Orí 24
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
1. Èrò òdì wo ló máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn, títí kan àwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá?
ǸJẸ́ Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan? Àwọn kan gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aráyé lápapọ̀, bí Jòhánù 3:16 ti wí. Àmọ́, wọ́n máa ń rò ó pé: ‘Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ èmi yìí láéláé.’ Àwọn Kristẹni tòótọ́ pàápàá lè máa ṣiyèméjì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọkùnrin kan tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá sọ pé: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti gbà pé Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa mi rárá.” Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń ṣiyèméjì bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?
2, 3. Ta ló fẹ́ ká máa lérò pé a kì í ṣèèyàn gidi tàbí pé Jèhófà kò lè nífẹ̀ẹ́ wa láé, báwo la sì ṣe lè gbógun ti irú èrò bẹ́ẹ̀?
2 Ohun tí Sátánì kúkú ń fẹ́ nìyẹn, ká máa lérò pé Jèhófà Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Òótọ́ ni pé Sátánì máa ń sún àwọn èèyàn gbéra ga, kí wọ́n sì jọ ara wọn lójú bí nǹkan míì. (2 Kọ́ríńtì 11:3) Àmọ́ téèyàn ò bá fura, Sátánì tún ń ṣeni débi pé èèyàn ò ní ka ara rẹ̀ séèyàn gidi mọ́. (Jòhánù 7:47-49; 8:13, 44) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” líle koko wọ̀nyí ló tiẹ̀ ń ṣe èyí jù. Lóde òní, ọ̀pọ̀ ló ń dàgbà nínú ìdílé tí kò ti sí “ìfẹ́ni àdánidá.” Ojoojúmọ́ ayé làwọn ẹlòmíràn ń dojú kọ àwọn èèyàn tó jẹ́ òǹrorò, onímọtara-ẹni-nìkan àti olùwarùnkì. (2 Tímótì 3:1-5) Tá a bá ti wá fojú wọn gbolẹ̀ tàbí tá a ti hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìkórìíra sí wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè kúkú wá gbà pé àwọn ò lè jẹ́ èèyàn gidi mọ́, pé àwọn kì í ṣẹni tó ṣeé nífẹ̀ẹ́.
3 Bí irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ bá ń wá sí ọ lọ́kàn, má sọ̀rètí nù. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ń fi ọwọ́ tó le koko jù mú ọ̀ràn ara wa nígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n rántí pé ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà fún ni “mímú àwọn nǹkan tọ́” àti ‘bíbi àwọn nǹkan tó fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ṣubú.’ (2 Tímótì 3:16; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Bíbélì sọ pé: “A óò . . . fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú níwájú rẹ̀ ní ti ohun yòówù nínú èyí tí ọkàn-àyà wa ti lè dá wa lẹ́bi, nítorí Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.” (1 Jòhánù 3:19, 20) Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́rin yẹ̀ wò, tí Ìwé Mímọ́ fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti “fún ọkàn-àyà wa ní ìdánilójú” pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.
Èèyàn Àtàtà Ni Ọ́ Lójú Jèhófà
4, 5. Báwo ni àpèjúwe Jésù nípa ológoṣẹ́ ṣe fi hàn pé a níye lórí lójú Jèhófà?
4 Èkíní, Bíbélì fi yé wa yékéyéké pé Ọlọ́run ka gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí. Fún àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29-31) Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn túmọ̀ sí létí àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹ̀ wò.
5 A lè máa ṣe kàyéfì nípa ohun tó lè mú kéèyàn fẹ́ ra ológoṣẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà ayé Jésù, ológoṣẹ́ ni ẹyẹ olówó pọ́ọ́kú jù lọ táwọn èèyàn ń rà fún jíjẹ. Ṣàkíyèsí pé èèyàn lè fi ẹyọ owó kan ṣoṣo tí ìníyelórí rẹ̀ kéré ra ológoṣẹ́ méjì. Àmọ́ Jésù sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé béèyàn bá ní ẹyọ owó méjì lọ́wọ́ tó fẹ́ fi ra ológoṣẹ́, kì í ṣe ológoṣẹ́ mẹ́rin ni wọ́n máa kó fún un, bí kò ṣe márùn-ún. Ńṣe ló dà bíi pé ọ̀kan tí wọ́n fi ṣe ènì yẹn kò níye lórí rárá. Àwọn ẹyẹ yẹn lé máà níye lórí lójú èèyàn, àmọ́ ojú wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wò wọ́n? Jésù sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn [àtèyí tí wọ́n fi ṣe ènì pàápàá] tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:6, 7) Òye ohun tí Jésù sọ lè wá bẹ̀rẹ̀ sí yé wa wàyí. Bí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo bá níye lórí tó bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, mélòómélòó wá ni ẹ̀dá ènìyàn! Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣàlàyé, Jèhófà mọ̀ wá látòkèdélẹ̀. Kódà, ó mọ iye irun tó wà lórí wa pàápàá!
6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù mọ ohun tó ń sọ nígbà tó sọ pé Ọlọ́run mọ iye irun orí wa?
6 Ó mọ iye irun orí wa kẹ̀? Àwọn kan le máa rò pé àbí Jésù ò mọ ohun tó ń sọ ni. Họ́wù, jẹ́ ká tibi ìrètí àjíǹde wò ó. Wo bí Jèhófà ṣe gbọ́dọ̀ mọ̀ wá dunjú-dunjú tó kó tó lè tún wa dá! A níye lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lójú rẹ̀ débi pé ó rántí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa, títí kan àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá wa àti gbogbo ohun tó wà nínú iyè wa àti gbogbo ìrírí wa látọjọ́ táláyé ti dáyé.a Nítorí náà, mímọ iye irun orí wa, tó jẹ́ pé ìpíndọ́gba tó wà lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000], kò lè jẹ́ nǹkan bàbàrà ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ ìyanu àjíǹde.
Kí Ni Jèhófà Rí Lára Wa?
7, 8. (a) Kí ni díẹ̀ lára ànímọ́ tí Jèhófà máa ń fẹ́ láti rí bó ṣe ń ṣàyẹ̀wò ọkàn àwọn ẹ̀dá ènìyàn? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe tí Jèhófà mọrírì?
7 Ìkejì, Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà mọrírì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Láìfọ̀rọ̀ gùn, inú rẹ̀ máa ń dùn sí àwọn ànímọ́ rere wa àti akitiyan wa. Dáfídì Ọba sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀.” (1 Kíróníkà 28:9) Bí Ọlọ́run ṣe ń ṣàyẹ̀wò ọ̀kẹ́ àìmọye ọkàn ẹ̀dá ènìyàn nínú ayé oníwà ipá, tó kún fún ìkórìíra yìí, ẹ sáà wo bí inú rẹ̀ á ti dùn tó nígbà tó bá rí ọkàn kan tó fẹ́ràn àlàáfíà, òtítọ́ àti òdodo! Bí Ọlọ́run bá wá rí ọkàn kan tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi, tó fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, tó sì fẹ́ tan irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn ńkọ́? Jèhófà sọ fún wa pé òun ń ṣàkíyèsí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ nípa òun fáwọn ẹlòmíràn. Ó tilẹ̀ ní “ìwé ìrántí kan” tó ń kọ nípa gbogbo “àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ ṣeyebíye lójú rẹ̀.
8 Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ rere tí Jèhófà mọrírì? Dájúdájú ó mọrírì ìsapá tí à ń ṣe láti fara wé Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. (1 Pétérù 2:21) Iṣẹ́ pàtàkì kan tí Ọlọ́run mọrírì ni iṣẹ́ títan ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ kálẹ̀. Róòmù 10:15 kà pé: “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!” Àwa lè má ka ẹsẹ̀ wa yìí sóhun tó “dára rèǹtè-rente.” Ṣùgbọ́n níhìn-ín, ńṣe ló dúró fún akitiyan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. Gbogbo irú akitiyan bẹ́ẹ̀ dára gan-an, ó sì ṣeyebíye lójú rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
9, 10. (a) Kí nìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé Jèhófà mọrírì ìfaradà wa lójú onírúurú ìṣòro? (b) Ojú òdì wo ni Jèhófà kì í fi í wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?
9 Jèhófà tún mọrírì ìfaradà wa pẹ̀lú. (Mátíù 24:13) Rántí o, ńṣe ni Sátánì ń fẹ́ kó o kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó o bá jẹ́ adúróṣinṣin lójú Jèhófà, ṣe lò ń jẹ́ kó túbọ̀ ṣeé ṣe láti fún Sátánì lésì gbogbo ìṣáátá rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. (Òwe 27:11) Nígbà mìíràn, ìfaradà kì í rọrùn. Àìlera, àìrówó-gbọ́-bùkátà, másùnmáwo àtàwọn òkè ìṣòro mìíràn lè mú kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan má rọgbọ rárá. Ìrẹ̀wẹ̀sì tún lè dé, bí ọ̀nà ò bá gba ibi téèyàn fojú sí. (Òwe 13:12) Ìfaradà wa lójú gbogbo irú ìṣòro wọ̀nyẹn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì Ọba fi sọ pé kí Jèhófà fi omijé òun sínú “ìgò awọ” kan, tó sì fi kún un pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?” (Sáàmù 56:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé, kò sì jẹ́ fojú kékeré wo gbogbo omijé àti ìyà tó ń jẹ wá bá a ṣe ń pa ìwà títọ́ mọ́ sí i. Gbogbo rẹ̀ ló ṣe iyebíye lójú rẹ̀ pẹ̀lú.
Jèhófà mọrírì ìfaradà wa lójú onírúurú àdánwò
10 Àmọ́ o, ọkàn tí kì í yéé dáni lẹ́bi lè má gbà pé òótọ́ ni gbogbo ẹ̀rí wọ̀nyí tó fi hàn pé a ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Irú ọkàn bẹ́ẹ̀ lè máa sọ ṣáá pé: ‘Hẹ̀, àìmọye èèyàn ni ìwà wọ́n dáa ju tèmi lọ jàre. Ọ̀ràn mi á sú Jèhófà pátápátá nígbà tó bá wo ìṣe mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ tàwọn míì!’ Jèhófà kì í ṣe irú ìfiwéra bẹ́ẹ̀; kì í sì í ṣe aláìgbatẹnirò tàbí ọ̀dájú nínú ìrònú rẹ̀. (Gálátíà 6:4) Jèhófà ń lo ìjìnlẹ̀ òye ńláǹlà nígbà tó bá ń gbé ohun tó wà lọ́kàn wa yẹ̀ wò. Ojú ribiribi ló sì fi ń wo ànímọ́ rere tó bá rí nínú wa, bó ti wù kó kéré mọ.
Jèhófà Ń Fa Iṣẹ́ Rere Ẹni Yọ Láàárín Ibi
11. Kí la lè rí kọ́ nípa Jèhófà bá a bá wo ìgbésẹ̀ tó gbé nínú ọ̀ràn Ábíjà?
11 Ìkẹta, bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ wá wò, ó ń fara balẹ̀ ṣe àṣàyàn, ó ń wá ibi tí a dáa sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà ṣòfin pé kí wọ́n run gbogbo ìlà ìdílé Jèróbóámù Ọba apẹ̀yìndà, Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìsìnkú ẹ̀yẹ fún Ábíjà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba yìí. Kí nìdí? Ó ní: “Ohun rere kan sí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni a ti rí nínú rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 14:1, 10-13) Lẹ́nu kan, Jèhófà ṣàyẹ̀wò ọkàn ọ̀dọ́kùnrin yẹn, ó sì rí “ohun rere kan” níbẹ̀. Bó ti wù kí ohun rere yẹn kéré mọ tàbí kó ṣe bín-ń-tín tó, lójú Jèhófà ó tó ohun tó yẹ ní kíkọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó tilẹ̀ san ẹ̀san ohun rere yẹn, ó ṣojú àánú ní ìwọ̀n yíyẹ sí ọ̀dọ́kùnrin yẹn tó wá láti agboolé apẹ̀yìndà.
12, 13. (a) Báwo ni ọ̀ràn Jèhóṣáfátì Ọba ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń rí iṣẹ́ rere wa kódà nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀? (b) Ní ti àwọn iṣẹ́ àti ànímọ́ rere wa, báwo ni Jèhófà ṣe dà bí Òbí tó fẹ́ràn ọmọ?
12 A tún rí àpẹẹrẹ títayọ nínú ọ̀ràn Jèhóṣáfátì Ọba rere. Nígbà tí ọba yẹn hu ìwà òmùgọ̀ kan, wòlíì Jèhófà sọ fún un pé: “Nítorí èyí, ìkannú wà sí ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” Ọ̀ràn rèé o! Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà kò parí síbẹ̀ yẹn. Ọ̀rọ̀ náà ń bá a lọ pé: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a rí àwọn ohun rere pẹ̀lú rẹ.” (2 Kíróníkà 19:1-3) Nítorí náà, ìbínú títọ́ tí Jèhófà fi hàn kò ní kí ó máà rójú rí ibi tí Jèhóṣáfátì dáa sí. Ẹ ò rí i pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà ẹ̀dá aláìpé! Nígbà tí inú bá ń bí wa sáwọn èèyàn, a lè máà rójú rí ohun rere tí wọ́n ṣe. Nígbà tí àwa alára bá sì dẹ́ṣẹ̀, ìjákulẹ̀, ìtìjú àti ẹ̀bi tó máa ń bò wá, lè máà jẹ́ ká rójú rí rere táwa alára ti ṣe. Àmọ́, rántí pé bá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì sapá láti má ṣe padà sídìí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò dárí jì wá.
13 Bí Jèhófà ṣe ń yẹ̀ ọ́ wò, ó ń fọwọ́ rọ́ irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ tì sápá kan, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń wá góòlù ṣe ń fọwọ́ rọ́ òkúta lásán tì sápá kan. Àwọn ànímọ́ àti iṣẹ́ rere rẹ ńkọ́? Hẹn-ẹn o, ìwọ̀nyẹn ni “góòlù” tó ń wá! Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí bí àwọn òbí kan tó fẹ́ràn ọmọ wọn ṣe máa ń tọ́jú àwòrán tí ọmọ wọn yà tàbí iṣẹ́ kan tó ṣe ní iléèwé, nígbà mìíràn lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́ tọ́mọ ọ̀hún lè ti gbàgbé pé òun ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀? Jèhófà ni Òbí tó fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀ jù lọ. Bá a bá sáà ti jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò lè gbàgbé àwọn isẹ́ àti ànímọ́ rere wa láé. Kódà, ìwà àìṣòdodo ló kà á sí láti gbàgbé wọn, a sì mọ̀ pé kì í ṣe aláìṣòdodo. (Hébérù 6:10) Ó tún ń yẹ̀ wá wò lọ́nà mìíràn.
14, 15. (a) Èé ṣe tí àìpé wa kò ní kí Jèhófà máà rójú rí àwọn ànímọ́ rere wa? Mú àpèjúwe wá. (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe lo àwọn ànímọ́ rere tó rí i pé a ní, ojú wo ló sì fi ń wo àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́?
14 Jèhófà máa ń wò ré kọjá àìpé wa, ó máa ń wo ohun rere tá a lè gbé ṣe. Àpèjúwe kan rèé: Àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe àtúnṣe àwọn àwòrán tàbí iṣẹ́ ọnà mìíràn tó bà jẹ́ gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin oníbọn kan ba àwòrán Leonardo da Vinci jẹ́, àwòrán tí iye owó rẹ̀ tó ọgbọ̀n mílíọ̀nù dọ́là, èyí tó wà ní Ibi Ìpàtẹ Iṣẹ́ Ọnà nílùú London, ní England, kò sẹ́ni tó dá a lábàá pé kí wọ́n lọ gbé àwòrán náà sọ nù torí pé ó ti bà jẹ́. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe àgbà iṣẹ́ ọnà yìí tí wọ́n ti yà láti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn. Èé ṣe? Nítorí pé ohun iyebíye ni lójú àwọn tó fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà. Ǹjẹ́ o ò níye lórí ju àwòrán tá a fi pẹ́ńsù yà, tá a sì kùn? Dájúdájú, o níye lórí ju irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run, láìka àkóbá tí àìpé tó o jogún ti ṣe fún ọ sí. (Sáàmù 72:12-14) Jèhófà Ọlọ́run, olóye iṣẹ́ tí í ṣe Ẹlẹ́dàá aráyé, yóò ṣe ohun tó bá yẹ láti mú gbogbo àwọn tó bá mọrírì àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé.—Ìṣe 3:21; Róòmù 8:20-22.
15 Dájúdájú, Jèhófà ń rí àwọn ànímọ́ rere tá a ní, èyí tí àwa fúnra wa lè máà rí. Bá a sì ṣe ń sìn ín, yóò mú kí àwọn ànímọ́ rere náà túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí a ó fi di ẹni pípé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ohun yòówù kí ayé Sátánì ti fojú wa rí, ó dájú pé ohun fífani lọ́kàn mọ́ra ni Jèhófà ka àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sí.—Hágáì 2:7.
Jèhófà Ń Fi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn Kedere
16. Ẹ̀rí wo ló lágbára jù lọ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ẹ̀bùn yìí wà fún àwa gan-an alára?
16 Ìkẹrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Ó dájú pé ẹbọ ìràpadà Kristi ni èsì pàtàkì tó já irọ́ Sátánì pé a ò wúlò lẹ́dàá tàbí pé a kì í ṣẹni tó ṣeé nífẹ̀ẹ́. Ká má ṣe gbàgbé láé pé ikú oró tí Jésù kú lórí igi oró àti ìrora ńláǹlà tí Jèhófà fara dà bó ṣe ń wo ikú Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa. Ó mà ṣe o, pé ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé ẹ̀bùn yìí wà fún àwọn gan-an alára. Wọ́n gbà pé irú àwọn kọ́ ló wà fún. Àmọ́, rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Síbẹ̀, ó kọ̀wé pé: ‘Ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ mi, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.’—Gálátíà 1:13; 2:20.
17. Kí ni ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fà wá sún mọ́ ara rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀?
17 Jèhófà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nípa ríràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti gbádùn àwọn àǹfààní ẹbọ Kristi. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Òdodo ọ̀rọ̀, Jèhófà ló ń fúnra rẹ̀ fà wá sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, òun ló sì fún wa ní ìrètí ìyè ayérayé. Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ni, tó ń dé ọ̀dọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àti nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tí Jèhófà fi ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye, ká sì máa fi àwọn òtítọ́ tẹ̀mí sílò láìka àwọn àléébù àti àìpé wa sí. Abájọ tí Jèhófà fi lè sọ nípa wa, bó ṣe sọ nípa Ísírẹ́lì, pé: “Ìfẹ́ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni mo fi nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ìdí nìyẹn tí mo fi fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́.”—Jeremáyà 31:3.
18, 19. (a) Kí ni ọ̀nà tó ṣe tímọ́tímọ́ jù lọ tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, kí ló sì fi hàn pé òun fúnra rẹ̀ ló ń bójú tó èyí? (b) Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe mú un dá wa lójú pé elétíi gbáròyé ni Jèhófà?
18 Ó jọ pé àǹfààní àdúrà ni ọ̀nà tó ṣe tímọ́tímọ́ jù lọ tá a gbà ń rí ẹ̀rí ìfẹ́ Jèhófà. Bíbélì rọ kálukú wa pé ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀” sí Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 5:17) Elétíi gbáròyé ni. Òun kúkú ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Kò fún ẹlòmíràn láṣẹ láti máa gbọ́ àdúrà, àní kò fún Ọmọ rẹ̀ pàápàá láṣẹ yẹn. Sáà rò ó wò ná: Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run rọ̀ wá pé ká tọ òun wá nínú àdúrà, ká wá sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn wa fóun. Irú olùgbọ́ wo sì ni? Ṣé aláìdásíni, tí kò lójú àánú, tí kò sì bìkítà ni? Rárá o.
19 Jèhófà ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Kí ni à ń pè ní ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò? Kristẹni olóòótọ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà sọ pé: “Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni mímọ ìrora rẹ nínú ọkàn mi.” Ǹjẹ́ ìrora wa tilẹ̀ kan Jèhófà rárá? Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ rèé nípa ìjìyà Ísírẹ́lì àwọn èèyàn rẹ̀, ó ní: “Nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísáyà 63:9) Kì í ṣe kìkì pé Jèhófà rí ohun tí àwọn èèyàn náà ń fojú winá rẹ̀; ó mọ̀ ọ́n lára. Bó ṣe mọ̀ ọ́n lára tó hàn nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà alára sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.”b (Sekaráyà 2:8) Ìrora ọ̀hún á mà pọ̀ o! Àní sẹ́, gbogbo bó ṣe ń ṣe wá ni Jèhófà ń mọ̀ lára. Bí nǹkan kan bá ń dùn wá, ó ń dun òun náà.
20. Èrò tí kò mọ́gbọ́n dání wo ló yẹ ká yẹra fún bí a óò bá ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tó wà ní Róòmù 12:3?
20 Kò sí Kristẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ tó máa wá tìtorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun àti pé òun níyì lójú Ọlọ́run tá á wá máa gbéra ga tàbí tá á máa ganpá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún mi, mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó bàa lè ní èrò inú yíyèkooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pín ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.” (Róòmù 12:3) Bíbélì mìíràn sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Èmi á sọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láàárín yín pé kí ó má ṣe gbé ara rẹ̀ ga ju bó ṣe mọ, ṣùgbọ́n kí ó ṣe bí ó ti mọ.” (A Translation in the Language of the People, látọwọ́ Charles B. Williams) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń gbádùn ìfẹ́ Baba wa ọ̀run tó tuni lára, ẹ jẹ́ ká ní èrò inú yíyèkooro, ká sì rántí pé fífẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ wa kì í ṣe èrè iṣẹ́ ọwọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹ̀tọ́ wa.—Lúùkù 17:10.
21. Kí làwọn irọ́ tí Sátánì ń pa tá ò gbọ́dọ̀ gbà gbọ́, òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wo ló sì yẹ ká máa fi mú ara wa lọ́kàn le?
21 Ẹ jẹ́ kí kálukú wa máa sa gbogbo ipá wa láti yàgò fún gbogbo irọ́ Sátánì, títí kan irọ́ náà pé a kò wúlò rárá tàbí pé a kì í ṣẹni tó ṣeé nífẹ̀ẹ́. Bí ohun tójú rẹ ti rí láyé bá jẹ́ kó o máa ka ara rẹ sẹ́ni tí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ Ọlọ́run kò lè kàn láé, tàbí pé gbogbo iṣẹ́ rere rẹ kò tó nǹkan kan rárá lójú Ọlọ́run arínúróde, tàbí pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ikú Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kò fi ní lè bò ó, irọ́ pátápátá ni o. Má gba irọ́ yẹn gbọ́ rárá o! Ẹ jẹ́ ká máa mú ara wa lọ́kàn le nípa rírántí òótọ́ ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 8:38, 39.
a Léraléra ni Bíbélì fi hàn pé ìrètí àjíǹde wé mọ́ agbára ìrántí Jèhófà. Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ nì, sọ fún Jèhófà pé: “Ì bá ṣe pé . . . ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!” (Jóòbù 14:13) Jésù sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí.” Èyí ṣe rẹ́gí, nítorí pé gbogbo àwọn òkú tí Jèhófà ní lọ́kàn láti jí dìde ló rántí pátá.—Jòhánù 5:28, 29.
b Báwọn kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí jẹ́ kó dà bíi pé ẹni tó bá fọwọ́ kan àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tọwọ́ bọ ara rẹ̀ lójú ni tàbí pé ó ń tọwọ́ bọ Ísírẹ́lì lójú ni, kì í ṣe pé ó ń tọwọ́ bọ Ọlọ́run lójú. Àwọn akọ̀wé kan ló túmọ̀ rẹ̀ gba ibòmíràn torí pé wọ́n ka ọ̀rọ̀ yẹn sí àrífín, wọ́n wá tìtorí ìyẹn yí i padà. Ìsapá òdì yìí kò wá jẹ́ káwọn èèyàn rí i bí ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jèhófà ní ṣe jinlẹ̀ tó.