Ẹ̀KỌ́ 35
Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dáa
Gbogbo wa la máa ń ṣe ìpinnu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lè ṣe wá láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún wa. Bákan náà, wọ́n lè mú ká sún mọ́ Jèhófà tàbí ká jìnnà sí i. Lára àwọn ìpinnu tá a máa ń ṣe ni ibi tá a máa gbé, iṣẹ́ tá a máa ṣe, tàbí bóyá a máa ní ọkọ tàbí ìyàwó. Tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, ayé wa máa dùn, àá sì máa ṣohun tó máa múnú Jèhófà dùn.
1. Báwo lo ṣe lè lo Bíbélì láti ṣe ìpinnu tó dáa?
Kó o tó ṣàwọn ìpinnu pàtàkì, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o sì wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà. (Ka Òwe 2:3-6.) Nígbà míì, o lè ráwọn ibi tí Jèhófà ti pàṣẹ nínú Bíbélì pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan tàbí pé ohun báyìí ni ká ṣe. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kó o tẹ̀ lé àwọn àṣẹ yẹn.
Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe tí Bíbélì ò bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní pàtó? Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, ó ṣì máa jẹ́ kó o mọ “ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.” (Àìsáyà 48:17) Báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Àwọn ìlànà tó lè tọ́ ẹ sọ́nà wà nínú Bíbélì. Àwọn ìlànà Bíbélì ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ń jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan. Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá ka ìtàn kan nínú Bíbélì, ó máa jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan. Tá a bá sì mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, èyí á jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó máa múnú rẹ̀ dùn.
2. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn kó o tó ṣèpinnu?
Bíbélì sọ pé: “Aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” (Òwe 14:15) Torí náà, ká tó ṣèpinnu, ó yẹ ká fara balẹ̀ dáadáa, ká sì ronú jinlẹ̀ nípa ohun tá a fẹ́ ṣe. Bó o ṣe ń ronú nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpinnu tó o fẹ́ ṣe, bi ara ẹ pé: ‘Ìlànà Bíbélì wo ló sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí? Ìpinnu wo ni mo lè ṣe tó máa jẹ́ kí n ní àlàáfíà, kí ọkàn mi sì balẹ̀? Ṣé ìpinnu tí mo fẹ́ ṣe yìí ò ní kó bá àwọn ẹlòmíì? Ìbéèrè tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ṣé ìpinnu yìí á múnú Jèhófà dùn?’—Diutarónómì 32:29.
Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ ohun tó yẹ ká ṣe àtohun tí kò yẹ ká ṣe. Tá a bá mọ àwọn òfin àtàwọn ìlànà rẹ̀ dáadáa, tá a sì pinnu pé àá máa tẹ̀ lé wọn, ẹ̀rí ọkàn wa á máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Ẹ̀rí ọkàn ni ohun tí Jèhófà dá mọ́ wa, tó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó dáa àtohun tí kò dáa. (Róòmù 2:14, 15) Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, á jẹ́ ká máa ṣàwọn ìpinnu tó dáa.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká túbọ̀ wo bí àwọn ìlànà Bíbélì àti ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè mú ká máa ṣe ìpinnu tó dáa.
3. Jẹ́ kí Bíbélì máa tọ́ ẹ sọ́nà
Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Òmìnira wo ni Jèhófà fún gbogbo wa?
Kí nìdí tí Jèhófà fi fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá?
Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún wa tó máa jẹ́ ká lo òmìnira wa lọ́nà tó dáa jù lọ?
Kó o lè rí àpẹẹrẹ ìlànà Bíbélì kan, ka Éfésù 5:15, 16. Lẹ́yìn náà, sọ bó o ṣe lè ‘lo àkókò ẹ lọ́nà tó dára jù lọ’ kó o lè . . .
máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.
jẹ́ ọkọ, aya, òbí tàbí ọmọ rere.
máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ.
4. Kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ kó lè máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó dáa
Tí òfin pàtó bá wà nínú Bíbélì nípa ohun tó yẹ ká ṣe tàbí ohun tá ò gbọ́dọ̀ ṣe, ó sábà máa ń rọrùn láti mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Àmọ́, kí la máa ṣe tí kò bá sírú àwọn òfin bẹ́ẹ̀? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, báwo ni arábìnrin yẹn ṣe kọ́ ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ kó lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ káwọn míì bá wa ṣe ìpinnu tó yẹ káwa fúnra wa ṣe? Ka Hébérù 5:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló yẹ kí àwa fúnra wa lè fi ìyàtọ̀ sí táwọn ẹlòmíì bá tiẹ̀ lè bá wa ṣèpinnu?
Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti ṣe fún wa tó lè jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ká sì lè ṣàwọn ìpinnu tó dáa?
5. Bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì
Ìpinnu wa máa ń yàtọ̀ síra. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì yìí:
Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́: Arábìnrin kan fẹ́ràn kó máa tọ́jú tọ́tè. Àmọ́, ó wá kó lọ sí àdúgbò míì táwọn ará ò ti gbà pé ó bójú mu kéèyàn máa tọ́jú tọ́tè.
Ka Róòmù 15:1 àti 1 Kọ́ríńtì 10:23, 24, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Pẹ̀lú ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ni arábìnrin yẹn lè ṣe? Ká sọ pé o fẹ́ ṣe ohun kan tí kò da ẹ̀rí ọkàn ẹ láàmú, àmọ́ tó ń da ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíì láàmú, kí ni wàá ṣe?
Àpẹẹrẹ kejì: Arákùnrin kan mọ̀ pé Bíbélì ò sọ pé kéèyàn má mu ọtí, tó bá ṣáà ti jẹ́ níwọ̀nba. Àmọ́ arákùnrin yìí ti pinnu pé òun ò ní máa mu ọtí. Wọ́n wá pè é síbi àpèjẹ kan tí àwọn ará ti ń mu ọtí.
Ka Oníwàásù 7:16 àti Róòmù 14:1, 10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Pẹ̀lú ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ni kò yẹ kí arákùnrin yẹn ṣe? Kí lo máa ṣe tó o bá rí i pé ẹnì kan ń ṣe ohun kan tí kò bá ẹ̀rí ọkàn tìẹ mu?
Bó o ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa
1. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.—Jémíìsì 1:5.
2. Ṣe ìwádìí nínú Bíbélì àtàwọn ìwé àti fídíò tó ń ṣàlàyé Bíbélì. O tún lè fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn.
3. Máa ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ tó o bá ń ṣèpinnu. Ronú nípa àkóbá tó lè ṣe fún ẹ, kó o sì wò ó bóyá kò ní da ẹ̀rí ọkàn àwọn míì láàmú.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ohun tó bá wù mi ni mo lè ṣe. Kò sóhun tó kàn mí pẹ̀lú bó ṣe rí lára àwọn ẹlòmíì.”
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan àti bó ṣe máa rí lára àwọn míì?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, ká sì wò ó bóyá ohun tá a fẹ́ ṣe yẹn máa ṣe àwọn míì láǹfààní àbí ó máa ṣàkóbá fún wọn.
Kí lo rí kọ́?
Báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn?
Báwo lo ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ?
Báwo lo ṣe lè máa fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn míì?
ṢÈWÁDÌÍ
Báwo lo ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
“Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga” (Ilé Ìṣọ́, April 15, 2011)
Wo fídíò yìí kó o lè túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn.
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu kan tí kò rọrùn.
Ka ìwé yìí kó o lè túbọ̀ mọ bó o ṣe lè ṣohun tó máa múnú Jèhófà dùn nígbà tí kò bá sí òfin kan pàtó nínú Bíbélì nípa ohun tó o fẹ́ ṣe.
“Ṣé Ìgbà Tó O Bá Rí Òfin Bíbélì Lo Tó Lè Ṣe Ohun Tó Yẹ?” (Ilé Ìṣọ́, December 1, 2003)