“Báyìí Ni Ọlọ́run Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Wa”
“Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kíní kejì.”—JÒHÁNÙ KÍNÍ 4:11.
1. Ní March 23 lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, èé ṣe tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yóò fi pé jọ sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ibi mìíràn tí a ti ń ṣe ìpàdé káàkiri ayé?
NÍ Sunday, March 23, 1997, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, kò sí iyè méjì pé iye ènìyàn yíká ayé tí yóò pé jọ pọ̀ sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ibi ìpàdé mìíràn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò yóò lé ní 13,000,000. Èé ṣe? Nítorí pé ọ̀nà gíga lọ́lá jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ hàn sí ìran aráyé ti gún ọkàn àyà wọn ní kẹ́ṣẹ́. Jésù Kristi darí àfiyèsí sí ẹ̀rí pípabanbarì yẹn tí ìfẹ́ Ọlọ́run ní, ní sísọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
2. Àwọn ìbéèrè wo ni ó ṣàǹfààní pé kí a bi ara wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nípa ìhùwàpadà wa sí ìfẹ́ Ọlọ́run?
2 Bí a ṣe ń gbé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ti fi hàn yẹ̀ wò, ó dára kí a béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Mo ha mọrírì ohun tí Ọlọ́run ti ṣe ní tòótọ́ bí? Ọ̀nà tí mo gbà ń lo ìgbésí ayé mi ha fi ẹ̀rí ìmọrírì yẹn hàn bí?’
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
3. (a) Èé ṣe tí fífi ìfẹ́ hàn kò fi jẹ́ ohun bàbàrà sí Ọlọ́run? (b) Báwo ni àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ṣe ṣe fi agbára àti ọgbọ́n hàn?
3 Níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, fífi ìfẹ́ hàn kì í ṣe ohun bàbàrà, nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (Jòhánù Kíní 4:8) Ìfẹ́ ni ànímọ́ rẹ̀ tí ó hàn gbangba jù lọ. Nígbà tí ó ń ṣètò ilẹ̀ ayé fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbé, mímú tí ó mú kí àwọn òkè ńlá yọrí jáde àti mímú tí ó mú kí omi kóra jọ pọ̀ sínú àwọn adágún àti agbami òkun jẹ́ fífi agbára hàn lọ́nà tí ń múni ṣe háà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:9, 10) Nígbà tí Ọlọ́run mú kí àyípoyípo omi àti àyípoyípo afẹ́fẹ́ oxygen bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, nígbà tí ó ṣẹ̀dá àìmọye ohun abẹ̀mí tí a kò lè fojú ìyójú rí àti onírúurú ewébẹ̀ láti yí àwọn èròjà kẹ́míkà ilẹ̀ ayé pa dà di oúnjẹ tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè jẹ láti lè gbé ìwàláàyè wọn ró, nígbà tí ó ṣètò agogo àdánidá inú sẹ́ẹ̀lì wa láti bá gígùn ọjọ́ àti oṣù lórí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé mu, èyí fi ọgbọ́n bíbùáyà hàn. (Orin Dáfídì 104:24; Jeremáyà 10:12) Síbẹ̀, ohun mìíràn tí ó tún ta yọ lọ́lá nínú àwọn ẹ̀dá tí a lè fojú rí ni ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run.
4. Nínú àwọn ìṣẹ̀dá tí a lè fojú rí, ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọ́run wo ni ó yẹ kí gbogbo wa rí, kí a sì mọrírì?
4 Òkè ẹnu wa ń sọ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa nígbà tí a bá bu èso mùkẹ̀mukẹ kan tí ó ti pọ́n jẹ, tí ó hàn gbangba pé a kò dá a láti gbé ẹ̀mí wa ró nìkan ṣùgbọ́n láti mú adùn wá fún wa pẹ̀lú. Ojú wa ń rí ẹ̀rí rẹ̀ tí kò ṣeé já ní koro nígbà tí a bá rí oòrùn tí wíwọ̀ rẹ̀ múni ṣe háà, nígbà tí a bá rí ojú ọ̀run tí ìràwọ̀ kún fọ́fọ́ ní alẹ́ kan tí ojú ọjọ́ mọ́ kedere, nígbà tí a bá rí onírúurú òdòdó àti àwọ̀ mèremère wọn, nígbà tí a bá rí àwọn ọmọ ẹranko tí ń gbókìtì, àti nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá fọ̀yàyà rẹ́rìn-ín músẹ́. Imú wa ń jẹ́ kí a nímọ̀lára rẹ̀ nígbà tí a bá gbóòórùn dídùn àwọn òdòdó ìgbà ìrúwé. Etí wa ń nímọ̀lára rẹ̀ nígbà tí a bá tẹ́tí sí ìró ìtàkìtì omi, orin àwọn ẹyẹ, àti ohùn àwọn olólùfẹ́. A ń nímọ̀lára rẹ̀ nígbà tí olólùfẹ́ kan bá fọwọ́ gbá wa mọ́ra. A fi agbára ìríran, ìgbọ́ràn, tàbí ìgbóòórùn àwọn nǹkan lọ́nà tí kò ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn jíǹkí irú àwọn ẹranko kan. Ṣùgbọ́n, ìran aráyé, tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run, ní agbára láti nímọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́nà kan tí ẹranko kò lè gbà ní in.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ gígadabú hàn sí Ádámù àti Éfà?
5 Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fi ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ yí wọn ká. Ó ti dá ọgbà kan sílẹ̀, párádísè, ó sì ti mú kí onírúurú igi hù nínú rẹ̀. Ó ti pèsè odò láti bomi rin ín, ó sì fi àwọn ẹyẹ àti ẹranko àrímáleèlọ kún inú rẹ̀. Gbogbo èyí ni ó fi fún Ádámù àti Éfà gẹ́gẹ́ bí ilé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8-10, 19) Jèhófà bá wọn lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀, apá kan ìdílé rẹ̀ àgbáyé. (Lúùkù 3:38) Níwọ̀n bí ó ti pèsè Édẹ́nì gẹ́gẹ́ bí àwòṣe, Bàbá ọ̀run tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ yìí gbé iṣẹ́ àyànfúnni tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá síwájú wọn, ti mímú kí Párádísè gbòòrò dé gbogbo apá ilẹ̀ ayé. Gbogbo ilẹ̀ ayé ni wọn yóò fi àtọmọdọ́mọ wọn kún.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
6. (a) Kí ni èrò rẹ nípa ipa ọ̀nà ọ̀tẹ̀ tí Ádámù àti Éfà tọ̀? (b) Kí ni ó lè fi hàn pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì àti pé a ti jàǹfààní láti inú ìmọ̀ yẹn?
6 Ṣùgbọ́n, kété lẹ́yìn náà, Ádámù àti Éfà dojú kọ ìdánwò ìgbọràn, ìdánwò ìdúróṣinṣin. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀kan kùnà láti fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ tí a fi jíǹkí wọn, èyí èkejì pẹ̀lú sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe múni gbọ̀n rìrì. Kò sí àwíjàre fún wọn! Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n pàdánù ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, a lé wọn jáde kúrò nínú ìdílé rẹ̀, a sì lé wọn jáde kúrò ní Édẹ́nì. Àwa lónìí ṣì ń nímọ̀lára àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-6, 16-19, 24; Róòmù 5:12) Ṣùgbọ́n a ha ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ bí? Báwo ni a ṣe ń hùwà pa da sí ìfẹ́ Ọlọ́run? Àwọn ìpinnu tí a ń ṣe lójoojúmọ́ ha ń fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ rẹ̀ bí?—Jòhánù Kíní 5:3.
7. Láìka ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe sí, báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ hàn sí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn?
7 Kódà àìnímọrírì rárá tí àwọn òbí wa ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ fi hàn sí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn kò dín ìfẹ́ ti Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kù. Láti inú ìyọ́nú tí ó ní fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí a kò tí ì bí nígbà náà—títí kan àwa tí a wà láàyè lónìí—Ọlọ́run yọ̀ǹda fún Ádámù àti Éfà láti tọ́ ìdílé kan dàgbà ṣáájú kí wọ́n tó kú. (Jẹ́nẹ́sísì 5:1-5; Mátíù 5:44, 45) Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí ẹni tí à bá bí nínú wa. Nípa ṣíṣí ìfẹ́ inú rẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, Jèhófà tún pèsè ìpìlẹ̀ fún ìrètí fún gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù tí ó bá lo ìgbàgbọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18; Aísáyà 9:6, 7) Ìṣètò rẹ̀ ní nínú àwọn ọ̀nà tí àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè lè gbà jèrè ohun tí Ádámù ti pàdánù pa dà, ìyẹn ni, ìwàláàyè pípé gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà nínú ìdílé rẹ̀ àgbáyé. Ó ṣe èyí nípa pípèsè ìràpadà.
Èé Ṣe Tí A Fi Nílò Ìràpadà?
8. Èé ṣe tí Ọlọ́run kò fi lè wulẹ̀ pàṣẹ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà gbọ́dọ̀ kú, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tí ó bá jẹ́ onígbọràn tí yóò kú?
8 Ó ha pọn dandan ní tòótọ́ pé kí a fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn kan san iye owó ìràpadà? Ọlọ́run kò ha lè pàṣẹ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà gbọ́dọ̀ kú fún ìwà ọ̀tẹ̀ wọn, gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn tí ó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run yóò wà láàyè títí láé? Bí a bá fi ojú ìwòye kúkúrú ti ẹ̀dá ènìyàn wò ó, ìyẹn lè dà bí ohun tí ó bọ́gbọ́n mu. Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà jẹ́ ẹni tí ó “fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́.” (Orin Dáfídì 33:5) Kìkì lẹ́yìn ìgbà tí Ádámù àti Éfà di ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n tó bímọ; nítorí náà kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yẹn tí a bí ní pípé. (Orin Dáfídì 51:5) Gbogbo wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀. Bí Jèhófà bá ti gbójú fo èyí dá, irú àpẹẹrẹ wo ni ìyẹn ì bá ti jẹ́ fún àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ àgbáyé? Kò lè gbójú fo àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo rẹ̀ dá. Ó bọ̀wọ̀ fún ohun tí ìdájọ́ òdodo ń béèrè. Kò sí ẹni tí ó lè rí àríwísí kankan tí ó tọ̀nà sí ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run gbà yanjú ọ̀ràn náà.—Róòmù 3:21-23.
9. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá, irú ìràpadà wo ni a nílò?
9 Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè pèsè ìpìlẹ̀ tí ó yẹ wẹ́kú fún ìdáǹdè àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tí wọn yóò fi ìgbọràn onífẹ̀ẹ́ hàn sí Jèhófà? Bí ẹ̀dá ènìyàn pípé kan yóò bá kú ikú ìrúbọ, ìdájọ́ òdodo lè mú kí ìtóye ìwàláàyè pípé yẹn pèsè ohun tí ó kájú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí yóò fi ìgbàgbọ́ tẹ́wọ́ gba ìràpadà náà. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, Ádámù, ni ó sọ gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn pípé mìíràn tí a ta sílẹ̀, ní jíjẹ́ ìtóye tí ó bá a dọ́gba, lè mú kí òṣùnwọ̀n ìdájọ́ òdodo wà déédéé. (Tímótì Kíní 2:5, 6) Ṣùgbọ́n níbo ni a ti lè rí irú ẹni bẹ́ẹ̀?
Báwo Ni Iye Tí Yóò Náni Ti Pọ̀ Tó?
10. Èé ṣe tí kò fi ṣeé ṣe fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù láti pèsè ìràpadà tí a nílò?
10 Lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè pèsè ohun tí a nílò láti lè ra ìfojúsọ́nà ìwàláàyè tí Ádámù gbé jùnù pa dà. “Kò sí ẹnì kan, bí ó ti wù kí ó ṣe, tí ó lè ra arákùnrin rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lè san owó ìràpadà fún Ọlọ́run nítorí rẹ̀. Nítorí ìràpadà ọkàn wọn iyebíye ni, ó sì dẹ́kun láéláé: Ní pé kí ó fi máa wà láéláé, kí ó má ṣe rí isà òkú.” (Orin Dáfídì 49:7-9) Kàkà tí yóò fi fi ìran aráyé sílẹ̀ láìsí ọ̀nà àbájáde, Jèhófà fúnra rẹ̀ fi àánú pèsè.
11. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà pèsè ìwàláàyè pípé ti ẹ̀dá ènìyàn tí a nílò fún ìràpadà tí ó ṣe wẹ́kú?
11 Jèhófà kò rán áńgẹ́lì kan sórí ilẹ̀ ayé láti díbọ́n bí ẹni tí ó kú nípa dídùbúlẹ̀ nínú ara ènìyàn tí ó gbé wọ̀ nígbà tí ó sì jẹ́ pé ó wà láàyè nínú ara ẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá náà, nìkan ni ó lè hùmọ̀ rẹ̀, ó tàtaré ipá ìwàláàyè àti bátànì àkópọ̀ ìwà ọmọkùnrin ọ̀run kan sínú ilé ọlẹ̀ obìnrin kan, Màríà ọmọbìnrin Hélì, ti ẹ̀yà Júdà. Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, dáàbò bo ìdàgbàsókè ọmọ náà nínú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀, a sì bí i ní ẹ̀dá ènìyàn pípé. (Lúùkù 1:35; Pétérù Kíní 2:22) Nítorí náà, ẹni yìí ní iye owó náà níkàáwọ́ láti pèsè ìràpadà tí yóò kúnjú ohun tí ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá ń béèrè fún lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.—Hébérù 10:5.
12. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo” ti Ọlọ́run? (b) Báwo ni rírán tí Ọlọ́run rán ẹni yìí láti pèsè ìràpadà ṣe túbọ̀ fi ìfẹ́ Rẹ̀ sí wa hàn?
12 Èwo nínú àwọn ẹgbàágbèje ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀run ni Jèhófà fún ní iṣẹ́ yìí? Èyí tí a ṣàpèjúwe nínú Ìwé Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí “Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” ni. (Jòhánù Kíní 4:9) A lo gbólóhùn yí láti ṣàpèjúwe ohun tí ó jẹ́ nígbà tí ó wà ní ọ̀run, kì í ṣe ohun tí ó dà nígbà tí a bí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Òun nìkan ṣoṣo ni ẹni tí Jèhófà dá ní tààràtà láìsí ẹnikẹ́ni mìíràn tí ó bá a lọ́wọ́ sí i. Òun ni Àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá. Òun ni ẹni náà tí Ọlọ́run lò láti mú àwọn ẹ̀dá yòó kù wá. Àwọn áńgẹ́lì jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ádámù ti jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n a ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní “ògo kan irúfẹ́ èyí tí ó jẹ́ ti ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo láti ọ̀dọ̀ bàbá kan.” A sọ pé ó ń gbé “ní ipò oókan àyà lọ́dọ̀ Bàbá.” (Jòhánù 1:14, 18) Ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Bàbá ṣe tímọ́tímọ́, pẹ́kípẹ́kí, ó sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Ó ní irú ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ ní fún ìran aráyé. Òwe 8:30, 31 fi hàn bí ìmọ̀lára Bàbá rẹ̀ nípa Ọmọkùnrin yìí ṣe rí àti bí ìmọ̀lára Ọmọkùnrin náà nípa ìran aráyé ṣe rí pé: “Èmi . . . jẹ́ dídùn inú rẹ̀ [Jèhófà] lójoojúmọ́, èmi ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀; . . . dídùn inú mi [Jésù, Ọ̀gá Oníṣẹ́ fún Jèhófà, ọgbọ́n tí a ṣàkàwé bí ènìyàn] sì wà sípa àwọn ọmọ ènìyàn.” Ọmọkùnrin tí ó ṣeyebíye jù lọ yìí ni Ọlọ́run rán wá sí ilẹ̀ ayé láti pèsè ìràpadà. Nítorí náà, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ti nítumọ̀ tó pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni”!—Jòhánù 3:16.
13, 14. Kí ni àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìgbìdánwò Ábúráhámù láti fi Aísíìkì rúbọ yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì nípa ohun tí Jèhófà ṣe? (Jòhánù Kíní 4:10)
13 Láti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye díẹ̀ nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Jésù tó wá sí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run fún Ábúráhámù nítọ̀ọ́ni, ní nǹkan bíi 3,890 ọdún sẹ́yìn pé: “Mú ọmọ rẹ nísinsìnyí, Aísíìkì, ọmọ rẹ náà kan ṣoso, ti ìwọ fẹ́, kí ìwọ kí ó sì lọ sí ilẹ̀ Mòráyà; kí o sì fi í rúbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú òkè tí èmi ó sọ fún ọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:1, 2) Nínú ìgbàgbọ́, Ábúráhámù ṣègbọràn. Fi ara rẹ sí ipò Ábúráhámù. Bí ìyẹn bá jẹ́ ọmọkùnrin rẹ ńkọ́, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi? Ìmọ̀lára wo ni ìwọ yóò ní bí o ṣe ń la igi tí ìwọ yóò fi dáná ìrúbọ, bí ó ṣe ń rìnrìn àjò ọlọ́jọ́ díẹ̀ sí ilẹ̀ Mòráyà, tí o sì gbé ọmọkùnrin rẹ sórí pẹpẹ?
14 Èé ṣe tí òbí oníyọ̀ọ́nú kan yóò fi ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀? Jẹ́nẹ́sísì 1:27 sọ pé, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara Rẹ̀. Lọ́nà tí kò tó nǹkan, ìmọ̀lára ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí a ní fi ìfẹ́ àti ìyọ́nú tí Jèhófà ní hàn. Nínú ọ̀ràn Ábúráhámù, Ọlọ́run dá sí i, tí ó fi jẹ́ pé a kò fi Aísíìkì rúbọ ní ti gidi. (Jẹ́nẹ́sísì 22:12, 13; Hébérù 11:17-19) Ṣùgbọ́n, nínú ọ̀ràn òun alára, Jèhófà kò dáwọ́ pípèsè ìràpadà náà dúró nígbẹ̀yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ná òun àti Ọmọkùnrin rẹ̀ ní ohun púpọ̀. Ohun tí Ọlọ́run ṣe kì í ṣe nítorí pé ó jẹ́ iṣẹ́ ọ̀ràn-an-yàn fún un, bí kò ṣe pé, ó jẹ́ fífi inú rere àrà ọ̀tọ̀ tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí hàn. A ha mọrírì èyí ní kíkún bí?—Hébérù 2:9.
Ohun Tí Ìràpadà Mú Kí Ó Ṣeé Ṣe
15. Báwo ni ìràpadà ṣe nípa lórí ìwàláàyè àní nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí pàápàá?
15 Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run pèsè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé àwọn tí wọ́n fi ìgbàgbọ́ tẹ́wọ́ gbà á. Tẹ́lẹ̀ rí, a ti sọ wọ́n di àjèjì sí Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti sọ, wọ́n jẹ́ ‘ọ̀tá nítorí tí èrò inú wọn wà lórí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú pin.’ (Kólósè 1:21-23) Ṣùgbọ́n “a mú” wọn “pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọkùnrin rẹ̀.” (Róòmù 5:8-10) Níwọ̀n bí wọ́n ti yí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn pa dà tí wọ́n sì ti tẹ́wọ́ gba ìdáríjì tí Ọlọ́run ń mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Kristi, a fi ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gaara ṣojú rere sí wọn.—Hébérù 9:14; Pétérù Kíní 3:21.
16. Àwọn ìbùkún wo ni a fún agbo kékeré nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú ìràpadà?
16 Jèhófà ti nawọ́ ojú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ti dídara pọ̀ mọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ ní Ìjọba ọ̀run sí díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí, agbo kékeré kan, pẹ̀lú èrò mímú ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. (Lúùkù 12:32) A mú àwọn wọ̀nyí jáde “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè . . . kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkoso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn wọ̀nyí pé: “Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípasẹ̀ ẹ̀mí tí àwa ń ké jáde pé: ‘Abba, Bàbá!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà náà, bí àwa bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá pẹ̀lú: àwọn ajogún Ọlọ́run ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 8:15-17) Nítorí sísọ tí Ọlọ́run sọ wọ́n dọmọ, a fún wọn ní ipò ìbátan tí wọ́n ní láti ṣìkẹ́, èyí tí Ádámù sọnù; ṣùgbọ́n a óò tún fún àwọn ọmọ wọ̀nyí ní àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ti ọ̀run—ohun kan tí Ádámù kò fìgbà kan rí ní. Abájọ tí àpọ́sítélì Jòhánù fi wí pé: “Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Bàbá ti fi fún wa, kí a lè pè wá ní ọmọ Ọlọ́run”! (Jòhánù Kíní 3:1) Fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà (a·gaʹpe) nìkan ni Ọlọ́run fi hàn ṣùgbọ́n ó tún fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ (phi·liʹa), èyí tí a fi ń dá ìdè tí ó wà láàárín àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́ mọ̀, hàn.—Jòhánù 16:27.
17. (a) Àǹfààní wo ni a fún gbogbo àwọn tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà? (b) Kí ni “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” yóò túmọ̀ sí fún wọn?
17 Fún àwọn mìíràn pẹ̀lú—gbogbo àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè ọ̀làwọ́ ti ìyè tí Ọlọ́run pèsè nípasẹ̀ Jésù Kristi—Jèhófà ṣí àǹfààní jíjèrè ipò ìbátan ṣíṣeyebíye tí Ádámù sọnù sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá [ẹ̀dá ènìyàn tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ádámù] ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run [ìyẹn ni pé, wọ́n ń dúró dé àkókò náà nígbà tí yóò hàn kedere pé àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ ajogún pẹ̀lú Kristi ní Ìjọba ọ̀run ń gbé ìgbésẹ̀ gidi fún àǹfààní ìran aráyé]. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo [a bí wọn sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìrètí pé wọn yóò kú, kò sì sí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà gba ara wọn sílẹ̀], kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ inú òun fúnra rẹ̀ ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, lórí ìpìlẹ̀ ìrètí [tí Ọlọ́run fún un] pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ lómìnira kúrò nínú ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́ yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:19-21) Kí ni òmìnira yẹn yóò túmọ̀ sí? Pé a ti gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò nínú òǹdè ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Wọn yóò ní ìjẹ́pípé èrò inú àti ti ara, wọn yóò ní Párádísè gẹ́gẹ́ bí ilé wọn, àti ìyè ayérayé nínú èyí tí wọn yóò gbádùn ìjẹ́pípé wọn, tí wọn yóò sì fi ìmọrírì wọn hàn fún Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Báwo sì ni gbogbo èyí ṣe ṣeé ṣe? Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.
18. Ní March 23 lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, kí ni a óò ṣe, èé sì ti ṣe?
18 Ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ní yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù, Jésù dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀. Ṣíṣèrántí ikú rẹ̀ lọ́dọọdún ti di ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé gbogbo Kristẹni tòótọ́. Jésù fúnra rẹ̀ pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ní 1997, a óò ṣe Ìṣe Ìrántí náà lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní March 23 (èyí jẹ́ ìgbà tí Nísàn 14 bẹ̀rẹ̀). Ní ọjọ́ yẹn, kò sí ohun mìíràn tí ó lè ṣe pàtàkì ju pípésẹ̀ síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí yìí lọ.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ti gbà fi ìfẹ́ gígadabú hàn fún ìran aráyé?
◻ Èé ṣe tí a fi nílò ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé láti ra àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù pa dà?
◻ Kí ni ohun ńlá tí pípèsè ìràpadà yẹn ná Jèhófà?
◻ Kí ni ìràpadà náà mú kí ó ṣeé ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọlọ́run fúnni ní Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo