Gbọ́ Ohun Tí Ẹ̀mí Ní Í Sọ
“Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”—AÍSÁYÀ 30:21.
1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn sọ̀rọ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé?
AWÒ awọ̀nàjíjìn kan tó ní rédíò alátagbà wà ní erékùṣù Puerto Rico, awò kan ṣoṣo ló ní, òun ló sì fẹ̀ jù lọ, tó tún lágbára jù lọ lágbàáyé. Àtọdúnmọ́dún, àtoṣùmóṣù làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti jókòó ti irinṣẹ́ gàgàgúgú yìí, tí wọ́n ń retí àtigbọ́ ohùn àwọn ará ọ̀run. Wọ́n ti retí-retí, wọn ò tíì gbọ́ nǹkan kan di báa ti ń wí yìí o. Àmọ́, ohun tí wọ́n ń wá lọ sí Ṣókótó wà lápò ṣòkòtò, àní ìsọfúnni kedere látòde ọ̀run pọ̀ rẹpẹtẹ tí olúkúlùkù wa lè gbọ́ nígbàkigbà—láìlo irinṣẹ́ dídíjú. Ìsọfúnni wọ̀nyí ń wá láti Orísun kan tó ga gidigidi ju ibi táwọn èèyàn yìí rò pé ìsọfúnni yóò ti wá lájùlé ọ̀run. Ta ni Orísun irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀, àwọn wo ló sì ń rí i gbà? Kí ló wà nínú ìsọfúnni náà?
2 Àkọsílẹ̀ Bíbélì ròyìn àwọn ìgbà mélòó kan táwọn èèyàn fetí gbọ́ ìsọfúnni àtọ̀runwá. Nígbà míì, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, ońṣẹ́ Ọlọ́run, ló wá jẹ́ iṣẹ́ wọ̀nyí. (Jẹ́nẹ́sísì 22:11, 15; Sekaráyà 4:4, 5; Lúùkù 1:26-28) Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn gbọ́ ohùn Jèhófà alára. (Mátíù 3:17; 17:5; Jòhánù 12:28, 29) Ọlọ́run tún gbẹnu àwọn wòlíì tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn tó gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ṣàkọsílẹ̀ ohun tó mí sí wọn láti sọ. Lónìí, a ní Bíbélì, níbi táa kọ púpọ̀ nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí, títí kan àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti tàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Hébérù 1:1, 2) Nítorí náà, kì í ṣòní, kì í ṣàná ni Jèhófà ti ń tàtaré ìsọfúnni sáwọn ẹ̀dá rẹ̀ tó jẹ́ ènìyàn.
3. Kí ni ète àwọn ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kí sì ni ojúṣe wa?
3 Gbogbo ìsọfúnni onímìísí wọ̀nyí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kò sọ púpọ̀ nípa àgbáálá ayé tó ṣeé fojú rí. Àwọn nǹkan pàtàkì ni ìsọfúnni wọ̀nyí dá lé lórí, àwọn nǹkan tó kan ìgbésí ayé wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. (Sáàmù 19:7-11; 1 Tímótì 4:8) Nípasẹ̀ ìsọfúnni wọ̀nyí ni Jèhófà fi ń sọ fún wa nípa ohun tí òun fẹ́, ó sì ń tipasẹ̀ wọn tọ́ wa sọ́nà. Ìsọfúnni wọ̀nyí jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà fi ń ní ìmúṣẹ, pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Jèhófà kì í fi túláàsì mú wa láti tẹ́tí sí “ọ̀rọ̀” rẹ̀. Ọwọ́ wa ló wà láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ká sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ìdí abájọ rèé tí Ìwé Mímọ́ fi gbà wá níyànjú pé ká fetí sí ìsọfúnni látọ̀dọ̀ Jèhófà. Nínú ìwé Ìṣípayá, ẹ̀ẹ̀meje ni ọ̀rọ̀ ìṣírí náà láti “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ” fara hàn.—Ìṣípayá 2:7, 11, 17, 29; 3:6, 13, 22.
4. Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti máa retí lóde òní pé kí Ọlọ́run bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà látọ̀run?
4 Lóde òní, Jèhófà kò bá wa sọ̀rọ̀ tààrà láti àjùlé ọ̀run mọ́. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá, àwọn ìgbà tó báni sọ̀rọ̀ látọ̀runwá ṣọ̀wọ́n, nígbà míì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rúndún máa ń kọjá tí kì í sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Látọjọ́ táláyé ti dáyé, ni Jèhófà kì í ti í sábà bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyí láyé ìsinyìí. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà gbà ń bá wa sọ̀rọ̀ lóde òní yẹ̀ wò.
‘Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ló Ní Ìmísí’
5. Kí ni lájorí ohun èlò tí Jèhófà fi ń bá wa sọ̀rọ̀ lóde òní, báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní látinú rẹ̀?
5 Bíbélì ni lájorí ohun èlò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín Ọlọ́run àtènìyàn. Ọlọ́run ló mí sí i, gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ ló sì lè ṣe wá láǹfààní. (2 Tímótì 3:16) Bíbélì kún fún àpẹẹrẹ àwọn èèyàn gidi tó pinnu láyè ara wọn, yálà láti fetí sí ohùn Jèhófà àbí láti má ṣe fetí sí i. Àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ rán wa létí ìdí tó fi ṣe kókó láti fetí sóhun tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Bíbélì tún ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ nínú, ó máa ń gbà wá nímọ̀ràn nígbà táa bá dojú kọ ìpinnu nínú ìgbésí ayé. Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn wa, tó ń sọ̀rọ̀ sí wa létí, pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”
6. Èé ṣe tí Bíbélì kì í fi í ṣẹgbẹ́ gbogbo ìwé tó kù?
6 Láti lè gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ nínú Bíbélì, a gbọ́dọ̀ máa kà á déédéé. Bíbélì kì í kàn-án ṣe ọ̀kan lára ìwé táwọn akọ̀wé-kọwúrà kọ, tàbí ìwé kan tó kàn gbajúmọ̀, torí àìmọye irú ìwé wọ̀nyí ló wà lóde òní. Ẹ̀mí ló mí sí Bíbélì, èrò inú Ọlọ́run ló sì wà nínú rẹ̀. Hébérù orí kẹrin, ẹsẹ ìkejìlá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” Bí a ti ń ka Bíbélì, ńṣe ni àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ máa ń wọ èrò inú wa lọ́hùn-ún, ó sì máa ń gúnni bí idà, ó máa ń jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé wa ṣe bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tó.
7. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa ka Bíbélì, báwo ló sì ṣe yẹ kí kíkà á ṣe déédéé tó?
7 Àwọn “ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà” lè yí padà bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àti bí ìrírí ayé ṣe ń nípa lórí wa—àwọn ìrírí tó lárinrin àtàwọn èyí tó le koko. Bí a kì í bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo, ìrònú wa, ìṣarasíhùwà wa, àti èrò wa lè máà sí níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ṣí wa létí pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Bí a bá fẹ́ máa bá a nìṣó ní gbígbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ, a ní láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn náà pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́.—Sáàmù 1:2.
8. Ọ̀rọ̀ wo, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ, la lè fi yẹ ara wa wò nípa ọ̀ràn Bíbélì kíkà?
8 Ìránnilétí pàtàkì kan rèé fáwọn olùka Bíbélì: Ẹ fàyè tó tó sílẹ̀, kí ohun tẹ́ẹ ń kà lè wọ̀ yín lọ́kàn dáadáa! A ò lè tìtorí pé a fẹ́ tiraka láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí à ń gbọ́ pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká wá máa sáré ka àwọn orí mélòó kan lọ gbuurugbu, láìlóye ohun tí à ń kà. Òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì láti máa ka Bíbélì déédéé, àmọ́ kì í kàn-án ṣe tìtorí títẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan la fi ń kà á; ohun tó yẹ kó wà ní góńgó ẹ̀mí wa ni ìfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀. Látàrí èyí, a lè wá fi ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yẹ ara wa wò. Nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Mo tẹ eékún mi ba fún Baba, kí ó bàa lè yọ̀ǹda fún yín . . . láti mú kí Kristi máa gbé inú ọkàn-àyà yín pẹ̀lú ìfẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín; kí ẹ lè ta gbòǹgbò, kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà, kí ẹ̀yin pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ bàa lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́, àti láti mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí Ọlọ́run ń fúnni kún yín.”—Éfésù 3:14, 16-19.
9. Báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà dàgbà, kó sì jinlẹ̀ lọ́kàn wa?
9 Tí a óò bá sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn kan wà lára wa tí ìwé kíkà ò bá lára mu rárá, àwọn míì sì rèé, ọ̀jẹ̀wé ni wọ́n. Àmọ́ ṣá o, bó ti wù kó rí lára wa, a lè mú ìfẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà dàgbà, kó sì jinlẹ̀ lọ́kàn wa. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé ó yẹ ká máa yán hànhàn fún ìmọ̀ Bíbélì, ó sì gbà pé ó lè di dandan láti mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà. Ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Pétérù 2:2) Ìsẹ́ra-ẹni ṣe pàtàkì bí a óò bá “ní ìyánhànhàn” fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè wá kúndùn oúnjẹ kan tí a ò jẹ rí, lẹ́yìn títọ́ ọ wò lẹ́ẹ̀mélòó kan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìwé kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ lè wá rọ̀ wá lọ́rùn, báa bá sẹ́ ara wa, táa sì fi ìlànà ṣíṣe nǹkan déédéé kọ́ra.
‘Oúnjẹ ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’
10. Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” báwo sì ni Jèhófà ṣe ń lò wọ́n lóde òní?
10 Ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà ń bá wa sọ̀rọ̀ lónìí ni Jésù tọ́ka sí nínú Mátíù 24:45-47. Níbẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa ìjọ Kristẹni ẹni àmì òróró tí a fi ẹ̀mí yàn—ìyẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí a yàn láti máa pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ yìí ni “ará ilé” Jésù. Àwọn wọ̀nyí, pa pọ̀ pẹ̀lú “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn,” ń rí ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà gbà. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Ọ̀pọ̀ lára oúnjẹ tó bákòókò mu yìí ni a ń rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde bí Ilé Ìṣọ́, Jí!, àtàwọn míì. A tún ń rí àfikún oúnjẹ tẹ̀mí gbà nípasẹ̀ àsọyé àti àṣefihàn láwọn ìpàdé àgbègbè, ìpàdé àyíká, àkànṣe, àtàwọn ìpàdé ìjọ.
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ elétí ọmọ nígbà tí ẹ̀mí bá ń gbẹnu “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bá wa sọ̀rọ̀?
11 Ìsọfúnni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè wà fún fífún ìgbàgbọ́ wa lókun, ó sì ń kọ́ agbára ìwòye wa. (Hébérù 5:14) Irú ìmọ̀ràn yẹn lè jẹ́ ti gbogbo gbòò, kí kálukú lè mú èyí tó kàn án nínú rẹ̀ lò. Látìgbà dégbà, wọ́n tún máa ń fún wa nímọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn apá kan pàtó nínú ìwà wa. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ là ń fetí sí ohun tí ẹ̀mí ń gbẹnu ẹgbẹ́ ẹrú náà sọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dáhùn, ó ní: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.” (Hébérù 13:17) Lóòótọ́, aláìpé ni gbogbo àwa táa wà nínú ètò yìí. Àmọ́, ó wu Jèhófà láti lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn náà, láti máa tọ́ wa sọ́nà lákòókò òpin yìí.
Ìtọ́sọ́nà Látọ̀dọ̀ Ẹ̀rí Ọkàn Wa
12, 13. (a) Kí ni orísun ìtọ́sọ́nà míì tí Jèhófà fún wa? (b) Agbára rere wo ni ẹ̀rí ọkàn lè sà, àní lórí àwọn èèyàn tí kò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàápàá?
12 Jèhófà tún fún wa ni orísun ìtọ́sọ́nà míì—ìyẹn ni ẹ̀rí ọkàn wa. Ó dá ohun kan mọ́ ènìyàn tó ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́. Ara àbùdá wa ni. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn ará Róòmù, ó ṣàlàyé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.”—Róòmù 2:14, 15.
13 Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò mọ Jèhófà ló lè mú ìrònú àti ìṣesí wọn bá àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́ mu, títí dé àyè kan. Ṣe ló dà bíi pé wọ́n ń gbọ́ ohùn kan tó ń dún fíntínfíntín nínú wọn lọ́hùn-ún, tó ń tọ́ wọn sọ́nà tó tọ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀ fáwọn tí kò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, mélòómélòó ló yẹ kí ohùn inú yẹn sọ̀rọ̀ fáwọn Kristẹni tòótọ́! Dájúdájú, ẹ̀rí ọkàn Kristẹni tí ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́, tó sì ń ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, lè pèsè ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.—Róòmù 9:1.
14. Báwo ni ẹ̀rí ọkàn táa fi Bíbélì kọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí Jèhófà?
14 Ẹ̀rí ọkàn rere, èyí táa fi Bíbélì kọ́, lè rán wa létí ọ̀nà tí ẹ̀mí fẹ́ ká tọ̀. Àwọn ìgbà míì lè wà tí Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tí ń ṣàlàyé Bíbélì kò sọ nǹkan kan pàtó nípa ipò kan táa bá ara wa. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀rí ọkàn wa lè ta wá lólobó, kí ó kì wá nílọ̀ nípa irú ipa ọ̀nà kan tó lè mú wa kàgbákò. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kíkọ etí ikún sóhun tí ẹ̀rí ọkàn wa sọ lè já sí kíkọ etí ikún sóhun tí ẹ̀mí Jèhófà wí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, táa bá fi kọ́ra láti máa gbára lé ẹ̀rí ọkàn Kristẹni wa táa ti kọ́, a lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání, kódà nígbà tí kò bá sí ìtọ́ni pàtó lákọọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n o, ó ṣe kókó láti fi sọ́kàn pé nígbà tí kò bá sí ìlànà, tàbí ọ̀pá ìdiwọ̀n, tàbí òfin àtọ̀runwá, kò ní bọ́ sí i rárá láti sọ ọ́ di kàráǹgídá fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa láti tẹ̀ lé ìpinnu táa dá ṣe nínú ẹ̀rí ọkàn wa nípa àwọn ọ̀ràn tó jẹ́ èyí-wù-mí-ò-wù-ẹ́.—Róòmù 14:1-4; Gálátíà 6:5.
15, 16. Kí ló lè jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gbòdì, báwo sì ni a ṣe lè dènà irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
15 Ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, táa fi Bíbélì kọ́, jẹ́ ẹ̀bùn rere látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:17) Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ẹ̀bùn yìí kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè sọ ọ́ dìbàjẹ́, bí yóò bá máa ṣiṣẹ́ dáadáa gẹ́gẹ́ bí atọ́nà ìwà rere. Báa bá ń tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, àtàwọn ìwà tó tako ìlànà Ọlọ́run, wọ́n lè jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gbòdì, tí kò fi ní lè tọ́ wa sọ́nà títọ́ mọ́. A lè wá di ẹni tí kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wa yàtọ̀ sí tòsì mọ́, àní a lè bẹ̀rẹ̀ sí tan ara wa jẹ, ká wá máa pe ohun tó burú ní rere.—Fi wé Jòhánù 16:2.
16 Báa bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa kọtí ikún sí ìkìlọ̀ ẹ̀rí ọkàn wa, nígbà tó bá pariwo-pariwo, ohùn rẹ̀ á há, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ a lè wá jingíri sínú ìwà ìbàjẹ́ tàbí kí ọkàn wa yigbì. Àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni onísáàmù ń sọ̀rọ̀ wọn nígbà tó sọ pé: “Ọkàn-àyà wọn ti di aláìnímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá.” (Sáàmù 119:70) Àwọn kan tó máa ń kọtí ikún sí ìkìlọ̀ ẹ̀rí ọkàn wọn kì í mọnúúrò mọ́. Àwọn ìlànà Ọlọ́run kọ́ ló ń darí wọn mọ́, wọn kì í sì í lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Láti lè yẹra fún irú ipò bẹ́ẹ̀, ẹ yáa jẹ́ ká máa ṣègbọràn sí ẹ̀rí ọkàn Kristẹni wa, bó tiẹ̀ jọ pé ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ ò tó nǹkan.—Lúùkù 16:10.
Aláyọ̀ Làwọn Tó Ń Fetí Sílẹ̀, Tó sì Ń Ṣègbọràn
17. Báwo la ó ṣe rí ìbùkún gbà báa ti ń fetí sí ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa,’ táa sì ń ṣègbọràn sí ẹ̀rí ọkàn wa táa fi Bíbélì kọ́?
17 Jèhófà yóò máa fi ẹ̀mí rẹ̀ bù kún wa báa ti ń sọ ọ́ dàṣà láti máa fetí sí ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wa’—bí Ìwé Mímọ́ àti ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti ń gbé ọ̀rọ̀ náà wá—àti báa ti ń kọbi ara sí àwọn ìránnilétí tí ẹ̀rí ọkàn wa táa ti fi Bíbélì kọ́ ń tẹ̀ mọ́ wa létí. Ẹ̀wẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ yóò jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti tẹ́wọ́ gba ohun tí Jèhófà ń sọ, ká sì lóye rẹ̀.
18, 19. Báwo ni ìtọ́sọ́nà Jèhófà ṣe lè ṣàǹfààní fún wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti nínú ìgbé-ayé wa?
18 Ẹ̀mí Jèhófà pẹ̀lú yóò ki wá láyà láti fi ọgbọ́n àti ìgboyà dojú kọ àwọn ipò lílekoko. Gẹ́gẹ́ bó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì, ẹ̀mí Ọlọ́run lè ru agbára ìrònú wa sókè, kí ó sì máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà gbogbo láti gbégbèésẹ̀ àti láti máa sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. (Mátíù 10:18-20; Jòhánù 14:26; Ìṣe 4:5-8, 13, 31; 15:28) Àpapọ̀ ẹ̀mí Jèhófà àti akitiyan àwa fúnra wa, yóò jẹ́ ká kẹ́sẹ járí báa ti ń ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nínú ìgbésí ayé, a ó sì ní ìgboyà láti dúró gbọn-in ti àwọn ìpinnu náà. Fún àpẹẹrẹ, o lè máa ronú nípa ṣíṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ, kí o lè ṣètò àkókò púpọ̀ sí i fáwọn nǹkan tẹ̀mí. Tàbí kẹ̀, o lè dojú kọ àwọn yíyàn kan tó ṣe pàtàkì, tó máa yí ìgbésí ayé ẹ padà, irú bíi yíyan ẹni tóo fẹ́ fẹ́, ṣíṣe ìpinnu lórí iṣẹ́ kan tóo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí, tàbí ríra ilé kan. Dípò wíwulẹ̀ fi ìwàǹwára ṣe ìpinnu, ẹ dákun ẹ jẹ́ ká máa fetí sí ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run ní í sọ, kí a sì gbégbèésẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
19 Ká sòótọ́, a mọrírì àwọn ìránnilétí àti ìmọ̀ràn onínúure táa ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, pàápàá àwọn alàgbà. Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa dúró dìgbà táwọn ẹlòmíì bá pe àfiyèsí wa sáwọn nǹkan. Báa bá mọ ipa ọ̀nà ọgbọ́n tó yẹ ká tọ̀, táa sì mọ àwọn àtúnṣe tó yẹ ká ṣe nínú ìṣesí àti ìwà wa, ká lè mú inú Ọlọ́run dùn, ẹ jẹ́ ká ṣe é. Jésù sá sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:17.
20. Ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn tó ń fetí sí ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wọn’?
20 Ó ṣe kedere pé, kò dìgbà táwọn Kristẹni bá gbọ́ ohùn kan látọ̀run, tàbí tí áńgẹ́lì bá yọ sí wọn, kí wọ́n tó lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ṣebí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táa kọ sílẹ̀ ń bẹ níkàáwọ́ wọn, ṣebí ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé sì ń pèsè ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́. Bí wọ́n bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ kọbi ara sí ‘ọ̀rọ̀ tí ń dún lẹ́yìn wọn,’ tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí ọkàn wọn tí wọ́n fi Bíbélì kọ́, wọ́n óò kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sì dájú pé wọn óò rí ìmúṣẹ ìlérí àpọ́sítélì Jòhánù, tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
Àtúnyẹ̀wò Ráńpẹ́
• Èé ṣe tí Jèhófà fi ń bá àwọn ẹ̀dá rẹ̀ tó jẹ́ ènìyàn sọ̀rọ̀?
• Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ètò kíkà Bíbélì déédéé?
• Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú náà?
• Èé ṣe tí kò fi yẹ ká kọtí ikún sóhun tí ẹ̀rí ọkàn táa fi Bíbélì kọ́ bá ń sọ fún wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Èèyàn ò nílò irinṣẹ́ dídíjú láti lè rí ìsọfúnni gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Arecibo Observatory/David Parker/Science Photo Library
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì àti nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”