Ẹ Fi Imuratan Bojuto Agbo Ọlọrun
“Ẹ maa tọju agbo Ọlọrun tí ń bẹ laaarin yin, ẹ maa bojuto o, kìí ṣe afipaṣe, bikoṣe tifẹtifẹ [pẹlu ìmúratán, “NW”].”—1 PETERU 5:2.
1. Eeṣe ti a fi nilati reti pe ki awọn Kristian alagba ‘fi imuratan bojuto agbo Ọlọrun’?
JEHOFA ń fi imuratan ṣoluṣọ-agutan awọn eniyan rẹ̀. (Orin Dafidi 23:1-4) “Oluṣọ-agutan rere,” naa Jesu Kristi, fi imuratan fi iwalaaye ẹda eniyan pipe rẹ̀ fun awọn eniyan ti wọn jẹ́ ẹni-bi-agutan. (Johannu 10:11-15) Fun idi yii, aposteli Peteru ṣí awọn Kristian alagba leti lati ‘fi imuratan bojuto agbo Ọlọrun.’—1 Peteru 5:2.
2. Awọn ibeere wo ni wọn yẹ fun igbeyẹwo nipa awọn igbokegbodo ṣiṣe oluṣọ-agutan ti awọn Kristian alagba?
2 Imuratan jẹ́ àmì animọ awọn iranṣẹ Ọlọrun. (Orin Dafidi 110:3) Ṣugbọn ohun ti o ju ami animọ imuratan Kristian ọkunrin kan lọ ni a beere fún iyannisipo gẹgẹ bi alaboojuto, tabi oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ kan. Ta ni o tootun lati jẹ́ iru oluṣọ-agutan bẹẹ? Ki ni ṣiṣe oluṣọ-agutan wọn ní ninu? Ọ̀nà wo ni o dara julọ lati ṣaṣepari rẹ̀?
Ṣiṣabojuto Lori Agbo-ile Kan
3. Eeṣe ti a fi lè sọ pe ọ̀nà ti Kristian ọkunrin kan ń gbà bojuto idile rẹ̀ ní ohun kan iṣe lori yala ó tootun lati jẹ́ oluṣọ-agutan ninu ijọ?
3 Ṣaaju ki a tó lè yan ọkunrin kan si “ipo alaboojuto,” oun gbọdọ doju awọn ohun ti Iwe Mimọ beerefun. (1 Timoteu 3:1-7; Titu 1:5-9) Fun ohun kan, aposteli Paulu sọ pe alaboojuto kan nilati jẹ́ “ẹni ti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mú awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu iwa àgbà gbogbo.” Idi rere wà fun eyi, nitori ti Paulu wi pe: “Ṣugbọn bi eniyan kò bá mọ bi a tii ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, oun ó ha ti ṣe lè tọju ijọ Ọlọrun?” (1 Timoteu 3:4, 5) Nigba ti ó ń yan awọn àgbà ọkunrin sipo ninu awọn ijọ ti o wà lori erekuṣu Krete, Titu ni a sọ fun lati wá ‘ẹnikan ti o jẹ́ alailẹgan, ọkọ aya kan, ti o ní awọn ọmọ ti o gbagbọ, ti a kò fi sùn fun wọbia, ti wọn kò sì jẹ́ alagidi.’ (Titu 1:6) Bẹẹni, ọ̀nà ti Kristian ọkunrin kan ń gbà bojuto idile rẹ̀ ni a gbọdọ gbeyẹwo lati pinnu yala ó tootun lati gba ẹrù-iṣẹ́ ti o tubọ wuwo ti bibojuto ijọ.
4. Ní afikun si ṣiṣe ikẹkọọ Bibeli ati gbigbadura deedee, bawo ni awọn Kristian òbí ṣe ń fi ifẹ hàn fun idile wọn?
4 Awọn ọkunrin ti wọn ń ṣe abojuto agbo-ile wọn ni ọ̀nà rere a maa ṣe ju wiwulẹ gbadura ati kikẹkọọ Bibeli pẹlu idile wọn deedee lọ. Wọn a maa muratan nigba gbogbo lati ran awọn ololufẹ wọn lọwọ. Fun awọn wọnni ti wọn di òbí, eyi bẹrẹ ni ọjọ ti a bí ọmọ kan. Awọn Kristian òbí mọ̀ pe bi awọn bá ti dìrọ̀ mọ́ ọ̀nà ìgbàṣe nnkan lọna ti Ọlọrun pẹkipẹki tó, bẹẹ ni awọn ọmọ wọn kekere yoo ti tètè mú ara wọn bá itolẹsẹẹsẹ igbokegbodo Kristian wọn mu ninu igbesi-aye ojoojumọ tó. Bi Kristian kan ti o jẹ́ baba bá ṣe ń ṣabojuto lọna daradara tó ninu awọn ipo-ayika wọnyi ni o ń fi awọn itootun rẹ̀ gẹgẹ bi alagba kan hàn.—Efesu 5:15, 16; Filippi 3:16.
5. Bawo ni Kristian kan ti o jẹ́ baba ṣe lè wo awọn ọmọ rẹ̀ dagba “ninu ibawi-ẹkọ ati ilana ero-ori ti Jehofa”?
5 Ní ṣiṣe abojuto agbo-ile rẹ̀, Kristian afẹ̀rí-ọkàn-ṣiṣẹ́ kan ti o jẹ́ baba ń kọbiara si imọran Paulu pe: “Ẹ maṣe maa mú awọn ọmọ yin binu, ṣugbọn ẹ maa bá a lọ ní títọ́ wọn dagba ninu ibawi-ẹkọ ati ilana ero-ori ti Jehofa.” (Efesu 6:4, NW) Ikẹkọọ Bibeli deedee pẹlu idile, pẹlu aya ati awọn ọmọ, pese awọn anfaani rere fun itọni onifẹẹ. Awọn ọmọ tipa bayii gba “ibawi-ẹkọ,” tabi itọni alátùn-ún-ṣe. “Ilana ero-ori” ti o wáyé nigba naa ń ran ọmọ kọọkan lọwọ lati wá mọ oju-iwoye Jehofa lori awọn ọ̀ràn. (Deuteronomi 4:9; 6:6, 7; Owe 3:11; 22:6) Ninu ipo ayika ti ó tunilara gbẹ̀dẹ̀gbẹdẹ ti ìwàpapọ̀ tẹmi yii, baba ti o bikita ń fetisilẹ tiṣọratiṣọra bi awọn ọmọ rẹ̀ ti ń sọrọ. Awọn ibeere atọnisọna ni a lò lati fi aṣeyọri fa awọn ọ̀rọ̀ alailabosi jade ninu wọn nipa aniyan ati iṣarasihuwa wọn. Baba naa kìí tànmọ́-ọ̀n pe oun mọ gbogbo ohun ti ń lọ ninu ero-inu wọn ti kò tíì gbọ́. Nitootọ, “ẹni ti ó bá dahun ọ̀rọ̀ ki o tó gbọ́, were ati itiju ni fun un,” ni Owe 18:13 sọ. Lonii, ọpọ julọ awọn òbí rí i pe awọn ipo ti awọn ọmọ wọn ń dojukọ yatọ gidigidi si iwọnni ti awọn funraawọn niriiri rẹ̀ nigba ti wọn jẹ́ ọ̀dọ́. Nitori idi eyi, baba kan yoo sakun lati mọ ipo ayika ati awọn kulẹkulẹ iṣoro kan ṣaaju ki o tó sọ bi a ṣe nilati bojuto o.—Fiwe Jakọbu 1:19.
6. Eeṣe ti Kristian kan ti o jẹ́ baba fi nilati wo inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nigba ti o bá ń ran idile rẹ̀ lọwọ?
6 Ki ni ń ṣẹlẹ lẹhin ti a bá ti mọ awọn iṣoro, aniyan, ati iṣarasihuwa awọn ọmọ ẹni? Baba ti ń ṣe abojuto ni ọ̀nà rere a maa fọranlọ Iwe Mimọ, eyi ti o “ni èrè fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni, fun ikọni ti o wà ninu òdodo.” Ó ń kọ́ awọn ọmọ rẹ̀ ni bi a tii fi awọn ilana Bibeli ti a mísí silo. Ní ọ̀nà yii, awọn wọnni ti wọn jẹ́ ọ̀dọ́ ni ọjọ ori ń di awọn ti o “pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timoteu 3:16, 17; Orin Dafidi 78:1-4.
7. Apẹẹrẹ wo ni awọn Kristian ti wọn jẹ́ baba nilati fi lelẹ nipa adura?
7 Awọn èwe oniwa-bi-Ọlọrun ń dojukọ awọn ipo lilekoko ni isopọ pẹlu awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ wọn. Nitori naa bawo ni awọn Kristian ti wọn jẹ baba ṣe lè pẹ̀tù si ibẹru wọn? Ọ̀nà kan ni nipa gbigbadura deedee pẹlu wọn ati fun wọn. Nigba ti awọn ọ̀dọ́ eniyan wọnyi bá dojukọ awọn ipo ti ń danniwo, ó ṣeeṣe pe wọn yoo ṣafarawe igbarale Ọlọrun ti awọn òbí wọn. Ọdọmọbinrin ẹni ọdun 13 kan, ti a fi ọ̀rọ̀ wá lẹnuwo ṣaaju ki a tó ṣe iribọmi fun un ni iṣapẹẹrẹ iyasimimọ rẹ̀ si Ọlọrun, sọ pe oun ti niriiri ifiniṣẹlẹya ati èébú lati ọ̀dọ̀ awọn ọmọ ile-ẹkọ ẹlẹgbẹ oun. Nigba ti ó gbèjà igbagbọ rẹ̀ ninu ijẹmimọ ẹ̀jẹ̀ ti a gbekari Bibeli, awọn ọdọmọbinrin yooku lù ú wọn sì tutọ́ sí i lara. (Iṣe 15:28, 29) Ó ha gbẹsan bi? Bẹẹkọ. “Mo ń baa lọ lati gbadura si Jehofa lati ràn mi lọwọ lati wà ni iparọrọ,” ni ó ṣalaye. “Mo tun ranti ohun ti awọn òbí mi ti kọ́ mi ninu ikẹkọọ idile wa nipa aini naa lati ká araawa lọ́wọ́kò labẹ ibi.”—2 Timoteu 2:24.
8. Bawo ni alagba kan ti kò ni awọn ọmọ ṣe lè ṣe abojuto lori agbo-ile rẹ̀ ni ọ̀nà rere?
8 Alagba kan ti kò ni awọn ọmọ tun lè ṣe ipese ohun tẹmi ati ti ara ti ó tó fun awọn wọnni ti wọn wà ninu agbo-ile rẹ̀. Eyi ní ninu olubaṣegbeyawo rẹ̀ ati boya awọn Kristian ibatan ti wọn gbarale e ti wọn ń gbé ninu ile rẹ̀. (1 Timoteu 5:8) Ṣiṣabojuto bayii ni ọ̀nà rere jẹ́ ọ̀kan lara awọn ohun ti a beere fun ti ọkunrin kan ti a yàn sipo lati gbé ẹrù-iṣẹ́ gẹgẹ bi alagba ijọ gbọdọ doju ìlà rẹ̀. Bawo, nigba naa, ni awọn àgbà ọkunrin ti a yàn sipo ṣe nilati wo anfaani ẹrù-iṣẹ́ wọn ninu ijọ?
Ṣe Abojuto “ni Oju Mejeeji”
9. Iṣarasihuwa wo ni awọn Kristian alagba nilati ní siha iṣẹ-isin ayanfunni wọn?
9 Ní ọrundun kìn-ín-ní ti Sanmanni Tiwa, aposteli Paulu ṣiṣẹsin gẹgẹ bi iriju ninu agbo-ile Ọlọrun, ijọ Kristian ti o wà labẹ ipo-ori Kristi. (Efesu 3:2, 7; 4:15) Ní ipa tirẹ̀, Paulu rọ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni Romu pe: “Bi awa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbun gbà gẹgẹ bi oore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a maa sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọ̀n igbagbọ; tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹni ti ń kọni, ki o kọjusi kíkọ́; tabi ẹni ti o ń gbani niyanju, si igbiyanju: ẹni ti o ń fi funni ki o maa fi inu kan ṣe é; ẹni ti ń ṣe [abojuto, NW], ki o maa ṣe é ni oju mejeeji; ẹni ti ń ṣaanu, ki o maa fi inu didun ṣe é.”—Romu 12:6-8.
10. Ní bibojuto agbo Ọlọrun, apẹẹrẹ wo ni Paulu fi lelẹ fun awọn alagba lonii?
10 Paulu rán awọn ará Tessalonika leti pe: “Awa . . . ń bá olukuluku yin lò gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ń gbà yin niyanju, a ń tù yin ninu, a sì kọ́, ki ẹyin ki o lè maa rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹni ti o ń pè yin sinu ijọba ati ògo Oun tikaraarẹ.” (1 Tessalonika 1:1; 2:11, 12) Iṣiti naa ni a ti fi funni ni iru ọ̀nà onijẹlẹnkẹ, onifẹẹ kan debi pe Paulu lè kọwe pe: “Awa ń ṣe pẹlẹ lọdọ yin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ń tọju awọn ọmọ oun tikaraarẹ: bẹẹ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si yin, inu wa dùn jọjọ lati fun yin kìí ṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmi awa tikaraawa pẹlu, nitori ti ẹyin jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fun wa.” (1 Tessalonika 2:7, 8) Ní ibamu pẹlu apẹẹrẹ bii ti baba ti Paulu, awọn àgbà ọkunrin aduroṣinṣin ní idaniyan jijinlẹ fun gbogbo awọn ti ń bẹ ninu ijọ.
11. Bawo ni awọn alagba ti a yàn sipo ṣe lè fi ìháragàgà hàn?
11 Iwa jẹlẹnkẹ, papọ pẹlu ìháragàgà, gbọdọ jẹ́ animọ iṣabojuto onifẹẹ tí awọn Kristian oluṣọ-agutan wa ń lò. Ihuwasi wọn ń gbé ohun pupọ jade. Peteru gba awọn alagba nimọran lati bojuto agbo Ọlọrun “kìí ṣe àfipáṣe” tabi fun “ọrọ èrè ijẹkujẹ.” (1 Peteru 5:2) Lori koko yii, ọmọwe William Barclay sọ akiyesi onikilọ kan jade, ni kikọwe pe: “Ọ̀nà titẹwọgba ipo àṣẹ kan ati ti ṣiṣe iṣẹ-isin gẹgẹ bii pe ó jẹ́ iṣẹ kan ti ń súni ti kò sì gbadunmọni, bi ẹni pe o jẹ́ àárẹ̀, bi ẹni pe ẹrù-ìnira kan ti a nilati kọ̀ ni wà. Ó ṣeeṣe daadaa ki a sọ fun ọkunrin kan lati ṣe ohun kan, ati fun un lati ṣe é, ṣugbọn lati ṣe é ni iru ọ̀nà kan ti kò sunwọn debi pe gbogbo igbesẹ naa ni a bajẹ. . . . Ṣugbọn [Peteru] sọ pe olukuluku Kristian nilati ni ìháragàgà onirusoke lati ṣe iru iṣẹ-isin bẹẹ gẹgẹ bi o bá ti lè ṣe tó, bi o tilẹ jẹ pe ó mọ̀ bi oun ti jẹ́ alaiyẹ lati ṣe é lẹkun-unrẹrẹ tó.”
Awọn Oluṣọ-Agutan Onimuuratan
12. Bawo ni awọn Kristian alagba ṣe lè fi imuratan hàn?
12 “Ẹ maa tọju agbo Ọlọrun ti ń bẹ laaarin yin . . . tifẹtifẹ [“pẹlu imuratan,” NW],” ni Peteru tun rọni. Kristian alaboojuto kan ti ń bojuto awọn agutan ń ṣe bẹẹ pẹlu imuratan, lati inu ominira ifẹ-inu tirẹ̀ funraarẹ, labẹ idari Oluṣọ-agutan Rere naa, Jesu Kristi. Ṣiṣiṣẹsin pẹlu imuratan tun tumọsi pe Kristian oluṣọ-agutan kan ń tẹriba fun àṣẹ Jehofa, ‘oluṣọ-agutan ati alaboojuto ọkàn wa.’ (1 Peteru 2:25) Kristian oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ kan a maa fi imuratan fi ọ̀wọ̀ hàn fun iṣeto iṣakoso Ọlọrun. Oun ń ṣe bẹẹ nigba ti o bá ń dari awọn wọnni ti ń wá amọran lati inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Bi o tilẹ jẹ pe iriri yoo ran alagba kan lọwọ lati ṣe ikojọ imọran ti a gbekari Bibeli, eyi kò tumọsi pe oun yoo ní ojutuu ti a gbekari Iwe Mimọ si gbogbo iṣoro níkàáwọ́ rẹ̀. Àní nigba ti oun bá mọ idahun si ibeere kan paapaa, ó lè rí i pe ó bá ọgbọn mu lati wo inu Watch Tower Publications Index tabi iru awọn atọka miiran bẹẹ pẹlu ẹni ti o beere ọ̀rọ̀ naa. Oun nipa bayii ń kọni ni ọ̀nà meji: O ṣaṣefihan bi a ṣe lè rí isọfunni oniranlọwọ ó sì fi tirẹlẹtirẹlẹ fi ọ̀wọ̀ hàn fun Jehofa nipa didari afiyesi si ohun ti eto-ajọ Ọlọrun ti tẹjade.
13. Igbesẹ wo ni a lè gbé lati ran awọn alagba lọwọ lati funni ni amọran yiyekooro, ki wọn si tipa bẹẹ yẹra fun iṣoro wo?
13 Ki ni alagba kan lè ṣe bi a kò bá tii tẹ ohunkohun jade ninu iwe ikẹkọọ Society lori iṣoro pàtó ti o wà lọwọ naa? Kò sí iyemeji, oun yoo gbadura fun ijinlẹ-oye yoo sì wá awọn ilana Bibeli ti o tanmọ́ ọ̀ràn naa ri. Ó tun lè rí i pe o ṣanfaani lati damọran pe ki ẹni ti ń wá iranlọwọ naa gbé apẹẹrẹ Jesu yẹwo. Alagba naa lè beere pe: “Bi Jesu, Olukọ Nla naa, bá wà ninu ipo rẹ, ki ni iwọ rò pe oun yoo ṣe?” (1 Korinti 2:16) Iru ironu bẹẹ lè ran oluṣewadii kan lọwọ lati ṣe ipinnu ọlọgbọn. Ṣugbọn yoo ti jẹ́ ohun ti kò bọgbọnmu tó fun alagba kan lati pese èrò ara-ẹni lasan kan gẹgẹ bi ẹni pe ó jẹ́ amọran yiyekooro ti o bá Iwe Mimọ mu! Kaka bẹẹ, awọn alagba lè jiroro awọn iṣoro lilekoko pẹlu araawọn ẹnikinni keji. Wọn tilẹ lè fi awọn ọ̀ràn pataki lélẹ̀ fun ijiroro ni ipade ẹgbẹ́ awọn alagba. (Owe 11:14) Awọn ipinnu ti ń ti ibẹ̀ jade yoo mú ki o ṣeeṣe fun gbogbo wọn lati sọrọ ohun kan-naa.—1 Korinti 1:10.
Iwatutu Ṣekoko
14, 15. Ki ni a beere lọwọ awọn alagba nigba ti wọn bá ń tún Kristian kan ti o ti ‘ṣi ẹsẹ gbé ṣaaju ki o tó mọ̀ nipa rẹ̀’ ṣe bọ̀ sípò?
14 Kristian alagba kan nilati fi iwatutu hàn nigba ti o bá ń kọ́ awọn ẹlomiran, ni pataki nigba ti ó bá ń gbà wọn nimọran. “Ará,” ni Paulu gbaninimọran, “bi a tilẹ mu eniyan ninu iṣubu kan [ki o tó mọ̀ nipa rẹ̀, NW], ki ẹyin tii ṣe ti Ẹmi ki o mú iru ẹni bẹẹ bọ̀ sípò ni ẹmi iwatutu.” (Galatia 6:1) Lọna ti o fanilọkan mọra, ọ̀rọ̀ Griki ti a tumọ níhìn-ín si “bọ̀ sípò” tan mọ́ èdè-ìsọ̀rọ̀ iṣẹ́-abẹ ti a lò lati ṣapejuwe títo egungun kan ki a baa lè ṣediwọ fun dídi abirun titi ọjọ́ ayé. Atumọ-ede W. E. Vine so eyi pọ̀ mọ́ imupadabọsipo “ẹnikan ti a lébá ninu aṣiṣe, nipasẹ awọn wọnni ti wọn jẹ́ tẹmi, iru ẹni bẹẹ dabi ẹ̀yà ara tẹmi kan ti a mú yẹ̀ kuro lórí oríkèé.” Awọn itumọ afidipo ni, “lati mupada si ipo yíyẹ; lati mú wá soju ìlà yíyẹ.”
15 Ìtúnṣebọ̀sípò ironu ẹni kò rọrun, ó sì lè lekoko gan-an lati mú awọn ironu ẹnikan ti o dẹṣẹ wá si oju ìlà yiyẹ. Ṣugbọn iranlọwọ ti a pese ninu ẹmi iwatutu ni o ṣeeṣe ki a gbà pẹlu imoore. Nitori idi eyi, awọn Kristian alagba nilati kọbiara si imọran Paulu pe: “Ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, iṣeun, irẹlẹ, [iwatutu, NW], ipamọra.” (Kolosse 3:12) Ki ni awọn alagba nilati ṣe nigba ti ẹnikan ti o nilo ìtúnṣebọ̀sípò bá ní iṣarasihuwa buburu? Wọn nilati “maa lepa . . . iwatutu.”—1 Timoteu 6:11.
Ṣiṣe Oluṣọ-Agutan Pẹlu Iṣọra
16, 17. Ewu wo ni awọn alagba nilati ṣọra fun nigba ti wọn bá ń fun awọn ẹlomiran ni imọran?
16 Pupọ sii wà fun imọran Paulu ni Galatia 6:1. Ó rọ awọn ọkunrin titootun nipa tẹmi pe: “Mú [ẹnikan ti o ti dẹṣẹ] bọ̀ sípò ni ẹmi iwatutu; ki iwọ tikaraarẹ maa kiyesara, ki a má baa dán iwọ naa wò pẹlu.” Ẹ wo iru abajade wiwuwo ti o lè tidii rẹ̀ yọ bi a kò bá kọbiara si iru imọran bẹẹ! Bi irohin nipa alufaa-ṣọọṣi Anglican kan ti a rí ti o jẹbi didẹṣẹ panṣaga pẹlu meji ninu awọn ara ṣọọṣi ti sún un, iwe-irohin The Times ti ilu London sọ pe eyi jẹ́ “ipo ọ̀ràn kan ti ń waye nigba gbogbo: ọkunrin agbaninimọran kan, ti ó ṣe kedere pe o dabii baba tabi arakunrin kan ti ń ṣubu sinu awọn idẹwo ẹṣẹ nitori pe a gbẹkẹle e.” Akọrohin inu abala iwe-irohin naa wá tọka si ijẹwọ Dokita Peter Rutter pe “awọn alaamọri ìkóninífà laaarin alaisan ati awọn ọkunrin olugbaninimọran ti wọn finútán—awọn dokita, adajọ, alufaa ati olugbanisiṣẹ—ti di ajakalẹ-arun ti a mọ̀ dunju, ti ń banijẹ ti o sì ń tiniloju, ninu awujọ wa ti iwa ibalopọ takọtabo ti jẹ́ fàlàlà.”
17 A kò nilati ronu pe awọn eniyan Jehofa ní àjẹsára fun iru awọn idẹwo bẹẹ. Alagba kan ti a bọwọ fun ti o ti fi iṣotitọ ṣiṣẹsin fun ọpọ ọdun di ẹni ti o kowọnu iwapalapala nitori pe o ṣe ikesini oluṣọ-agutan sọdọ arabinrin kan ti o ti ṣegbeyawo nigba ti arabinrin naa wà ni oun nikan. Bi o tilẹ jẹ pe ó ronupiwada, arakunrin naa padanu gbogbo anfaani iṣẹ-isin rẹ̀. (1 Korinti 10:12) Bawo, nigba naa, ni awọn àgbà ọkunrin ti a yàn sipo ṣe lè ṣe ibẹwo oluṣọ-agutan ni iru ọ̀nà kan ti wọn kò fi ni ṣubu sinu idẹwo? Bawo ni wọn ṣe lè ṣeto fun ìwọ̀n idanikanwa, fun adura, ati fun anfaani lati wá inu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati awọn itẹjade Kristian?
18. (a) Bawo ni fifi ilana ipo-ori silo ṣe lè ran awọn alagba lọwọ lati yẹra fun awọn ipo ti o lè tẹ́nilógo? (b) Awọn eto wo ni a lè ṣe fun ṣiṣe ikesini oluṣọ-agutan sọdọ arabinrin kan?
18 Koko-abajọ kan ti awọn alagba nilati kiyesi ni ilana ipo-ori. (1 Korinti 11:3) Bi ọ̀dọ́ kan bá ń wá itọsọna, sakun lati mú awọn òbí rẹ̀ wọnu ijiroro naa nigba ti o bá yẹ. Nigba ti arabinrin kan ti o ti ṣegbeyawo bá beere fun iranlọwọ tẹmi, iwọ ha lè ṣeto fun ọkọ rẹ̀ lati wà nibẹ nigba ibẹwo naa bi? Ki ni bi eyi kò bá ṣeeṣe tabi bi oun bá jẹ́ alaigbagbọ ti ó ti ń lo obinrin naa nilokulo lọna kan ṣáá? Nigba naa ṣe iru iṣeto kan-naa ti iwọ yoo ṣe nigba ti o bá ń ṣe ikesini oluṣọ-agutan sọdọ arabinrin kan ti kò tii gbeyawo. Yoo bá ọgbọn mu fun awọn arakunrin meji ti wọn tootun nipa tẹmi lati bẹ arabinrin naa wò papọ. Bi eyi kò bá bojumu, boya akoko yiyẹ kan ni a lè yàn fun awọn arakunrin meji lati ní ijiroro pẹlu rẹ̀ ni Gbọngan Ijọba, ó sàn jù ki o jẹ́ ninu yàrá kan ti o faaye silẹ fun ìdákọ́ńkọ́. Pẹlu awọn arakunrin ati arabinrin miiran nibẹ ninu gbọngan, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò si ni ipo lati rí ki wọn sì fetíkọ́ ijiroro naa, okunfa eyikeyii fun ikọsẹ ni ó ṣeeṣe ki a yẹra fun.—Filippi 1:9, 10.
19. Fifi imuratan bojuto awọn agutan Ọlọrun ń mú awọn iyọrisi rere wo wá, ta ni a sì fi imoore hàn si fun awọn oluṣọ-agutan onímùúratan?
19 Bibojuto awọn agutan Ọlọrun pẹlu imuratan ń mú iyọrisi rere wá—agbo ti o lagbara nipa tẹmi, ti a dari lọna didara. Bi aposteli Paulu, awọn Kristian alagba ode-oni ní idaniyan ńláǹlà fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn. (2 Korinti 11:28) Eyi ti o tun wuwo ni pataki ni ẹrù-iṣẹ́ ti bibojuto awọn eniyan Ọlọrun ni awọn akoko lilekoko wọnyi. Nitori naa, a kun fun imoore nitootọ fun iṣẹ rere ti awọn arakunrin wa ti wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba ń ṣe. (1 Timoteu 5:17) Fun bibukun wa pẹlu “ẹbun ninu awọn ọkunrin” ti wọn ń fi imuratan ṣabojuto, a fi iyin fun Olufunni ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pípé,” Oluṣọ-Agutan wa onifẹẹ ti ọrun, Jehofa.—Efesu 4:8, NW; Jakọbu 1:17.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni ọkunrin kan ṣe lè ṣe abojuto agbo-ile rẹ̀ ni ọ̀nà rere?
◻ Awọn animọ wo ni o nilati sami si iṣabojuto nipasẹ awọn Kristian alagba?
◻ Bawo ni awọn alagba ṣe lè fi irẹlẹ ati iwatutu hàn ninu fifunni ni imọran?
◻ Ki ni o ń ṣeranwọ lati mú kí ìtúnṣebọ̀sípò tẹmi gbeṣẹ?
◻ Bawo ni awọn alagba ṣe lè yẹra fun awọn ipo ti ń tẹ́nilógo nigba ti wọn bá ń bojuto agbo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kristian alagba kan gbọdọ ṣe abojuto lori agbo-ile rẹ̀ ni ọ̀nà rere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ṣiṣe oluṣọ-agutan Kristian ni a nilati ṣe pẹlu iwatutu ati idajọ rere