-
Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun ỌIlé-Ìṣọ́nà—1993 | March 15
-
-
Eyi ti o tun tanmọlẹ sori ìṣèrántí iku Kristi ni awọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pe: “Nitori pe lọwọ Oluwa ni emi ti gba eyi ti mo sì ti fifun yin, pe Jesu Oluwa ni òru ọjọ naa ti a fi í hàn, ó mú àkàrà: nigba ti ó sì ti dupẹ, ó bù ú, ó sì wi pe, Gbà, jẹ: eyi [tumọsi, NW] ara mi ti a bù fun yin: ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi. Gẹgẹ bẹẹ ni ó sì mú ago, lẹhin ounjẹ, ó wi pe, Ago yii [tumọsi, NW] majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ̀ mi: nigbakugba ti ẹyin bá ń mu un, ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi. Nitori nigbakugba ti ẹyin bá ń jẹ àkàrà yii, ti ẹyin bá sì ń mu ago yii, ẹyin ń kede ikú Oluwa titi yoo fi dé.”—1 Korinti 11:23-26.
-
-
Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun ỌIlé-Ìṣọ́nà—1993 | March 15
-
-
Bawo Ni Ṣíṣe É Ṣe Nilati Jẹ́ Nigbakugba Tó?
Ki ni awọn ọ̀rọ̀ Paulu pe: “Nigbakugba ti ẹyin bá ń jẹ àkàrà yii, ti ẹyin bá sì ń mu ago yii, ẹyin ń kede iku Oluwa titi yoo fi dé” tumọsi? Awọn Kristian oluṣotitọ ẹni-ami-ororo yoo jẹ ninu awọn ohun iṣapẹẹrẹ Iṣe-iranti “nigbakugba” titi ti wọn ó fi kú, ti a o sì jí wọn dide si ìyè ti ọrun lẹhin ìgbà naa. Niwaju Ọlọrun ati ayé, wọn yoo tipa bayii figba gbogbo polongo igbagbọ wọn ninu ẹbọ Jesu ti Jehofa pese. Yoo ti pẹ́ tó? “Titi yoo fi dé,” ni Paulu sọ, ti ó tumọ ni kedere si pe awọn ààtò àkíyèsí wọnyi yoo maa baa lọ titi di ìgbà dídé Jesu lati gba awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni-ami-ororo soke ọrun nipasẹ ajinde nigba “wiwanihin-in” rẹ̀. (1 Tessalonika 4:14-17, NW) Eyi wà ni ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ Kristi si awọn aposteli aduroṣinṣin 11 pe: “Bi mo bá sì lọ ípèsè ààyè silẹ fun yin, emi ó tún pada wá, emi ó sì mu yin lọ sọdọ emi tikaraami; pe nibi ti emi gbé wà, ki ẹyin lè wà nibẹ pẹlu.”—Johannu 14:3.
Iku Kristi ni a ha nilati ṣèrántí rẹ̀ lojoojumọ tabi boya lọsọọsẹ bi? Ó dara, Jesu dá Ounjẹ Alẹ́ Oluwa silẹ a sì pa á ni Ajọ-irekọja, eyi ti ó mú idande Israeli kuro ni oko-òǹdè Egipti wá sí iranti. Ni tootọ, oun ni a pè ni ‘Kristi irekọja wa’ nitori pe oun ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ti a fi rubọ fun awọn Kristian. (1 Korinti 5:7) Ajọ-irekoja ni a ń ṣe kìkì lẹẹkan lọdun, ni Nisan 14. (Eksodu 12:6, 14; Lefitiku 23:5) Eyi damọran pe iku Jesu ni a nilati ṣèrántí niwọn kan-naa ti a ń gba ṣe Ajọ-irekọja—lọdọọdun, kìí ṣe lojoojumọ tabi lọsọọsẹ.
Fun ọrundun melookan ọpọlọpọ awọn ti wọn jẹwọ jijẹ Kristian ṣèrántí iku Jesu lẹẹkan lọdun. Nitori pe wọn ṣe bẹẹ ni Nisan 14, awọn ni a pè ni Quartodecimans, ti o tumọsi “awọn ọlọjọ kẹrinla.” Nipa wọn, opitan J. L. von Mosheim kọwe pe: “Awọn Kristian Asia Kekere ni o ti mọ́ lara lati maa ṣe ayẹyẹ àsè mímọ́, ti ń ṣèrántí ìdásílẹ̀ ounjẹ-alẹ Oluwa, ati iku Jesu Kristi, ni akoko kan-naa nigba ti awọn Ju jẹ ọ̀dọ́-àgùtàn Irekọja wọn, iyẹn ni ní irọlẹ ọjọ kẹrinla oṣu kìn-ín-ní [Nisan]. . . . Wọn kà á si pe apẹẹrẹ Kristi ni awọn nilati tẹle gẹgẹ bi awọn yoo ti tẹle ofin.
-