-
Máa Rìn Ní Ọ̀nà JèhófàIlé Ìṣọ́—1999 | May 15
-
-
6, 7. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tilẹ̀ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà, kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó mú wọn ṣáko lọ, èé sì ti ṣe?
6 Èyí ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì ìgbàanì, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti fi hàn. Ó kọ̀wé pé: “Nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má bàa jẹ́ ẹni tí ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe ní ìfẹ́-ọkàn sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”—1 Kọ́ríńtì 10:6-8.
7 Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ tọ́ka sí ìgbà tí Ísírẹ́lì jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà ní ẹsẹ̀ Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 32:5, 6) Èyí jẹ́ àìgbọràn ní tààràtà sí àṣẹ Ọlọ́run tí wọ́n ṣàdéhùn pé àwọn yóò ṣègbọràn sí níwọ̀nba ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. (Ẹ́kísódù 20:4-6; 24:3) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wá tọ́ka sí àkókò tí Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọbìnrin Móábù tẹrí ba fún Báálì. (Númérì 25:1-9) Ìjọsìn ọmọ màlúù kún fún ìkẹ́ra ẹni bàjẹ́ tó bùáyà, ‘gbígbádùn ara ẹni.’a Ìjọsìn Báálì máa ń kún fún ìṣekúṣe tó ré kọjá ààlà. (Ìṣípayá 2:14) Èé ṣe táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dá ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ti jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn di èyí tí “ń ní ìfẹ́-ọkàn sí àwọn ohun tí ń ṣeni léṣe”—ì báà jẹ́ ìbọ̀rìṣà tàbí àwọn ìwà pálapàla tí ń bá a rìn.
8. Kí ni a lè rí kọ́ láti inú ìrírí Ísírẹ́lì?
8 Pọ́ọ̀lù sọ pé ó yẹ kí a kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n nínú ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́? Kò ṣeé ronú kàn, pé Kristẹni kan yóò bẹ̀rẹ̀ sí tẹrí ba fún ère ọmọ màlúù oníwúrà tàbí ọlọ́run Móábù ìgbàanì. Ṣùgbọ́n ìṣekúṣe àti ìkẹ́ra ẹni bàjẹ́ ńkọ́? Ìwọ̀nyí wọ́pọ̀ lónìí, báa bá sì gbà kí ìfẹ́ fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dàgbà nínú ọkàn-àyà wa, wọn yóò yà wá nípa sí Jèhófà. Àbájáde rẹ̀ kò ní yàtọ̀ sí lílọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà—yóò sì sọ wá di ọ̀tá Ọlọ́run. (Fi wé Kólósè 3:5; Fílípì 3:19.) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kádìí ìjíròrò rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn nípa gbígba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.”—1 Kọ́ríńtì 10:14.
-
-
Máa Rìn Ní Ọ̀nà JèhófàIlé Ìṣọ́—1999 | May 15
-
-
a Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni alálàyé kan ń ṣàlàyé nípa ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa tú sí “gbádùn ara wọn” níhìn-ín, ó sọ pé ó tọ́ka sí àwọn ijó tí wọ́n máa ń jó níbi ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà, ó wá fi kún un pé: “Ohun tí gbogbo èèyàn mọ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ irú ijó bẹ́ẹ̀ ni a pète ní tààràtà láti fi ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó burú jáì sókè.”
-