Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun Ọ
JESU KRISTI dá Ounjẹ Alẹ́ Oluwa silẹ ni alẹ́ rẹ̀ ti ó kẹhin gẹgẹ bi ẹda eniyan. Iyẹn jẹ́ irọlẹ ọjọ Thursday, March 31, Jesu sì kú ni ọsan ọjọ Friday, April 1. Niwọn bi awọn ọjọ kalẹnda Ju ti bẹrẹ lati irọlẹ ọjọ kan si irọlẹ ọjọ keji, Ounjẹ Alẹ́ Oluwa papọ pẹlu iku Jesu wáyé ni Nisan 14, 33 C.E.
Eeṣe ti Jesu fi dá ounjẹ yii silẹ? Ki ni ijẹpataki àkàrà ati waini ti ó lò? Ta ni ó nilati jẹ ninu rẹ̀? Bawo ni a ṣe nilati ṣe ayẹyẹ ounjẹ yii lemọlemọ tó? Bawo ni ó sì ṣe lè ní itumọ fun ọ?
Eeṣe Ti A Fi Dá a Silẹ?
Nipa Ounjẹ Alẹ́ Oluwa, Jesu sọ fun awọn aposteli rẹ̀ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” Ni ibamu pẹlu ìtumọ̀ miiran, ó sọ pe: “Ẹ ṣe eyi gẹgẹ bi iṣe-iranti mi.” (1 Korinti 11:24; The New English Bible) Nitootọ, Ounjẹ Alẹ́ Oluwa ni a sábà maa ń tọkasi gẹgẹ bi Iṣe-iranti iku Kristi.
Jesu kú gẹgẹ bi olupawatitọmọ kan ti o di ipo ọba-alaṣẹ Jehofa mú ti o sì tipa bayii fi Satani hàn bi èké olùṣáátá kan fun fífẹ̀sùn kàn pe awọn eniyan aduroṣanṣan ń sin Ọlọrun kìkì fun ète-ìsúnniṣe onimọtara-ẹni-nikan lasan. (Jobu 2:1-5) Iku rẹ̀ mu ki ọkan-aya Ọlọrun layọ.—Owe 27:11.
Nipasẹ iku rẹ̀ gẹgẹ bi ẹ̀dá eniyan pipe kan, Jesu tun ‘fi ọkàn rẹ̀ funni gẹgẹ bi irapada ni paṣipaarọ fun ọpọlọpọ.’ (Matteu 20:28) Ni didẹṣẹ lodisi Ọlọrun, ọkunrin akọkọ padanu iwalaaye eniyan pipe ati awọn ifojusọna rẹ̀. Ṣugbọn “Ọlọrun fẹ́ arayé tobẹẹ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn ki o lè ni ìyè ainipẹkun.” (Johannu 3:16) Bẹẹni, “ikú ni èrè ẹṣẹ; ṣugbọn ẹbun ọfẹ Ọlọrun ni ìyè ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Romu 6:23.
‘Gbà Lọwọ Oluwa’
Eyi ti o tun tanmọlẹ sori ìṣèrántí iku Kristi ni awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pe: “Nitori pe lọwọ Oluwa ni emi ti gba eyi ti mo sì ti fifun yin, pe Jesu Oluwa ni òru ọjọ naa ti a fi í hàn, ó mú àkàrà: nigba ti ó sì ti dupẹ, ó bù ú, ó sì wi pe, Gbà, jẹ: eyi [tumọsi, NW] ara mi ti a bù fun yin: ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi. Gẹgẹ bẹẹ ni ó sì mú ago, lẹhin ounjẹ, ó wi pe, Ago yii [tumọsi, NW] majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ̀ mi: nigbakugba ti ẹyin bá ń mu un, ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi. Nitori nigbakugba ti ẹyin bá ń jẹ àkàrà yii, ti ẹyin bá sì ń mu ago yii, ẹyin ń kede ikú Oluwa titi yoo fi dé.”—1 Korinti 11:23-26.
Niwọn bi Paulu kò ti wà nibẹ pẹlu Jesu ati awọn aposteli 11 ni Nisan 14, 33 C.E., isọfunni yii ni kedere ni ó ‘gbà lọwọ Oluwa’ nipasẹ ìfihàn onimiisi. Jesu dá Iṣe-iranti naa silẹ “ni òru ọjọ naa ti a fi í hàn” nipasẹ Judasi fun awọn onisin Ju ti wọn jẹ́ ọ̀tá rẹ̀, ti wọn jẹ́ ki awọn ará Romu kan Kristi mọ́ igi. Awọn wọnni ti wọn lẹtọọ si jíjẹ ninu àkàrà ati waini iṣapẹẹrẹ naa yoo ṣe bẹẹ ni iranti rẹ̀.
Bawo Ni Ṣíṣe É Ṣe Nilati Jẹ́ Nigbakugba Tó?
Ki ni awọn ọ̀rọ̀ Paulu pe: “Nigbakugba ti ẹyin bá ń jẹ àkàrà yii, ti ẹyin bá sì ń mu ago yii, ẹyin ń kede iku Oluwa titi yoo fi dé” tumọsi? Awọn Kristian oluṣotitọ ẹni-ami-ororo yoo jẹ ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti “nigbakugba” titi ti wọn ó fi kú, ti a o sì jí wọn dide si ìyè ti ọrun lẹhin ìgbà naa. Niwaju Ọlọrun ati ayé, wọn yoo tipa bayii figba gbogbo polongo igbagbọ wọn ninu ẹbọ Jesu ti Jehofa pese. Yoo ti pẹ́ tó? “Titi yoo fi dé,” ni Paulu sọ, ti ó tumọ ni kedere si pe awọn ààtò àkíyèsí wọnyi yoo maa baa lọ titi di ìgbà dídé Jesu lati gba awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni-ami-ororo soke ọrun nipasẹ ajinde nigba “wiwanihin-in” rẹ̀. (1 Tessalonika 4:14-17, NW) Eyi wà ni ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ Kristi si awọn aposteli aduroṣinṣin 11 pe: “Bi mo bá sì lọ ípèsè ààyè silẹ fun yin, emi ó tún pada wá, emi ó sì mu yin lọ sọdọ emi tikaraami; pe nibi ti emi gbé wà, ki ẹyin lè wà nibẹ pẹlu.”—Johannu 14:3.
Iku Kristi ni a ha nilati ṣèrántí rẹ̀ lojoojumọ tabi boya lọsọọsẹ bi? Ó dara, Jesu dá Ounjẹ Alẹ́ Oluwa silẹ a sì pa á ni Ajọ-irekọja, eyi ti ó mú idande Israeli kuro ni oko-òǹdè Egipti wá sí iranti. Ni tootọ, oun ni a pè ni ‘Kristi irekọja wa’ nitori pe oun ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ti a fi rubọ fun awọn Kristian. (1 Korinti 5:7) Ajọ-irekoja ni a ń ṣe kìkì lẹẹkan lọdun, ni Nisan 14. (Eksodu 12:6, 14; Lefitiku 23:5) Eyi damọran pe iku Jesu ni a nilati ṣèrántí niwọn kan-naa ti a ń gba ṣe Ajọ-irekọja—lọdọọdun, kìí ṣe lojoojumọ tabi lọsọọsẹ.
Fun ọrundun melookan ọpọlọpọ awọn ti wọn jẹwọ jijẹ Kristian ṣèrántí iku Jesu lẹẹkan lọdun. Nitori pe wọn ṣe bẹẹ ni Nisan 14, awọn ni a pè ni Quartodecimans, ti o tumọsi “awọn ọlọjọ kẹrinla.” Nipa wọn, opitan J. L. von Mosheim kọwe pe: “Awọn Kristian Asia Kekere ni o ti mọ́ lara lati maa ṣe ayẹyẹ àsè mímọ́, ti ń ṣèrántí ìdásílẹ̀ ounjẹ-alẹ Oluwa, ati iku Jesu Kristi, ni akoko kan-naa nigba ti awọn Ju jẹ ọ̀dọ́-àgùtàn Irekọja wọn, iyẹn ni ní irọlẹ ọjọ kẹrinla oṣu kìn-ín-ní [Nisan]. . . . Wọn kà á si pe apẹẹrẹ Kristi ni awọn nilati tẹle gẹgẹ bi awọn yoo ti tẹle ofin.
Ijẹpataki Awọn Ohun-Iṣapẹẹrẹ Naa
Paulu sọ pe Jesu “mú àkàrà: nigba ti ó sì ti dupẹ, ó bù ú.” Àkàrà ti a fi ìyẹ̀fun ati omi laisi ìwúkàrà (tabi, ìmúyẹ̀funwú) ti o dabi ìpékeré ṣe yẹn ni a nilati bù fun jíjẹ. Ni èdè iṣapẹẹrẹ ti Bibeli, ìwúkàrà duro fun ẹṣẹ tabi idibajẹ. Ní rírọ awọn Kristian ni Korinti lati lé ọkunrin oniwa-palapala kan jade kuro ninu ijọ, Paulu sọ pe: “Ẹyin kò mọ̀ pe ìwúkàrà diẹ níí mú gbogbo ìyẹ̀fun di wíwú? Nitori naa ẹ mú ìwúkàrà atijọ kuro ninu yin, ki ẹyin ki o lè jẹ́ ìyẹ̀fun titun, gẹgẹ bi ẹyin ti jẹ́ àìwúkàrà. Nitori a ti fi irekọja wa, àní Kristi, rubọ fun wa. Nitori naa ẹ jẹ ki a ṣe àjọ naa, kìí ṣe pẹlu ìwúkàrà atijọ, bẹẹ ni kìí ṣe pẹlu ìwúkàrà arankan ati iwa buburu; bikoṣe pẹlu àìwúkàrà òdodo ati otitọ.” (1 Korinti 5:6-8) Bi iwọnba àpòrọ́-kíkan ti lè sọ gbogbo ìyẹ̀fun tabi apapọ burẹdi di wíwú, bẹẹ ni ijọ ṣe lè di alaimọ ni oju Ọlọrun bi a kò bá mú agbara-idari isọdibajẹ ọkunrin ẹlẹṣẹ kan kuro. Wọn nilati mú “ìwúkàrà” naa kuro laaarin wọn, gan-an bi o ti jẹ́ pe awọn ọmọ Israeli kò lè ní ìwúkàrà ninu ile wọn nigba Àjọ̀dún Àkàrà Alaiwu ti ó tẹle Ajọ-irekọja.
Nipa àkàrà aláìwú ti Iṣe-iranti, Jesu sọ pe: “Eyi [tumọsi, NW] ara mi ti a bù fun yin.” (1 Korinti 11:24) Àkàrà naa duro fun ara ẹlẹ́ran-ara pípé ti Jesu, nipa eyi ti Paulu kọwe pe: “Nigba ti [Jesu] wá sí ayé, ó wi pe, Iwọ kò fẹ́ ẹbọ ati ọrẹ, ṣugbọn ara ni iwọ ti pese fun mi: Ẹbọ sísun ati ẹbọ fun ẹṣẹ ni iwọ kò ni inu didun si. Nigba naa ni mo wi pe, Kiyesi i (ninu ìwé-kíká nì ni a gbé kọ ọ́ nipa ti emi) mo dé lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun. . . . Nipa ifẹ naa ni a ti sọ wá di mímọ́ nipa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹẹkanṣoṣo.” (Heberu 10:5-10) Ara ẹ̀dá eniyan pípé ti Jesu jẹ alailẹṣẹ ó sì ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹbọ irapada fun iran eniyan.—Heberu 7:26.
Lẹhin gbigbadura sori ago waini pupa ti a kò dàlù naa, Jesu sọ pe: “Ago yii [tumọsi, NW] majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ̀ mi.” (1 Korinti 11:25) Ọ̀nà ìgbàtúmọ̀ miiran ni pe: “Ago yii tumọsi majẹmu titun tí ẹ̀jẹ̀ mi mú dájú.” (Moffatt) Gan-an gẹgẹ bi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ akọ-maluu ati ewurẹ ti fidii majẹmu Ofin mulẹ laaarin Ọlọrun ati orilẹ-ede Israeli, bẹẹ ni ẹ̀jẹ̀ Jesu ti a tú jade ninu iku ṣe fidii majẹmu titun mulẹ. Otitọ naa pe a mẹnukan majẹmu yẹn ràn wá lọwọ lati dá awọn ti ń fi ẹ̀tọ́ jẹ awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti naa mọ̀.
Ta Ni Ó Nilati Jẹ Ẹ́?
Awọn ọmọlẹhin Jesu ẹni-ami-ororo, ti wọn wà ninu majẹmu titun, naa ń fi ẹ̀tọ́ jẹ́ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti naa. Majẹmu yii ni a dá laaarin Ọlọrun ati Israeli tẹmi. (Jeremiah 31:31-34; Galatia 6:16) Ṣugbọn majẹmu titun naa yoo mú awọn ibukun wá lẹhin-ọ-rẹhin fun gbogbo araye onigbọran, iwọ sì lè jẹ́ ọ̀kan lara awọn olùgba ibukun wọnni.
Awọn ti wọn ń jẹ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti gbọdọ dá wà ninu majẹmu Ijọba naa ti Jesu dá. Nigba ti ó ń fidii ounjẹ yii mulẹ, Jesu sọ fun awọn aposteli rẹ̀ aduroṣinṣin pe: “Mo sì yan ijọba fun yin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi.” (Luku 22:29) Majẹmu Ijọba naa ti Ọlọrun dá pẹlu Ọba Dafidi tọka siwaju si dídé Jesu, ẹni naa ti yoo ṣakoso titilae ninu Ijọba ti ọrun. Awọn 144,000 Israeli tẹmi ti yoo ṣajọpin ipo-iṣakoso pẹlu rẹ̀, ni a yaworan wọn gẹgẹ bi awọn tí ń duro lori Oke Sioni ti ọrun pẹlu Ọ̀dọ́-àgùtàn, Jesu Kristi. Nigba ti a bá ti jí wọn dide, wọn yoo ṣakoso pẹlu Kristi gẹgẹ bi ọba ati alufaa alájùmọ̀ṣàkóso. (2 Samueli 7:11-16; Ìfihàn 7:4; 14:1-4; 20:6) Kìkì awọn wọnni ti wọn wà ninu majẹmu titun ti wọn sì dá wà ninu majẹmu pẹlu Jesu ni wọn ń fi ẹ̀tọ́ jẹ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Ounjẹ Alẹ́ Oluwa.
Ẹmi Ọlọrun ń jẹrii pẹlu ẹmi awọn ẹni-ami-ororo pe ọmọ Rẹ̀ ati ajumọjogun pẹlu Kristi ni wọn jẹ. Paulu kọwe pe: “Ẹmi tikaraarẹ ni ó ń bá ẹmi wa jẹrii pe, ọmọ Ọlọrun ni awa íṣe: bi awa bá sì jẹ́ ọmọ, ǹjẹ́ ajogun ni awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọjogun pẹlu Kristi; bi o bá ṣe pe awa bá a jiya, ki a sì lè ṣe wá lógo pẹlu rẹ̀.” (Romu 8:16, 17) Ẹmi mimọ Ọlọrun, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ́, ń mú idaniloju naa pe a ti kadara wọn fun ìyè ti ọrun dagba ninu awọn ẹni-ami-ororo. Wọn wo gbogbo ohun ti Iwe Mimọ sọ nipa ìyè ti ọrun gẹgẹ bi eyi ti a darí rẹ̀ si wọn wọn sì muratan lati fi gbogbo ohun ti ayé rubọ, papọ pẹlu ìyè ẹ̀dá eniyan. Bi o tilẹ jẹ pe ìyè ninu Paradise ilẹ̀-ayé yoo jẹ́ ohun agbayanu, wọn kò ni ireti yẹn. (Luku 23:43) Ireti ti ọrun ti ó dájú ti kò sì ṣeeyipada ti a kò gbekari oju-iwoye awọn isin èké kà wọn yẹ lati jẹ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti naa.
Inu Jehofa kò ní dùn bi ẹnikan bá fi araarẹ̀ hàn gẹgẹ bi ẹnikan ti a pè lati jẹ́ ọba ati alufaa ti ọrun nigba ti oun kò ní iru ìpè bẹẹ. (Romu 9:16; Ìfihàn 22:5) Ọlọrun fiya iku jẹ Korah fun fifi ìkùgbù wá ipo-alufaa. (Eksodu 28:1; Numeri 16:4-11, 31-35) Nitori naa, ki ni bi awọn ero-imọlara lilagbara tabi awọn èrò isin tẹlẹri bá mú ki ẹnikan fi aitọ jẹ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti? Nigba naa oun lọkunrin tabi lobinrin nilati dáwọ́ jíjẹ ẹ́ duro ki ó sì fi taduratadura gbadura fun idariji Ọlọrun.—Orin Dafidi 19:13.
Bi Ọ̀ràn Ṣe Kàn Ọ́
Ẹnikan ni a kò beere lọwọ rẹ̀ pe ki ó jẹ ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti ki ó baa lè di ẹni ti ẹbọ irapada Jesu ṣe lanfaani ki ó sì gba ìyè ayeraye lori ilẹ̀-ayé. Fun apẹẹrẹ, Bibeli kò funni ni itọka kankan pe awọn eniyan olubẹru Ọlọrun bi Abrahamu, Sara, Isaaki, Rebeka, Boasi, Rutu, ati Dafidi yoo jẹ laelae ninu awọn ohun-iṣapẹẹrẹ wọnyi. Ṣugbọn awọn ati gbogbo awọn miiran ti wọn ń fẹ́ ìyè ti kò lopin lori ilẹ̀-ayé yii yoo nilati lo igbagbọ ninu Ọlọrun ati Kristi ati ninu ẹbọ irapada Jesu tí Jehofa pese. (Johannu 3:36; 14:1) Ìṣayẹyẹ iku Kristi lọ́dọọdún ṣiṣẹ gẹgẹ bi irannileti fun ẹbọ ńláǹlà yẹn.
Ijẹpataki ẹbọ Jesu ni a fihàn nigba ti aposteli Johannu wi pe: “Iwe nǹkan wọnyi ni mo kọ si yin, ki ẹ má baa dẹṣẹ. Bi ẹnikẹni bá sì dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olódodo: oun sì ni ètùtù fun ẹṣẹ wa; kìí sìí ṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araye pẹlu.” (1 Johannu 2:1, 2) Awọn Kristian ẹni-ami-ororo lè sọ pe Jesu ni “ètùtù fun ẹṣẹ [wọn].” Bi o ti wu ki o ri, oun tún ni ẹbọ fun ẹṣẹ gbogbo ayé pẹlu, eyi ti o mu kí ìyè ayeraye ṣeeṣe fun araye onigbọran ninu Paradise ilẹ̀-ayé ti ó ti kù sí dẹ̀dẹ̀ gan-an nisinsinyi!
Nipa wíwà nibẹ fun ìṣèrántí ikú Kristi, iwọ yoo janfaani lati inu awiye Bibeli tí ń ru ironu soke. A o rán ọ létí bi Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi ti ṣe pupọpupọ fun wa tó. Yoo jẹ́ itẹlọrun nipa tẹmi lati péjọ pẹlu awọn wọnni ti wọn ní ìkàsí jijinlẹ fun Ọlọrun ati Kristi ati fun ẹbọ irapada Jesu. Iṣẹlẹ naa lè fun ìfẹ́-ọkàn rẹ lókun daradara lati di olùgba inurere ailẹtọọsi Ọlọrun, ti ń ṣamọna si ìyè ayeraye. A fi tọkantọkan késí ọ lati pade pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹhin ti oòrùn bá wọ̀ ni April 6, 1993, lati ṣe iranti iku Jesu Kristi nitori pe Ounjẹ Alẹ́ Oluwa lè ní itumọ ńláǹlà fun ọ.