Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Títí dé àyè wo ló yẹ kí aya Kristẹni tòótọ́ kan kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìgbésẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ tí ọkọ rẹ̀ gbé?
Nígbà tí ìgbéyàwó ẹ̀dá ènìyàn bẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run sọ pé ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ “fà mọ́” ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24) Àwọn èèyàn di aláìpé, pẹ̀lú àwọn ìṣòro tó ń yọjú nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó, àmọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé àwọn tọkọtaya ṣì ní láti fà mọ́ ara wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn tí wọ́n gbéyàwó ni mo fún ní àwọn ìtọ́ni, síbẹ̀ kì í ṣe èmi bí kò ṣe Olúwa, pé kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó bá lọ ní ti gidi, kí ó wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:10, 11.
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé láàárín àwọn ènìyàn aláìpé, ọkọ tàbí aya lè pinnu àtilọ nígbà mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé bí ọ̀kan nínú wọn bá lọ, àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ ‘wà láìlọ́kọ tàbí láìláya.’ Èé ṣe? Tóò, òótọ́ lẹnìkan kúrò lọ́dọ̀ ẹnì kejì, àmọ́ àwọn méjèèjì ṣì wà ní ìsopọ̀ lójú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù lè sọ èyí nítorí pé Jésù ti gbé ìlànà tí ìgbéyàwó Kristẹni gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé kalẹ̀ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè [por·neiʹa, lédè Gíríìkì], tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo fún ìkọ̀sílẹ̀ tó lè fòpin sí ìgbéyàwó lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu ni “àgbèrè,” ìyẹn ni, ìwà pálapàla takọtabo. Látàrí èyí, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ni ìgbà tí kò bá sí èyí tó jẹ́ oníwà pálapàla nínú àwọn méjèèjì, bí ọkọ tàbí aya bá wá lọ nígbà náà, ìgbéyàwó wọn kò parí lójú Ọlọ́run.
Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rọ̀ nípa ipò kan tí Kristẹni tòótọ́ kan ti ní ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Gbé àwọn ìlànà Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò: “Bí ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ, jẹ́ kí ó lọ; arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan kò sí ní ipò ìsìnrú lábẹ́ irúfẹ́ àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.” (1 Kọ́ríńtì 7:12-16) Kí ni aya olóòótọ́ kan lè ṣe bí ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́ bá fi í sílẹ̀ lọ, tó tiẹ̀ fẹ́ kó fún òun ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá?
Obìnrin náà lè fẹ́ kó máa bá òun gbé nìṣó. Ó ṣì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí ó mọ̀ pé alábàárò òun ni àti ẹni tí òun ń yíjú si fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ó sì tún mọ̀ pé òun àtàwọn ọmọ yóò nílò ìtìlẹ́yìn rẹ̀ nípa ti ara. Ó sì tún lè nírètí pé, bí àkókò ti ń lọ, ọkọ òun yóò di onígbàgbọ́, a óò sì gbà á là. Ṣùgbọ́n bí ó bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti fòpin sí ìgbéyàwó náà (lórí àwọn ìpìlẹ̀ kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu), aya náà lè “jẹ́ kí ó lọ,” bí Pọ́ọ̀lù ṣe kọ̀wé. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ bí ọkọ kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ bá ṣàìka ojú tí Ọlọ́run fi wo ìgbéyàwó sí, tí ó sì rin kinkin láti lọ.
Àmọ́ ṣa o, lábẹ́ irú ipò yẹn, aya náà lè rí i pé ó yẹ kí òun dáàbò bo ara òun àti àwọn ọmọ òun. Lọ́nà wo? Yóò fẹ́ kí àwọn ọmọ òun olùfẹ́ ọ̀wọ́n máa gbé lọ́dọ̀ òun, kí ó bàa lè máa báa lọ ní fífi ìfẹ́ ìyá hàn sí wọn, kí ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìwà rere, kí ó sì gbin ìgbàgbọ́ tí a gbé ka àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà látinú Bíbélì sí wọn lọ́kàn. (2 Tímótì 3:15) Ìkọ̀sílẹ̀ náà lè máà jẹ́ kí àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. Nítorí náà, ó lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan kí àwọn aláṣẹ lè rí ọ̀ràn náà bó ṣe rí gan-an kí wọ́n lè fún un ní ẹ̀tọ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ sọ́dọ̀ kí ó sì rí i dájú pé wọ́n pa á láṣẹ fún ọkọ rẹ̀ láti máa ti ìdílé tó fẹ́ já jù sílẹ̀ náà lẹ́yìn. Láwọn ibì kan, ó lè ṣeé ṣe fún obìnrin kan tí kò fara mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ láti fọwọ́ sí àwọn ìwé tó fòté lé ẹni tí yóò kó àwọn ọmọ sọ́dọ̀ àti fífowó ṣètìlẹ́yìn, láìfi hàn pé ó fara mọ́ ìgbésẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ tí ọkọ rẹ̀ gbé. Láwọn ibòmíràn, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé náà fi hàn pé ó fara mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ náà; nípa bẹ́ẹ̀, bí ọkọ rẹ̀ bá jẹ̀bi ẹ̀sùn panṣágà, fífi tí aya náà bá fọwọ́ sí irú èyí yóò túmọ̀ sí pé ó ń kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wà lágbègbè yẹn àtàwọn tó wà nínú ìjọ ni kò ní mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀, bí irú pé bóyá wọ́n ṣe ìkọ̀sílẹ̀ náà lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Nítorí ìdí èyí, kó tó di pé ọ̀ràn náà di iṣu ata yán-anyàn-an báyẹn, yóò bọ́gbọ́n mu jù lọ fún aya náà láti sọ òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ fún alábòójútó olùṣalága àti alàgbà mìíràn nínú ìjọ (ó sàn jù kí ó kọ ọ́ sínú ìwé). Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn òkodoro òtítọ́ wọ̀nyẹn yóò lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbàkigbà tí àwọn ìbéèrè bá ń dìde nípa rẹ̀—lákòókò yẹn tàbí lọ́jọ́ iwájú.
Ẹ jẹ́ ká padà sórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” Tó bá wá jẹ́ lóòótọ́ ni ọkọ kan jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà pálapàla takọtabo, ṣùgbọ́n ti kò fẹ́ fi aya rẹ̀ sílẹ̀, aya náà (tó jẹ́ aláìṣẹ̀ nínú àpẹẹrẹ Jésù) gbọ́dọ̀ yàn yálà láti dárí jì í, kí ó sì máa báa ṣàjọpín ibùsùn ìgbéyàwó nìṣó tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Bí ó bá fẹ́ dárí jì í, kí ó sì máa bá ọkọ rẹ̀ tó fẹ́ lábẹ́ òfin gbé nìṣó, kò ṣe ìṣekúṣe rárá ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—Hóséà 1:1-3; 3:1-3.
Nínú ọ̀ràn tí ọkọ oníwà pálapàla kan bá ti sọ pé òun fẹ́ ìkọ̀sílẹ̀, aya rẹ̀ ṣì lè fẹ́ dárí jì í, ní ìrètí pé òun yóò gbà á padà. Ọwọ́ rẹ̀ ló kù sí láti pinnu bóyá kí òun tẹ́wọ́ gba ìgbésẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó sinmi lórí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ní kó ṣe àti bí ipò nǹkan ṣe rí fún un. Láwọn ibì kan, ó lè ṣeé ṣe fún obìnrin kan tí kò fara mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ láti fọwọ́ sí àwọn ìwé tó fòté lé ẹni tí yóò kó àwọn ọmọ sọ́dọ̀ àti fífowó ṣètìlẹ́yìn, láìfi hàn pé ó fara mọ́ ìgbésẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀; fífọwọ́ sí irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ó ń kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn ibòmíràn wà tí wọ́n ti lè sọ pé kí aya tí kò fara mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ wá fọwọ́ sí àwọn ìwé kan tó fi hàn pé ó fara mọ́ ìkọ̀sílẹ̀ náà; fífi tó bá fọwọ́ sí irú àwọn ìwé ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn gbangba pé ó kọ ọkọ rẹ̀ tó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ náà sílẹ̀.
Láti yẹra fún irú èdè àìyedè tó ṣeé ṣe kó wáyé, yóò bọ́gbọ́n mu jù nínú ọ̀ràn yìí àti fún aya náà pàápàá láti mú lẹ́tà tó ní àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n fẹ́ gbé náà nínú àti àwọn ìdí tí wọ́n fi kọ ọ́ wá sọ́dọ̀ àwọn aṣojú ìjọ. Ó tiẹ̀ lè kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé òun ti sọ fún ọkọ òun pé òun ṣe tán láti dárí jì í àti láti jẹ́ ìyàwó rẹ̀. Ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé inú rẹ̀ kò dùn sí ìkọ̀sílẹ̀ náà; kàkà tí ì bá fi kọ ọ̀kọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ó ṣì ṣe tán láti dárí jì í. Lẹ́yìn tó bá ṣe báyẹn láti jẹ́ kó hàn gbangba pé òun ṣe tán láti dárí jì í kí òun sì jẹ́ ìyàwó rẹ̀ síbẹ̀, fífi tí ó fi ọwọ́ sí ìwé tí wọ́n wulẹ̀ fi yanjú àwọn ọ̀ràn nípa ìṣúnná owó àti/tàbí nípa ẹni tó máa kó àwọn ọmọ sọ́dọ̀ kò túmọ̀ sí pé ó ń kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.a
Lẹ́yìn tó bá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun múra tán láti dárí jì í, kódà lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá, kò sẹ́ni to lẹ́tọ̀ọ́ láti fẹ́ ẹlòmíràn nínú òun àti ọkọ rẹ̀. Bí aya aláìṣẹ̀ tí ọkọ rẹ̀ kò fara mọ́ dídáríjì tí ó dárí jì òun bá wá pinnu láti tìtorí ìwà pálapàla ọkọ náà kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níkẹyìn, ìgbà yẹn làwọn méjèèjì lómìnira àtifẹ́ ẹlòmíràn. Jésù fi hàn pé ọkọ tàbí aya tí kò lẹ́bi náà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.—Mátíù 5:32; 19:9; Lúùkù 16:18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tí wọ́n ń ṣe lábẹ́ òfin àti àwọn ìwé yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíràn. Àwọn ọ̀rọ̀ ìkọ̀sílẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé tó bófin mu la gbọ́dọ̀ yẹ̀ wò dáadáa ká tó fọwọ́ sí wọn. Bí ọkọ tàbí aya tí kò lẹ́bi bá lọ fọwọ́ sí àwọn ìwé kan tó fi hàn pé aya (tàbí ọkọ) náà kò tako ìkọ̀sílẹ̀ tí ẹnì kejì rẹ̀ fẹ́ gbà, ìyẹn túmọ̀ sí pé ó ń kọ ẹnì kejì rẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn.—Mátíù 5:37.