Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ Náà Mọ Ẹ́
“Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.”—SM. 73:24.
1, 2. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbé àpẹẹrẹ àwọn kan yẹ̀ wò nínú Ìwé Mímọ́ nípa ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá wọn wí?
“NÍ TÈMI, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.” (Sm. 73:28) Ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí fi hàn pé ó gbọ́kàn lé Ọlọ́run. Kí ló mú kí onísáàmù náà sọ ọ̀rọ̀ yìí? Nígbà tó kíyè sí pé nǹkan ń lọ déédéé fáwọn èèyàn burúkú, inú rẹ̀ kọ́kọ́ bà jẹ́. Ó sọ pé: “Lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.” (Sm. 73:2, 3, 13, 21) Àmọ́ nígbà tó fi máa wá sí “ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,” ó pe orí ara rẹ̀ wálé ó sì pinnu pé òun ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lòun á túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Sm. 73:16-18) Ìrírí yìí kọ́ onísáàmù náà lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ẹ̀kọ́ náà ni pé: Téèyàn bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run, kó máa gba ìbáwí kó sì máa fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò.—Sm. 73:24.
2 Ó wu àwa náà pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ ká sì máa gba ìbáwí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á mọ wá bí amọ̀kòkò ṣe máa ń mọ nǹkan. Lédè míì, a máa mú kí Jèhófà sọ wá di irú ẹni tó fẹ́ ká jẹ́. Láyé àtijọ́, Ọlọ́run fi àánú hàn sáwọn èèyàn kan àtàwọn orílẹ̀-èdè kan, ní ti pé ó fún wọn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìbáwí rẹ̀. Jèhófà rí i pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì “fún ìtọ́ni wa,” wọ́n sì jẹ́ “ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (Róòmù 15:4; 1 Kọ́r. 10:11) A máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nínú àpilẹ̀kọ yìí. A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú bó ṣe ń mọ wá.
JÈHÓFÀ LÁṢẸ LÓRÍ WA BÍ AMỌ̀KÒKÒ ṢE LÁṢẸ LÓRÍ AMỌ̀
3. Báwo ni Aísáyà 64:8 àti Jeremáyà 18:1-6 ṣe ṣàpèjúwe ọlà àṣẹ tí Jèhófà ní lórí àwa èèyàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Bíbélì fi Jèhófà wé amọ̀kòkò torí pé ó láṣẹ lórí àwa èèyàn, ó sì lè darí àwọn orílẹ̀-èdè bó ṣe fẹ́. Aísáyà 64:8 sọ pé “Wàyí o, Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Ohun tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ mọ. Kì í ṣe amọ̀ ló máa sọ ohun tí amọ̀kòkò máa fòun mọ. Bákan náà làwa èèyàn rí lọ́wọ́ Ọlọ́run. A ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún Ọlọ́run pé báyìí ni kí ó ṣe mọ wá, gẹ́gẹ́ bí amọ̀ kò ṣe lè sọ ohun tí amọ̀kòkò máa fi òun mọ.—Ka Jeremáyà 18:1-6.
4. Ṣé àrà tó bá ṣáà ti wu Ọlọ́run ló ń fàwọn èèyàn tàbí orílẹ̀-èdè dá? Ṣàlàyé.
4 Bí amọ̀kòkò ṣe máa ń mọ nǹkan ni Jèhófà ṣe mọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. Àmọ́, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín amọ̀kòkò àti Jèhófà? Ohun kan ni pé Jèhófà fún àwa èèyàn lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ó sì fún àwọn orílẹ̀-èdè náà láǹfààní láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Kì í ṣe pé ó dá àwọn kan lẹ́ni rere, nígbà tó jẹ́ pé ó dá àwọn míì lẹ́ni burúkú. Bákan náà, kì í fipá mú àwọn èèyàn láti ṣe ohun tó fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa èèyàn la máa yàn bóyá a máa fẹ́ kí Jèhófà Ẹlẹ́dàá mọ wá, ìyẹn ni pé kó sọ wá di èèyàn tó dára lójú rẹ̀.—Ka Jeremáyà 18:7-10.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo ọlá àṣẹ rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn ò bá jẹ kí ó mọ àwọn?
5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò gbà kí Jèhófà mọ òun ńkọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo àṣẹ lórí onítọ̀hún? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ká sọ pé amọ̀kòkò kan rí i pé kò ṣeé ṣe láti fi amọ̀ mọ ohun kan tí òun ní lọ́kàn, ó lè fi amọ̀ náà mọ nǹkan míì tàbí kó dà á nù. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ọwọ́ amọ̀kòkò ni àṣìṣe yẹn ti wá. Àmọ́ Jèhófà kì í ṣàṣìṣe ní tiẹ̀. (Diu. 32:4) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jèhófà pa ẹnì kan tì, onítọ̀hún ló fà á. Ohun tí ẹnì kan bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ ọ sọ́nà ló máa pinnu ohun tó máa fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ. Tó bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó máa wúlò fún un. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ “ohun èlò àánú,” tí Ọlọ́run sọ di ohun èlò fún “ìlò ọlọ́lá.” Àmọ́, àwọn tí kò gbà kí Jèhófà tọ́ wọn sọ́nà di “àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.”—Róòmù 9:19-23.
6, 7. Nígbà tí Jèhófà fún Dáfídì Ọba nímọ̀ràn, kí ló ṣe? Nígbà tí Jèhófà fún Sọ́ọ̀lù Ọba nímọ̀ràn, kí ló ṣe?
6 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà máa ń gbà mọ àwa èèyàn bí ìgbà tí amọ̀kòkò bá ń mọ nǹkan ni pé, ó máa ń fún wa nímọ̀ràn, ó sì máa ń bá wa wí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọba méjì tó kọ́kọ́ jẹ ní Ísírẹ́lì wí, ìyẹn Sọ́ọ̀lù àti Dáfídì. Nígbà tí Dáfídì bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà, ńṣe ni nǹkan dojú rú fún òun àtàwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba ni, Jèhófà bá a wí gidigidi. Ọlọ́run rán wòlíì Nátánì láti bá Dáfídì wí. (2 Sám. 12:1-12) Ǹjẹ́ ó gba ìbáwí náà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe gan-an, ó sì tọrọ àforíjì. Torí pé Dáfídì ronú pìwà dà, Ọlọ́run fi àánú hàn sí i.—Ka 2 Sámúẹ́lì 12:13.
7 Sọ́ọ̀lù ò dà bíi Dáfídì ní tiẹ̀. Kò gbàmọ̀ràn tí Jèhófà fún un. Jèhófà rán wòlíì Sámúẹ́lì pé kó sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé kó pa gbogbo àwọn ọmọ Ámálékì run tó fi mọ́ gbogbo àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Àmọ́ ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ṣe tinú ẹ̀, ó dá Ágágì Ọba àtàwọn ẹran tó sanra sí. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé ńṣe ló fẹ́ fi gba iyì fún ara rẹ̀. (1 Sám. 15:1-3, 7-9, 12) Torí náà, Jèhófà rán Sámúẹ́lì láti tọ́ Sọ́ọ̀lù sọ́nà. Kàkà tí Sọ́ọ̀lù ì bá fi gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, kí Jèhófà lè sọ ọ́ dẹni tó wúlò, ńṣe ló fárígá. Ó gbà pé kò sóhun tó burú nínú bí òun kò ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run. Ó sọ pé torí kí òun lè fi àwọn ẹran náà rúbọ sí Jèhófà lòun ṣe dá wọn sí. Torí ohun tí Sọ́ọ̀lù ṣe yìí, Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba, ó sì pàdánù àjọṣe rere tó ní pẹ̀lú Jèhófà.—Ka 1 Sámúẹ́lì 15:13-15, 20-23.
ỌLỌ́RUN KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ
8. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí Jèhófà bá wọn wí?
8 Láyé àtijọ́, Jèhófà fún àwọn orílẹ̀-èdè kan láǹfààní láti fi hàn pé àwọn á máa tẹ̀ lé ìtọ́ni òun. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lómìnira kúrò ní oko ẹrú ní Íjíbítì lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó bá wọn dá májẹ̀mú kan. Wọ́n di àkànṣe dúkìá fún un, ó sì ṣèlérí pé òun máa mọ wọ́n bí ìgbà tí amọ̀kòkò ń mọ nǹkan, kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́, àwọn èèyàn náà ò gbà kí Jèhófà mọ àwọn, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń ṣe ohun tó burú ní ojú rẹ̀. Kódà, wọ́n bọ àwọn òrìṣà tí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ń bọ. Àìmọye ìgbà ni Jèhófà rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí wọn pé kí wọ́n yí pa dà, àmọ́ wọn ò kọbi ara sóhun táwọn wòlíì náà ń sọ fún wọn. (Jer. 35:12-15) Torí bẹ́ẹ̀, Jèhófà bá wọn wí gidigidi. Ó kà wọ́n sí ohun èlò tó yẹ fún ìparun, ó sì mú kí àwọn ará Ásíríà pa àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà lápá àríwá run. Àwọn ará Bábílónì sì pa àwọn ẹ̀yà méjì tó kù ní apá gúúsù run. Ẹ̀kọ́ gidi mà lèyí o! Tá a bá gba ìbáwí Jèhófà, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tó ń fún wa nìkan la lè ṣe ara wa láǹfààní.
9, 10. Nígbà tí Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn ará Nínéfè pé kí wọ́n yí pa dà, kí ni wọ́n ṣe?
9 Àwọn míì tí Jèhófà tún fún láǹfààní láti fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò ni àwọn èèyàn ìlú Nínéfè. Jèhófà sọ fún Jónà pé: “Dìde, lọ sí Nínéfè ìlú ńlá títóbi náà, kí o sì pòkìkí lòdì sí i pé ìwà búburú wọn ti gòkè wá síwájú mi.” Ìwà búburú táwọn èèyàn náà ń hù ló mú kí Jèhófà fẹ́ pa wọ́n run.—Jónà 1:1, 2; 3:1-4.
10 Nígbà tí Jónà sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn náà, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀, láti orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn àní dórí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn.” Àní ọba wọn pàápàá “dìde lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ ẹ̀wù oyè rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ bo ara rẹ̀, ó sì jókòó nínú eérú.” Àwọn ará Nínéfè fetí sí ìkìlọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ronú pìwà dà. Torí náà, Jèhófà kò pa wọ́n run mọ́.—Jónà 3:5-10.
11. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ará Nínéfè?
11 Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run yàn kò ní kí Ọlọ́run má bá wọn wí. Ọlọ́run kò bá àwọn ará Nínéfè dá májẹ̀mú kankan. Síbẹ̀, Jèhófà rán wòlíì rẹ̀ láti kìlọ̀ fún wọn, ó sì fi àánú hàn sí wọn nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ṣe ohun tó fẹ́. Ẹ ò rí i pé àwọn àpẹẹrẹ méjèèjì yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà “kì í fi ojúsàájú bá ẹnikẹ́ni lò”!—Diu. 10:17.
JÈHÓFÀ MỌ ÌGBÀ TÓ YẸ KÓ YÍ ÌPINNU RẸ̀ PA DÀ
12, 13. (a) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa ń yí ìpinnu rẹ̀ pa dà nígbà táwọn èèyàn kan bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀? (b) Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe máa ń kẹ́dùn tàbí bó ṣe máa ń pèrò dà?
12 Jèhófà lè yí ìpinnu rẹ̀ pa dà táwọn èèyàn bá yí ìwà wọn pa dà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà kẹ́dùn pé òun fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba Ísírẹ́lì. (1 Sám. 15:11) Nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà tí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìwà búburú wọn, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.”—Jónà 3:10.
13 Nígbà tí Bíbélì bá sọ pé Jèhófà kẹ́dùn tàbí pé ó pèrò dà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ó yí èrò rẹ̀ nípa ẹnì kan pa dà tàbí pé ó yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà. Òótọ́ ni pé Jèhófà ló yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì tì í lẹ́yìn. Àmọ́, nígbà tó ṣàìgbọràn, Ọlọ́run kọ̀ ọ́ lọ́ba. Ṣé àṣìṣe ni Ọlọ́run ṣe bó ṣe yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, àìgbọràn Sọ́ọ̀lù ló mú kí Ọlọ́run kẹ́dùn pé òun fi jọba. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run pèrò dà nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, ó sì dá wọn sí. Ó mà tuni nínú o pé Jèhófà jẹ́ onínúure, aláàánú àti pé ó ṣe tán láti yí ìpinnu rẹ̀ pa dà nígbà táwọn èèyàn bá yíwà pa dà tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀!
MÁ ṢE KỌ ÌBÁWÍ JÈHÓFÀ
14. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń mọ wá lónìí? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tí Ọlọ́run bá ń mọ wá?
14 Lóde òní, Jèhófà ń lo Bíbélì àti ètò rẹ̀ láti mọ wá. (2 Tím. 3:16, 17) Ó yẹ kí inú wa máa dùn pé Jèhófà ń fún wa nímọ̀ràn ó sì ń bá wa wí nípasẹ̀ Bíbélì àti ètò rẹ̀. Torí náà, láìka bó ti pẹ́ to tá a ti ṣèrìbọmi tàbí bí àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní nínú ètò Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó, ẹ jẹ́ ká máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á máa mọ wá gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò ṣe máa ń fi amọ̀ mọ nǹkan, ohun èlò tó yẹ fún ọlá ló sì máa fi wá mọ.
15, 16. (a) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn tó bá pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Kí ló lè mú kéèyàn borí ìtìjú, téèyàn ò sì ní bara jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ nígbà tí wọ́n bá báni wí?
15 Oríṣiríṣi ni ìbáwí, ó lè jẹ́ ìtọ́ni tàbí kí wọ́n tún ojú ìwòye wa ṣe. Àmọ́ nígbà míì, wọ́n lè bá wa wí torí pé a ṣe ohun tí kò tọ́. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ lè mú kí wọ́n gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan lọ́wọ́ wa. Àpẹẹrẹ kan ni ti arákùnrin Dennisa tó jẹ́ alàgbà tẹ́lẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, ó lọ́wọ́ sí okòwò kan tí kò yẹ, èyí sì kó o sí wàhálà, ìgbìmọ̀ onídàájọ́ sì bá a wí. Báwo ló ṣe rí lára Dennis lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n kéde fún ìjọ pé kì í ṣe alàgbà mọ́? Ó sọ pé: “Ńṣe ni mo dà bí aláìjámọ́ nǹkan kan. Onírúurú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ni mo ti ní láti ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn. Mo ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sìn ní Bẹ́tẹ́lì, mo di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo sì tún di alàgbà. Àìpẹ́ yìí ni mo sì ṣiṣẹ́ ní àpéjọ àgbègbè fún ìgbà àkọ́kọ́. Àmọ́, ọ̀sán kan òru kan ni gbogbo rẹ̀ wọmi. Ojú tì mí, ìbànújẹ́ sì bá mi, mi ò gbà pé mo tún lè wúlò mọ́ nínú ètò Ọlọ́run.”
16 Nígbà tó yá, Arákùnrin Dennis ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Àmọ́, báwo ló ṣe borí ìtìjú tí kò sì jẹ́ kí ìbànújẹ́ sorí òun kodò? Ó sọ pé: “Mo rí i dájú pé mò ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Bákan náà, àwọn ará ò fi mí sílẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde wa náà sì tù mí nínú. Àpilẹ̀kọ tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2009, tó sọ pé ‘Ṣé O Ti Sìn Nígbà Kan Rí? Ǹjẹ́ O Tún Lè Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I?’ bọ́ sákòókò gan-an fún mi, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà dìídì kọ lẹ́tà sí mi. Mi ò lè gbàgbé ìmọ̀ràn inú àpilẹ̀kọ náà tó sọ pé, ‘Nísinsìnyí tí o kò ní àfikún iṣẹ́ nínú ìjọ, o ò ṣe kúkú tẹra mọ́ bí wàá ṣe túbọ̀ di alágbára nípa tẹ̀mí.’” Ǹjẹ́ Dennis kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìbáwí tí wọ́n fún un? Ẹ gbọ́ ohun tó sọ lẹ́yìn ọdún mélòó kan, ó ní, “Jèhófà tún ti fojú àánú hàn sí mi torí pé ní báyìí, mo ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.”
17. Báwo lẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ ṣe lè jàǹfààní látinú ìbáwí tí wọ́n fún un? Sọ àpẹẹrẹ kan.
17 Ọ̀nà míì tí Jèhófà máa ń gbà bá wa wí ni ìyọlẹ́gbẹ́. Ó máa ń dáàbò bo ìjọ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà má bàa kó èèràn ran àwọn ará, ó sì máa ń mú kí onítọ̀hún ṣe àyípadà tó yẹ. (1 Kọ́r. 5:6, 7, 11) Ó tó nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlógún [16] tí Robert fi wà nípò ìyọlẹ́gbẹ́. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ìlànà Bíbélì làwọn òbí àtàwọn arákùnrin rẹ̀ tẹ̀ lé, èyí tó sọ pé ká máa ṣe máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́, àti pé ká má tiẹ̀ kí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tí wọ́n ti gba Robert pa dà, ó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n bi í pé kí ló mú kó pa dà sínú ètò Ọlọ́run, ó sọ pé báwọn ìdílé òun ṣe kọ̀ láti bá òun kẹ́gbẹ́ láwọn ọdún yẹn ló mú kí òun pinnu láti pa dà sínú òtítọ́. Ó wá sọ pé, “Ká ní wọ́n máa ń bá mi kẹ́gbẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa béèrè àlàáfíà mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni, ì bá ṣòro fún mi láti pa dà sínú òtítọ́. Ìdí sì ni pé, ìyẹn á ti tẹ́ mi lọ́rùn débi pé mi ò ní rí ìdí láti pa dà sínú ètò Jèhófà kí n sì máa bá àwọn ará kẹ́gbẹ́.”
18. Irú amọ̀ wo ló yẹ ká jẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?
18 Wọ́n lè má bá wa wí bíi ti Dennis tàbí kí wọ́n yọ wá lẹ́gbẹ́ bíi ti Robert, àmọ́ irú amọ̀ wo la fẹ́ jẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tí í ṣe Amọ̀kòkò tí kò lẹ́gbẹ́ náà? Kí la máa ṣe tí Ọlọ́run bá bá wa wí? Ṣé Dáfídì la máa fìwà jọ ni àbí Sọ́ọ̀lù? Baba wa ni Amọ̀kòkò tí kò lẹ́gbẹ́ náà. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé, “ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” Torí náà, “má kọ ìbáwí Jèhófà; má sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà rẹ̀.”—Òwe 3:11, 12.
a A ti yí orúkọ náà pa dà.