ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gbogbo Èèyàn Yóò Lómìnira
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • “Ìṣípayá Àwọn Ọmọ Ọlọ́run”

      Jèhófà tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo “nítorí ìrètí” pé lọ́jọ́ kan, ìdílé ènìyàn yóò gba òmìnira nípasẹ̀ akitiyan “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Àwọn wo ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run” wọ̀nyí? Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, àwọn tó jẹ́ pé bíi ti ìyókù “ìṣẹ̀dá [tó jẹ́ ènìyàn],” a bí wọn sínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Tó bá jẹ́ ti báa ṣe bí wọn ni, wọn kò ní àyè kankan nínú ìdílé àgbáyé ti Ọlọ́run, ìdílé pípé, ìdílé mímọ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà ṣe ohun ribiribi fún wọn. Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Jèhófà gbà wọ́n kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún, ó sì polongo wọn ní “olódodo,” tàbí ẹni mímọ́ nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́ríńtì 6:11) Lẹ́yìn náà ó gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ Ọlọ́run,” ó mú wọn padà wá sínú ìdílé àgbáyé rẹ̀.—Róòmù 8:14-17.

      Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí Jèhófà gbà ṣọmọ, wọn yóò ní àǹfààní ológo. Wọn yóò jẹ́ “àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí,” wọn yóò bá Jésù Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí apá kan Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4) Èyí jẹ́ ìjọba kan táa fìdí rẹ̀ sọlẹ̀ gbọn-in lórí ìpìlẹ̀ òmìnira àti ìdájọ́ òdodo—kì í ṣe èyí táa fi ń nini lára, táa fi ń gboni mọ́lẹ̀. (Aísáyà 9:6, 7; 61:1-4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ọmọ Ọlọ́run wọ̀nyí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Jésù, ẹni táa ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ pé òun ni yóò jẹ́ ‘irú-ọmọ Ábúráhámù.’ (Gálátíà 3:16, 26, 29) Nítorí èyí, wọ́n kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe fún Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ rẹ̀. Apá kan ìlérí náà ni pé, nípasẹ̀ irú-ọmọ Ábúráhámù (tàbí, àtọmọdọ́mọ rẹ̀), “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

  • Gbogbo Èèyàn Yóò Lómìnira
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • Ìgbà wo ni “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀? Láìpẹ́ yìí ni, nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kí gbogbo gbòò mọ àwọn tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ní àmọ̀dájú. Èyí yóò jẹ́ nígbà tí a bá jí “àwọn ọmọ” wọ̀nyí dìde sí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí, tí wọ́n bá ń bá Jésù Kristi lọ́wọ́ nínú fífọ ilẹ̀ ayé mọ́ kúrò nínú ìwà ibi àti ìnira nígbà ogun Ọlọ́run ní Hamágẹ́dọ́nì. (Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14, 27; Ìṣípayá 2:26, 27; 16:16; 17:14; 19:11-21) Láyìíká wa, a rí ẹ̀rí pelemọ tó fi hàn pé a ti wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” jìnnàjìnnà, nígbà tí ìfaradà tí Ọlọ́run ní fún ìṣọ̀tẹ̀ àti àbájáde ìwà ibi yóò dópin.—2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:3-31.

  • Gbogbo Èèyàn Yóò Lómìnira
    Ilé Ìṣọ́—1999 | May 1
    • Bóo ti “ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run,” o lè mú irú ìgbọ́kànlé tí Pọ́ọ̀lù ní nínú ààbò onítọ̀ọ́jú tí Kristi ń fúnni àti ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fúnni dàgbà, ìgbọ́kànlé tí kì í yẹ̀ àní nígbà tí ìjìyà àti àìfẹ̀tọ́bánilò bá dà bí ohun tí kò ṣeé fara dà. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti jíròrò ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run, ó béèrè pé: “Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ṣé ìpọ́njú ni tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu tàbí idà?” (Róòmù 8:35) Àmọ́ ṣá o, báa bá ní ká lo àwọn ọ̀rọ̀ Rousseau, àwọn Kristẹni ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù ṣì wà “nígbèkùn” onírúurú àwọn agbára tí ń fara nini. Wọ́n “ń fi ikú pa [wọ́n] láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀” bí “àgùntàn fún pípa.” (Róòmù 8:36) Ǹjẹ́ wọ́n gbà kíyẹn mú ọkàn wọn pòrúurùu bí?

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́