Ọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ—Èé Ṣe Tó Fi Ṣe Kókó?
TA NI kì í dúpẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá ní àṣẹ láti mú àwọn ọ̀daràn tó wá jí àwọn nǹkan ìní wa tàbí tó fẹ́ ṣe ìdílé wa léṣe? Ǹjẹ́ inú wa ò sì dùn pé ilé ẹjọ́ ní àṣẹ láti fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn láti lè dáàbò bo àwọn èèyàn láwùjọ?
A tún lè rántí àwọn iṣẹ́ ìlú tó ń ṣe wá láǹfààní, irú bí iṣẹ́ títún ọ̀nà ṣe, iṣẹ́ ìmọ́tótó, àti ẹ̀kọ́ ìwé—tó jẹ́ pé owó orí tí à ń san fún ìjọba ni wọ́n ń ná sórí nǹkan wọ̀nyí. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ló gbawájú nínú gbígbà pé ọ̀wọ̀ fún àwọn tó wà nípò àṣẹ ṣe kókó. Ṣùgbọ́n ibo ni ọ̀wọ̀ yẹn mọ? Nínú àwọn ọ̀ràn wo nínú ìgbésí ayé ló sì ti yẹ ká bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?
Àwọn Aláṣẹ Ìlú
Bíbélì sọ fún gbogbo èèyàn, yálà onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́, pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ ìlú, tí ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn aráàlú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Kristẹni kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Róòmù nípa èyí, yóò sì dáa ká gbé ohun tó sọ yẹ̀ wò, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú ìwé Róòmù orí kẹtàlá, ẹsẹ kìíní sí ìkeje.
Ará Róòmù ni Pọ́ọ̀lù, Róòmù sì ni agbára ayé nígbà yẹn. Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Tiwa, gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere nílùú. Ó kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
Àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe níhìn-ín ni pé ẹ̀dá ènìyàn kì bá ní ọlá àṣẹ kankan bí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run fàyè gbà á. Tí a bá tibẹ̀ yẹn wò ó, a óò rí i pé Ọlọ́run ló fi àwọn aláṣẹ onípò gíga sí ipò kan tó ní ààlà nínú ète rẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé “ẹni tí ó bá tako ọlá àṣẹ ti mú ìdúró kan lòdì sí ìṣètò Ọlọ́run.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ onípò gíga lè yin àwọn aráàlú tó bá ṣe rere, lẹ́sẹ̀ kan náà àwọn aláṣẹ wọ̀nyí lágbára láti fìyà jẹ àwọn arúfin. Àwọn tó ń ṣe búburú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí láti bẹ̀rù ẹ̀tọ́ tí àwọn aláṣẹ ní láti gbé ìgbésẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùgbẹ̀san,” nítorí pé àwọn ìjọba ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”
Pọ́ọ̀lù dé àlàyé rẹ̀ ládé nípa sísọ pé: “Nítorí náà, ìdí tí ń múni lọ́ranyàn wà fún yín láti wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe ní tìtorí ìrunú yẹn nìkan, ṣùgbọ́n ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹ̀lú. Nítorí ìdí nìyẹn tí ẹ fi ń san owó orí pẹ̀lú; nítorí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí gbogbo ènìyàn ní sísìn nígbà gbogbo fún ète yìí gan-an.”
Ọrùn àwọn aláṣẹ onípò gíga ni ẹrù iṣẹ́ bí wọ́n ṣe ná owó orí wà, kì í ṣe ọrùn ẹni tó san owó orí. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlúwàbí tí ń ṣòótọ́, Kristẹni kan máa ń ní ẹ̀rí ọkàn rere. Ó mọ̀ pé nípa fífi ara òun sábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, tí òun sì ń san owó orí òun bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, òun ń kọ́wọ́ ti àwọn ètò tó ń mú kí àwọn nǹkan máa lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀ láwùjọ, ṣùgbọ́n kò mọ síbẹ̀ o, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ó tún ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè.
Ìdílé àti Ọlá Àṣẹ
Ọlá àṣẹ inú ìdílé ńkọ́? Nígbà táa bá kọ́kọ́ bí ọmọ tuntun sílé ayé, ẹkún sísun tàbí igbe kíké ló fi máa ń pe àfiyèsí. Ṣùgbọ́n òbí tó mòye yóò mọ ohun tí ọmọ ọwọ́ náà ń fẹ́ gan-an, kò sì ní jẹ́ kí gbogbo igbe yẹn sọ òun di ràdàràdà. Àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé bí wọ́n ti ń dàgbà sí i, wọn kò ní ìkálọ́wọ́kò kankan, ṣe ni wọ́n sì ń dá ìpinnu tara wọn ṣe. Níwọ̀n bí wọn kò ti ní ìrírí, wọ́n lè di arúfin tàbí kí wọ́n máa hùwà àìtọ́ mìíràn, kí wọ́n máa da ilé àti ìgboro rú, gbogbo rẹ̀ ló kúkú ń ṣojú àwọn aláṣẹ àdúgbò.
Rosalind Miles, tó kọ ìwé Children We Deserve, sọ pé: “Ó ti máa ń pẹ́ jù káwọn òbí tó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ wí. Gbàrà téèyàn bá bímọ sílẹ̀ ló yẹ kó bẹ̀rẹ̀.” Bó bá jẹ́ pé láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá làwọn òbí ti ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ohùn sùúrù gbé ọlá àṣẹ kalẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí wọ́n ń sọ, kíá làwọn ọmọ wọ́n máa tẹ́wọ́ gba ọlá àṣẹ yẹn àti ìbáwí onífẹ̀ẹ́ tí ń bá a rìn.
Ìsọfúnni rẹpẹtẹ wà nínú Bíbélì nípa ọlá àṣẹ tó wà nínú ìdílé. Nínú ìwé Òwe, ọkùnrin ọlọgbọ́n náà, Sólómọ́nì, pe àfiyèsí sí ìṣọ̀kan àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá wà níwájú àwọn ọmọ wọn, ó sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi, sí ìbáwí baba rẹ, má sì ṣá òfin ìyá rẹ tì.” (Òwe 1:8) Bí ohùn àwọn òbí bá ṣọ̀kan níṣojú àwọn ọmọ wọn, àwọn ọmọ á mọ ohun táwọn òbí fẹ́ káwọn ṣe. Wọ́n lè gbìyànjú láti dẹ òbí kan sí èkejì, kí wọ́n lè ráyè ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, àmọ́ ọlá àṣẹ táwọn òbí fìmọ̀ ṣọ̀kan nípa rẹ̀ jẹ́ ààbò fún àwọn èwe.
Bíbélì ṣàlàyé pé ọkọ ló ni ẹrù iṣẹ́ pàtàkì láti bójú tó ire tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀, àti ti aya rẹ̀ pẹ̀lú. Èyí ni à ń pè ní ipò orí. Báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n lo ipò orí yìí? Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí i pé gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe jẹ́ Orí ìjọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkùnrin ṣe jẹ́ orí aya rẹ̀. Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ [tí í ṣe ìyàwó rẹ̀ nípa tẹ̀mí], tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Bí ọkùnrin kan bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, tó sì ń lo ipò orí tìfẹ́tìfẹ́, yóò jèrè “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” lọ́dọ̀ aya rẹ̀. (Éfésù 5:33) Àwọn ọmọ tó bá wà nínú irú agboolé bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú yóò rí ìjẹ́pàtàkì ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, yóò sì rọrùn fún wọn láti bọ̀wọ̀ fún un.—Éfésù 6:1-3.
Ọgbọ́n wo làwọn òbí tí ń dá tọ́mọ, títí kan àwọn tí ọkọ tàbí aya wọ́n ti kú, lè rí dá sí ọ̀ràn yìí? Yálà wọ́n jẹ́ bàbá tàbí ìyá, wọ́n lè tọ́ka sí ọlá àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi ní tààràtà. Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń fi ọlá àṣẹ sọ̀rọ̀—ìyẹn ọlá àṣẹ Bàbá rẹ̀ àti ọlá àṣẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí a mí sí.—Mátíù 4:1-10; 7:29; Jòhánù 5:19, 30; 8:28.
Bíbélì pèsè ọ̀pọ̀ ìlànà tó níye lórí nípa àwọn ìṣòro táwọn ọmọ ń dojú kọ. Bí òbí kan bá lè wá àwọn ìlànà yìí kàn, tó sì ń tẹ̀ lé wọn, yóò ṣeé ṣe fún un láti pèsè ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó wúlò fáwọn ọmọ. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22; Òwe 13:20; Mátíù 6:33; 1 Kọ́ríńtì 15:33; Fílípì 4:8, 9) Àwọn òbí tún lè tọ́ka sí àwọn ìsọfúnni táa gbé ka Bíbélì, èyí tí a ṣètò ní pàtó láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n lè mọyì àǹfààní bíbọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ Ìwé Mímọ́.a
Ìjọ Kristẹni àti Ọlá Àṣẹ
“Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà; ẹ fetí sí i.” (Mátíù 17:5) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí Jèhófà Ọlọ́run tìkára rẹ̀ sọ, fi hàn pé Ọlọ́run ló fún Jésù ní ọlá àṣẹ tó fi ń sọ̀rọ̀. Ohun tó sọ ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa.
Ní kété ṣáájú kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ rẹ̀, kì í ṣe kìkì pé Jésù ń dáàbò bo àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, tí ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ẹ̀mí mímọ́ ti bà lé wọn ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ló tún ti ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47; Ìṣe 2:1-36) Kí ló ti ṣe láti ṣe gbogbo èyí láṣeyọrí, kí ó bàa lè fún ìjọ Kristẹni lókun? “Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga lókè . . . , ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfésù 4:8) “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí ni àwọn Kristẹni alàgbà, tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn, tí a sì fún ní ọlá àṣẹ láti máa bójú tó ire tẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn.—Ìṣe 20:28.
Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” Níwọ̀n bí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyí ti ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù tímọ́tímọ́, láìsí àní-àní, yóò jẹ́ ipa ọ̀nà ọgbọ́n láti máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn. Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, [“kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ wọn lórí yín nígbà gbogbo,” The Amplified Bible] nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Hébérù 13:7, 17.
Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ táa bá tàpá sí irú ìtọ́ni bẹ́ẹ̀? Ohun tí àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni ìjímìjí ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, wọ́n sì di apẹ̀yìndà. Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára àwọn tó jin ìgbàgbọ́ àwọn kan lẹ́sẹ̀, tí àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ sì “fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́.” Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n ń polongo ni pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ó ṣeé ṣe kí wọ́n sọ pé ó ti ṣẹlẹ̀ nípa tẹ̀mí tàbí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àti pé nítorí náà, kò sí àjíǹde kankan mọ́ lọ́jọ́ iwájú lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—2 Tímótì 2:16-18.
Àwọn tó wà nípò àṣẹ ló wá rí sí ọ̀ràn náà. Ó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni alàgbà láti já irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ní koro, nítorí pé gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń ṣojú fún Jésù Kristi, wọ́n lo ọlá àṣẹ inú Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:16, 17) Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí lónìí nínú ìjọ Kristẹni, tí í ṣe “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Láéláé, a ò ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ èké ba “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” jẹ́, èyí tí a ti bá wa tọ́jú gẹ́gẹ́ bí ohun ìtọ́júpamọ́ àtàtà sínú Bíbélì.—2 Tímótì 1:13, 14.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ń pa rẹ́ lọ kíákíá nínú ayé, síbẹ̀ àwa Kristẹni gbà pé àwọn aláṣẹ yíyẹ tí ń bẹ láwùjọ, nínú ìdílé, àti nínú ìjọ Kristẹni wà fún àǹfààní wa. Ọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ ṣe kókó fún ire wa nípa ti ara, nípa ti èrò orí, àti nípa tẹ̀mí. Nípa títẹ́wọ́ gba irú ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, tí a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn, àwọn aláṣẹ gíga jù lọ—ìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi—yóò dáàbò bò wá fún ire wa ayérayé.—Sáàmù 119:165; Hébérù 12:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ ìwé méjèèjì yìí jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ìsọfúnni rẹpẹtẹ wà nínú Bíbélì nípa ọlá àṣẹ tó wà nínú ìdílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ lè tọ́ka sí ọlá àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi ní tààràtà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Kristẹni gbà pé àwọn aláṣẹ yíyẹ nínú ìdílé, nínú ìjọ Kristẹni, àti nínú ìlú, wà fún àǹfààní wọn
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Josh Mathes ló ya fọ́tò yìí, látinú Àkójọ ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà