Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MARCH 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 12-14
“Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fi Ìfẹ́ Hàn Síra Wa”
it-1 55
Ìfẹ́ni
Ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni ní ìfẹ́ ará (lédè Gíríìkì phi·la·del·phiʹa, ó túmọ̀ sí “ìfẹ́ téèyàn ní sí arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ̀”) láàárín ara wa. (Ro 12:10; Heb 13:1; tún wo 1Pe 3:8.) Torí náà, ó yẹ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín àwọn ará ìjọ, kó jẹ́ ìfẹ́ alọ́májàá, kò sì dà bíi ti ọmọ ìyá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ìjọ ti ń fi ìfẹ́ yìí hàn sí ara wọn, síbẹ̀ a rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀n tó kún rẹ́rẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.—1Tẹ 4:9, 10.
Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà phi·loʹstor·gos, túmọ̀ sí “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” a sì sábà máa ń lò ó fún àwọn tó bá sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. A sábà máa ń lo ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ alákànpọ̀ náà, ìyẹn sterʹgo, láti tọ́ka sí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ní irú ìfẹ́ yìí. (Ro 12:10) Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn èèyàn máa jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá” (ìyẹn ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, aʹstor·goi) láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sì tún sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ fún ikú.—2Ti 3:3; Ro 1:31, 32.
“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
3 Ka Róòmù 12:17. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a kò gbọ́dọ̀ gbẹ̀san nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa. Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá nínú ilé tó jẹ́ pé ọkọ tàbí aya nìkan ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ó lè fẹ́ ṣe èyí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nínú àwọn méjèèjì bíi pé kó fi ọ̀rọ̀ burúkú fèsì ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ sí i, tàbí kó foró yaró. Ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sí èrè kankan nídìí kéèyàn máa “fi ibi san ibi.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń fọ́ ọ̀rọ̀ lójú pọ̀.
“Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi Fún Ẹnì Kankan”
12 Ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn onígbàgbọ́ àtàwọn aláìgbàgbọ́ ni pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” Gbólóhùn yìí ló jẹ́ àbárèbábọ̀ ohun tó ti kọ́kọ́ sọ tẹ́lẹ̀, pé: “Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” Àbí, báwo lẹnì kan á ṣe sọ pé lóòótọ́ lòun kórìíra ohun búburú tàbí ibi, tó bá ń fi ibi san ibi táwọn mìíràn ṣe sí i? Òdìkejì níní ìfẹ́ “láìsí àgàbàgebè” ni ṣíṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́. Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ pèsè àwọn ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lójú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:9, 17) Báwo la ṣe lè fi ohun tó sọ yìí sílò?
13 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù ti kọ́kọ́ kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ nípa inúnibíni táwọn àpọ́sítélì ń dojú kọ. Ó kọ̀wé pé: “Àwa ti di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn. . . . Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.” (1 Kọ́ríńtì 4:9-13) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí fáwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí, àwọn èèyàn ayé ń kíyè sí wọn. Nígbà táwọn tó wà láyìíká wa bá rí àwọn nǹkan dáadáa tí à ń ṣe, kódà nígbà táwọn kan bá ń ṣe ohun tí kò dára sí wa, èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ fojú tó dára wo ohun tí à ń wàásù rẹ̀.—1 Pétérù 2:12.
Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín Fàlàlà
13 Bí ẹnì kan bá hùwà tí kò dáa sí ẹ, o lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ fún irú ẹni bẹ́ẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “‘Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.’ Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:20, 21) Tí o kì í bá gbé e gbóná fún ẹni tó ṣe ohun tó bí ẹ nínú, o lè mú kí ẹni tí ìwà rẹ̀ burú jáì pàápàá yí pa dà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa. Bí ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ bá rí i pé o fòye bá òun lo, tó sì rí i pé o gba tòun rò, ó ṣeé ṣe kó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ìwà rere tó o hù á mú kó ronú nípa ìdí tí ìwà rẹ fi yàtọ̀.—1 Pét. 2:12; 3:16.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Bó O Ṣe Lè Yan Eré Ìnàjú Tó Gbámúṣé
5 Kò sí ohun yòówù tá a lè máa ṣe láyé yìí tó yọ ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó lo gbankọgbì ọ̀rọ̀ láti fi tẹ òtítọ́ yìí mọ́ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ lọ́kàn. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Ara wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ yẹn ná? Èrò inú wa, ọkàn-àyà wa àti okun wa ni. Gbogbo wọn là ń lò nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Máàkù 12:30) Pọ́ọ̀lù pe irú iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá bẹ́ẹ̀ ní ẹbọ. Bá a bá yẹ gbólóhùn yẹn wò dáadáa, a óò rí i pé ìkìlọ̀ ló jẹ́. Lábẹ́ Òfin Mósè, Ọlọ́run kì í gba ẹbọ tó bá ní àléébù. (Léfítíkù 22:18-20) Bákan náà, bí ẹbọ tẹ̀mí tí Kristẹni kan ń rú bá ní àbààwọ́n èyíkéyìí, Ọlọ́run ò ní gbà á. Báwo wá ni ẹbọ tẹ̀mí Kristẹni kan ṣe lè di alábààwọ́n?
6 Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa bá a lọ ní jíjọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀.” Pọ́ọ̀lù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n “fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara.” (Róòmù 6:12-14; 8:13) Nínú lẹ́tà tó kọ́kọ́ kọ sí wọn, ó fún wọn ní àpẹẹrẹ irú “àwọn ìṣe ti ara” bẹ́ẹ̀. A kà nípa aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ pé: “Ẹnu wọ́n sì kún fún ègún.” “Ẹsẹ̀ wọ́n yára kánkán láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.” “Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run níwájú wọn.” (Róòmù 3:13-18) Bí Kristẹni kan bá ń lo “àwọn ẹ̀yà ara” ẹ̀ láti dẹ́ṣẹ̀ nípa híhu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, ó máa sọ ara ẹ̀ di èyí tó ní àléébù. Bí àpẹẹrẹ, bí Kristẹni kan lóde òní bá ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán rádaràda tí ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń wo ìwà ipá tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn bí omi, ńṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ‘jọ̀wọ́ ojú rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀,’ tó sì ń ba gbogbo ara rẹ̀ jẹ́. Ìjọsìn èyíkéyìí tó bá ṣe kì í ṣe ẹbọ mímọ́ mọ́, Ọlọ́run ò sì ní í tẹ́wọ́ gbà á. (Diutarónómì 15:21; 1 Pétérù 1:14-16; 2 Pétérù 3:11) Ẹ ò rí i pé ìyọnu ńlá gbáà ni fẹ́ni tó bá ń lọ́wọ́ sí eré ìnàjú tí kò gbámúṣé!
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Róòmù
13:1—Ọ̀nà wo ni a gbà gbé àwọn aláṣẹ onípò gíga “dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”? Àwọn aláṣẹ ni a gbé “dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ní ti pé, Ọlọ́run ló gbà wọ́n láyè kí wọ́n máa ṣàkóso àti pé nígbà míì Ọlọ́run máa ń sọ bí ìṣàkóso wọn ṣe máa rí ṣáájú. Èyí hàn kedere látinú ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn aláṣẹ kan.
Bíbélì Kíkà
MARCH 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 15-16
“Bẹ Jèhófà Pé Kó Fún Ẹ Ní Ìfaradà Kó sì Tù Ẹ́ Nínú”
“Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún”
11 Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ń tuni nínú pọ̀ gan-an nínú Bíbélì, ọ̀kan lára wọn lèyí tó sọ bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe bá Jésù tó sì sunkún níbi òkú Lásárù. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé, “nítorí gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí lè tù ẹ́ nínú nígbàkígbà tó o bá ń ṣọ̀fọ̀:
▪ “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sm. 34:18, 19.
▪ “Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.”—Sm. 94:19.
▪ “Kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in.” —2 Tẹs. 2:16, 17.
“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
5 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Jèhófà ni “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú.” (Róòmù 15:5) Òun nìkan lọ̀rọ̀ wa yé, òun nìkan ló mọ ohun tá à ń bá yí, ó sì mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Torí náà, ó mọ ohun tá a nílò gan-an ká lè máa fara dà á. Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.” (Sáàmù 145:19) Àmọ́ lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, báwo ló ṣe máa fún wa lókun ká lè máa fara dà á?
“Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run Rẹ”
11 Jèhófà ń fún wa ní ìrètí tó ń mú kí inú wa dùn ká sì ní àlàáfíà ọkàn. (Róòmù 15:13) Ìrètí tí Ọlọ́run ń fúnni máa ń mú ká lè fara da àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́. Àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n bá ‘jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, máa gba adé ìyè, ní ọ̀run.’ (Ìṣí. 2:10) Àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n sì ń pa ìwà títọ́ mọ́ máa gbádùn ìbùkún ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Lúùkù 23:43) Báwo ni irú ìlérí yìí ṣe máa ń rí lára wa? Ó dájú pé ó ń mú inú wa dùn, ó ń mú ká ní àlàáfíà ọkàn, ó sì ń mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—Ják. 1:17.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w89 12/1 24 ¶3
“Ìdánwòyẹ̀wò Ìjójúlówó Ìfẹ́ Rẹ”
Dajudaju, awọn Keferi tí wọn di arakunrin wọn ni a ti nilati sún láti dahunpada sí ipò-ọ̀ràn-ìṣòro wọn. Ó ṣetán, wọn jẹ awọn Kristain ní Jerusalem ní “gbèsè” àkànṣe kan. Kii ha ṣe lati Jerusalem ni ihinrere naa ti tankalẹ lọ sọdọ awọn Keferi? Paul ṣèṣirò pé: “Bí awọn Kristain Jew bá ṣàjọpín awọn ìṣúra tẹmi wọn pẹlu awọn keferi, awọn Keferi ní ojúṣe tí ó hàn gbangba lati ṣèrànlọ́wọ́-ìtìlẹhìn fun awọn aini wọn ti ara.”—Rome 15:27, The New English Bible.
it-1 858 ¶5
Ìmọ̀tẹ́lẹ̀, Ìyàntẹ́lẹ̀
Àsọtẹ́lẹ̀ ti wà pé Mèsáyà tàbí Kristi ló máa jẹ́ Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, láti ara rẹ̀ la ó sì ti bù kún gbogbo olóòótọ́ èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ga 3:8, 14) Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì lọ̀rọ̀ náà “irú-ọmọ” ti kọ́kọ́ jáde, ìyẹn kí wọ́n tó bí Ébẹ́lì. (Jẹ 3:15) A ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọdún sẹ́yìn, ó sì jẹ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀,” ẹ̀yín náà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ṣe kedere pé Mèsáyà ni “irú-ọmọ náà.” Òótọ́ ni pé a ti ‘pa á mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tipẹ́tipẹ́.’—Ro 16:25-27; Ef 1:8-10; 3:4-11.
Bíbélì Kíkà
MARCH 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 1-3
“Ṣé Ẹni Tara Ni Ẹ́ Tàbí Ẹni Tẹ̀mí?”
Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kéèyàn Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?
4 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìwà tẹ́ni tara máa ń hù. Nínú ayé lónìí, báwọn èèyàn ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn ló jẹ wọ́n lógún. Pọ́ọ̀lù pe ohun tó ń darí àwọn èèyàn náà ní “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfé. 2:2) Ẹ̀mí yìí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa hùwà kan náà, ibi táyé bá kọjú sí làwọn náà máa ń kọjú sí, wọn ò sì mọ̀ ju nǹkan tara lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó tọ́ lójú ara wọn ni ọ̀pọ̀ ń ṣe, kò sóhun tó kàn wọ́n nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ tàbí kò tọ́. Ohun tó jẹ ẹni tara lọ́kàn kò ju bó ṣe máa wà nípò gíga, táá sì lówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ láìgba tàwọn míì rò.
5 Kí lohun míì tá a fi lè dá ẹni tara mọ̀? Ẹni tara ni ẹni tó bá ń lọ́wọ́ nínú ohun tí Bíbélì pè ní “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19-21) Lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì sọ àwọn ìwà míì táwọn ẹni tara máa ń hù. Díẹ̀ rèé lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe: Wọ́n máa ń fa ìpínyà, wọ́n máa ń gbè sẹ́yìn àwọn tó ń fa aáwọ̀, wọ́n máa ń gba ìwà ọ̀tẹ̀ láyè, wọ́n máa ń gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́, wọn kì í bọ̀wọ̀ fún ipò orí, wọ́n sì máa ń ṣàṣejù nídìí oúnjẹ àti ọtí. Yàtọ̀ síyẹn, wẹ́rẹ́ ni ẹni tara máa ń ṣubú sínú ìdẹwò. (Òwe 7:21, 22) Júúdà tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn sọ pé ipò ẹni tara máa ń burú débi pé á di “aláìní ìfẹ́ nǹkan tẹ̀mí.”—Júúdà 18, 19.
Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kéèyàn Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?
6 Kí wá ló túmọ̀ sí pé ẹnì kan jẹ́ “ènìyàn ti ẹ̀mí”? Ẹni tẹ̀mí yàtọ̀ pátápátá sí ẹni tara ní ti pé èrò Ọlọ́run lẹni tẹ̀mí máa ń ní. Ẹni tẹ̀mí máa ń sapá kó lè “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfé. 5:1) Lédè míì, ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú èrò rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu, ó sì máa ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Ó máa ń ro ti Ọlọ́run mọ́ gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu làwọn ẹni tẹ̀mí máa ń ṣe, wọn ò dà bí àwọn ẹni tara tí kò mọ̀ ju nǹkan tara lọ. (Sm. 119:33; 143:10) Ẹni tẹ̀mí kì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí Bíbélì pè ní iṣẹ́ ti ara, kàkà bẹ́ẹ̀ “èso ti ẹ̀mí” ló fi ń ṣèwà hù. (Gál. 5:22, 23) Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹni tẹ̀mí báyìí: Tẹ́nì kan bá já fáfá nídìí iṣẹ́ rẹ̀ tí kì í sì í fi iṣẹ́ ṣeré, a máa ń pe onítọ̀hún ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Lọ́nà kan náà, tẹ́nì kan bá ń fọwọ́ gidi mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, a máa ń pè é ní ẹni tẹ̀mí.
Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kéèyàn Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?
15 Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè fara wé Kristi? Ìwé 1 Kọ́ríńtì 2:16 sọ pé ká ní “èrò inú ti Kristi.” Bákan náà ni Róòmù 15:5 rọ̀ wá pé ká ní “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.” Torí náà, tá a bá fẹ́ dà bíi Kristi, ó ṣe pàtàkì ká mọ bí Kristi ṣe ń ronú ká sì mọ ohun tó máa ṣe lábẹ́ ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bí Jésù ṣe máa wu Ọlọ́run lohun tó jẹ ẹ́ lógún. Torí náà, tá a bá fìwà jọ Jésù, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa ronú bí Jésù ṣe ń ronú.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 1193 ¶1
Ọgbọ́n
Bí ayé ṣe rò pé àwọn gbọ́n tó, wọ́n ka gbogbo ọgbọ́n tí Ọlọ́run ń pèsè nípasẹ̀ Jésù sí òmùgọ̀; àwọn alákòóso wọn lè ti máa fi ọgbọ́n ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn, síbẹ̀ àwọn náà ló “kan Olúwa ológo mọ́gi.” (1Kọ 1:18; 2:7, 8) Àmọ́, Ọlọ́run ń fi hàn pé òmùgọ̀ làwọn tó ń pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n. Ó ń lo àwọn ẹni tí wọ́n kà sí “ohun òmùgọ̀ ti Ọlọ́run” láti kó ìtìjú bá wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tún ń lo àwọn ẹni tí wọ́n kà sí ‘òmùgọ̀, aláìlera’ àti àwọn tí a kò bí láti inú ilé ọlá láti ṣe àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe. (1Kọ 1:19-28) Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì létí pé “ọgbọ́n ti ètò àwọn nǹkan yìí [àti] ti àwọn olùṣàkóso ètò àwọn nǹkan yìí,” máa di asán; torí náà kì í ṣe irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ló wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì yìí sọ. (1Kọ 2:6, 13) Ó kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí “ìmọ̀ ọgbọ́n orí [phi·lo·so·phiʹas, lédè Gíríìkì, ìfẹ́ fún ọgbọ́n] àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn” mú wọn lẹ́rú.—Kol 2:8; fi wé ẹsẹ 20 sí 23.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kọ́ríńtì Kìíní àti Ìkejì
2:3-5. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù nílùú Kọ́ríńtì níbi tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ Gíríìkì ti gbilẹ̀, ó ṣeé ṣe kó máa ṣàníyàn nípa ọ̀nà táá fi lè yí àwọn tó ń wàásù fún lérò padà. Àmọ́ kò jẹ́ kí àìlera tàbí ìbẹ̀rù kankan dí i lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Táwa náà bá bá ara wa nínú ipò kan tá ò rírú ẹ̀ rí, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ṣèdíwọ́ fún wa láti polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. A ní láti fọkàn balẹ̀, ká máa wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe.
Bíbélì Kíkà
MARCH 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 4-6
“Ìwúkàrà Díẹ̀ Ní Í Mú Gbogbo Ìṣùpọ̀ Di Wíwú”
it-2 230
Ìwúkàrà
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ yìí kan náà nígbà tó ń sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n yọ ẹni tó jẹ́ oníṣekúṣe kúrò nínú ìjọ, ó ní: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìṣùpọ̀ di wíwú? Ẹ mú ògbólógbòó ìwúkàrà kúrò, kí ẹ lè jẹ́ ìṣùpọ̀ tuntun, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ aláìní amóhunwú. Nítorí, ní tòótọ́, a ti fi Kristi ìrékọjá wa rúbọ.” Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá sọ ìtúmọ̀ “ìwúkàrà” tó mẹ́nu kan lẹ́ẹ̀kan, ó ní: “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a pa àjọyọ̀ mọ́, kì í ṣe pẹ̀lú ògbólógbòó ìwúkàrà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pẹ̀lú ìwúkàrà ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà burúkú, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àkàrà aláìwú ti òtítọ́ inú àti òtítọ́.” (1Kọ 5:6-8) Níbí, ṣe ni Pọ́ọ̀lù ń sọ ohun tí Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú tí àwọn Júù máa ń ṣe túmọ̀ sí, ìyẹn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lẹ́yìn ayẹyẹ Ìrékọjá. Bí ìwọ̀nba ìyẹ̀fun àpòrọ́ kíkan ṣe lè mú kí gbogbo ìṣùpọ̀ tàbí búrẹ́dì di wíwú, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rí fún ìjọ, ó máa di aláìmọ́ lójú Jèhófà tí wọn ò bá yọ ẹni tó jẹ́ oníwà àìmọ́ kúrò láàárín wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ yọ “ìwúkàrà” náà kúrò láàárín wọn, bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ṣe kí í ń ní ìwúkàrà nínú ilé wọn nígbà àjọyọ̀.
it-2 869-870
Sátánì
Kí ló túmọ̀ sí láti fi ẹnì kan “lé Sátánì lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara”?
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fún àwọn tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì ní ìtọ́ni nípa ohun tí wọ́n máa ṣe sí ará ìjọ kan tó hùwà àìtọ́, tó lọ ń fẹ́ ìyàwó bàbá rẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ lé Sátánì lọ́wọ́ fún ìparun ẹran ara.” (1Kọ 5:5) Ohun tó ń sọ ni pé kí wọ́n lé ẹni náà kúrò nínú ìjọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀. (1Kọ 5:13) Bí wọ́n ṣe fà á lé Sátánì lọ́wọ́—wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ mú un kúrò nínú ìjọ, wọ́n sì fà á lé ayé yìí lọ́wọ́, ìyẹn ayé tí Sátánì ń ṣàkóso. Bíi ti “ìwúkàrà díẹ̀” nínú “gbogbo ìṣùpọ̀,” ọkùnrin yìí ni “ẹran ara,” tó ń hùwà burúkú nínú ìjọ. Bí wọ́n sì ṣe yọ ọkùnrin oníwà àìtọ́ yìí, àwọn ará ìjọ tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa yẹra fún “ẹran ara” yẹn, kó má bàa kéèràn ràn wọ́n. (1Kọ 5:6, 7) Lọ́nà kan náà, Pọ́ọ̀lù fi Híméníọ́sì àti Alẹkisáńdà lé Sátánì lọ́wọ́, torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ mọ́, ẹ̀rí ọkàn wọn ò sì ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ìgbàgbọ́ wọn sì ti forí ṣánpọ́n.—1Ti 1:20.
lv àfikún 207 ¶1-3
Ọwọ́ Tó Yẹ Ká Fi Mú Ẹni Tí Wọ́n Bá Yọ Lẹ́gbẹ́
Kò sóhun tó máa ń dunni bíi kí wọ́n yọ ìbátan ẹni tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ nítorí pó dẹ́ṣẹ̀ tí kò sì ronú pìwà dà. Bá a ṣe ń ṣègbọràn sí ìlànà tí Bíbélì fi lélẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí, lè fi hàn bóyá a nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá sí Ọlọ́run a sì fẹ́ láti máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tó gbé kalẹ̀. Gbé àwọn ìbéèrè díẹ̀ tó wáyé lórí kókó yìí yẹ̀ wò.
Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.” (1 Kọ́ríńtì 5:11) Ní ti ẹnikẹ́ni tí kò bá “dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi,” a kà pé: “Ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i. Nítorí ẹni tí ó bá kí i jẹ́ alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀.” (2 Jòhánù 9-11) Àjọṣe tẹ̀mí tàbí jíjẹ, mímu ò gbọ́dọ̀ da àwa àti ẹni tí wọ́n bá yọ lẹ́gbẹ́ pọ̀. Ile-Iṣọ Naa January 15, 1982, ojú ìwé 24, sọ pé: “‘Bawo ni o!’ ti a sọ si ẹnikan le jẹ igbesẹ akọkọ ti yoo dagbasoke di ijumọsọrọpọ ati boya ibadọrẹ pàápàá. Awa yoo ha fẹ lati gbe igbesẹ akọkọ nì pẹlu ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ bi?”
Ṣó pọn dandan kéèyàn yẹra pátápátá fún ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìdí mélòó kan wà tó fi yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdúróṣinṣin wa àti bá a ṣe ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí pàtàkì tó ni. Kì í ṣe ìgbà tó bá wù wá nìkan ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà, ó tún yẹ ká máa ṣègbọràn sí i nígbà tó bá tiẹ̀ nira pàápàá. Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa ń mú ká ṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ rẹ̀, torí a mọ̀ pé ó jẹ́ aláìṣègbè àti Ọlọ́run ìfẹ́ àti pé àǹfààní wa làwọn òfin rẹ̀ wà fún. (Aísáyà 48:17; 1 Jòhánù 5:3) Èkejì, bá a bá ta kété sí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà, ìyẹn máa dáàbò bo àwa àtàwọn tá a jọ wà nínú ìjọ kúrò lọ́wọ́ ohun tó lè kó àbààwọ́n bá ìdúró wa àti ìwà rere wa, a kò sì ní kó àbùkù èyíkéyìí bá orúkọ rere ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 5:6, 7) Ẹ̀kẹta, bá a bá dúró gbọn-in lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ìyẹn lè ṣe ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ náà láǹfààní. Bá a bá fara mọ́ ìpinnu tí ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ṣe, ìyẹn lè gún oníwà àìtọ́ kan tó ti ń ṣe gbọ́ńkú gbọ́ńkú sáwọn alàgbà látìgbà yìí wá ní kẹ́ṣẹ́, kó bàa lè gba ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n fẹ́ fún un. Léyìí tí tẹbí tará ti kẹ̀yìn sí i báyìí, ìyẹn lè pe “orí rẹ̀ wálé,” kó bàa lè rí bí nǹkan tóun ṣe ti burú tó, kó sì gbé ìgbésẹ̀ láti padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà.—Lúùkù 15:17.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
16 Àwọn Kristẹni tí wọ́n ń fara da àdánwò jẹ́ ‘ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún àwọn áńgẹ́lì.’ (1 Kọ́r. 4:9) Inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń kíyèsí ìwà títọ́ wa, wọ́n tiẹ̀ máa ń yọ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:10) Àwọn áńgẹ́lì ń kíyè sí bí àwọn Kristẹni obìnrin ṣe ń hùwà tínú Ọlọ́run dùn sí. Bíbélì sọ pé ó “yẹ kí obìnrin ní àmì ọlá àṣẹ ní orí rẹ̀ nítorí àwọn áńgẹ́lì.” (1 Kọ́r. 11:3, 10) Ó dájú pé inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn tí wọ́n bá rí àwọn Kristẹni obìnrin àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí. Ìránnilétí tó yẹ ni ṣíṣègbọràn lọ́nà bẹ́ẹ̀ jẹ́ fáwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí.
it-2 211
Òfin
Òfin tó fún àwọn Áńgẹ́lì. Àwọn áńgẹ́lì lágbára ju àwọn èèyàn lọ, síbẹ̀ wọ́n ń ṣègbọràn sí òfin àtàwọn àṣẹ́ Ọlọ́run. (Heb 1:7, 14; Sm 104:4) Kódà, Jèhófà pàṣẹ fún Sátánì tó jẹ́ elénìní rẹ̀, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé ó níbi tí agbára rẹ̀ mọ. (Job 1:12; 2:6) Máíkẹ́lì tó jẹ́ olú-áńgẹ́lì bọlá fún Jèhófà torí pé Jèhófà ni Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ. Nígbà tí awuyewuye kan wáyé láàárín òun àti Èṣù, Jésù sọ pé: “Kí Jèhófà bá ọ wí.” (Jud 9; fi wé Sek 3:2.) Jèhófà Ọlọ́run ti ṣe Jésù Kristi lógo, ó sì ti fi gbogbo àwọn ańgẹ́lì sí abẹ́ àṣẹ rẹ̀. (Heb 1:6; 1Pe 3:22; Mt 13:41; 25:31; Flp 2:9-11) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè pàṣẹ pé kí ańgẹ́lì kan lọ jíṣẹ́ fún Jòhánù. (Iṣi 1:1) Àmọ́, nínú 1 Kọ́ríńtì 6:3 àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé a ti yan àwọn arákùnrin Kristi láti ṣèdájọ́ àwọn ańgẹ́lì, ó dájú pé ó jẹ́ torí pé wọ́n máa kópa nínú ṣíṣe ìdájọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú.
Bíbélì Kíkà