Àwọn Ìṣẹ̀dá Jèhófà Ń Fi Ọgbọ́n Rẹ̀ Hàn
‘Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a ń fi òye mọ̀ nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.’—RÓÒMÙ 1:20.
1. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ayé lónìí?
Ọ̀PỌ̀ àwọn táráyé ń pè ní ọlọ́gbọ́n lónìí ni kì í ṣe ọlọ́gbọ́n. Táwọn kan bá sáà ti rí i pé ìmọ̀ ẹnì kan pọ̀, wọ́n á sọ pé ọlọ́gbọ́n ni onítọ̀hún. Àmọ́ àwọn táwọn èèyàn ayé yìí kà sí ọ̀mọ̀ràn kò ní ìmọ̀ràn gidi kan tí wọ́n lè fúnni tí ìgbésí ayé èèyàn á fi nítumọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àwọn tó ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ayé yìí máa ń dẹni “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.”—Éfé. 4:14.
2, 3. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n”? (b) Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọgbọ́n Ọlọ́run àti ọgbọ́n ayé?
2 Ọ̀ràn ti àwọn tó ní ọgbọ́n tòótọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run mà yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ọlọ́gbọ́n ayé yìí o! Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” (Róòmù 16:27) Ó mọ ohun gbogbo pátápátá nípa ayé òun ọ̀run, títí kan bó ṣe dá wọn àti ìtàn wọn. Jèhófà ló ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìlànà tó so ilé ayé ró, èyí táwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń tẹ̀ lé kí wọ́n tó lè ṣe àwọn ìwádìí wọn. Ìdí nìyẹn tí gbogbo àwọn nǹkan ìyanu táwọn èèyàn ń gbé ṣe kò fi jọ ọ́ lójú, tí èrò orí àwọn ẹni táráyé kà sí ọ̀mọ̀ràn tó moyún inú ìgbín kò sì fi já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ọgbọ́n ayé yìí jẹ́ nǹkan òmùgọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 3:19.
3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé Jèhófà máa ‘ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n.’ (Òwe 2:6) Ọgbọ́n tí Ọlọ́run ń fúnni kò lọ́jú pọ̀ bíi ti ọgbọ́n orí èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ọgbọ́n yìí ń jẹ́ ká lè máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dáni, ó sì dá lórí ìmọ̀ àti òye tó péye. (Ka Jákọ́bù 3:17.) Àgbàyanu ọgbọ́n Jèhófà jọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú débi tó fi sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Torí pé Jèhófà lẹni tó gbọ́n jù lọ, ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn òfin rẹ̀ máa ń tọ́ wa sọ́nà láti máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó dáa jù lọ. Ó ṣe tán, Jèhófà ló mọ ohun tá a nílò tó lè fún wa láyọ̀, kò tún sẹ́lòmíì tó mọ̀ ọ́n tó o.—Òwe 3:5, 6.
“Àgbà Òṣìṣẹ́” Ni Jésù
4. Ibo la ti lè rí ọgbọ́n Jèhófà?
4 A lè rí ọgbọ́n Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù tí kò lẹ́gbẹ́ látinú àwọn ohun tó dá. (Ka Róòmù 1:20.) Àwọn iṣẹ́ Jèhófà, látorí èyí tó kéré jù dórí èyí tó tóbi jù, ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn. Ibi yòówù ká yíjú sí, lójú ọ̀run tàbí ní ilẹ̀ ayé, a óò rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ó sì jẹ́ ẹni tó gbọ́n jù lọ. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ nípa rẹ̀ tá a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó dá.—Sm. 19:1; Aísá. 40:26.
5, 6. (a) Ta ni ẹni tó bá Jèhófà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?
5 Jèhófà kò dá nìkan wà nígbà tó “dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:1) Bíbélì fi hàn pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó ṣẹ̀dá àwọn ohun tó ṣeé fojú rí yìí, ó ti dá ẹni ẹ̀mí kan, tó tipasẹ̀ rẹ̀ dá “gbogbo ohun mìíràn.” Ẹ̀dá ẹ̀mí yẹn ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” Nígbà tó yá, Ọmọ rẹ̀ yìí wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó sì dẹni tá a wá ń pè ní Jésù. (Kól. 1:15-17) Bíi ti Jèhófà, Jésù náà ní ọgbọ́n. Kódà Òwe orí 8 ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n. Ìwé Òwe yẹn tún ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” Ọlọ́run.—Òwe 8:12, 22-31.
6 Torí náà, ìṣẹ̀dá fi ọgbọ́n Jèhófà àti ti Jésù Àgbà Òṣìṣẹ́ rẹ̀ hàn. Ó sì tún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́rin kan tí Jèhófà dá tí Òwe 30:24-28 sọ pé “wọ́n ní ọgbọ́n àdámọ́ni.”a
Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Òṣìṣẹ́ Aláápọn
7, 8. Kí ni ohun tó wú ọ lórí nípa èèrà?
7 Tá a bá ṣàyẹ̀wò ìrísí àti ìṣe àwọn ohun tá a tiẹ̀ lè sọ pé wọ́n “kéré jù lọ ní ilẹ̀ ayé” pàápàá, a óò rí i pé a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, wo ọgbọ́n àdámọ́ni tí èèrà ní.—Ka Òwe 30:24, 25.
8 Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé iye èèrà tó wà láyé jẹ́ ìlọ́po ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba [200,000] iye èèyàn tó wà láyé, tí gbogbo àwọn èèrà yìí sì ń ṣiṣẹ́ kára lórí ilẹ̀ àti nínú ihò ilẹ̀. Àwọn èèrà máa ń kó ara wọn jọ lágbo-lágbo ni, ìsọ̀rí mẹ́ta táwọn èèrà inú agbo kọ̀ọ̀kan sì sábà máa ń pín sí ni ọbabìnrin, akọ àti òṣìṣẹ́. Àwọn èèrà tó wà ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan sì ní ipa tí wọ́n ń kó nínú agbo àwọn èèrà náà. Irú èèrà kan wà tó jẹ́ jáwéjáwé. A lè pe èèrà náà ní olùtọ́jú ọgbà tó dáńgájíá. Irú olú kan tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ni kòkòrò kékeré yìí máa ń tọ́jú, ó máa ń fi ajílẹ̀ sí i, ó máa ń tún un gbìn síbòmíì, ó sì máa ń rẹ́wọ́ rẹ̀ kó bàa lè máa ṣe dáadáa. Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé èèrà tó ń ṣiṣẹ́ bí olùtọ́jú ọgbà yìí lè dín iṣẹ́ rẹ̀ kù tàbí kó fi kún un bó bá ṣe ń rí i pé oúnjẹ tí wọ́n nílò ní agbo èèrà wọn pọ̀ sí.b
9, 10. Báwo la ṣe lè jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn bíi ti èèrà?
9 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn èèrà. Ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára wọn ni pé a ní láti ṣiṣẹ́ taápọntaápọn tá a bá fẹ́ kóhun tá a ń ṣe yọrí sí rere. Bíbélì sọ pé: “Tọ eèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ; wo àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì di ọlọ́gbọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, tàbí onípò àṣẹ tàbí olùṣàkóso, ó ń pèsè oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ àní ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ó ti kó àwọn ìpèsè oúnjẹ rẹ̀ jọ àní nígbà ìkórè.” (Òwe 6:6-8) Òṣìṣẹ́ aláápọn ni Jèhófà àti Jésù Àgbà Òṣìṣẹ́ rẹ̀ jẹ́. Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.”—Jòh. 5:17.
10 Àwa pẹ̀lú tá a jẹ́ aláfarawé Ọlọ́run àti Kristi gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn. Iṣẹ́ yòówù tí wọ́n bá yàn fún wa nínú ètò Ọlọ́run, gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́r. 15:58) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín. Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú yín. Ẹ máa sìnrú fún Jèhófà.” (Róòmù 12:11) Gbogbo akitiyan wa láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà kì í ṣe asán, torí Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Héb. 6:10.
Bá A Ṣe Lè Dáàbò Bo Àjọṣe Àárín Àwa àti Ọlọ́run
11. Sọ díẹ̀ nípa ohun tó o mọ̀ nípa ẹranko tó ń jẹ́ gara orí àpáta.
11 Ẹranko kan tó ń jẹ́ gara orí àpáta tún jẹ́ ẹ̀dá míì tó kéré díẹ̀, àmọ́ tó lè kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Ka Òwe 30:26.) Ó fẹ́ jọ ehoro ńlá, àmọ́ ẹsẹ̀ tiẹ̀ kúrú, róbótó ni etí tiẹ̀ rí, kò gún tó ti ehoro. Ibi àpáta ni ẹranko kékeré yìí máa ń gbé. Ojú rẹ̀ tó máa ń ríran gan-an yẹn ló fi ń dáàbò bo ara rẹ̀, inú ihò àti pàlàpálá àpáta tó fi ṣelé ló sì máa ń tètè sá wọ̀ kọ́wọ́ ohun tó bá fẹ́ pa á jẹ má bàa tẹ̀ ẹ́. Bí ọ̀pọ̀ àwọn gara orí àpáta tún ṣe máa ń gbé pa pọ̀ tí wọ́n sì máa ń wà pọ̀ tímọ́tímọ́ tún máa ń jẹ́ kára tù wọ́n, ààbò lèyí jẹ́ fún wọn, kì í sì í jẹ́ kí òtútù lù wọ́n pa nígbà òtútù.c
12, 13. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára gara orí àpáta?
12 Kí la lè rí kọ́ lára gara orí àpáta? Kọ́kọ́ kíyè sí i pé ẹranko yìí kì í wà níbi tí ọwọ́ ọ̀tá ti lè tó o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń lo àǹfààní ojú rẹ̀ tó máa ń ríran gan-an láti rí ohun tó bá fẹ́ pa á jẹ látọ̀ọ́kán, kì í sì í jìnnà sétí ihò àti pàlàpálá àpáta táá lè sá wọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ káwa náà wà lójúfò, ká lè tètè fòye mọ àwọn ewu tó fara sin sínú ayé Sátánì yìí. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Nígbà tí Jésù wà láyé, kò fìgbà kankan gbàgbéra, ó wà lójúfò sí gbogbo ọgbọ́n tí Sátánì ń ta láti ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́. (Mát. 4:1-11) Àpẹẹrẹ rere mà ni Jésù fi lélẹ̀ fáwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ o!
13 Ọ̀nà kan tá a lè gbà wà lójúfò ni pé ká má ṣe kúrò lábẹ́ ààbò Jèhófà. A gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lílọ sípàdé déédéé. (Lúùkù 4:4; Héb. 10:24, 25) Bákan náà, ńṣe ni ara máa ń tu gara orí àpáta nígbà tó bá wà láàárín àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ wà pọ̀ tímọ́tímọ́. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ káwa náà máa sún mọ́ àwọn ará wa ká bàa lè jọ máa fún ara wa ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Tá a bá fi ara wa sábẹ́ ààbò Jèhófà, à ń fi hàn pé a fara mọ́ ohun tí Dáfídì onísáàmù náà sọ nìyẹn, pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi. Ọlọ́run mi ni àpáta mi. Èmi yóò sá di í.”—Sm. 18:2.
Bá A Ṣe Lè Máa Bá Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Lọ Lójú Àtakò
14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ eéṣú kan ṣoṣo lè má jọjú, kí la lè sọ nípa agbo àwọn eéṣú?
14 A tún lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára eéṣú. Téèyàn bá ń wo ẹyọ eéṣú kan ṣoṣo tí kò gùn tó ìka ọwọ́ èèyàn, ó lè má jọjú, àmọ́ ẹni bá ti rí agbo eéṣú rí á mọ̀ pé òun rí nǹkan àrà. (Ka Òwe 30:27.) Àwọn eéṣú jẹ́ ẹ̀dá kan tó máa ń jẹ fóò nínú oúnjẹ, torí náà tí wọ́n bá ya wọ oko kan tí irè ibẹ̀ ti tó kó, wọ́n lè parí gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ kíákíá. Bíbélì sọ pé ìró àwọn kòkòrò kan tó ń ya bọ̀ dà bí ìrò kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àti ìrò iná ajófòfò tó ń jó àgékù pòròpórò run. Eéṣú sì wà lára àwọn kòkòrò náà. (Jóẹ́lì 2:3, 5) Àwọn èèyàn ti dá iná tó ń jó ròkè lala láti dá àwọn eéṣú tó ń ya bọ̀ dúró, àmọ́ iná yẹn kì í sábàá dá wọn dúró. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé táwọn tí iná pa lára àwọn eéṣú náà bá ti já bọ́ sínú iná, ṣe ni wọ́n á bo iná náà mọ́lẹ̀ títí yóò fi kú, tí àwọn ìyókù á sì máa lọ láìsóhun tó ń dá wọn dúró mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eéṣú kò ní ọba tàbí aṣáájú, ńṣe ni wọ́n máa ń wà létòlétò bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tí wọ́n sì máa ń borí ohunkóhun tó bá fẹ́ dí wọn lọ́nà.d—Jóẹ́lì 2:25.
15, 16. Báwo làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tòde òní ṣe dà bí agbo eéṣú?
15 Wòlíì Jóẹ́lì fi ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Jèhófà wé ìṣe àwọn eéṣú, ó ní: “Wọ́n sáré bí àwọn ọkùnrin alágbára. Wọ́n gun ògiri gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin ogun. Wọ́n sì ń lọ, olúkúlùkù ní ọ̀nà tirẹ̀, wọn kò sì yí ipa ọ̀nà wọn padà. Wọn kò sì ti ara wọn. Gẹ́gẹ́ bí abarapá ọkùnrin ní ipa ọ̀nà rẹ̀, wọ́n ń lọ ṣáá; ká ní àwọn kan lára wọn ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́ pàápàá, àwọn yòókù kì yóò yà kúrò ní ipa ọ̀nà.”—Jóẹ́lì 2:7, 8.
16 Àpèjúwe inú àsọtẹ́lẹ̀ yìí mà bá àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tòde òní mu o! Kò sí àtakò èyíkéyìí tó dà bí “ògiri” tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù wọn dúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀. (Aísá. 53:3) Lóòótọ́, àwọn Kristẹni kan ti “ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́” ní ti pé wọ́n ti kú ikú ajẹ́rìíkú nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Síbẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù náà kò dáwọ́ dúró, ńṣe làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni inúnibíni máa ń jẹ́ kí ìhìn rere tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ì bá má gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ká ní kò sí inúnibíni. (Ìṣe 8:1, 4) Ṣé ìwọ náà máa ń tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù rẹ bíi ti eéṣú, kódà nígbà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ tàbí tí wọ́n ń ṣàtakò?—Héb. 10:39.
“Ẹ Rọ̀ Mọ́ Ohun Rere”
17. Kí ló fà á tí ẹsẹ̀ ọmọńlé kì í fi í yọ̀ lára ibi tó ń dán?
17 Ó dà bíi pé òfin òòfà kì í fi bẹ́ẹ̀ nípa lórí ọmọńlé ní tiẹ̀. (Ka Òwe 30:28.) Kódà, ìyàlẹ́nu ló ṣì ń jẹ́ fáwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bí ọmọńlé ṣe máa ń lè sáré gun ara ògiri, táá tún máa rìn lára àjà tó ń dán bọ̀rọ́bọ̀rọ́, táá sì tún dẹ̀yìn kọ ilẹ̀ láìní já bọ́. Ọgbọ́n wo ni ọmọńlé ń dá sí i? Kì í kúkú ṣe pé ó ní àtè tàbí òòlẹ̀ kan tó fi ń lẹ ọwọ́ rẹ̀ mọ́ ògiri. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn nǹkan tó dà bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún irun wà lára ọmọ ìka àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé. Lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tó dà bí irun wọ̀nyí ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn nǹkan tẹ́ẹ́rẹ́-tẹ́ẹ́rẹ́ wà. Àwọn ohun tó wà lórí irun ẹsẹ̀ ọmọńlé yìí lágbára débi pé kì í jẹ́ kí ẹsẹ̀ ọmọńlé yọ̀ lára nǹkan, kódà kò ní já bọ́ tó bá dẹ̀yìn kọ ilẹ̀ tó sì ń sáré kiri lára ohun tó ń dán bíi gíláàsì! Ohun táwọn olùṣèwádìí rí nípa ọmọńlé jọ wọ́n lójú débi pé wọ́n ní tí wọ́n bá lè ṣe ohun kan tó dà bíi àwọn ìka ẹsẹ̀ ọmọńlé, òòlẹ̀ tó lágbára ló máa jẹ́.e
18. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé à ń “rọ̀ mọ́ ohun rere”?
18 Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára ọmọńlé? Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ rọ̀ mọ́ ohun rere.” (Róòmù 12:9) Àwọn ohun búburú tó wọ́ pọ̀ nínú ayé Sátánì yìí lè nípa lórí wa débi tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í juwọ́ sílẹ̀ lórí àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bá àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kẹ́gbẹ́, bóyá níléèwé tàbí lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nípasẹ̀ eré ìnàjú tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ó lè mú ká yà kúrò lórí ìpinnu wa láti ṣohun tó tọ́. Má ṣe jẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí ọ láé! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Má ṣe di ọlọ́gbọ́n ní ojú ara rẹ.” (Òwe 3:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Mósè fáwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ ni kó o máa tẹ̀ lé, ó ní: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o bẹ̀rù. Òun ni kí o máa sìn, òun ni kí o sì rọ̀ mọ́.” (Diu. 10:20) Tá a bá ń rọ̀ mọ́ Jèhófà, à ń fara wé Jésù nìyẹn, torí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin.”—Heb. 1:9.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Ìṣẹ̀dá
19. (a) Àwọn ànímọ́ Jèhófà wo ni ìwọ fúnra rẹ ti rí nínú ìṣẹ̀dá? (b) Àǹfààní wo ni ọgbọ́n Ọlọ́run lè ṣe fún wa?
19 A ti wá rí i báyìí pé àwọn ànímọ́ Jèhófà ń hàn kedere lára àwọn ohun tó dá, àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ sì tún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye. Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ yóò ṣe máa yà wá lẹ́nu tó. Tá a bá ń bá a lọ láti máa kíyè sí ọgbọ́n Ọlọ́run, yóò mú kí ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i nísinsìnyí, yóò sì dáàbò bò wá lọ́jọ́ iwájú. (Oníw. 7:12) Àwa fúnra wa yóò sì rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú tó wà nínú Òwe 3:13, 18, tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí ẹ̀yin èwe ní pàtàkì bá ka àwọn ìwé ìròyìn tá a tọ́ka sí nínú àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í rí lẹ́yìn eléyìí, ẹ máa gbádùn rẹ̀, ẹ ó sì lè fi ohun tẹ́ ẹ rí nínú wọn kún ìdáhùn yín nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò àpilẹ̀kọ yìí nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nínú ìjọ yín.
b Tó o bá fẹ́ rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa èèrà jáwéjáwé yìí, wo Jí! ti March 22, 1997, ojú ìwé 31, àti September 8, 2002, ojú ìwé 22.
c Tó o bá fẹ́ rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa gara orí àpáta, wo Jí! ti March 8, 1991 ojú ìwé 15 sí 16.
d Tó o bá fẹ́ rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa eéṣú, wo Jí! ti July 8, 1977, ojú ìwé 26.
e Tó o bá fẹ́ rí ìsọfúnni síwájú sí i nípa ọmọńlé, wo Jí! ti February 8, 2001 ojú ìwé 30.
Ǹjẹ́ O Rántí?
Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ lára . . .
• èèrà?
• gara orí àpáta?
• eéṣú?
• ọmọńlé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ṣé o máa ń fi aápọn ṣiṣẹ́ bíi ti èèrà jáwéjáwé?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Gara orí àpáta máa ń gbé pa pọ̀ wọ́n sì máa ń wà pọ̀ tímọ́tímọ́ kí ààbò lè wà fún wọn. Ṣé ìwọ náà máa ń sún mọ́ àwọn ará?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Kristẹni oníwàásù ń tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ wọn, bíi tàwọn eéṣú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí ọmọńlé ṣe máa ń lẹ̀ mọ́ ògiri àti àjà làwọn Kristẹni náà ṣe máa ń rọ̀ mọ́ ohun rere
[Credit Line]
Stockbyte/Getty Images