Ẹ Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ àti Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Bíi Ti Jésù
“Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 PÉT. 2:21.
1. Kí nìdí tí títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù fi máa jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà?
A SÁBÀ máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí ìwà àti ìṣe wọn tẹ́ wa lọ́rùn. Nínú gbogbo ẹ̀dá èèyàn tó tíì gbé láyé yìí rí, kò sí ẹlòmíì tí àpẹẹrẹ rẹ̀ ta yọ ti Jésù Kristi. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Jésù sọ nígbà kan pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòh. 14:9) Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ délẹ̀délẹ̀ débi pé téèyàn bá kíyè sí Ọmọ ṣe ló máa dà bíi pé Baba ló ń rí. Nítorí náà, bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ṣe la túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ Ẹni gíga jù lọ láyé àti lọ́run. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la máa ní tá a bá fìwà jọ Ọmọ rẹ̀ tá a sì ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀!
2, 3. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa ní àkọsílẹ̀ nípa Ọmọ rẹ̀, kí sì ni Jèhófà retí pé ká ṣe? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e?
2 Àmọ́, báwo la ṣe lè mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́? A dúpẹ́ pé a ní àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù. Àkọsílẹ̀ tí Jèhófà fún wa yẹn wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, torí pé ó fẹ́ ká mọ Ọmọ rẹ̀ dáadáa ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Ka 1 Pétérù 2:21.) Bíbélì fi àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ wé “ìṣísẹ̀” tàbí ipasẹ̀. Torí náà, ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa ni pé ká máa tọ Jésù lẹ́yìn, ká sì máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀. Lóòótọ́ àpẹẹrẹ pípé ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa, àwa sì jẹ́ aláìpé. Àmọ́, Jèhófà ò retí pé ká tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù lọ́nà tó pé pérépéré. Kàkà bẹ́ẹ̀, Baba retí pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ òun débi tí agbára wa bá gbé e dé, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé.
3 Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Jésù tó jẹ́ káwọn èèyàn lè sún mọ́ ọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́; nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bó ṣe jẹ́ onígboyà àti ẹni tó ní ìfòyemọ̀. Tá a bá ti ń jíròrò ànímọ́ kọ̀ọ̀kan, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Kí ló túmọ̀ sí? Báwo ni Jésù ṣe lò ó? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?
JÉSÙ JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀
4. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tí ìrẹ̀lẹ̀ túmọ̀ sí?
4 Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Ayé táwọn èèyàn ti jẹ́ agbéraga là ń gbé, àwọn kan sì rò pé òmùgọ̀ àti ojo èèyàn lẹni tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ẹni tó bá máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ gbọ́dọ̀ nígboyà, kó sì jẹ́ akíkanjú. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ni “òdìkejì ìwà ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ìrẹ̀lẹ̀” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni a lè tú sí “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” (Fílí. 2:3) Ojú tí ẹnì kan bá fi ń wo ara rẹ̀ ló máa pinnu bóyá ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: “Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe rẹlẹ̀ gan-an tó lójú Ọlọ́run.” Tá a bá dìídì rẹ ara wa sílẹ̀ lójú Ọlọ́run, a ò ní rò ó lọ́kàn ara wa pé a ṣe pàtàkì ju àwọn èèyàn tó kù lọ. (Róòmù 12:3) Kò rọrùn fún ẹ̀dá aláìpé láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ a lè kọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tá a bá ronú lórí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run, tá a sì ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀.
5, 6. (a) Ta ni Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì? (b) Báwo ni Máíkẹ́lì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
5 Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Ọjọ́ pẹ́ tí Ọmọ Ọlọ́run ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ní ọ̀run àti ìgbà tó jẹ́ ẹ̀dá pípé lórí ilẹ̀ ayé. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
6 Ìwà rẹ̀. Ìwé Júúdà nínú Bíbélì sọ àpẹẹrẹ kan nípa Jésù kó tó di pé ó wá sáyé. (Ka Júúdà 9.) Jésù tó jẹ́ Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì “ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù,” ó sì bá ẹ̀dá burúkú yìí “ṣe awuyewuye.” “Òkú Mósè” ló dá awuyewuye yìí sílẹ̀. Ẹ rántí pé lẹ́yìn tí Mósè kú, Jèhófà sin òkú rẹ̀, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó mọ sàréè rẹ̀. (Diu. 34:5, 6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Èṣù fẹ́ lo òkú Mósè kó lè fi gbé ìjọsìn èké lárugẹ. Ète ibi yòówù kí Èṣù ní lọ́kàn, Máíkẹ́lì ò gbà fún un. Ìwé kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ní aáwọ̀” àti “ṣe awuyewuye” ni “wọ́n tún máa ń lò nígbà tí ọ̀ràn òfin bá dá awuyewuye sílẹ̀,” èyí tó lè túmọ̀ sí pé “Máíkẹ́lì ‘ò gbà pé Èṣù ní ẹ̀tọ́’ lórí òkú Mósè.” Síbẹ̀, Olórí Áńgẹ́lì mọ̀ pé òun ò ní ọlá àṣẹ láti dá ẹjọ́ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbé ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ̀ Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ, ìyẹn Jèhófà. Bí Máíkẹ́lì tiẹ̀ ń bínú síbẹ̀ kò ṣe kọjá ibi tí ọlá àṣẹ rẹ̀ mọ. Máíkẹ́lì mà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ o!
7. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
7 Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àti ìwà rẹ̀ nígbà tó ń wàásù lórí ilẹ̀ ayé fi hàn pé ó ní ojúlówó ìrẹ̀lẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó sọ. Kò fìgbà kankan gba ògo ohunkóhun tó bá ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, Baba rẹ̀ ló ní káwọn èèyàn máa fi ògo fún. (Máàkù 10:17, 18; Jòh. 7:16) Kì í sọ̀rọ̀ burúkú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tàbí kó mú kí wọ́n máa wo ara wọn bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń pọ́n wọn lé, ó máa ń yìn wọ́n tó bá rí i tí wọ́n ṣe ohun tó dáa, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun gbọ́kàn lé wọn. (Lúùkù 22:31, 32; Jòh. 1:47) Ìṣe rẹ̀. Jésù yàn láti gbé láàárín àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ohun ìní rẹpẹtẹ. (Mát. 8:20) Ó fínnúfíndọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ gan-an. (Jòh. 13:3-15) Ó tún fi hàn pé òun níwà ìrẹ̀lẹ̀ gan-an bó ṣe jẹ́ onígbọràn. (Ka Fílípì 2:5-8.) Jésù ò dà bí àwọn agbéraga èèyàn kan tí wọ́n ya aláìgbọràn, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ mú kó ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì di “onígbọràn títí dé ikú.” Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé Jésù, Ọmọ ènìyàn jẹ́ ‘ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn’?—Mát. 11:29.
Ẹ JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀ BÍI TI JÉSÙ
8, 9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
8 Báwo la ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù? Ìwà wa. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ò ní kọjá ààyè wa. Tá a bá mọ̀ pé tiwa kọ́ ni láti dáni lẹ́jọ́, a ò ní máa ṣàríwísí àwọn èèyàn tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí ká máa fẹ́ mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. (Lúùkù 6:37; Ják. 4:12) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ á mú ká ṣọ́ra ká má di “olódodo àṣelékè,” kò ní jẹ́ ká máa fojú pa àwọn kan rẹ́ torí pé wọn ò lè ṣe ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe, wọn ò sì ní àwọn àǹfààní tá a ní. (Oníw. 7:16) Àwọn alàgbà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kì í wò ó pé àwọn lọ́lá ju àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ “kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá,” wọ́n sì gbà pé àwọn rẹlẹ̀ gan-an sáwọn ẹlòmíì.—Fílí. 2:3; Lúùkù 9:48.
9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ W. J. Thorn, tó ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1894. Lẹ́yìn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ yẹn, ètò Ọlọ́run pè é sí Oko Watchtower tó wà ní ìpínlẹ̀ New York, wọ́n sì ní kó máa ṣiṣẹ́ ní ilé adìyẹ. Ó sọ pé: “Ìgbàkígbà tí mo bá ti ń ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ, ńṣe ni mo máa ń pe orí ara mi wálé, màá sì sọ pé: ‘Ìwọ ekuru kíún lásánlàsàn yìí. Kí lo ní tó fẹ́ máa jẹ́ kó o gbéra ga?’” (Ka Aísáyà 40:12-15.) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ lèyí lóòótọ́!
10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ àti ìṣe wa?
10 Ọ̀rọ̀ tá à ń sọ. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ la jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn wa, àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa fi hàn bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 6:45) Tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, a ò ní máa sọ̀rọ̀ ṣáá nípa àwọn ohun tá a ti gbé ṣe àtàwọn àǹfààní tá a ní. (Òwe 27:2) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àá máa wá ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, tí à sì máa yìn wọ́n torí ìwà dáadáa tí wọ́n ń hù, àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n ti gbé ṣe sẹ́yìn. (Òwe 15:23) Ìṣe wa. Àwọn Kristẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kì í wá ipò ńlá nínú ayé yìí. Ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n ní ìwọ̀nba ohun ìní tara, kódà wọ́n ń ṣe iṣẹ́ táwọn èèyàn lè kà sí iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ gan-an torí kí wọ́n lè ráyè fi gbogbo àkókò wọn sin Jèhófà débi tí wọ́n bá lè ṣe é dé. (1 Tím. 6:6, 8) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a bá ń ṣègbọràn. Ó gba ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú ká tó lè jẹ́ “onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú” nínú ìjọ, ká gba ìtọ́sọ́nà tí ètò Jèhófà ń fún wa ká sì tẹ̀ lé e.—Héb. 13:17.
ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́ NI JÉSÙ
11. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́?
11 Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ọ̀rọ̀ náà “jẹ̀lẹ́ńkẹ́” túmọ̀ sí fífi bí nǹkan ṣe rí lára ẹni hàn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ìfẹ́ ló máa ń jẹ́ kéèyàn fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn, ohun tí ẹni tó jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti ẹni tó lójú àánú sì máa ṣe nìyẹn. Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” àti “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” (Lúùkù 1:78; 2 Kọ́r. 1:3; Fílí. 1:8) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ká jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, ó ní: “Èyí kọjá pé ká kàn ṣojú àánú sáwọn aláìní. Ohun tó ń sọ ni pé ká sọ ìṣòro wọn di tiwa, ká sì ṣe ohun tó máa sọ ìgbésí ayé àwọn èèyàn dọ̀tun.” Táwa náà bá jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí. Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ èèyàn máa ń fẹ́ ṣe ohun tó máa mú kí nǹkan sàn fáwọn èèyàn.
12. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ní ìyọ́nú fáwọn èèyàn, kí sì ní èyí mú kó ṣe?
12 Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ọwọ́ tó fi mú àwọn èèyàn. Jésù máa ń ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sáwọn èèyàn. Nígbà tí Jésù rí Màríà ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sunkún nígbà tí Lásárù àbúrò Màríà kú, òun náà “da omijé” lójú. (Ka Jòhánù 11:32-35.) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìyọ́nú tó mú kí Jésù jí ọmọkùnrin opó kan dìde náà ló mú kó jí Lásárù dìde. (Lúùkù 7:11-15; Jòh. 11:38-44) Bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde yìí, ó ṣeé ṣe kí Lásárù láǹfààní láti wà lára àwọn tó máa wà ní òkè ọ̀run. Ṣáájú kí Jésù tó jí Lásárù dìde, ó fi “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” yìí hàn sáwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Torí pé Jésù jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, “ó . . . bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Ẹ ò rí i pé nǹkan máa sàn fún ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù! Ẹ kíyè sí i pé kì í ṣe pé ó kàn wu Jésù láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mú kó ṣe nǹkan tó máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.—Mát. 15:32-38; 20:29-34; Máàkù 1:40-42.
13. Báwo ni Jésù ṣe bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
13 Jésù sọ̀rọ̀ jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Torí pé Jésù jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, pàápàá àwọn tí ìbànújẹ́ sorí wọn kodò. Àpọ́sítélì Mátíù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ọ̀rọ̀ Aísáyà, ó wá sọ nípa Jésù pé: “Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí yóò tẹ̀ fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí yóò fẹ́ pa.” (Aísá. 42:3; Mát. 12:20) Ọ̀rọ̀ Jésù jẹ́ ìtura fáwọn tá a lè sọ pé wọ́n dà bí esùsú tàbí òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú. Ọ̀rọ̀ tó máa fún wọn nírètí ló ń wàásù rẹ̀ fún wọn, kó lè “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn.” (Aísá. 61:1) Ó ké sí àwọn “tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn” pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun, ó fi dá wọn lójú pé wọ́n máa “rí ìtura” fún ara wọn. (Mát. 11:28-30) Ó mú un dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run ò fi ọ̀rọ̀ àwọn tó ń jọ́sìn Rẹ̀ ṣeré rárá, títí kan “àwọn ẹni kékeré,” ìyẹn àwọn tí ayé lè kà sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.—Mát. 18:12-14; Lúùkù 12:6, 7.
Ẹ JẸ́ ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́ BÍI TI JÉSÙ
14. Báwo la ṣe lè máa fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn?
14 Báwo la ṣe lè jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ bíi ti Jésù? Ọwọ́ tá a fi mú àwọn èèyàn. A lè jẹ́ ẹ̀dá tí kò fi bẹ́ẹ̀ lójú àánú, àmọ́ Bíbélì rọ̀ wá pé ká sa gbogbo ipá wa láti kọ́ ọ. “Ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú” wà lára ìwà tuntun tí Ọlọ́run retí pé kí gbogbo Kristẹni máa fi sílò. (Ka Kólósè 3:9, 10, 12.) Báwo lo ṣe lè máa fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn? Ohun tó o máa ṣe ni pé kó o túra ká sí gbogbo èèyàn. (2 Kọ́r. 6:11-13) Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí ẹnì kan bá ń sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún ẹ. (Ják. 1:19) Ronú jinlẹ̀ dáadáa, kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé èmi nirú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí, báwo ló ṣe máa rí lára mi? Kí ni màá fẹ́ kí wọ́n ṣe fún mi?’—1 Pét. 3:8.
15. Ìrànwọ́ wo la lè ṣe fáwọn tó dà bí esùsú tàbí òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú?
15 Ìwà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Tá a bá jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó máa wù wá ká ṣe ohun tó máa yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà, pàápàá àwọn tá a lè sọ pé wọ́n dà bí esùsú tàbí òwú àtùpà tí ń jó lọ́úlọ́ú. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ìwé Róòmù 12:15 sọ pé: “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè gba pé ká tu àwọn tó sorí kọ́ nínú ju pé ká kàn máa wá ojútùú sí ìṣòro wọn. Arábìnrin kan táwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tù nínú lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ kú sọ pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn táwọn èèyàn bá wá kí mi, táwọn náà sì ń sunkún pẹ̀lú mi.” A tún lè fi hàn pé à ń fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn tá a bá ń ṣoore fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣèrànwọ́ fún opó tó ń wá ẹni tó lè bá a tún nǹkan ṣe nílé rẹ̀. Tàbí kó o ṣèrànwọ́ fún àgbàlagbà tó ń wá ẹni táá máa gbé e wá sípàdé, táá gbé e lọ sóde ẹ̀rí tàbí lọ sọ́dọ̀ dókítà. Kódà oore tá a rò pé kò tó nǹkan tá a ṣe fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà lè ṣe nǹkan pàtàkì nígbèésí ayé wọn. (1 Jòh. 3:17, 18) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀nà pàtàkì lèyí jẹ́ tá a bá fẹ́ kí ìyípadà bá ìgbésí ayé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́!
16. Kí la lè sọ tó máa tu àwọn tó sorí kọ́ nínú?
16 Ọ̀rọ̀ wa. Tá a bá ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn èèyàn á mú ká máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹs. 5:14) Ọ̀rọ̀ wo la lè sọ tó máa fún irú àwọn ẹni yìí níṣìírí? A lè fún wọn níṣìírí tá a bá ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tọkàntọkàn. A lè yìn wọ́n látọkàn wá kí wọ́n lè rí àwọn ìwà tó dáa tí wọ́n ní àti pé àwọn nǹkan kan wà tí wọ́n lè ṣe dáadáa. A lè rán wọn létí pé Jèhófà fà wọ́n sún mọ́ Ọmọ rẹ̀, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Jòh. 6:44) A lè mú un dá wọn lójú pé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ‘oníròbìnújẹ́ ní ọkàn’ àtàwọn “tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀” jẹ Jèhófà lógún gan-an ni. (Sm. 34:18) Ọ̀rọ̀ tá a sọ fún wọn tìfẹ́tìfẹ́ lè jẹ́ ìtura fáwọn tó nílò ìtùnú.—Òwe 16:24.
17, 18. (a) Irú ọwọ́ wo ni Jèhófà retí pé káwọn alàgbà fi mú àwọn àgùntàn òun? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Ẹ̀yin alàgbà, Jèhófà retí pé kí ẹ fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn àgùntàn òun. (Ìṣe 20:28, 29) Ẹ rántí pé iṣẹ́ yín ni láti máa bọ́ wọn, kẹ́ ẹ máa fún wọn níṣìírí, kẹ́ ẹ sì máa jẹ́ kára tù wọ́n. (Aísá. 32:1, 2; 1 Pét. 5:2-4) Torí náà, alàgbà kan tó ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ kì í sọ pé ohun tí òun bá ti sọ làwọn ará gbọ́dọ̀ ṣe tàbí kó ṣe òfin rẹpẹtẹ fún wọn. Kò sì ní máa dá wọn lẹ́bi pé wọn ò ṣe tó nígbà tó jẹ́ pé ipò wọn kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ju ohun tí wọ́n ń ṣe lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe láá máa ṣe ohun táá máa múnú wọn dùn, á sì dá a lójú pé ìfẹ́ Jèhófà tí wọ́n ní máa jẹ́ kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa sìn ín.—Mát. 22:37.
18 Ó dájú pé ó wù wá gan-an láti máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù ní báyìí tá a ti jíròrò bí Jésù ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò méjì míì nínú àwọn ànímọ́ Jésù tó fani mọ́ra, ìyẹn ìgboyà àti ìfòyemọ̀.