Ní Ìrètí Nínú Jèhófà Kó o Sì Jẹ́ Onígboyà
“Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.”—SÁÀMÙ 27:14.
1. Báwo ni ìrètí ṣe ṣe pàtàkì tó, àwọn ọ̀nà wo sì ni Bíbélì gbà lò ó?
BÍ ÌMỌ́LẸ̀ tó mọ́lẹ̀ rekete ni ojúlówó ìrètí rí. Kì í jẹ́ ká máa ronú púpọ̀ jù nípa àwọn àdánwò tó ń bá wa fínra nísinsìnyí, ó sì ń jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà àti ayọ̀ retí ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè fún wa ní ìrètí tó dájú, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí. (2 Tímótì 3:16) Ká sòótọ́, ó lé ní ìgbà ọgọ́jọ [160] táwọn ọ̀rọ̀ bí “ìrètí” àti “ní ìrètí” fara hàn nínú Bíbélì. Ohun táwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì ń tọ́ka sí ni, kéèyàn máa hára gàgà fún ohun kan tó dára, kó sì tún dáni lójú pé nǹkan tí à ń retí náà á rí bẹ́ẹ̀.a Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ lágbára ju pé kí nǹkan kàn wuni lásán, tó lè má sí ìdánilójú pé nǹkan ọ̀hún á ṣẹlẹ̀.
2. Ipa wo ni ìrètí kó nínú ìgbésí ayé Jésù?
2 Nígbà tí Jésù wà nínú àdánwò àti ìṣòro, kò ronú púpọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i lákòókò yẹn, ńṣe ló nírètí nínú Jèhófà. “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 12:2) Nítorí pé ohun tó jẹ Jésù lógún jù ni bóun ṣe máa fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ, tóun sì máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, kò jáwọ́ nínú ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ohun tójú rẹ̀ rí.
3. Ipa wo ni ìrètí ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
3 Dáfídì Ọba sọ bí ìrètí ṣe ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, ó ní: “Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.” (Sáàmù 27:14) Tá a bá fẹ́ kí ọkàn wa jẹ́ alágbára, ìyẹn ni pé tá a bá fẹ́ jẹ́ onígboyà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrètí wa dohun tí à ń ṣiyèméjì nípa rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ máa wà lọ́kàn wa kó sì ṣeyebíye lójú wa gan-an. Èyí á jẹ́ ká lè fara wé Jésù ní ti pé, a óò ní ìgboyà àti ìtara bá a ti ń kópa nínú iṣẹ́ tó pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àní, láfikún sí ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, Bíbélì sọ pé ìrètí tún ṣe pàtàkì gan-an, pé ó jẹ́ ànímọ́ tó ń wà títí lọ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń fi hàn nígbèésí ayé wọn.—1 Kọ́ríńtì 13:13.
Ǹjẹ́ O Ní ‘Ìrètí Tó Pọ̀ Gidigidi’?
4. Kí làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń wọ̀nà fún lójú méjèèjì?
4 Ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn Ọlọ́run á lárinrin gan-an. Ara àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti wà lọ́nà láti bá Kristi ṣàkóso lọ́run. “Àwọn àgùntàn mìíràn” sì ń retí dídi ẹni tá a ‘dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, kí wọ́n sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.’ (Jòhánù 10:16; Róòmù 8:19-21; Fílípì 3:20) Lára ohun tó wà nínú “òmìnira ológo” yẹn ni ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn ohun bíburú jáì tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà. Àní, Jèhófà, Ẹni tí ń fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” yóò rí i dájú pé òun fún àwọn ìránṣẹ́ òun tó jẹ́ olóòótọ́ ní ẹ̀bùn tó dára jù lọ.—Jákọ́bù 1:17; Aísáyà 25:8.
5. Báwo la ṣe ń dẹni tó ní ‘ìrètí tó pọ̀ gidigidi’?
5 Báwo ló ṣe yẹ kí ìrètí àwa Kristẹni nípa lórí ìgbésí ayé wa tó? Nínú Róòmù 15:13, a kà pé: “Kí Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú yín nípa gbígbàgbọ́ yín, kí ẹ lè ní ìrètí púpọ̀ gidigidi pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrètí kò dà bí àbẹ́là tó wà nínú òkùnkùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè fi wé ìtànṣán oòrùn òwúrọ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò, tó ń fúnni ní àlàáfíà, ayọ̀, àti ìgboyà, tó sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. Kíyè sí i pé nípa níní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípa rírí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gbà la fi lè “ní ìrètí púpọ̀ gidigidi.” Róòmù 15:4 sọ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” Nítorí náà, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mò ń mú kí ìrètí mi túbọ̀ dá mi lójú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, ṣé mò ń kà á lójoojúmọ́? Ṣé mò ń gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?’—Lúùkù 11:13.
6. Tá a bá fẹ́ kí ìrètí wa máa dá wa lójú nígbà gbogbo, kí la gbọ́dọ̀ yàgò fún?
6 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún Jésù tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa lágbára gan-an. Bá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ rẹ̀, kò ní ‘rẹ̀ wá, a ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wa.’ (Hébérù 12:3) A mọ̀ dájú pé bí ìrètí tí Ọlọ́run fún wa kò bá ṣe kedere mọ́ lọ́kàn wa tàbí báwọn nǹkan mìíràn bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wá lọ́kàn, bóyá àwọn nǹkan tara tàbí àwọn nǹkan tá a fẹ́ dà láyé, a lè dẹni táwọn nǹkan tẹ̀mí ò fi bẹ́ẹ̀ jẹ lọ́kàn mọ́. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, a kò ní lágbára àti ìgboyà láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù mọ́. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá sì ti ṣẹlẹ̀, a lè dẹni tí “ọkọ̀ ìgbàgbọ́” rẹ̀ rì. (1 Tímótì 1:19) Àmọ́, ojúlówó ìrètí yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára.
Ká Tó Lè Nígbàgbọ́, Ìrètí Ṣe Kókó
7. Ọ̀nà wo ni ìrètí gbà ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́?
7 Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Nítorí náà, ìgbàgbọ́ àti ìrètí kò ṣeé yà sọ́tọ̀, láìsí ìrètí kò sí ìgbàgbọ́. Ìwọ gbé ọ̀rọ̀ Ábúráhámù yẹ̀ wò. Lójú èèyàn, òun àti ìyàwó rẹ̀ Sérà ti kọjá ọjọ́ orí téèyàn ń bímọ nígbà tí Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé wọ́n máa ní ajogún. (Jẹ́nẹ́sísì 17:15-17) Báwo ni Ábúráhámù ṣe ṣe nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí yìí? “Bí ó tilẹ̀ ré kọjá ìrètí, síbẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìrètí, ó ní ìgbàgbọ́, kí ó lè di baba ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìrètí tí Ọlọ́run fún Ábúráhámù ló jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ pé yóò bímọ fìdí múlẹ̀ gan-an. Ìgbàgbọ́ tó ní yìí sì tún wá mú kí ìrètí rẹ̀ túbọ̀ dá a lójú, ó mú kó lágbára sí i. Àní, Ábúráhámù àti Sárà ní ìgboyà láti fi ilé wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn sílẹ̀, wọ́n sì lọ ń gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ àjèjì ní gbogbo ìyókù ìgbésí ayé wọn!
8. Báwo ni níní ìfaradà ṣe ń mú kí ìrètí ẹni lágbára?
8 Ohun tó mú kí ìrètí Ábúráhámù dá a lójú ni pé ó jẹ́ ẹni tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà, kódà nígbà tí kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 22:2, 12) Táwa náà bá ń ṣègbọràn tá a sì ní ìfaradà nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ọkàn wa á balẹ̀ pé àá rí èrè gbà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfaradà” máa ń yọrí sí “ipò ìtẹ́wọ́gbà,” èyí sì ń jẹ́ ká ní ìrètí. “Ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀.” (Róòmù 5:4, 5) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù tún fi kọ̀wé pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin.” (Hébérù 6:11) Irú ìdánilójú yìí, tó dá lórí àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà, yóò jẹ́ ká lè kojú ìṣòro èyíkéyìí pẹ̀lú ìgboyà, kódà, á jẹ́ ká lè kojú rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
“Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí”
9. Kí ló yẹ ká máa ṣe ní gbogbo ìgbà ká lè máa “yọ̀ nínú ìrètí”?
9 Ìrètí tí Ọlọ́run fún wa ṣeyebíye gan-an ju ohunkóhun tá a lè rí nínú ayé yìí lọ. Sáàmù 37:34 sọ pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.” Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sí ìdí kankan tí kò fi yẹ ká máa “yọ̀ nínú ìrètí.” (Róòmù 12:12) Àmọ́ ká tó lè máa yọ̀ nínú ìrètí, ohun tá à ń retí yẹn gbọ́dọ̀ máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ gbogbo ìgbà lo máa ń ronú nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun fẹ́ ṣe fún wa? Ṣé ò ń fojú inú wo ara rẹ nínú Párádísè, tí ara rẹ yá gágá, tí kò sí ohunkóhun tó ń da ọkàn rẹ láàmú, táwọn èèyàn tó o fẹ́ràn yí ọ ká, tó o sì ń ṣe iṣẹ́ tó ń múnú rẹ dùn gan-an? Ǹjẹ́ o máa ń ṣàṣàrò lórí àwọn àwòrán Párádísè tó máa ń wà nínú àwọn ìwé wa? A lè fi irú àṣàrò yìí wé kéèyàn máa nu gíláàsì wíńdò kan nígbà gbogbo, téyìí sì ń jẹ́ ká rí àyíká kan tó lẹ́wà gan-an. Bí a kò bá nu gíláàsì wíńdò náà mọ́, láìpẹ́ ìdọ̀tí ò ní jẹ́ ká rí àyíká ẹlẹ́wà yẹn mọ́. Ọkàn wa sì lè ṣí lọ sórí àwọn nǹkan mìíràn. Ká má ṣe jẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa láé!
10. Báwo ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé a óò gba èrè ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà?
10 Lóòótọ́, ìfẹ́ Jèhófà tá a ní ni olórí ìdí tá a fi ń sìn ín. (Máàkù 12:30) Síbẹ̀, ó yẹ ká máa wọ̀nà lójú méjèèjì fún èrè tí Ọlọ́run yóò fún wa. Àní, Jèhófà retí pé ká ṣe bẹ́ẹ̀! Hébérù 11:6 sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa wo òun gẹ́gẹ́ bí Olùsẹ̀san? Ìdí ni pé tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé a mọ Baba wa ọ̀run dáadáa, pé ó jẹ́ ẹni tó lawọ́ àtẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Ká sọ pé a ò ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan” ni, wo bi ìbànújẹ́ àti ìrẹ̀wẹ̀sì wa ì bá ti pọ̀ tó?—Jeremáyà 29:11.
11. Báwo ni ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀ ṣe ran Mósè lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu?
11 Mósè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó tayọ tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣàì gbé ọkàn ẹni kúrò lórí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Níwọ̀n bí Mósè ti jẹ́ “ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò,” ó lè lo agbára, ipò iyì, àti ọrọ̀ ilẹ̀ Íjíbítì bó bá wù ú. Ǹjẹ́ Mósè lé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, àbí ó fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà? Tìgboyàtìgboyà, Mósè yàn láti fi ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà. Kí nìdí? Nítorí pé ó “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” (Hébérù 11:24-26) Dájúdájú, Mósè kò fojú kékeré wo ìrètí tí Jèhófà gbé ka iwájú rẹ̀.
12. Kí nìdí tí ìrètí àwa Kristẹni fi dà bí àṣíborí?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí wé àṣíborí. Àṣíborí ìṣàpẹẹrẹ wa yìí máa ń dáàbò bo èrò ọkàn wa, ó ń jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu, ó ń jẹ́ ká lè fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì gan-an ṣáájú nígbèésí ayé wa, ó sì ń jẹ́ ká lè máa jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Ǹjẹ́ o máa ń dé àṣíborí ìṣàpẹẹrẹ tìrẹ nígbà gbogbo? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Mósè àti Pọ́ọ̀lù, o kò ní gbé “ìrètí [rẹ] lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” Lóòótọ́, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè pinnu pé òun ò ní ṣe nǹkan táyé ńṣe, ìyẹn ni lílé nǹkan tara lójú méjèèjì, àmọ́ ìsapá yẹn tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ o! Ó ṣe tán, kí nìdí tí wàá fi fara mọ́ ohun tí kì í ṣe “ìyè tòótọ́,” níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ìyè tòótọ́” ló ń dúró de àwọn tó ní ìrètí nínú Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?—1 Tímótì 6:17, 19.
“Èmi Kì Yóò Fi Ọ́ Sílẹ̀ Lọ́nàkọnà”
13. Ìdánilójú wo ni Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?
13 Àwọn tó gbé ìrètí wọn ka ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa ọjọ́ iwájú, kí wọ́n mọ ewu ńlá tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ níwájú wọn bí “ìroragógó wàhálà” ti túbọ̀ ń bá ayé. (Mátíù 24:8) Àmọ́ irú ẹ̀rù yìí kò ba àwọn tó nírètí nínú Jèhófà rárá. Wọ́n á máa ‘gbé nínú ààbò, wọn yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.’ (Òwe 1:33) Nítorí pé ìrètí wọn kò sí nínú ètò ìsinsìnyí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, ó sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”—Hébérù 13:5.
14. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn Kristẹni máa ṣàníyàn láìnídìí nípa àwọn ohun tara tí wọ́n nílò?
14 “Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” Gbólóhùn tí Bíbélì tẹnu mọ́ yìí fi hàn dájúdájú pé Ọlọ́run yóò bójú tó wa. Jésù náà mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ọ̀rọ̀ wa jẹ̀ ẹ́ lọ́kàn. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí [àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémáàní tá a nílò nígbèésí ayé wa] ni a ó sì fi kún un fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” (Mátíù 6:33, 34) Jèhófà mọ̀ pé kò rọrùn fún wa láti gbájú mọ́ Ìjọba rẹ̀ ká sì tún máa gbọ́ bùkátà ara wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá pé ó lè pèsè àwọn ohun tá a nílò, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 6:25-32; 11:28-30.
15. Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń ní ‘ojú tó mú ọ̀nà kan’?
15 Tá a bá ń jẹ́ kí ‘ojú wa mú ọ̀nà kan,’ ìyẹn á fi hàn pé a gbára lé Jèhófà. (Mátíù 6:22, 23) Ẹni tójú rẹ̀ mú ọ̀nà kan kì í ṣe àgàbàgebè, ẹ̀mí tó dáa ló fi ń ṣe nǹkan, kì í ṣe olójúkòkòrò èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tó ń wá tara rẹ̀ ṣáá. Níní ojú tó mú ọ̀nà kan kò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì o, tàbí kéèyàn wá fọwọ́ yẹpẹrẹ mú gbígbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé, ká máa fi “ìyèkooro èrò inú” hàn bá a ti ń fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣáájú nígbèésí ayé wa.—2 Tímótì 1:7.
16. Kí nìdí tá a fi nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà ká tó lè ní ojú tó mú ọ̀nà kan?
16 Ká tó lè jẹ́ ẹni tójú rẹ̀ mú ọ̀nà kan, ó gba ìgbàgbọ́ àti ìgboyà. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ọ̀gá rẹ níbi iṣẹ́ sọ pé dandan o gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ lákòókò tó bọ́ sígbà ìpàdé ńkọ́, ṣé wàá jẹ́ kí nǹkan tẹ̀mí gba ipò iwájú? Bí kò bá dá ẹnì kan lójú pé Jèhófà á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé á sì bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, Sátánì á kàn mú kí iyèméjì ẹni yẹn máa pọ̀ sí i ni, bó bá sì yá, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè má lọ sípàdé mọ́ rárá. Ó dájú pé àìnígbàgbọ́ lè sọ wá dẹni tí Sátánì ń darí rẹ̀, táá fi jẹ́ pé dípò Jèhófà, Sátánì ni yóò wá máa sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ fi ṣáájú nígbèésí ayé wa. Jàǹbá ńlá lèyí á mà jẹ́ o!—2 Kọ́ríńtì 13:5.
“Ní Ìrètí Nínú Jèhófà”
17. Báwo làwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ṣe ń gba èrè, kódà lákòókò yìí pàápàá?
17 Léraléra ni Ìwé Mímọ́ fi hàn pé, àwọn tó nírètí nínú Jèhófà tí wọ́n sì gbọ́kàn wọn lé e kò pàdánù rí. (Òwe 3:5, 6; Jeremáyà 17:7) Lóòótọ́, láwọn ìgbà mìíràn, nǹkan lè má ṣẹnuure fún wọn, àmọ́, àwọn ìbùkún tí wọ́n máa rí lọ́jọ́ iwájú kò jẹ́ kí wọ́n ka ìyẹn sí bàbàrà. Wọ́n ń tipa báyìí fi hàn pé àwọn “ní ìrètí nínú Jèhófà” ọkàn àwọn sì balẹ̀ pé bópẹ́bóyá, yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní gbogbo ohun tọ́kàn wọn fẹ́ tó sì bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Sáàmù 37:4, 34) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń láyọ̀ gan-an, àní lákòókò yìí pàápàá. “Ìfojúsọ́nà àwọn olódodo jẹ́ ayọ̀ yíyọ̀, ṣùgbọ́n ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.”—Òwe 10:28.
18, 19. (a) Ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ni Jèhófà fìfẹ́ ṣe fún wa? (b) Ọ̀nà wo là ń gbà fi Jèhófà sí “ọwọ́ ọ̀tún wa”?
18 Nígbà tí ọmọ kékeré kan bá di bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ mú tí wọ́n sì jọ ń rìn lọ, ẹ̀rù kì í bà á rárá, ọkàn rẹ̀ sì máa ń balẹ̀ gan-an. Ẹ̀rù kò ba àwa náà bá a ti ń bá Baba wa ọ̀run rìn. Jèhófà sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. . . . Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. . . . Nítorí pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”—Aísáyà 41:10, 13.
19 Jèhófà ń dini lọ́wọ́ mú kẹ̀! Gbólóhùn yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Dáfídì kọ̀wé pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.” (Sáàmù 16:8) Báwo la ṣe ń fi Jèhófà sí “ọwọ́ ọ̀tún” wa? Ó kéré tán, ọ̀nà méjì là ń gbà ṣe èyí. Àkọ́kọ́, à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa. Èkejì, à ń pọkàn wa pọ̀ sórí èrè ológo tí Jèhófà gbé ka iwájú wa. Ásáfù, ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù, kọrin pé: “Èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.” (Sáàmù 73:23, 24) Irú ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí ń jẹ́ ká máa retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láìmikàn.
“Ìdáǹdè Yín Ń Sún Mọ́lé”
20, 21. Báwo lọjọ́ iwájú ṣe máa rí fáwọn tó nírètí nínú Jèhófà?
20 Bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń kọjá lọ ló túbọ̀ ń pọn dandan pé ká fi Jèhófà sọ́wọ́ ọ̀tún wa. Láìpẹ́, bí Ọlọ́run bá ti ń pa ìsìn èké run tán ni ìpọ́njú yóò bá ayé Sátánì lọ́nà tírú ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí. (Mátíù 24:21) Jìnnìjìnnì yóò bá gbogbo àwọn tí kò nígbàgbọ́. Síbẹ̀, lákòókò tí gbogbo nǹkan á dojú rú yẹn, ńṣe làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ onígboyà yóò máa yọ̀ nítorí ìrètí tí wọ́n ní! Jésù sọ pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:28.
21 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa yọ̀ nínú ìrètí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wa, ká má ṣe jẹ́ kí Sátánì fi àwọn ohun tó ń lò láti pín ọkàn àwọn èèyàn níyà, tàn wá jẹ. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ ẹni tó ní ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe èyí, àá nígboyà láti ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ipòkípò tá a bá bá ara wa, àá sì lè kọjú ìjà sí Èṣù. (Jákọ́bù 4:7, 8) Bẹ́ẹ̀ ni o, “ẹ jẹ́ onígboyà, kí ọkàn-àyà yín sì jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jèhófà.”—Sáàmù 31:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, èrè ti ọ̀run tó ń dúró de àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìrètí” fún lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ bá a ṣe sábà máa ń lo ìrètí la jíròrò nínú àpilẹkọ yìí.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?
• Ọ̀nà wo ni ìrètí tí Jésù ní gbà ràn án lọ́wọ́ láti ní ìgboyà?
• Ọ̀nà wo ni ìrètí fi lè jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́?
• Ọ̀nà wo ni ìrètí àti ìgbàgbọ́ lè gbà fún Kristẹni kan nígboyà láti fi àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ṣáájú nígbèésí ayé rẹ̀?
• Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó “ní ìrètí nínú Jèhófà” máa retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láìbẹ̀rù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Yálà ọmọdé ni ọ́ tàbí àgbàlagbà, ǹjẹ́ ò ń fojú inú wo ara rẹ nínú Párádísè?