Ẹ Má Ṣe Dẹ́kun Pípàdé Pọ̀
Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:25) Ní tòótọ́, a sọ pé káwọn Kristẹni tòótọ́ máa kóra jọ pọ̀ síbi ìjọsìn kí wọ́n sì ‘gba ti ara wọn rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’—Hébérù 10:24.
NÍ ÀKÓKÒ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, tẹ́ńpìlì ńlá kan wà ní Jerúsálẹ́mù, ibẹ̀ làwọn Júù sì ti ń jọ́sìn. Àwọn sínágọ́gù náà wà nígbà yẹn. Jésù “kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì, níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọpọ̀ sí.”—Jòhánù 18:20.
Irú ibi ìpàdé wo ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa kóra jọpọ̀ láti fún ara wọn níṣìírí? Ṣé àwọn ilé ńláńlá táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ fi ohunkóhun jọ ti ìṣètò tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù? Ìgbà wo làwọn tí wọ́n ní Kristẹni làwọn bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ilé ìjọsìn ńláńlá wọ̀nyí?
‘Ilé fún Orúkọ Ọlọ́run’
Inú ìwé Ẹ́kísódù la ti kọ́kọ́ pàṣẹ kíkọ́ ilé ìjọsìn Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé kí wọ́n kọ́ “àgọ́ ìjọsìn,” tàbí “àgọ́ ìpàdé.” Inú ibẹ̀ ni wọ́n á gbé àpótí májẹ̀mú àtàwọn ohun èlò mímọ́ mìíràn sí. “Ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà” nígbà tí wọ́n kọ́ ọ tán ní 1512 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àgọ́ kékeré yìí ni lájorí ibi tí Ọlọ́run ṣètò pé káwọn èèyàn ti máa bá òun sọ̀rọ̀ fún ohun tó lé ní ọ̀rúndún mẹ́rin. (Ẹ́kísódù, orí 25 sí 27; 40:33-38) Bíbélì tún pe àgọ́ yìí ní “tẹ́ńpìlì Jèhófà” àti “ilé Jèhófà.”—1 Sámúẹ́lì 1:9, 24.
Nígbà tó yá, tí Dáfídì di ọba ní Jerúsálẹ́mù, ó wù ú gan-an láti kúkú kọ́ ilé gidi kan láti fi gbé ògo Jèhófà ga. Àmọ́ jagunjagun ni Dáfídì, ìdí rèé tí Jèhófà fi sọ fún un pé: “Ìwọ kì yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi.” Ó wá yan ọmọ Dáfídì, ìyẹn Sólómọ́nì láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíróníkà 22:6-10) Sólómọ́nì ya tẹ́ńpìlì náà sí mímọ́ lọ́dún 1026 ṣáájú Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn odidi ọdún méje ààbọ̀ tí wọ́n fi kọ́ ilé náà. Jèhófà fọwọ́ sí ilé yìí, ó sọ pé: “Mo ti sọ ilé yìí tí o kọ́ di mímọ́ nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin; dájúdájú, ojú mi àti ọkàn-àyà mi yóò sì wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.” (1 Ọba 9:3) Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ti lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́, Jèhófà náà á máa ṣojú rere sí ilé náà. Àmọ́ tí wọ́n bá lọ dáwọ́ rere ṣíṣe dúró pẹ́nrẹ́n, Jèhófà ò ní ṣojú rere sí i mọ́, ‘ilé náà yóò sì di òkìtì àwókù.’—1 Ọba 9:4-9; 2 Kíróníkà 7:16, 19, 20.
Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. (2 Ọba 21:1-5) “Nítorí náà, [Jèhófà] gbé ọba àwọn ará Kálídíà dìde sí wọn, ẹni tí ó . . . fi iná sun ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì bi ògiri Jerúsálẹ́mù wó; gbogbo àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ sì ni wọ́n fi iná sun àti gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra pẹ̀lú, láti lè mú ìparun wá. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ idà lọ sí Bábílónì ní òǹdè, wọ́n sì wá di ìránṣẹ́ fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa lèyí ṣẹlẹ̀.—2 Kíróníkà 36:15-21; Jeremáyà 52:12-14.
Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run lo Kírúsì Ọba Páṣíà láti gba àwọn Júù sílẹ̀ lọ́wọ́ agbára Bábílónì. (Aísáyà 45:1) Lẹ́yìn tí wọ́n ti lo àádọ́rin ọdún nígbèkùn, wọ́n padà sí Jerúsálẹ́mù ní 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa láti tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Ẹ́sírà 1:1-6; 2:1, 2; Jeremáyà 29:10) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé náà, wọ́n parí rẹ̀ lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Tiwa, wọ́n sì mú ìjọsìn mímọ́ Ọlọ́run bọ̀ sípò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tẹ́ńpìlì náà kò lógo tó èyí tí Sólómọ́nì kọ́, ó lò tó nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún. Àmọ́ ṣá, tẹ́ńpìlì yìí náà padà di ráuràu nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún pa ìjọsìn Jèhófà tì. Nígbà tí Jésù Kristi wá sáyé, ńṣe ni Hẹ́rọ́dù Ọba ṣì ń gbìyànjú láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ńpìlì yìí o?
‘A Kì Yóò Fi Òkúta Kan Sílẹ̀ Lórí Òmíràn’
Nígbà tí Jésù ń tọ́ka sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lọ́nàkọnà a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yóò sì wó palẹ̀.” (Mátíù 24:1, 2) Ọ̀rọ̀ yìí kúkú rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ogun Róòmù tó wá paná ọ̀tẹ̀ àwọn Júù pa ibi tó ti fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún jẹ́ ojúkò ìjọsìn Ọlọ́run run ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa.a Kò sẹ́ni tó tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ mọ́ látìgbà náà. Ní ọ̀rúndún keje, wọ́n kọ́ ibi ìjọsìn àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tí wọ́n ń pè ní Ilé Olórùlé Rìbìtì Orí Àpáta sí ibi tí ilé ìjọsìn àwọn Júù wà tẹ́lẹ̀, ibẹ̀ ló sì wà títí dòní olónìí.
Irú ètò ìjọsìn wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù á wá tẹ̀ lé báyìí? Ṣé àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ẹ̀yà Júù wá á ṣì máa sin Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì náà tó máa tó pa run ni? Ibo làwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù á ti máa jọ́sìn Ọlọ́run? Ṣé ilé táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ ló máa dípò tẹ́ńpìlì ni? Ìjíròrò Jésù àti obìnrin ará Samáríà kan jẹ́ ká lóye ọ̀ràn yìí.
Látọdún gbọ́nhan làwọn ará Samáríà ti ń jọ́sìn Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì ńlá kan tó wà lórí Òkè Gérísímù ní Samáríà. Obìnrin ará Samáríà náà sọ fún Jésù pé: “Àwọn baba ńlá wa jọ́sìn ní òkè ńlá yìí; ṣùgbọ́n ẹ̀yin sọ pé Jerúsálẹ́mù ni ibi tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn ti máa jọ́sìn.” Jésù wá dá a lóhùn pé: “Gbà mí gbọ́, obìnrin yìí, Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba.” Èèyàn ò ní nílò ilé tẹ́ńpìlì tá a lè fojú rí mọ́ láti máa fi jọ́sìn Jèhófà nítorí Jésù ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:20, 21, 24) Nígbà tó ṣe, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Áténì pé: “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹni yìí ti jẹ́, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́.”—Ìṣe 17:24.
Ó ṣe kedere pé ilé ìjọsìn táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìṣètò tẹ́ńpìlì tó wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé. Kò sì sí ìdí kankan fáwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní láti kọ́ irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà táwọn àpọ́sítélì kú tán, ohun tó ti wà lákọọ́lẹ̀ pé àwọn kan á fi ẹ̀kọ́ tòótọ́ sílẹ̀, tí í ṣe ìpẹ̀yìndà, wáyé. (Ìṣe 20:29, 30) Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò tí Olú Ọba Róòmù, ìyẹn Kọnsitatáìnì, sọ pé òun di ẹlẹ́sìn Kristẹni lọ́dún 313 Sànmánì Tiwa, làwọn tó sọ pé Kristẹni ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí yapa kúrò nínú ohun tí Jésù fi kọ́ni.
Kọnsitatáìnì pa kún dídà tí wọ́n da “ẹ̀sìn Kristẹni” pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kèfèrí tàwọn ará Róòmù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Kọnsitatáìnì fúnra rẹ̀ ló pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ràgàjì-ràgàjì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ní Róòmù, ìyẹn: Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ti Pétérù Mímọ́, ti San Paolo Fuori le Mura àti ti S. Giovanni ní Laterano. Òun . . . ló dá ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù ní gbogbo Sànmánì Ojú Dúdú sílẹ̀.” Títí dòní làwọn èèyàn ṣì ń ka Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ti Pétérù Mímọ́ tí wọ́n tún kọ́ ní Róòmù sí ibi tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Ìjọ Roman Kátólíìkì.
Òpìtàn Will Durant sọ pé: “Ìjọ yìí tẹ́wọ́ gba àwọn ààtò ìsìn àti ọ̀nà ìjọsìn tó wọ́pọ̀ lásìkò tí ẹ̀sìn Kristẹni ò tíì dé Róòmù [ìlú abọ̀rìṣà].” Lára ààtò ìsìn wọ̀nyí ni “ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńláńlá.” Iye ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké àti ṣọ́ọ̀ṣì kàǹkà-kàǹkà tí wọ́n kọ́ láàárín ọ̀rúndún kẹwàá sí ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún kò lóǹkà, ohun tó sì jẹ wọ́n lógún jù lọ ni ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ́ ọ. Ìgbà yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn ilé ńláńlá tàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń pè ní iṣẹ́ ọnà àpéwò báyìí dáyé.
Ǹjẹ́ àwọn èèyàn sábà máa ń rí ìtura nípa tẹ̀mí àti ìṣírí gbà bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì? Francisco ọmọ ilẹ̀ Brazil sọ pé: “Ní tèmi o, ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ ibi tó ń fi ìsìn súni tó sì ń dáni lágara. Ìsìn tá à ń ṣe níbẹ̀ kò ju ààtò ìsìn aláìnítumọ̀ kan náà téèyàn kàn ń ṣe láṣetúnṣe ṣáá tí ò sì pèsè ohun tí mo nílò. Tí ìsìn bá ti jàjà parí báyìí ńṣe ni inú mi máa ń dùn.” Síbẹ̀síbẹ̀, a pa á láṣẹ fáwọn onígbàgbọ́ tòótọ́ pé kí wọ́n máa pàdé pọ̀. Ètò wo ló yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé fún ṣíṣe irú ìpàdé bẹ́ẹ̀?
“Ìjọ Tí Ó Wà ní Ilé Wọn”
A rí àpẹẹrẹ ọ̀nà táwọn Kristẹni gbà ń ṣèpàdé látinú àyẹ̀wò báwọn onígbàgbọ́ ọ̀rúndún kìíní ṣe ń pàdé pọ̀. Ìwé Mímọ́ fi yéni pé inú ilé àdáni ni wọ́n ti máa ń pàdé pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ bá mi kí Pírísíkà àti Ákúílà àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jésù, ẹ sì kí ìjọ tí ó wà ní ilé wọn.” (Róòmù 16:3, 5; Kólósè 4:15; Fílémónì 2) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ìjọ” (ek·kle·siʹa), làwọn “ìtumọ̀ Bíbélì kan, irú bí ìtumọ̀ King James Version pè ní “ṣọ́ọ̀ṣì.” Àmọ́ àwùjọ àwọn èèyàn tó kóra jọ fún ètè kan náà ni ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí, kì í ṣe ilé tá a kọ́ kalẹ̀. (Ìṣe 8:1; 13:1) Ìjọsìn táwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe kò nílò àwọn ilé ìjọsìn ràgàjì-ràgàjì.
Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣèpàdé nínú àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù lo oríṣi ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà sy·na·go·geʹ láti tọ́ka sí ìpàdé Kristẹni. (Jákọ́bù 2:2) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí “kíkójọ pọ̀” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà ek·kle·siʹa. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ náà “sínágọ́gù” di èyí tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lò fún ibi tàbí ilé táwọn èèyàn ti kóra jọ pọ̀. Àwọn Júù tó kọ́kọ́ di Kristẹni mọ ohun tí wọ́n ń ṣe nínú sínágọ́gù dáadáa.b
Nígbà táwọn Júù ń pàdé pọ̀ ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù fún ayẹyẹ wọn ọdọọdún, sínágọ́gù ní tiẹ̀ jẹ́ ilé tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tí wọ́n sì tún ti ń kọ́ nípa Òfin. Ó dà bí ẹni pé àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú sínágọ́gù ní nínú àdúrà gbígbà àti kíka Ìwé Mímọ́, wọ́n tún ń jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ wọ́n sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí sínágọ́gù tó wà ní Áńtíókù, “àwọn alága sínágọ́gù ránṣẹ́ sí wọn, pé: ‘Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, bí ọ̀rọ̀ ìṣírí èyíkéyìí bá wà tí ẹ ní fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́.’” (Ìṣe 13:15) Nígbà táwọn Júù tó kọ́kọ́ di Kristẹni pàdé pọ̀ láwọn ilé àdáni, ó dájú pé ọ̀nà yìí kan náà ni wọ́n tẹ̀ lé. Wọ́n jẹ́ kí ìpàdé náà kún fún ẹ̀kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ kó sì tún gbéni ró nípa tẹ̀mí.
Ìjọ Tó Ń Gbéni Ró
Gẹ́gẹ́ bíi tàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ lónìí láti gba ìtọ́ni látinú Bíbélì kí wọ́n sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé láwọn ibi ìjọsìn tá ò kọ́ lọ́nà aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti fi ń pàdé pọ̀ láwọn ilé àdáni, wọ́n tiẹ̀ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ibì kan títí dòní. Nísinsìnyí, iye ìjọ wọn ti lé ní ẹgbàá márùnlélógójì [90,000], ibi tí wọ́n sì ti ń pàdé pọ̀ ní pàtàkì jù lọ ni wọ́n ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ilé yìí kì í ṣe èyí tá a kọ́ lọ́nà afẹfẹyẹ̀yẹ̀ kò sì dà bíi tàwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n jẹ́ ilé alábọ́ọ́dé tó sì bójú mu tí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún sí igba èèyàn ti lè máa kóra jọ fún àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀pọ̀ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pàdé pọ̀ lọ́sẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìpàdé yìí ni àsọyé fún gbogbo èèyàn tó dá lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó bágbà mu. Lẹ́yìn èyí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan látinú Bíbélì. Inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ èyí. Ìpàdé mìíràn tún ni ilé ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni láti mọ bá a ṣe ń sọ ìhìn inú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn. Lẹ́yìn rẹ̀ ni ìpàdé kan tó ń pèsè àbá tó gbéṣẹ́ fún lílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń pàdé ní àwùjọ kéékèèké fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn ilé àdáni. Ẹnikẹ́ni ló lè wá sáwọn ìpàdé yìí. Wọn kì í gbowó.
Francisco tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ rí i pé àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ń ṣeni láǹfààní gan-an ni. Ó sọ pé: “Àárín ìgboro ni ilé ìpàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ wà, ibẹ̀ sì tuni lára gan-an. Nígbà tí mo fi máa kúrò níbẹ̀, àwọn ohun tí mo ti rí wú mi lórí gan-an ni. Àwọn tó wà níbẹ̀ yá mọ́ni, mo sì rí i pé lóòótọ́ ni ìfẹ́ ń bẹ láàárín wọn. Ara mi sì wà lọ́nà láti tún padà lọ síbẹ̀. Kódà, mi ò tíì pa ìpàdé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo jẹ látìgbà náà. Àwọn ìpàdé Kristẹni yìí ń tani jí, wọ́n sì ń pèsè àwọn ohun tí mo nílò nípa tẹ̀mí. Kódà nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí mi kodò fún àwọn ìdí kan, mo máa ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọkàn mi á sì balẹ̀ pé ara mi á yá gágá nígbà tí mo bá fi máa padà sílé.”
Ẹ̀kọ́ Bíbélì, ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró àti àǹfààní láti yin Ọlọ́run ń dúró de ìwọ náà láwọn ìpàdé Kristẹni ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ọ jù lọ. O ò ní kábàámọ̀ pé o ṣe bẹ́ẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ará Róòmù pa tẹ́ńpìlì náà run ráúráú. Ibi Àwókù Odi, tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù máa ń ti ọ̀nà jíjìn lọ síbẹ̀ láti gbàdúrà kò sí lára tẹ́ńpìlì náà. Ó kàn jẹ́ ara odi àgbàlá tẹ́ńpìlì ni.
b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárín àádọ́rin ọdún tí wọ́n fi wà nígbèkùn Bábílónì, tí kò sí tẹ́ńpìlì kankan rárá ni wọ́n dá sínágọ́gù sílẹ̀ tàbí kó jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé tí wọ́n ṣì ń ṣàtúnkọ́ tẹ́ńpìlì lọ́wọ́. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní, ìlú kọ̀ọ̀kan nílẹ̀ Palẹ́sìnì ló ní sínágọ́gù tirẹ̀, àwọn ìlú ńláńlá sì máa ń ní ju ẹyọ kan lọ.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Àgọ́ ìjọsìn àtàwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ lẹ́yìn ìgbà náà, jẹ́ ibi dáadáa táwọn èèyàn ti ń pàdé pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá ti Pétérù Mímọ́ ní Róòmù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń pàdé pọ̀ láwọn ilé àdáni
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ìpàdé Kristẹni láwọn ilé àdáni àti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba