè dára ẹ̀ láre tàbí káwọn èèyàn lè bá a kẹ́dùn torí pé ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ ọ́ lọ́rùn débi pé kò mọ ohun tó lè ṣe mọ́. Ó ṣe tán, Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí àti ẹni àmì òróró tí Jésù yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” ló jẹ́. (Róòmù 1:1; 11:13) Kí ló wá fà á tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà sáwọn ará Róòmù nípa bí ẹran ara rẹ̀ ṣe ń bá èrò inú rẹ̀ jagun?
4 Ohun tó dá Pọ́ọ̀lù lójú nípa ara rẹ̀ ló ń sọ. Ó gbà pé òun kò lè dá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ débi tó wu òun láti ṣe é dé. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Torí pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù, kò bọ́ lọ́wọ́ àkóbá tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń ṣe fún ẹran ara aláìpé. Ohun tó ń sọ ò sì ṣàjèjì sí wa torí pé gbogbo wa la jẹ́ aláìpé, ojoojúmọ́ sì ni ẹran ara wa ń bá èrò inú wa jagun bíi tirẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó lè pín ọkàn wa níyà, tó lè darí àfiyèsí wa síbòmíràn, tó sì lè mú ká kúrò lójú ‘ọ̀nà tóóró tó lọ sínú ìyè.’ (Mát. 7:14) Àmọ́, ọ̀nà àbáyọ wà fún Pọ́ọ̀lù, ó sì wà fún àwa náà.
5. Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtura?
5 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ta ni yóò gbà mí . . . ? Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:24, 25) Lẹ́yìn náà, ó sọ̀rọ̀ nípa “àwọn tí wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,” ìyẹn àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn. (Ka Róòmù 8:1, 2.) Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, Jèhófà gbà wọ́n ṣọmọ, ó sì sọ wọ́n di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 8:14-17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, ẹran ara tiwọn náà bá èrò inú wọn jagun, ẹ̀mí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi mú kí wọ́n ṣẹ́gun, nípa bẹ́ẹ̀ wọn “kò ní ìdálẹ́bi kankan.” A ti dá wọn sílẹ̀ “kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.”
6. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fiyè sí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù?
6 Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn ni Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, síbẹ̀ ohun tó sọ nípa ẹ̀mí Ọlọ́run àti ẹbọ ìràpadà Kristi lè ṣe gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà láǹfààní yálà wọ́n ní ìrètí láti lọ sọ́run tàbí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn yẹn ni ìmọ̀ràn tí Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ wà fún, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóye ohun tó sọ kí wọ́n sì sapá láti jàǹfààní nínú rẹ̀.
Bí Ọlọ́run Ṣe “Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Lẹ́bi Nínú Ẹran Ara”
7, 8. (a) Ọ̀nà wo ni Òfin gbà “jẹ́ aláìlera nípasẹ̀ ẹran ara”? (b) Kí ni Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ àti ẹbọ ìràpadà?
7 Nínú orí keje ìwé Róòmù, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa agbára tí ẹ̀ṣẹ̀ ní lórí ẹran ara aláìpé. Nínú orí kẹjọ, ó ṣàlàyé nípa agbára tí ẹ̀mí mímọ́ ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ bí wọ́n ti ń bá agbára ẹ̀ṣẹ̀ jagun kí wọ́n lè máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run àti ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Ọlọ́run ti ṣe ohun kan tí Òfin Mósè kò lè ṣe.
8 Òfin dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi torí pé kò ṣeé ṣe fún wọn láti pa gbogbo ohun tó sọ mọ́. Síwájú sí i, aláìpé ni àwọn àlùfáà àgbà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin, wọn kò sì lè rú ẹbọ tó péye fún ẹ̀ṣẹ̀. Torí náà, Òfin “jẹ́ aláìlera nípasẹ̀ ẹran ara.” Nígbà tí Ọlọ́run ‘rán Ọmọ tirẹ̀ ní ìrí ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀’ tó sì yọ̀ǹda pé kó kú ikú ìrúbọ, Ó “dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ẹran ara,” ó sì tipa bẹ́ẹ̀ borí ‘àìgbéṣẹ́ tó wà níhà ti Òfin.’ Látàrí èyí, Ọlọ́run ka àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn sí olódodo nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. A rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa “rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.” (Ka Róòmù 8:3, 4.) Wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ láìyẹsẹ̀ títí tí wọ́n máa fi parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè gba “adé ìyè.”—Ìṣí. 2:10.
9. Kí ni ìtumọ̀ “òfin” tí ìwé Róòmù 8:2 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
9 Ní àfikún sí “òfin,” Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan “òfin ẹ̀mí yẹn” àti “òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.” (Róòmù 8:2) Kí ni àwọn òfin yìí túmọ̀ sí? “Òfin” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí kì í ṣe àwọn àṣẹ ṣe-tibí-má-ṣe-tọ̀hún, irú èyí tó wà nínú Òfin Mósè. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí òfin níbí yìí dúró fún ohun tó ń súnni láti hùwà rere tàbí búburú, bí ìgbà tí òfin ń darí ẹni. Ó tún lè túmọ̀ sí ìlànà tẹ́nì kan gbà kó máa darí òun.”
10. Kí ló fi hàn pé a kò bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú nínú gbogbo wa torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá. Ìgbà gbogbo ni ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ tá a gbé wọ̀ máa ń sún wa láti ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kò fẹ́, ikú ló sì máa ń yọrí sí. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Gálátíà, ó pe àwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fẹ́ ká ṣe yìí ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gál. 5:19-21) Ìwé Róòmù tún sọ pé àwọn tó ń fi irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣèwà hù ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara. (Róòmù 8:4) Ohun ‘tó ń sún wọn láti hùwà’ àti ‘ìlànà tí wọ́n gbà kó máa darí àwọn’ jẹ́ ti ẹran ara látòkèdélẹ̀. Àmọ́, ṣé àwọn tó ń ṣe panṣágà, tí wọ́n ń bọ̀rìṣà, tí wọ́n ń bẹ́mìí lò tàbí tí wọ́n ń dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míì tó burú jáì nìkan ni wọ́n ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara? Rárá o, torí pé ohun táwọn míì lè kà sí àléébù pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ náà wà lára àwọn iṣẹ́ ti ara, irú bí owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀ àti ìlara. Tá lo lè fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí ohun tó lè mú kóun rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara?
11, 12. Kí ni Jèhófà ti ṣe fún wa ká lè bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run lè fojú rere hàn sí wa?
11 Inú wá mà dùn gan-an o pé Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti borí òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú! Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Bá a bá mọyì ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa tá a sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, a lè bọ́ lọ́wọ́ ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. (Jòh. 3:16-18) Torí náà, àwa pẹ̀lú lè fẹ́ láti sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!”
12 Ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bí ìgbà tá à ń ṣàìsàn gan-an tí dókítà sì ń tọ́jú wa. Kí àìsàn náà lè lọ kúrò lára wa, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí dókítà bá sọ pé ká ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà, ó lè mú ká bọ́ lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, síbẹ̀ aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ níní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà àti bá a ṣe lè máa gbádùn ojú rere Ọlọ́run àti ìbùkún rẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe “ohun òdodo tí Òfin béèrè,” ó tún mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.
Báwo La Ṣe Lè Máa Rìn Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ẹ̀mí?
13. Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí?
13 Tá a bá ń rìn ńṣe la máa ń gbé ẹsẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé títí tá a fi máa débi tá à ń lọ tàbí tọ́wọ́ wa fi máa tẹ ohun tá a fẹ́. Torí náà, ká lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ká lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a kò lè ṣe àṣìṣe. (1 Tím. 4:15) Lójoojúmọ́, a gbọ́dọ̀ máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa rìn tàbí ká lè máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí wa sí. A máa rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run tá a bá ń “rìn nípa ẹ̀mí.”—Gál. 5:16.
14. Kí làwọn tó ń gbé “ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara” máa ń fẹ́ láti ṣe?
14 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù ó tún sọ̀rọ̀ nípa oríṣi àwọn èèyàn méjì tí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú yàtọ̀ síra. (Ka Róòmù 8:5.) Kì í wulẹ̀ ṣe ara ìyára wa ni ẹran ara tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbí yìí o. Nínú Bíbélì, ìgbà míì wà tí ọ̀rọ̀ náà “ẹran ara” máa ń dúró fún jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé. Èyí ló máa ń fà á tí ẹran ara àti èrò inú fi máa ń bára wọn jagun, bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ò rí bíi tàwọn tó “wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara” tí ẹran ara wọn kì í bá èrò inú wọn jagun rárá. Dípò kí wọ́n máa ronú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe kí wọ́n sì jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ tó ń pèsè, ńṣe ni wọ́n máa ń “gbé èrò inú wọn ka àwọn ohun ti ẹran ara.” Bí wọ́n ṣe máa tẹ́ ara wọn lọ́rùn tí wọ́n á sì jẹ̀gbádùn bí wọ́n ṣe fẹ́ ló sábà máa ń gbà wọ́n lọ́kàn. Ọ̀nà tí àwọn tí wọ́n wà “ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí” ń gbà ronú yàtọ̀ síyẹn. Ńṣe ni wọ́n máa ń gbé èrò inú wọn ka “àwọn ohun ti ẹ̀mí,” ìyẹn ni àwọn ohun tó lè mú kí wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
15, 16. (a) Báwo ni ohun tá a gbé ọkàn wa kà ṣe ń nípa lórí ohun tá a ń ṣe? (b) Kí la lè sọ nípa ohun tó ń gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn lóde òní?
15 Ka Róòmù 8:6. Kéèyàn tó lè ṣe ohunkóhun, yálà ohun tó dára tàbí ohun tó burú, ó ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbé ọkàn rẹ̀ ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kì í pẹ́ tí àwọn tó máa ń gbé ọkàn wọn ka àwọn nǹkan tara ní gbogbo ìgbà fi máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tàbí ṣe àwọn nǹkan tó dá lórí àwọn nǹkan ti ẹran ara nìkan. Ohun tí ìrònú wọn, ohun tí wọ́n fẹ́ àtàwọn ohun tí wọ́n yàn láàyò sì sábà máa ń dá lé lórí nìyẹn.
16 Kí ló máa ń gba àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ lọ́kàn lóde òní? Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” (1 Jòh. 2:16) Lára àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni àwọn nǹkan bí ìṣekúṣe, òkìkí àti ohun ìní. Ìsọfúnni nípa irú àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí sì kún inú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ohun tó sì fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ìyẹn ni ohun tí àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ń gbé ọkàn wọn kà, kódà ìyẹn gan-an ni ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ ṣá o, “gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú” torí pé ní báyìí ó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ kó sì yọrí sí ikú fún wa lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí? “Nítorí pé gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí kò sí lábẹ́ òfin Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti gidi, kò lè rí bẹ́ẹ̀. Torí náà, àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara kò lè wu Ọlọ́run.”—Róòmù 8:7, 8.
17, 18. Báwo la ṣe lè máa gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí, kí ló sì máa yọrí sí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?
17 Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, “gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà,” ìyẹn ni ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú pẹ̀lú àlàáfíà àtọkànwá àti àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run nísinsìnyí. Báwo la ṣe lè máa ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí’? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tẹ̀mí gbà wá lọ́kàn nígbà gbogbo tá a sì ń jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń ronú àti ìwà tá à ń hù bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ mu. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò mú kí èrò inú wa wà “lábẹ́ òfin Ọlọ́run” àti “ní ìbámu pẹ̀lú” èrò rẹ̀. Tá a bá dojú kọ ìdẹwò, a kò ní máa ṣiyè méjì nípa ohun tó yẹ ká ṣe. Ó máa wù wá láti ṣe ìpinnu tó tọ́, tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí.
18 Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká gbé èrò inú wa ka àwọn nǹkan ti ẹ̀mí. À ń ṣe èyí nípa ‘mímú èrò inú wa gbára dì fún ìgbòkègbodò,’ ká ní ìṣètò tá à ń tẹ̀ lé láti mú kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i, irú bíi gbígbàdúrà déédéé, kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé àti lílọ sóde ẹ̀rí. (1 Pét. 1:13) Dípò tá a ó fi jẹ́ kí àwọn nǹkan ti ẹran ara pín ọkàn wa níyà, ẹ jẹ́ ká gbé èrò inú wa ka àwọn ohun ti ẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó máa bá a nìṣó láti rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á máa rí ìbùkún gbà torí pé gbígbé èrò inú ka ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè àti àlàáfíà.—Gál. 6:7, 8.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni ‘àìgbéṣẹ́ tó wà níhà ti Òfin’ báwo sì ni Ọlọ́run ṣe borí rẹ̀?
• Kí ni “òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú,” báwo la sì ṣe lè dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀?
• Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè máa ‘gbé èrò inú wa ka ẹ̀mí’?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Ṣé ò ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara àbí ò ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí?