Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Obìnrin Kan Tí Ó Lọ́gbọ́n Kòòré Ìjábá
OBÌNRIN onílàákàyé tí ó jẹ́ aya alákọrí ọkùnrin kan—bí ọ̀ràn Ábígẹ́lì àti Nábálì ti rí nìyẹn. Ábígẹ́lì jẹ́ “olóye obìnrin, àti arẹwà ènìyàn.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá, Nábálì jẹ́ “òǹrorò àti oníwà búburú.” (Sámúẹ́lì Kíní 25:3) Ọ̀ràn tí ó ṣẹlẹ̀ náà, tí ó ní tọkọtaya tí wọn kò bára mu yìí nínú mú kí orúkọ wọn di ohun tí a kò lè gbá gbé nínú ìtàn Bíbélì. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ṣe ṣẹlẹ̀.
Ojú Rere Tí A Kò Kà Sí
Ọ̀rúndún kọkànlá ṣááju Sànmánì Tiwa ni. A ti fi òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì lọ́la, ṣùgbọ́n kàkà tí ì bá fi máa ṣàkóso ṣe ni ó ń sá káàkiri. Ọba tí ń ṣàkóso lọ́wọ́, Sọ́ọ̀lù, ti pinnu láti pa á. Nítorí èyí, ó di dandan fún Dáfídì láti máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òun pẹ̀lú 600 ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ibi ìsádi ní aginjù Páránì, gúúsù Júdà àti ní ìhà aginjù Sínáì.—Sámúẹ́lì Kíní 23:13; 25:1.
Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, wọ́n ṣalábàápàdé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nábálì gbà síṣẹ́. Ọlọ́rọ̀ yí tí ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Kélẹ́ẹ̀bù ní 3,000 àgùntàn àti 1,000 ewúrẹ́, ó sì rẹ́ irun àgùntàn rẹ̀ ní Kámélì, ìlú kan tí ó wà ní gúúsù Hébúrónì, tí ó sì lè jẹ́ nǹkan bí 40 kìlómítà péré sí Páránì.a Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ran àwọn olùṣọ́ àgùntàn Nábálì lọ́wọ́ láti ṣọ́ agbo ẹran wọn nítorí àwọn olè tí ń rìn gbéregbère kiri inú aginjù.—Sámúẹ́lì Kíní 25:14-16.
Ní àkókò yí, rírẹ́ irun àgùntàn ti bẹ̀rẹ̀ ní Kámélì. Àkókò pọ̀pọ̀ ṣinṣin ni èyí jẹ́, tí ó fara jọ ìgbà ìkórè fún àwọn àgbẹ̀. Ó sì tún jẹ́ àkókò fífi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, nígbà tí àwọn tí ó ni àgùntàn ń san èrè fún àwọn tí wọ́n ti bá wọn ṣiṣẹ́. Nítorí náà, Dáfídì kò hùwà ọ̀yájú nígbà tí ó rán ọkùnrin mẹ́wàá lọ sí ìlú Kámélì láti béèrè oúnjẹ lọ́wọ́ Nábálì gẹ́gẹ́ bí àsanpadà fún iṣẹ́ tí wọ́n ti bá a ṣe ní bíbójútó agbo ẹran rẹ̀.—Sámúẹ́lì Kíní 25:4-9.
Ìdáhùnpadà Nábálì kò fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn rárá. Ó pẹ̀gàn ní sísọ pé: “Ta ní í jẹ́ Dáfídì?” Lẹ́yìn náà, ní dídọ́gbọ́n sọ pé alárìnkiri ìránṣẹ́ lásán ni Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ kí èmi kí ó ha mú oúnjẹ mi, àti omi mi àti ẹran mi tí mo pa fún àwọn olùrẹ́run mi, kí èmi kí ò sì fi fún àwọn ọkùnrin tí èmi kò mọ ibi tí wọ́n gbé ti wá?” Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa èyí, ó wí fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Kí olúkúlùkù yín kí ó di idà rẹ̀ mọ́ ìdí!” Nǹkan bí 400 ọkùnrin gbára dì fún ogun náà.—Sámúẹ́lì Kíní 25:10-13.
Ọgbọ́n Inú Ábígẹ́lì
Àwọn ọ̀rọ̀ èébú tí Nábálì sọ dé etígbọ̀ọ́ aya rẹ̀, Ábígẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kí èyí máà jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí yóò ní láti bẹ̀bẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, kí ó sì bá Nábálì pẹ̀tù síjà. Bí ó ti wù kí ó rí, Ábígẹ́lì gbégbèésẹ̀ lọ́gán. Láìsọ fún Nábálì, ó kó ìpèsè jọ—títí kan àgùntàn márùn-ún àti oúnjẹ rẹpẹtẹ—ó sì lọ pàdé Dáfídì ní aginjù.—Sámúẹ́lì Kíní 25:18-20.
Nígbà tí Ábígẹ́lì tajú kán rí Dáfídì, kíá ni ó wólẹ̀ síwájú rẹ̀. Ó rọ̀ ọ́ pé: “Kí olúwa mi má fi ọkàn àyà rẹ̀ sí Nábálì ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun yìí. . . . Ní ti ẹ̀bùn ìbùkún yìí tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ ti mú wá fún olúwa mi, kí a fi fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ń rìn káàkiri ní ìṣísẹ̀ olúwa mi.” Ó fi kún un pé: “Má sì jẹ́ kí èyí [ohun tí Nábálì ṣe] di okùnfà títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́ rẹ tàbí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún ọkàn àyà olúwa mi.” Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a tú sí “títa gọ̀ọ́gọ̀ọ́” dọ́gbọ́n túmọ̀ sí kí ẹ̀rí ọkàn ẹni dani láàmú. Nítorí náà, Ábígẹ́lì kílọ̀ fún Dáfídì pé kí ó má fi ìwàǹwára gbégbèésẹ̀ tí yóò kábàámọ̀ rẹ̀ nígbẹ̀yìn.—Sámúẹ́lì Kíní 25:23-31, NW.
Dáfídì fetí sí Ábígẹ́lì. Ó wí fún un pé: “Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkúnfún sì ni ìwọ, tí ó dá mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. . . . Bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì ti wá pàdé mi, ní tòótọ́ kì bá tí kù fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn tí ń tọ̀ sára ògiri.”b—Sámúẹ́lì Kíní 25:32-34.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Àkọsílẹ̀ Bíbélì yí fi hàn pé kò lòdì rárá fún obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run láti lo àtinúdá tí ó yẹ bí ó bá pọn dandan. Ábígẹ́lì ṣe ohun tí ọkọ rẹ̀, Nábálì, kò fẹ́, ṣùgbọ́n Bíbélì kò dá a lẹ́bi fún èyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yìn ín gẹ́gẹ́ bí obìnrin ọlọ́gbọ́n inú àti onílàákàyè. Nípa lílo àtinúdá ní àkókò yánpọnyánrin yìí, Ábígẹ́lì gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbogbòò, ó yẹ kí aya kan fi ẹ̀mí ìtẹríba oníwà-bí-Ọlọ́run hàn, lọ́nà yíyẹ, ó lè ṣàìfohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nígbà tí ọ̀ràn bá kan àwọn ìlànà tí ó tọ́. Àmọ́ ṣáá o, ó yẹ kí ó làkàkà láti di “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù” mú, kí ó má sì fi ẹ̀mí fífẹ́ láti wà ní dáńfó gedegbe hùwà, tí ń jẹ yọ kìkì láti inú àránkàn, ìgbéraga, tàbí ọ̀tẹ̀. (Pétérù Kíní 3:4) Ṣùgbọ́n, kò yẹ kí aya oníwà-bí-Ọlọ́run nímọ̀lára pé a ń fipá mú òun ṣe ohun tí ó mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu rárá tàbí tí ó tẹ ìlànà Bíbélì lójú. Ní tòótọ́, àkọsílẹ̀ nípa Ábígẹ́lì pèsè àlàyé ọ̀rọ̀ tí ó múná dóko, tí ó ta ko àwọn tí wọ́n ń rin kinkin pé Bíbélì fi àwọn obìnrin hàn gẹ́gẹ́ bí ẹrú lásán.
Àkọsílẹ̀ yí tún kọ́ wa ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Nígbà míràn, Dáfídì máa ń fi ànímọ́ yìí hàn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ó kọ̀ láti pa Ọba Sọ́ọ̀lù ẹlẹ́mìí ìgbẹ̀sàn, bí ó tilẹ̀ ní àǹfààní púpọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí ikú Sọ́ọ̀lù ì bá sì ti mú ìbàlẹ̀ ọkàn wá fún Dáfídì. (Sámúẹ́lì Kíní 24:2-7) Ní ìyàtọ̀ pátápátá, nígbà tí Nábálì gàn án tìkàtẹ̀gbin, ó bá Dáfídì lójijì, ó sì búra láti gbẹ̀san. Ìkìlọ̀ ṣíṣe kedere ni èyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni, tí ń làkàkà láti “má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Ní gbogbo ipò, ó yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé ìṣílétí Pọ́ọ̀lù pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú.”—Róòmù 12:17-19.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A gbọ́ pé aginjù Páránì gbòòrò títí dé ìhà àríwá Bíá-Ṣébà. Ilẹ̀ yí ní pápá oko tí ó tóbi.
b Àpólà ọ̀rọ̀ náà “àwọn tí ń tọ̀ sára ògiri” jẹ́ àkànlò èdè Hébérù fún àwọn ọkùnrin, tí ó hàn gbangba pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.—Fi wé Àwọn Ọba Kìíní 14:10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ábígẹ́lì mú ẹ̀bùn wá fún Dáfídì