-
Ṣé O Ti Múra Tán Láti Ṣèrìbọmi?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o bẹ̀rù láti ṣèrìbọmi?
Àwọn kan máa ń bẹ̀rù pé àwọn ò ní lè mú ìlérí tí wọ́n ṣe fún Jèhófà ṣẹ. Òótọ́ kan ni pé o lè ṣàṣìṣe, ó ṣe tán àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn náà ṣàṣìṣe. Rántí pé Jèhófà ò retí pé àwọn tó ń jọ́sìn òun ò ní ṣàṣìṣe rárá. (Ka Sáàmù 103:13, 14.) Inú Jèhófà máa dùn tó o bá ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kódà, Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun tó “lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ [òun].”—Ka Róòmù 8:38, 39.
-
-
O Lè Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Táwọn Èèyàn Bá Tiẹ̀ Ń Ta Kò Ẹ́Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Bó pẹ́ bó yá, gbogbo àwa Kristẹni la máa kojú inúnibíni. Ṣé ó yẹ kíyẹn dẹ́rù bà wá?
1. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sí wa?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí.” (2 Tímótì 3:12) Àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí Jésù torí pé kì í ṣe apá kan ayé. Àwa náà ò kì í ṣe apá kan ayé, torí náà kò yà wá lẹ́nu pé àwọn ìjọba ayé yìí àtàwọn ẹlẹ́sìn ń ṣenúnibíni sí wa.—Jòhánù 15:18, 19.
2. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?
Àsìkò tá a wà yìí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Rí i pé ò ń wáyè láti máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Àwọn nǹkan yìí á fún ẹ lókun, á sì jẹ́ kó o nígboyà láti kojú inúnibíni tàbí àtakò èyíkéyìí, kódà tó bá jẹ́ pé ìdílé rẹ ló ń ta kò ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ṣenúnibíni sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.”—Hébérù 13:6.
Bákan náà, a máa túbọ̀ jẹ́ onígboyà tá a bá ń wàásù déédéé. Torí ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbára lé Jèhófà, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká bẹ̀rù ẹnikẹ́ni. (Òwe 29:25) Tó o bá ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa fìgboyà wàásù báyìí, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa wàásù táwọn ìjọba bá tiẹ̀ pàṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù.—1 Tẹsalóníkà 2:2.
3. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá fara da inúnibíni?
Ó dájú pé ara kì í tù wá tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, àmọ́ tá a bá fara da inúnibíni ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, torí àá rí bó ṣe ń fún wa lókun láti máa fara dà á nígbà tó bá ṣe wá bíi pé a ò lókun mọ́. (Ka Jémíìsì 1:2-4.) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ń jìyà, àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn tó bá rí i pé a ò juwọ́ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Tí ẹ bá fara da ìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere, èyí dáa lójú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:20) Tá a bá fara dà á dé òpin, Jèhófà máa fún wa láǹfààní láti wà ní ayé tuntun, níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní máa ta ko ìjọsìn tòótọ́ mọ́, àá sì máa gbébẹ̀ títí láé.—Mátíù 24:13.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé a lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa bù kún wa tá ò bá juwọ́ sílẹ̀.
4. Fara dà á táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá ń ta kò ẹ́
Jésù mọ̀ pé inú àwọn kan nínú ìdílé wa lè má dùn sí wa tá a bá pinnu pé a máa sin Jèhófà. Ka Mátíù 10:34-36, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló ṣeé ṣe káwọn tó wà nínú ìdílé kan ṣe tẹ́nì kan nínú ìdílé náà bá pinnu láti sin Jèhófà?
Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ni wàá ṣe tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ní kó o má sin Jèhófà mọ́?
Ka Sáàmù 27:10 àti Máàkù 10:29, 30. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo làwọn ìlérí tó wà nínú ẹsẹ yìí ṣe lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ táwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ta kò ẹ́?
5. Má fi Jèhófà sílẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ
A nílò ìgboyà tá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí lo rí nínú fídíò yẹn tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà lè jẹ́ onígboyà?
Ka Ìṣe 5:27-29 àti Hébérù 10:24, 25. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù tàbí lọ sí ìpàdé mọ́?
6. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́
Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́mọdé àti lágbà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láìka ti pé àwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí wọn. Kó o lè rí ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí ló ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin yẹn lọ́wọ́ láti fara dà á?
Ka Róòmù 8:35, 37-39 àti Fílípì 4:13. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè fara da àdánwò èyíkéyìí?
Ka Mátíù 5:10-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló lè mú kó o máa láyọ̀ tó o bá tiẹ̀ ń kojú inúnibíni tàbí àtakò?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò rò pé màá lè fara da inúnibíni.”
Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹni náà táá mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da inúnibíni?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè máa sìn ín láìka ti pé àwọn èèyàn ń ta kò wá tàbí ṣenúnibíni sí wa. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á dé òpin.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni?
Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?
Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé o ò ní pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí Jèhófà ṣe ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ kó lè fara dà á nígbà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.
Wo ohun tó ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìka pé àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí wọn.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti jẹ́ onígboyà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ.
“Ìsinsìnyí Gan-An Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni” (Ilé Ìṣọ́, July 2019)
Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí ìdílé wa bá ń ṣenúnibíni sí wa, àwọn nǹkan wo la sì lè ṣe ká lè fara dà á láìfi Jèhófà sílẹ̀?
“Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà” (Ilé Ìṣọ́, October 2017)
-