Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
“Lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti gba èyíinì tí èmi pẹ̀lú fi lé yín lọ́wọ́.”—1 Kọ́ríńtì 11:23.
1, 2. Kí ni Jésù ṣe ní alẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
ỌMỌ kan ṣoṣo tí Jèhófà bí wà níbẹ̀. Àwọn ọkùnrin mọ́kànlá tí wọ́n ‘ti dúró tì í gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò rẹ̀’ sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Lúùkù 22:28) Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Thursday, March 31, ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni. Ó sì ṣeé ṣe kí òṣùpá àrànmọ́jú ti mú kí ojú òfuurufú Jerúsálẹ́mù lẹ́wà gan-an lákòókò yẹn. Kò tíì pẹ́ rárá tí Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ parí àjọ̀dún Ìrékọjá. Ó ti ní kí Júdásì Ísíkáríótù aláìṣòótọ́ nì jáde, àmọ́ àkókò táwọn tó kù máa jáde ò tíì tó. Kí nìdí? Nítorí pé Jésù fẹ́ ṣe ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an. Kí ni nǹkan ọ̀hún?
2 Níwọ̀n bí Mátíù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere ti wà níbẹ̀, ẹ jẹ́ kó sọ fún wa. Ó kọ ọ́ pé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’” (Mátíù 26:26-28) Ṣé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé? Kí ni ìjẹ́pàtàkì rẹ̀? Ǹjẹ́ ó nítumọ̀ kankan fún wa lónìí?
“Ẹ Máa Ṣe Èyí”
3. Kí nìdí tí ohun tí Jésù ṣe lálẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa fi ṣe pàtàkì?
3 Ohun tí Jésù Kristi ṣe lálẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa kì í ṣe ohun àkọsẹ̀bá lásán nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa èyí nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Kọ́ríńtì, níbi tí wọ́n ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ yìí ní ohun tó lé ní ogún ọdún lẹ́yìn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ò sí lọ́dọ̀ Jésù àtàwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá náà ní 33 Sànmánì Tiwa, ó dájú pé ó ti ní láti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi àṣeyẹ náà lẹ́nu àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì. Yàtọ̀ síyẹn, ó hàn gbangba pé Pọ́ọ̀lù á ti rí ẹ̀rí ìdánilójú onírúurú apá tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní nípasẹ̀ ìṣípayá onímìísí. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti gba èyíinì tí èmi pẹ̀lú fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú ìṣù búrẹ́dì ní òru tí a ó fi í léni lọ́wọ́, àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù ú, ó sì wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’ Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ti ife náà pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ó ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: ‘Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’”—1 Kọ́ríńtì 11:23-25.
4. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni máa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
4 Lúùkù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere jẹ́rìí gbè é pé lóòótọ́ ni Jésù pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) A tún ti túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí: “Ẹ máa ṣe èyí fún ìrántí mi” (Today’s English Version) àti “Ẹ máa ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ìrántí mi.” (The Jerusalem Bible) Ní ti tòótọ́, àṣeyẹ yìí la sábà máa ń pè ní Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Pọ́ọ̀lù tún pè é ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—ohun tó pè é yìí sì bá a mu wẹ́kú nítorí pé alẹ́ ni a ṣe àṣeyẹ náà. (1 Kọ́ríńtì 11:20) A pà á láṣẹ pé káwọn Kristẹni máa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àmọ́ kí nìdí tá a fi dá àṣeyẹ yìí sílẹ̀?
Ìdí Tá A Fi Dá A Sílẹ̀
5, 6. (a) Kí ni ìdí àkọ́kọ́ tí Jésù fi dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀? (b) Sọ ìdí mìíràn tá a fi dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀.
5 Ìdí àkọ́kọ́ tá a fi dá Ìṣe Ìrántí náà sílẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ète tí Jésù fi kú. Ó kú gẹ́gẹ́ bí ẹni tó dá ipò ọba aláṣẹ Baba rẹ̀ ọ̀run láre. Kristi wá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì Èṣù, ẹni tó ti fi ẹ̀sùn èké kan àwọn èèyàn pé kìkì nítorí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń sìn ín. (Jóòbù 2:1-5) Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú fi hàn pé irọ́ pátápátá lọ̀rọ̀ yẹn, ó sì mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.
6 Ìdí mìíràn tó fi dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ni láti rán wa létí pé Jésù “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” nípasẹ̀ ikú tó kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (Mátíù 20:28) Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ó pàdánù ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé àti gbogbo àǹfààní ibẹ̀. Àmọ́, Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Láìsí àní-àní, “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Ṣíṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ń rán wa létí ìfẹ́ gíga tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ikú ìrúbọ tí Jésù kú. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká mọrírì ìfẹ́ yẹn gan-an!
Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Máa Ṣe É?
7. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gbà ń jẹ nínú ohun tá a fi ṣe Ìṣe Ìrántí náà “nígbàkúùgbà”?
7 Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni pé: “Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ ìṣù búrẹ́dì yìí, tí ẹ sì ń mu ife yìí, ẹ ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.” (1 Kọ́ríńtì 11:26) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò máa jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tá a fi ń ṣe Ìṣe ìrántí náà títí dọjọ́ ikú wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, níwájú Jèhófà Ọlọ́run àti gbogbo èèyàn, léraléra ni wọ́n á máa pòkìkí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú pípèsè tí Ọlọ́run pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù.
8. Ìgbà wo làwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀ máa ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa dà?
8 Ìgbà wo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lápapọ̀ yóò ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi náà dà? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Títí yóò fi dé,” tó túmọ̀ sí pé àṣeyẹ yìí yóò máa bá a lọ títí dìgbà tí Jésù yóò fi dé láti gba àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sí òkè ọ̀run nípasẹ̀ àjíǹde nígbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:14-17) Èyí bá ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin náà mu pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín, èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.”—Jòhánù 14:3.
9. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Máàkù 14:25?
9 Nígbà tí Jésù dá Ìṣe Ìrántí náà sílẹ̀, ó tọ́ka sí ife wáìnì, ó sì sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Èmi kì yóò mu nínú àmújáde àjàrà mọ́ lọ́nàkọnà títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 14:25) Níwọ̀n bí Jésù ò ti ní máa mu wáìnì lọ́run, ó hàn gbangba pé ohun tó ní lọ́kàn ni ayọ̀ tí wáìnì máa ń dúró fún nígbà mìíràn. (Sáàmù 104:15; Oníwàásù 10:19) Wíwà pa pọ̀ nínú Ìjọba náà yóò jẹ́ ìrírí aláyọ̀ tí òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ń fi ìháragàgà wọ̀nà fún.—Róòmù 8:23; 2 Kọ́ríńtì 5:2.
10. Báwo ló ṣe yẹ ka máa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà léraléra tó?
10 Ṣe oṣooṣù, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tàbí ojoojúmọ́ pàápàá ló yẹ ká máa ṣayẹyẹ ikú Jésù? Rárá o. Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ ní ọjọ́ Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí “ìrántí” ìdáǹdè Ísírẹ́lì kúrò ní oko ẹrú àwọn ará Íjíbítì ní 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọjọ́ náà sì ni wọ́n pa á. (Ẹ́kísódù 12:14) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ́dún ni wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá náà, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn ti àwọn Júù. (Ẹ́kísódù 12:1-6; Léfítíkù 23:5) Èyí fi hàn pé kìkì iye ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá náà ló yẹ ká máa ṣe ìrántí ikú Jésù—ìyẹn lọ́dọọdún, kì í ṣe lóṣooṣù, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tàbí lójoojúmọ́.
11, 12. Kí ni ìtàn sọ nípa bí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ní ìjímìjí?
11 Nítorí náà, ó bá a mu wẹ́kú láti máa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí náà ní Nísàn 14 lọ́dọọdún. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Quartodeciman [Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá] làwọn èèyàn máa ń pe àwọn Kristẹni tó wà ní Éṣíà Kékeré nítorí àṣà wọn ti ṣíṣayẹyẹ pascha [Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa] ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn . . . Déètì náà lè bọ́ sí ọjọ́ Friday tàbí ọjọ́ mìíràn nínú ọ̀sẹ̀.”—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge, Apá Kẹrin, ojú ìwé 44.
12 Nígbà tí òpìtàn nì, J. L. von Mosheim, ń sọ̀rọ̀ nípa àṣà tó gbòde ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, ó ní àwọn Quartodeciman máa ń ṣe Ìṣe Ìrántí ní Nísàn 14 nítorí pé “wọ́n ka àpẹẹrẹ Kristi sí èyí tó lágbára bí òfin.” Òpìtàn mìíràn sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Quartodeciman ti Éṣíà kò yàtọ̀ sí ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Jerúsálẹ́mù. Ní ọ̀rúndún kejì, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí níbi ayẹyẹ Pascha wọn, ní Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá, máa ń ṣèrántí ìràpadà tí ikú Kristi ṣe.”—Studia Patristica, Apá Kárùn-ún, 1962, ojú ìwé 8.
Ìjẹ́pàtàkì Búrẹ́dì Náà
13. Irú búrẹ́dì wo ni Jésù lò nígbà tó ń dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀?
13 Nígbà tí Jésù dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀, “ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó súre, ó bù ú, ó sì fi í fún [àwọn àpọ́sítélì].” (Máàkù 14:22) Búrẹ́dì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà yẹn ni irú èyí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lò fún Ìrékọjá. (Ẹ́kísódù 13:6-10) Nítorí pé wọn ò fi ìwúkàrà sí i, ó rí pẹlẹbẹ, ó ṣeé kán sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì ní láti bù ú kí wọ́n pín in kiri. Nígbà tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu sọ búrẹ́dì di púpọ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, èyí tó ṣe pẹlẹbẹ tó sì ṣeé kán sí wẹ́wẹ́ náà ni èyí tó lò, nítorí pé ó bù ú kó lè ṣe é pín káàkiri. (Mátíù 14:19; 15:36) Ó hàn gbangba nígbà náà pé bíbù tá a máa ń bu búrẹ́dì tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí kì í ṣe ọ̀ràn ààtò ìsìn.
14. (a) Kí nìdí tó fi dára gan-an pé búrẹ́dì aláìwú la fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí? (b) Irú búrẹ́dì wo la lè rà tàbí tá a lè ṣe fún lílò nígbà ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
14 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa búrẹ́dì tó lò nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ara mi tí ó wà nítorí yín.” (1 Kọ́ríńtì 11:24; Máàkù 14:22) Jíjẹ́ tí búrẹ́dì náà jẹ́ aláìwú dára gan-an ni. Kí nìdí? Nítorí pé ìwúkàrà lè túmọ̀ sí ìwà ìbàjẹ́, ìwà ibi, tàbí ẹ̀ṣẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 5:6-8) Búrẹ́dì náà dúró fún ara ẹ̀dá ènìyàn pípé, aláìlẹ́ṣẹ̀ ti Jésù, tó sì ti fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. (Hébérù 7:26; 10:5-10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi èyí sọ́kàn, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nípa lílo búrẹ́dì aláìwú níbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí. Láwọn ìgbà mìíràn, àkàrà àwọn Júù tí kò ní èròjà kankan bí àlùbọ́sà àti ẹyin nínú ni wọ́n máa ń lò. Bí wọn ò bá sì lo ìyẹn, wọ́n lè lo búrẹ́dì tí wọ́n fi kìkì ìyẹ̀fun (tàbí àlìkámà, tó bá ṣeé ṣe) tí wọ́n fi omi díẹ̀ pò ṣe. A gbọ́dọ̀ lọ ìyẹ̀fun tá a fi omi pò náà di pẹlẹbẹ, a sì lè yan án nínú agolo tá a rọra fi òróró díẹ̀ pa títí tí búrẹ́dì náà á fi gbẹ táá sì rọrùn láti kán sí wẹ́wẹ́.
Ìjẹ́pàtàkì Wáìnì
15. Kí ló wà nínú ife tí Jésù lò nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀?
15 Lẹ́yìn tí wọ́n pín búrẹ́dì aláìwú náà káàkiri, Jésù mú ife, “ó dúpẹ́, ó sì fi í fún [àwọn àpọ́sítélì], gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.” Jésù ṣàlàyé pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 14:23, 24) Kí ló wà nínú ife náà? Wáìnì kíkan ni, kì í ṣe omi àjàrà tí kò kan. Nígbà tí Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ọ wáìnì, kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa omi àjàrà tí kò kan ló ń sọ. Bí àpẹẹrẹ, wáìnì kíkan ló lè bẹ́ “ògbólógbòó àpò awọ,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, kì í ṣe omi àjàrà. Àwọn ọ̀tá Kristi náà tún fẹ̀sùn kàn án pé ó “fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì.” Ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá nìyẹn ì bá jẹ́ tí wáìnì náà bá jẹ́ omi àjàrà lásán. (Mátíù 9:17; 11:19) Wáìnì ni wọ́n máa ń mu nígbà ayẹyẹ Ìrékọjá, òun náà ni Kristi sì lò nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀.
16, 17. Irú wáìnì wo ló tọ́ tó sì yẹ fún ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí, kí sì nìdí?
16 Kìkì wáìnì pupa ló tọ́ tó si yẹ fún ohun tí nǹkan tó wà nínú ife náà ń ṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ni ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Àpọ́sítélì Pétérù náà sì kọ̀wé pé: “Ẹ [àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró] mọ̀ pé kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́, pẹ̀lú fàdákà tàbí wúrà, ni a fi dá yín nídè kúrò nínú ọ̀nà ìwà yín aláìléso, tí ẹ gbà nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn baba ńlá yín. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí, àní ti Kristi.”—1 Pétérù 1:18, 19.
17 Ó dájú pé wáìnì àjàrà pupa ni irú èyí tí Jésù lò nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn wáìnì pupa kan wà lóde òní tá ò lè lò, nítorí pé wọ́n máa ń lú ọtí bọ́lugi tàbí egbòogi àti nǹkan amóúnjẹ-ta-sánsán mọ́ ọn. Ẹ̀jẹ̀ Jésù pé pérépéré, kò nílò pé ká lú ohunkóhun mọ́ ọn. Ìdí nìyẹn tá ò fi lè lo àwọn wáìnì tó ní irú àwọn èròjà bẹ́ẹ̀. Ohun tó gbọ́dọ̀ wà nínú ife Ìṣe Ìrántí náà ni wáìnì pupa tí kò ládùn tá ò sì ṣàdàlù rẹ̀. A lè lo wáìnì àjàrà pupa tí kò dùn, èyí téèyàn fọwọ́ ara rẹ̀ ṣe, bẹ́ẹ̀ náà la tún lè lo àwọn wáìnì pupa bíi burgundy àti claret.
18. Kí nìdí tí Jésù ò fi ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan nípa búrẹ́dì àti wáìnì Ìṣe Ìrántí náà?
18 Nígbà tí Jésù dá oúnjẹ yìí sílẹ̀, kò fi iṣẹ́ ìyanu yí àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà padà sí ara àti ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ gan-an. Jíjẹ ẹran ara àti mímu ẹ̀jẹ̀ dà bíi jíjẹ ènìyàn fúnra rẹ̀, rírú òfin Ọlọ́run sì nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Léfítíkù 17:10) Kò sì séyìí tó yingin nínú ẹran ara Jésù àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà. Ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ẹbọ pípé, ó sì tú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde ní ọ̀sán ọjọ́ kan náà ìyẹn Nísàn 14 tàwọn Júù. Nítorí náà, búrẹ́dì àti wáìnì tá à ń lò fún Ìṣe Ìrántí jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ, tó dúró fún ara àti ẹ̀jẹ̀ Kristi.a
Ìṣe Ìrántí—Oúnjẹ Àjọjẹ
19. Kí nìdí tá a fi lè lò ju àwo pẹrẹsẹ kan àti ife kan nígbà tá a bá ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
19 Nígbà tí Jésù dá Ìṣe Ìrántí náà sílẹ̀, ó ní kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mu láti inú ife kan náà. Ìhìn Rere Mátíù sọ pé: “[Jésù] mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín.’” (Mátíù 26:27) Lílo “ife kan” dípò ife bíi mélòó kan kò lè jẹ́ ìṣòro rárá nítorí pé àwọn mọ́kànlá péré ló mu nínú ife náà, ó sì hàn gbangba pé tábìlì kan ni gbogbo wọn jókòó yí ká, kò sì ní ṣòro fún wọn láti gbé ife náà láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan bọ́ sí ọ̀dọ̀ ẹni kejì. Lọ́dún yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa kóra jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà nínú ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Níwọ̀n bó ti jẹ pé ọ̀pọ̀ ibi la ti máa pé jọ fún àṣeyẹ yìí ni alẹ́ ọjọ́ kan náà, kò sí bí gbogbo wa ṣe lè lo ife kan ṣoṣo. Àmọ́ ohun kan náà ni ife yìí ṣì dúró fún láwọn ìjọ ńlá nígbà tá a bá lo ife bíi mélòó kan kí wọ́n lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tó wà láwùjọ láàárín àkókò kúkúrú. Bákan náà la lè lò ju àwo pẹrẹsẹ kan lọ láti gbé búrẹ́dì náà káàkiri. Kò sí ohunkóhun nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé ife náà gbọ́dọ̀ jẹ́ irú kan pàtó. Àmọ́ ṣá o, òun àti àwo pẹrẹsẹ náà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí ó buyì kún àṣeyẹ náà. Ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé ká máà jẹ́ kí ife náà kún dẹ́nu kó máà di pé wáìnì náà ń dà nù nígbà tá a bá ń gbé e káàkiri.
20, 21. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ìṣe Ìrántí jẹ́ oúnjẹ àjọjẹ?
20 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lò ju àwo búrẹ́dì kan àti ife wáìnì kan, síbẹ̀ oúnjẹ àjọjẹ ni Ìṣe Ìrántí náà jẹ́. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọkùnrin kan lè pèsè oúnjẹ àjọjẹ kan nípa mímú ẹran kan wá sínú ibùjọsìn Ọlọ́run, níbi tí wọ́n ti máa pa ẹran náà. Wọ́n á sun lára ẹran náà lórí pẹpẹ, díẹ̀ lára rẹ̀ á lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ibẹ̀, òmíràn lára rẹ̀ a lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Áárónì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, ẹni tó mú ẹran náà wá àti agbo ilé rẹ̀ á tún jẹ níbẹ̀ pẹ̀lú. (Léfítíkù 3:1-16; 7:28-36) Bẹ́ẹ̀ náà ni Ìṣe Ìrántí ṣe jẹ́ oúnjẹ àjọjẹ nítorí ó ní í ṣe pẹ̀lú jíjùmọ̀ ṣàjọpín.
21 Jèhófà ń jẹ nínú oúnjẹ yìí nítorí pé òun ni Ẹni tó ṣe ètò náà. Jésù ni ẹbọ náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sì ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà gẹ́gẹ́ bí àwọn alájùmọ̀ ṣàjọpín. Jíjẹun lórí tábìlì Jèhófà túmọ̀ sí pé àwọn tó ń jẹ níbẹ̀ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ife ìbùkún tí àwa ń súre sí, kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Ìṣù búrẹ́dì tí àwa ń bù, kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ara Kristi bí? Nítorí pé ìṣù búrẹ́dì kan ni ó wà, àwa, bí a tilẹ̀ pọ̀, jẹ́ ara kan, nítorí pé gbogbo wa ń ṣalábàápín ìṣù búrẹ́dì kan yẹn.”—1 Kọ́ríńtì 10:16, 17.
22. Àwọn ìbéèrè wo ló kù tá ó gbé yẹ̀ wò nípa Ìṣe Ìrántí?
22 Ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa nìkan ṣoṣo ni ohun ìrántí ọdọọdún táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe. Èyí bójú mu nítorí pé Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Nígbà Ìṣe Ìrántí, a máa ń ṣayẹyẹ ikú Jésù, ìyẹn ikú tó dá Jèhófà láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a ti kíyè sí, níbi oúnjẹ àjọjẹ yìí, búrẹ́dì náà dúró fún ara ènìyàn tí Kristi fi rúbọ, wáìnì náà sì dúró fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀. Síbẹ̀ ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà. Èé ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ Ìṣe Ìrántí náà nítumọ̀ gidi fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí kò jẹ nínú rẹ̀? Ní ti tòótọ́, kí ló yẹ kí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà túmọ̀ sí fún ọ?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Apá kejì, ojú ìwé 271, nínú ìwé Insight on the Scriptures, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Kí nìdí tí Jésù fi dá ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà sílẹ̀?
• Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí léraléra tó?
• Kí ni ìjẹ́pàtàkì búrẹ́dì aláìwú tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí?
• Kí ni wáìnì tá a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí dúró fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù dá ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀