‘Ẹ Jẹ́ Kí Iná Ẹ̀mí Máa Jó Nínú Yín’
“Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.”—RÓÒMÙ 12:11.
1. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa ń fi ẹran àtàwọn nǹkan míì rúbọ?
JÈHÓFÀ máa ń mọrírì ìrúbọ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń ṣe tinútinú láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé àwọn fara mọ́ ohun tó fẹ́. Nígbà àtijọ́, ó máa ń gba onírúurú ọrẹ ẹbọ tí wọ́n fi ẹran ṣe àtàwọn ọrẹ míì. Bí Òfin Mósè ṣe lànà àwọn ọrẹ náà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe máa ń ṣètò wọn, láti lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà àti láti lè fi dúpẹ́ oore. Jèhófà kò ní káwọn Kristẹni máa rú irú àwọn ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran àtàwọn ohun míì rú yẹn. Àmọ́ ní orí kejìlá lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó fi hàn pé Ọlọ́run ṣì ń retí pé ká máa rú àwọn ẹbọ kan. Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe máa ń ṣe é.
Ẹbọ Ààyè
2. Irú ìgbé ayé wo ló yẹ kí àwa Kristẹni máa gbé, báwo nìyẹn sì ṣe lè ṣeé ṣe?
2 Ka Róòmù 12:1, 2. Lápá ìbẹ̀rẹ̀ lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sáwọn ará Róòmù yìí, Pọ́ọ̀lù ti fi hàn kedere pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni a fi polongo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní olódodo níwájú Ọlọ́run, kì í ṣe nípa iṣẹ́, yálà wọ́n jẹ́ Júù tàbí Kèfèrí tó di Kristẹni. (Róòmù 1:16; 3:20-24) Nínú orí kejìlá, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ó yẹ káwa Kristẹni máa fi ẹ̀mí ìmoore hàn nípa gbígbé ìgbé ayé onífara-ẹni-rúbọ. Kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe, a ní láti yí èrò inú wa pa dà. Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ti sọ wá dẹni tó wà lábẹ́ “òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.” (Róòmù 8:2) Torí náà, a ní láti para dà, ká “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú [wa] ṣiṣẹ́.” Ìyẹn ni pé ká yí ọkàn wa pa dà pátápátá, kó má ṣe máa fà sí ohun tí kò dára. (Éfé. 4:23) Nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ nìkan la fi lè ṣe irú ìyípadà pátápátá bẹ́ẹ̀. Ó tún gba pé káwa náà sapá gidigidi, ká sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” wa. Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i dájú pé a kò bá wọn ‘dáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí’ tòun ti ìwà pálapàla rẹ̀ àti eré ìnàjú tó kún fún ẹ̀gbin, pẹ̀lú ìrònú rẹ̀ tó dorí kodò.—Éfé. 2:1-3.
3. Kí nìdí tá a fi ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni?
3 Pọ́ọ̀lù tún rọ̀ wá pé ká lo “agbára ìmọnúúrò” wa láti lè ní ìdánilójú ohun tó jẹ́ “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Kí nìdí tá a fi ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá à ń gbàdúrà, tá à ń lọ sípàdé tá à sì ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? Ṣé torí pé àwọn alàgbà ń rọ̀ wá pé ká máa ṣe àwọn nǹkan yẹn ni? Lóòótọ́, a mọrírì báwọn alàgbà ṣe máa ń rán wa létí o. Àmọ́, torí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń sún wa láti fi hàn pé a ní ìfẹ́ Jèhófà látọkànwá ló jẹ́ ká máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti dá wa lójú pé ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan yẹn. (Sek. 4:6; Éfé. 5:10) Inú wa máa ń dùn gan-an, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ torí a mọ̀ pé bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa bíi Kristẹni tòótọ́, a lè dẹni tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Àwọn Ẹ̀bùn Tó Yàtọ̀ Síra
4, 5. Báwo ló ṣe yẹ káwọn alàgbà máa lo ẹ̀bùn wọn?
4 Ka Róòmù 12:6-8, 11. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a “ní àwọn ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún wa.” Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀bùn tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa wọn kan àwọn alàgbà ní pàtàkì jù lọ, torí pé àwọn ló gbà níyànjú láti fi “ẹ̀mí ìfitaratara-ṣe-nǹkan” ṣe iṣẹ́ àbójútó. Lára irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀bùn ìgbani-níyànjú àti ṣíṣe àbójútó.
5 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ẹ̀mí ìfitaratara ṣe nǹkan yìí tún gbọ́dọ̀ hàn lára àwọn alábòójútó bí wọ́n ṣe ń kọ́ni àti bí wọ́n ṣe ń ṣe “iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá dé ibẹ̀ yẹn fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “iṣẹ́ òjíṣẹ́” tá à ń ṣe nínú ìjọ tó jẹ́ “ara kan” ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. (Róòmù 12:4, 5) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí jọ èyí tí Ìṣe 6:4 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, níbi táwọn àpọ́sítélì ti sọ pé: “Ṣùgbọ́n àwa yóò fi ara wa fún àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” Àwọn nǹkan wo ló wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí? Àwọn alàgbà ní láti lo ẹ̀bùn wọn láti pèsè ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà fún ìjọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó ń jẹ́ kí wọ́n lè ṣe èyí ni pé wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ tàdúràtàdúrà, wọ́n ń ṣèwádìí, wọ́n ń kọ́ni wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Nípa ṣíṣe gbogbo èyí àwọn alàgbà ń fi hàn pé àwọn “wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí.” Àwọn alábòójútó ní láti máa fi ẹ̀bùn wọn bójú tó àwọn àgùntàn tọkàntọkàn, kí wọ́n sì “máa fi ọ̀yàyà ṣe é.”—Róòmù 12:7, 8; 1 Pét. 5:1-3.
6. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 12:11 tó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà?
6 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.” Tá a bá rí i pé a ti fẹ́ dẹni tó ń dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó lè jẹ́ pé a ní láti yí ọ̀nà tá a gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ pa dà ká sì jẹ́ kí àdúrà wa túbọ̀ máa ṣe lemọ́lemọ́ látọkàn wá. Ká máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀ tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí ohun tó lè fẹ́ sọ wá di kò-gbóná–kò-tutù, ẹ̀mí rẹ̀ yìí yóò sì sọ okun wa dọ̀tun. (Lúùkù 11:9, 13; Ìṣí. 2:4; 3:14, 15, 19) Ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lókun láti sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:4, 11) Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ lè mú káwa náà jẹ́ onítara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí ‘iná ẹ̀mí sì máa jó nínú wa.’
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ àti Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa?
7 Ka Róòmù 12:3, 16. Ọlá “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Jèhófà la fi ní àwọn ẹ̀bùn tá a ní. Pọ́ọ̀lù sọ níbòmíràn pé: “Títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 3:5) Torí náà, kò yẹ ká máa fẹ́ láti gba ògo. Ó yẹ kí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mú ká gbà pé ìbùkún Ọlọ́run ló ń múni ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn, kì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Lórí kókó yìí, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” Lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ẹni àpọ́nlé, ká sì máa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ tá a bá jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà, tá a mọ ìbi tágbára wa mọ, kò ní jẹ́ ká di ẹni tó jẹ́ pé tiẹ̀ nìkan ló máa ń yé e. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fẹ́ ‘ronú kí á bàa lè ní èrò inú yíyèkooro.’
8. Kí ló máa mú ká yẹra fún jíjẹ́ “olóye ní ojú ara [wa]”?
8 Ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ tá a bá lọ ń fọ́nnu nítorí àṣeyọrí tá a ṣe. Ìdí ni pé Ọlọ́run ló ń mú kí ohun tá a bá fúnrúgbìn dàgbà. (1 Kọ́r. 3:7) Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run ti pín “ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún” olúkúlùkù wa nínú ìjọ. Dípò tí a ó fi máa ka ara wa sẹ́ni tó ṣe pàtàkì ju àwọn míì lọ, ó yẹ ká mọ̀ pé àwọn míì náà ń ṣe àṣeyọrí débi tí ìwọ̀n ìgbàgbọ́ wọn gbé e dé. Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i pé: “Irú èrò inú kan náà tí ẹ ní sí ara yín ni kí ẹ ní sí àwọn ẹlòmíràn.” Nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà míì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ, ó rọ̀ wá pé kí á má máa ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí á máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Fílí. 2:3) Ojúlówó ìrẹ̀lẹ̀ àti ìsapá gidi ló máa jẹ́ ká rí i pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin àti arábìnrin lọ́lá jù wa lọ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká “jẹ́ olóye ní ojú ara [wa].” Àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn táwọn kan ní lè jẹ́ kí wọ́n gbajúmọ̀, àmọ́ gbogbo wa la máa rí ayọ̀ ńlá tá a bá ń ṣe “àwọn ohun rírẹlẹ̀,” ìyẹn àwọn iṣẹ́ táwọn èèyàn kì í sábà kíyè sí.—1 Pét. 5:5.
Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Àwa Kristẹni
9. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fàwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí bí wé àwọn ẹ̀yà tó wà nínú ara kan?
9 Ka Róòmù 12:4, 5, 9, 10. Pọ́ọ̀lù fi àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé àwọn ẹ̀yà tó wà nínú ara kan, ó ní wọ́n ń sìn níṣọ̀kan lábẹ́ Kristi tó jẹ́ Orí wọn. (Kól. 1:18) Ó rán àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí bí yìí létí pé oríṣiríṣi ẹ̀yà ló wà nínú ara, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé bákan náà “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [àwọn ẹni àmì òróró náà] pọ̀, [wọ́n] jẹ́ ara kan ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.” Lọ́nà kan náà, ó gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Éfésù níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.”—Éfé. 4:15, 16.
10. Àṣẹ ta ni “àwọn àgùntàn mìíràn” ń tẹrí ba fún?
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn àgùntàn mìíràn” kò sí lára àwọn ẹni àmì òróró tó para pọ̀ jẹ́ ara Kristi, àwọn náà lè kọ́ ohun tó pọ̀ látinú àpèjúwe yìí. (Jòh. 10:16) Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ [Kristi], ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.” (Éfé. 1:22) Lóde òní, àwọn àgùntàn mìíràn wà lára “ohun gbogbo” tí Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ ṣe orí fún. Wọ́n tún wà lára “àwọn nǹkan ìní” tí Kristi fi síkàáwọ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” rẹ̀. (Mát. 24:45-47) Torí náà, ó yẹ káwọn tó nírètí láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé mọ̀ pé Kristi ni Orí àwọn, kí wọ́n sì máa tẹrí ba fún àṣẹ ẹrú olóòótọ́ àti olóye àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀ àtàwọn ọkùnrin tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ. (Héb. 13:7, 17) Èyí ń fi kún ìṣọ̀kan àwa Kristẹni.
11. Kí ló ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa, ìmọ̀ràn míì wo ni Pọ́ọ̀lù sì fún wa?
11 Ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ló ń jẹ́ ká ní irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:14) Pọ́ọ̀lù gbé kókó yìí jáde nínú Róòmù orí 12, ó ní ìfẹ́ wa gbọ́dọ̀ wà “láìsí àgàbàgebè” àti pé “nínú ìfẹ́ ará” a gbọ́dọ̀ ní “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì.” Èyí máa ń jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fún ara wa. Ó tún sọ pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” Àmọ́ ṣá o, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ru bò wá lójú débi tá ò fi ní mọ ohun tó tọ́. A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fúnni nímọ̀ràn nípa ìfẹ́, ó ní: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.”
Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ipa Ọ̀nà Aájò Àlejò
12. Tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ ọ̀làwọ́, kí la lè rí kọ́ látara àwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà ayé ọjọ́un?
12 Ka Róòmù 12:13. Ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa yóò sún wa láti “máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn” àti ní ìbámu pẹ̀lú ohun tágbára wa gbé. Kódà, ká jẹ́ aláìní, a ṣì lè fún àwọn míì nínú ohun tá a ní. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Makedóníà, ó ní: “Nígbà ìdánwò ńlá lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́, ọ̀pọ̀ yanturu ìdùnnú wọn àti ipò òṣì paraku wọn mú kí ọrọ̀ ìwà ọ̀làwọ́ wọn pọ̀ gidigidi. Nítorí ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn gan-an, bẹ́ẹ̀ ni, mo jẹ́rìí pé, èyí ré kọjá agbára wọn gan-an, nígbà tí àwọn, láti inú ìdánúṣe àwọn fúnra wọn, ń bẹ̀ wá ṣáá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpàrọwà fún àǹfààní ìfúnni onínúrere àti fún ìpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ti yán tẹ́lẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́ [tó wà ní Jùdíà].” (2 Kọ́r. 8:2-4) Bó tílẹ̀ jẹ́ pé aláìní làwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà yìí, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́. Wọ́n kà á sí àǹfààní láti fún àwọn ará wọn tó di aláìní ní Jùdíà lóhun tí wọ́n ní.
13. Kí ló túmọ̀ sí láti “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò”?
13 Gbólóhùn ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà tá a tú sí “ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò” túmọ̀ sí pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa lo ìdánúṣe, ká máa wá ọ̀nà láti ṣe é. Bí gbólóhùn náà ṣe kà nínú Bibeli Yoruba Atọ́ka ni pé: “ẹ fi ara yin fun alejò ṣiṣe.” Nígbà míì, a lè fi hàn pé a lẹ́mìí aájò àlejò tá a bá pe ẹnì kan pé kó wá bá wa jẹun, èyí sì máa ń wuyì gan-an tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ ló sún wa ṣe é. Àmọ́ tá a bá ń lo ìdánúṣe, tá a fi ara wa fún ṣíṣe àlejò, a óò rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà míì tá a lè gbà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn. Tágbára wa ò bá gbé e láti pe àwọn èèyàn wá jẹun nílé wa, tá a bá fún àwọn èèyàn ní èso tàbí àwọn nǹkan ìpápánu míì, ẹ̀mí aájò àlejò náà là ń fi hàn yẹn.
14. (a) Ọ̀rọ̀ méjì wo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ẹ̀mí aájò àlejò”? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè jẹ wá lógún lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
14 Níní ẹ̀mí aájò àlejò ní í ṣe pẹ̀lú ojú tá a fi ń wo ọ̀ràn ìgbésí ayé. Ọ̀rọ̀ méjì ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ tó jẹ́ èdè Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ẹ̀mí aájò àlejò.” Àwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “ìfẹ́” àti “àjèjì.” Irú ojú wo la fi máa ń wo àwọn àjèjì tàbí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè? A lè sọ pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ń sapá láti kọ́ èdè míì torí kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fún àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn jẹ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò. A mọ̀ pé gbogbo wa kọ́ ló máa ṣeé ṣe fún láti kọ́ èdè míì o. Síbẹ̀, gbogbo wa la lè kópa tó jọjú nínú ríran àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́ tá a bá ń lo ìwé kékeré náà Good News for People of All Nations, èyí tó ní ìwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú lọ́pọ̀ èdè. Ǹjẹ́ o ti ní àbájáde rere kan látàrí lílo ìwé kékeré yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
Ẹ̀mí Ìbánikẹ́dùn
15. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí bá a ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Róòmù 12:15?
15 Ka Róòmù 12:15. Kókó ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà níbí yìí ni pé ká ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Ó yẹ ká gbìyànjú láti máa mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn. Ká máa bá wọn yọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń yọ̀, ká sì máa bá wọn kẹ́dùn nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́dùn. Tí iná ẹ̀mí bá ń jó nínú wa, yóò hàn lára wa bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn yọ̀ tàbí bá a ṣe ń bá wọn kẹ́dùn. Nígbà tí àádọ́rin àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pa dà dé láti ẹnu iṣẹ́ ìwàásù, tí wọ́n ń yọ̀ tí wọ́n sì ń ròyìn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe, Jésù fúnra rẹ̀ “ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ.” (Lúùkù 10:17-21) Ó bá wọn yọ̀. Lọ́wọ́ kejì, Jésù “sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún” nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú.—Jòh. 11:32-35.
16. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn, àwọn wo ní pàtàkì ló sì yẹ kó máa ṣe bẹ́ẹ̀?
16 A fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Tí Kristẹni kan bá ń yọ̀, a máa ń fẹ́ bá a yọ̀. Bákan náà, a ní láti máa tètè fòye mọ ohun tó jẹ́ ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé tá a bá fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu àwọn ará wa tó ní ẹ̀dùn ọkàn tá a sì bá wọn kẹ́dùn a lè mú kí ara tù wọ́n. Nígbà míì, a sì lè rí i pé bá a ṣe ń fi ọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò, ọ̀rọ̀ wọn lè ká wa lára débi pé a ó máa yọ omijé lójú. (1 Pét. 1:22) Ó yẹ káwọn alàgbà ní pàtàkì máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fúnni lórí níní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò.
17. Kí làwọn ohun tá a ti kọ́ nínú Róòmù orí 12, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
17 Àwọn ẹsẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú Róòmù orí 12 ti fún wa nímọ̀ràn tá a lè mú lò nínú ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará wa. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a ó ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ tó kù nínú orí yìí. Ohun tá a ó jíròrò nínú wọn ni ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, títí kan àwọn alátakò àtàwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa, a ó sì jíròrò bó ṣe yẹ ká máa hùwà sí wọn.
Àtúnyẹ̀wò
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé ‘iná ẹ̀mí ń jó nínú wa’?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká sin Ọlọ́run pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn sáwọn ará wa ká sì máa bá wọn káàánú?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Kí nìdí tá a fi ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni wọ̀nyí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè kópa nínú ríran àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run?