Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ó dé ìlú Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni. Ó ti gbọ́ nípa èdèkòyédè tó wà láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni ní ìlú Róòmù. Pọ́ọ̀lù wá pinnu láti kọ lẹ́tà sí wọn, kí wọ́n bàa lè wà níṣọ̀kan nínú Kristi.
Nínú Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù yẹn, ó ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe polongo àwọn èèyàn ní olódodo àti bó ṣe yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù yìí jẹ́ kí ìmọ̀ wa nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, ó tẹnu mọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ipa tí Kristi kó nínú ìgbàlà wa.—Héb. 4:12.
Ọ̀NÀ WO NI ỌLỌ́RUN GBÀ POLONGO WỌN NÍ OLÓDODO?
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run, [Ọlọ́run] sì ń polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” Pọ́ọ̀lù tún ní: “A ń polongo ènìyàn ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ láìka àwọn iṣẹ́ òfin sí.” (Róòmù 3:23, 24, 28) Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú “ìṣe ìdáláre kan,” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” lè dẹni tí Ọlọ́run “polongo ní olódodo.” Pípolongo tí Ọlọ́run polongo àwọn ẹni àmì òróró ní olódodo túmọ̀ sí pé wọn yóò lọ sọ́run gẹ́gẹ́ bí ajogún pẹ̀lú Kristi, ní ti àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá wọn yóò di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ la “ìpọ́njú ńlá” já.—Róòmù 5:18; Ìṣí. 7:9, 14; Jòh. 10:16; Ják. 2:21-24; Mát. 25:46.
Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Àwa yóò ha dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí a kò sí lábẹ́ òfin bí kò ṣe lábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí?” Ìdáhùn rẹ̀ ni pé: “Kí èyíinì má ṣẹlẹ̀ láé!” Ó wá ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ẹrú . . . , yálà ti ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ikú níwájú tàbí ti ìgbọràn pẹ̀lú òdodo níwájú.” (Róòmù 6:15, 16) Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Bí ẹ bá fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara nípasẹ̀ ẹ̀mí, ẹ ó yè.”—Róòmù 8:13.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:24-32—Ṣé àwọn Júù ló ń hùwà ìbàjẹ́ tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ àbí àwọn Kèfèrí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àpèjúwe yẹn bá àwọn méjèèjì mu, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà tipẹ́tipẹ́ ni Pọ́ọ̀lù dìídì ń tọ́ka sí. Lóòótọ́ wọ́n mọ òfin òdodo Ọlọ́run, àmọ́ “wọn kò . . . tẹ́wọ́ gba mímọ Ọlọ́run nínú ìmọ̀ pípéye.” Torí náà ìbáwí tọ́ sí wọn.
3:24, 25—Báwo ni “ìràpadà tí Kristi Jésù san” ṣe kan “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá” kí wọ́n tó san ìràpadà náà? Ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nípa Mèsáyà tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ní ìmúṣẹ, ìyẹn nígbà tí wọ́n pa Jésù lórí òpó igi oró. (Gál. 3:13, 16) Gbàrà tí Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló ti dà bí pé ó ti ní ìmúṣẹ lójú rẹ̀, torí pé kò sí ohun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ kó má mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, èyí tí kò tíì wáyé nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí yẹn. Ìràpadà yẹn yóò tún jẹ́ kí àjíǹde lè ṣeé ṣe fáwọn tó ti wà ṣáájú kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé.—Ìṣe 24:15.
6:3-5—Kí ló túmọ̀ sí láti dẹni tá a batisí sínú Kristi Jésù àti sínú ikú rẹ̀? Nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi, wọ́n dẹni tó wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di apá kan ìjọ, ìyẹn ara Kristi, tí Kristi fúnra rẹ̀ sì jẹ́ Orí ìjọ náà. (1 Kọ́r. 12:12, 13, 27; Kól. 1:18) Bí wọ́n ṣe dẹni tá a batisí sínú Kristi Jésù nìyẹn. A “batisí” àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró “sínú ikú” Kristi ní ti pé, wọ́n ń gbé ìgbé ayé ẹni tó fi ara rẹ̀ rúbọ, wọ́n sì yááfì gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ikú ẹni tó fara rẹ̀ rúbọ ni wọ́n ń kú bíi ti Jésù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fi ikú tiwọn ṣe ìràpadà. Ó dìgbà táwọn ẹni àmì òróró bá jíǹde sí ọ̀run lẹ́yìn ikú wọn kí batisí tá a batisí wọn sínú ikú Kristi tó parí.
7:8-11—Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe gba “ìsúnniṣe nípasẹ̀ àṣẹ”? Òfin ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹlẹ́sẹ̀ làwọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ rí oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n gbà jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn sì wá mọ̀ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju bí wọ́n ṣe rò lọ. Torí náà a lè sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ gba ìsúnniṣe nípasẹ̀ Òfin.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:14, 15. A ní ìdí tó pọ̀ tó fi yẹ ká máa fìtara wàásù ìhìn rere. Ọ̀kan lára wọn ni pé a jẹ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run fi ẹ̀jẹ̀ Jésù rà ní gbèsè, ó sì tún jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ṣèlérí.
1:18-20. Àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aláìṣòdodo kò ní “àwíjàre” kankan, torí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí a kò lè fojú rí ni a rí kedere nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.
2:28; 3:1, 2; 7:6, 7. Tí Pọ́ọ̀lù bá sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bí àwọn Júù nínú, ó tún máa ń sọ ohun tó máa tù wọ́n nínú. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa nípa bá a ṣe lè máa fọgbọ́n bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ta kókó, tó lè bí àwọn èèyàn nínú.
3:4. Tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn bá ta ko ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ńṣe ni ká “jẹ́ kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́” nípa títẹ̀lé ohun tí Bíbélì sọ, ká sì máa ṣe ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn, a óò lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí Ọlọ́run ní olóòótọ́.
4:9-12. Ọlọ́run ti ka ìgbàgbọ́ Ábúráhámù sí òdodo fún un tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó dádọ̀dọ́ ní ẹni ọdún mọ́kàn-dín-lọ́gọ́rùn-ún. (Jẹ́n. 12:4; 15:6; 16:3; 17:1, 9, 10) Ọlọ́run sì wá tipa bẹ́ẹ̀ fi ohun tó ń mú kéèyàn lè rí ojú rere òun hàn gbangba.
4:18. Kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́, ó gbọ́dọ̀ ní ìrètí, nítorí pé láìní ìrètí èèyàn kò lè ní ìgbàgbọ́.—Héb. 11:1.
5:18, 19. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi àlàyé ṣókí sọ bí Jésù àti Ádámù ṣe jọra, ńṣe ló ń fi hàn kedere pé ó ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan láti fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Ṣíṣe àlàyé ṣókí tó sì ṣe kedere jẹ́ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbà kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.—1 Kọ́r. 4:17.
7:23. Àwọn ẹ̀yà ara bí ọwọ́, ẹsẹ̀ àti ahọ́n lè ‘mú wa lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀,’ torí náà a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa ṣì wọ́n lò.
8:26, 27. Tí ìṣòro wa bá pọ̀ débì pé a ò tiẹ̀ mọ ohun tá a lè gbàdúrà lé lórí, “ẹ̀mí tìkára rẹ̀ [máa] ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa.” Nírú ìgbà yẹn Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” máa ń ka àdúrà inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó bá ìṣòro wa mú sí ohun tá a fẹ́ sọ.—Sm. 65:2.
8:38, 39. Àwọn àjálù, àwọn ẹ̀mí burúkú àtàwọn alákòóso ayé kò lè dí Jèhófà lọ́wọ́ kó má nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì yẹ kí wọ́n dí àwa náà lọ́wọ́ ká má nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
9:22-28; 11:1, 5, 17-26. Ara ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run “pè kì í ṣe láti àárín àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú” ni ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò Ísírẹ́lì ti ní ìmúṣẹ.
10:10, 13, 14. Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn àti ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀, yóò jẹ́ ká máa fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.
11:16-24, 33. “Inú rere àti ìmúnájanjan Ọlọ́run” bára dọ́gba gan-an ni láìfì síbì kankan! Bẹ́ẹ̀ ni o, “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—Diu. 32:4.
GBÉ ÌGBÉ AYÉ RẸ LỌ́NÀ TÓ BÁ BÍ ỌLỌ́RUN ṢE POLONGO WA NÍ OLÓDODO MU
Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí náà, mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.” (Róòmù 12:1) “Nítorí náà” tàbí nítorí pé Ọlọ́run ti polongo àwọn Kristẹni ni olódodo nítorí ìgbàgbọ́ wọn, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e máa nípa lórí bí wọ́n ṣe ń hùwà síra wọn, sáwọn ẹlòmíì àti sáwọn aláṣẹ.
Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” Ó tún gbà wọn níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè.” (Róòmù 12:3, 9) Ó tún sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni lórí ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn kálukú ni pé: “Kí a má ṣe máa dá ara wa lẹ́jọ́. . . lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 14:13.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
12:20—Báwo la ṣe ń kó “òkìtì ẹyín iná” lé ọ̀tá lórí? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, táwọn èèyàn bá ti kó irin tí wọ́n fẹ́ yọ́ sínú ìléru, wọ́n máa ń kó ẹyín iná sórí rẹ̀ àti sábẹ́ rẹ̀. Ooru gbígbóná tó ń wá látinú ẹyín iná tó wà lókè irin náà ló máa yọ́ ọ, tí yóò sì jẹ́ kí ìdàrọ́ ara rẹ̀ kúrò. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣe ohun rere sáwọn ọ̀tá wa, ńṣe là ń kó ẹyín iná lé wọn lórí, ìyẹn ló máa jẹ́ kí inú wọn yọ́, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà dáadáa sí wa.
12:21—Báwo la ṣe lè “máa fi ire ṣẹ́gun ibi”? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé, ká máa bá a lọ ní fífi ìgboyà ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ títí dìgbà tó máa fi tẹ́ ẹ lọ́rùn.—Máàkù 13:10.
13:1—Ọ̀nà wo ni a gbà gbé àwọn aláṣẹ onípò gíga “dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”? Àwọn aláṣẹ ni a gbé “dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ní ti pé, Ọlọ́run ló gbà wọ́n láyè kí wọ́n máa ṣàkóso àti pé nígbà míì Ọlọ́run máa ń sọ bí ìṣàkóso wọn ṣe máa rí ṣáájú. Èyí hàn kedere látinú ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn aláṣẹ kan.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
12:17, 19. Tá a bá gbẹ̀san ohun burúkú tí wọ́n bá ṣe sí wa, ńṣe là ń gba iṣẹ́ Jèhófà ṣe. Ẹ ò rí i pé ìwà ọ̀yájú gbáà ló jẹ́ tá a bá lọ ń fi “ibi san ibi”?
14:14, 15. A ò gbọ́dọ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ará wa tàbí ká mú wọn kọsẹ̀ nípasẹ̀ oúnjẹ tàbí ohun mímu.
14:17. Ohun tá a jẹ tàbí tá a mu tàbí ohun tá a kò jẹ tàbí tá a kò mu kọ́ ló máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí ká má ní i. Kàkà bẹ́ẹ̀, níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ mọ́ jíjẹ́ olódodo, ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti ìdùnnú.
15:7. A gbọ́dọ̀ fi àìṣojúsàájú tẹ́wọ́ gba gbogbo àwọn tó ń fẹ́ òtítọ́ sínú ìjọ, ká sì máa sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo àwọn tí a bá bá pàdé.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ǹjẹ́ ẹbọ ìràpadà kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn ti dá kí Jésù tó san ìràpadà náà?