-
Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun GbogboGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?
Jèhófà fẹ́ ká ‘máa bá ara wa sọ òtítọ́.’ (Sekaráyà 8:16, 17) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Bóyá àwọn ìdílé wa là ń bá sọ̀rọ̀, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, kò yẹ ká máa parọ́ tàbí ká fún wọn láwọn ìsọfúnni tó ń ṣini lọ́nà. Àwọn olóòótọ́ kì í ja àwọn míì lólè tàbí kí wọ́n lù wọ́n ní jìbìtì. (Ka Òwe 24:28 àti Éfésù 4:28.) Bákan náà, wọ́n máa ń san àwọn owó tó yẹ kí wọ́n san fún ìjọba. (Róòmù 13:5-7) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, tá a sì tún ń jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọ̀nà míì, ńṣe là ń fi hàn pé a “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
-
-
Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ ÒṣèlúGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 45
Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Má Ṣe Dá Sí Ogun àti Ọ̀rọ̀ Òṣèlú
Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Lára ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ogun. Ká sòótọ́, kò rọrùn láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Àwọn èèyàn lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run?
1. Èrò wo làwa Kristẹni tòótọ́ ní nípa ìjọba èèyàn?
Àwa Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba. A máa ń ṣègbọràn sí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì.” Ọ̀nà tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a máa ń ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè, irú bí òfin tó sọ pé ká máa san owó orí. (Máàkù 12:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló gba àwọn ìjọba èèyàn láyè láti máa ṣàkóso. (Róòmù 13:1) Torí náà, a mọ̀ pé ó níbi tí agbára wọn mọ. Ó sì dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro tó wà láyé.
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Bíi ti Jésù, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Nígbà táwọn kan rí ọ̀kan lára iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, wọ́n fẹ́ fi jọba, àmọ́ kò gbà fún wọn. (Jòhánù 6:15) Kí nìdí tí Jésù ò fi gbà? Ó sọ pé, “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Torí pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún ká lè fi hàn pé a ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, a kì í lọ́wọ́ sí ogun. (Ka Míkà 4:3.) A máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àmì orílẹ̀-èdè bí àsíá, àmọ́ a kì í júbà wọn. (1 Jòhánù 5:21) A kì í dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, bẹ́ẹ̀ la kì í ta kò wọ́n. Bákan náà, a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú láwọn ọ̀nà èyíkéyìí míì. Ńṣe ni èyí ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan la fara mọ́.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú àtàwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu táá múnú Jèhófà dùn.
3. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú
Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa. Ka Róòmù 13:1, 5-7 àti 1 Pétérù 2:13, 14. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a tẹrí ba fún wọn?
Nígbà ogun, àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń sọ pé àwọn kì í dá sí ogun, àmọ́ wọ́n máa ń fi owó tàbí àwọn ohun ìjà ṣètìlẹyìn fáwọn tó ń jagun. Ṣé a lè sọ pé wọn ò dá sí ogun lóòótọ́? Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí ogun tàbí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Ka Jòhánù 17:16. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Kí ló yẹ ká ṣe táwọn aláṣẹ bá sọ pé ká ṣe ohun tó ta ko òfin Ọlọ́run? Ka Ìṣe 5:28, 29. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Tí ìjọba bá ní ká ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́, ta ló yẹ ká ṣègbọràn sí?
Ṣé o lè sọ àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ìjọba lè ní káwa Kristẹni ṣe àmọ́ tá ò ní ṣègbọràn sí wọn?
4. Má ṣe dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò àti ìṣe rẹ
Ka 1 Jòhánù 5:21. Lẹ́yìn náà, wo FÍDÍÒ yìí kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí nìdí tí Ayenge fi pinnu pé òun ò ní dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú, òun ò sì ní tẹrí ba fún àsíá orílẹ̀-èdè?
Ṣé o rò pé ìpinnu tó ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu?
Àwọn nǹkan míì wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Tó bá dọ̀rọ̀ eré ìdárayá, kí la lè ṣe ká má bàa ṣohun tó fi hàn pé a ka orílẹ̀-èdè wa sí pàtàkì ju àwọn orílẹ̀-èdè míì lọ?
Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn olóṣèlú fẹ́ ṣe máa pa wá lára tàbí ṣe wá láǹfààní?
Báwo ni ohun táwọn oníròyìn ń gbé jáde àtàwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe lè mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí ló dé tẹ́ ò kì í tẹrí ba fún àsíá tàbí kẹ́ ẹ kọ orin orílẹ̀-èdè?”
Kí lo máa sọ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Àwọn Kristẹni máa ń sapá gan-an kí wọ́n má bàa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn.
Kí lo rí kọ́?
Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ìjọba èèyàn?
Kí nìdí táwa Kristẹni ò fi ń dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè fẹ́ mú ká dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
ṢÈWÁDÌÍ
Àwọn nǹkan tí ò rọrùn wo ló lè gba pé ká ṣe tá ò bá fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Kí ni ìdílé lè ṣe láti múra sílẹ̀ ṣáájú fún àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú?
Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Tó O Bá Wà Níbi Tí Wọ́n Ti Ń Kí Àsíá (4:25)
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn máa ṣe ohun táá gbé orílẹ̀-èdè ẹ̀ ga kọ́ lohun tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè ṣe?
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bí o ò ṣe ní jẹ́ “apá kan ayé” tó o bá fẹ́ pinnu irú iṣẹ́ tí wàá ṣe.
“Olúkúlùkù Ni Yóò Ru Ẹrù Ti Ara Rẹ̀” (Ilé Ìṣọ́, March 15, 2006)
-