ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34
Gbogbo Wa La Wúlò Nínú Ìjọ!
“Bí ara ṣe jẹ́ ọ̀kan àmọ́ tó ní ẹ̀yà púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà ara yẹn sì jẹ́ ara kan bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Kristi.”—1 KỌ́R. 12:12.
ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àǹfààní wo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní?
ÀǸFÀÀNÍ ńlá la ní pé a wà nínú ètò Jèhófà. Inú Párádísè tẹ̀mí la wà yìí, láàárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà, tí wọ́n sì ń láyọ̀. Àmọ́ ìbéèrè kan ni pé, ṣé gbogbo wa la wúlò nínú ìjọ Ọlọ́run?
2. Àpèjúwe wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò nínú àwọn lẹ́tà kan tó kọ?
2 A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú àpèjúwe kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò nínú àwọn lẹ́tà kan tó kọ. Nínú àwọn lẹ́tà yìí, Pọ́ọ̀lù fi ìjọ wé ara èèyàn. Bákan náà, ó fi àwọn tó wà nínú ìjọ wé ẹ̀yà ara.—Róòmù 12:4-8; 1 Kọ́r. 12:12-27; Éfé. 4:16.
3. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́ta wo la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́ta kan tá a rí kọ́ látinú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò. Àkọ́kọ́, a máa rí i pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló wúlò nínú ètò Ọlọ́run, oníkálukú ló sì ní àyè tiẹ̀.b Ìkejì, a máa jíròrò ohun tá a lè ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò wúlò nínú ìjọ. Ìkẹta, a máa jíròrò ìdí tó fi yẹ kí ọwọ́ wa dí bí oníkálukú wa ti ń ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìjọ.
GBOGBO WA LA NÍ OJÚṢE NÍNÚ ÌJỌ ỌLỌ́RUN
4. Kókó wo ló ṣe kedere nínú Róòmù 12:4, 5?
4 Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ tá a rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò ni pé gbogbo wa pátá la ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ Ọlọ́run. Ohun tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe náà ni pé: “Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ara ṣe wà nínú ara kan, àmọ́ tí gbogbo ẹ̀yà ara kì í ṣe iṣẹ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ ni àwa, bí a tiẹ̀ pọ̀, a jẹ́ ara kan ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a jẹ́ ẹ̀yà ara fún ẹnì kejì wa.” (Róòmù 12:4, 5) Kí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ gan-an? Kókó náà ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló ní ojúṣe tiẹ̀ nínú ìjọ, kò sì sí èyí tí kò ṣe pàtàkì nínú wọn.
5. Àwọn wo ni Bíbélì pè ní “ẹ̀bùn” nínú ìjọ?
5 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ní ojúṣe nínú ìjọ, ọkàn wa sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń múpò iwájú. (1 Tẹs. 5:12; Héb. 13:17) Òótọ́ nìyẹn, torí pé Jèhófà ti tipasẹ̀ Jésù fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” nínú ìjọ Rẹ̀. (Éfé. 4:8) Lára “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí ni àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run, àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ̀mí mímọ́ ló yan gbogbo àwọn arákùnrin yìí kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ sìn wọ́n.—1 Pét. 5:2, 3.
6. Bó ṣe wà nínú 1 Tẹsalóníkà 2:6-8, kí làwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí máa ń sapá láti ṣe?
6 Ojúṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ní. Bí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara míì ṣe máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ara, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn arákùnrin tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kí gbogbo ìjọ lè jàǹfààní. Wọn kì í wá ògo fún ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa gbé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ró, kí ìjọ sì wà níṣọ̀kan. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:6-8.) A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún wa láwọn arákùnrin tó ń fi ara wọn jìn fún wa yìí!
7. Ìbùkún wo làwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún máa ń ní?
7 Àwọn míì tó tún ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ ni àwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kódà, kárí ayé làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí ti ń fi gbogbo ayé wọn ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Èyí sì ti mú kí wọ́n sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba nǹkan tara làwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yìí máa ń ní, Jèhófà ń bù kún wọn lọ́pọ̀ jaburata. (Máàkù 10:29, 30) A mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí, a sì dúpẹ́ pé wọ́n wà pẹ̀lú wa nínú ìjọ!
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo akéde tó ń wàásù ìhìn rere ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà?
8 Ṣé àwọn tó ń múpò iwájú àtàwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìkan ló ní ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ? Rárá! Ìdí ni pé gbogbo akéde tó ń wàásù ìhìn rere ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà. (Róòmù 10:15; 1 Kọ́r. 3:6-9) Kódà, ọ̀kan lára iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù nínú ìjọ ni pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; 1 Tím. 2:4) Torí náà, gbogbo akéde tó wà nínú ìjọ ló ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ yìí, yálà wọ́n ti ṣèrìbọmi tàbí wọn ò tíì ṣe bẹ́ẹ̀.—Mát. 24:14.
9. Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn arábìnrin wa?
9 Jèhófà mọyì àwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ gan-an, iṣẹ́ pàtàkì ló sì gbé fún wọn. Ó mọyì gbogbo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sin òun yálà wọ́n jẹ́ ìyàwó ilé, ìyá, opó tàbí àwọn tí kò tíì lọ́kọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì mẹ́nu ba àwọn obìnrin kan tó múnú Jèhófà dùn. Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn dáadáa torí pé wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n nítara, wọ́n nígboyà, wọ́n lawọ́, wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere. (Lúùkù 8:2, 3; Ìṣe 16:14, 15; Róòmù 16:3, 6; Fílí. 4:3; Héb. 11:11, 31, 35) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún wa láwọn arábìnrin tó láwọn ànímọ́ yìí nínú ìjọ!
10. Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa?
10 Inú wa dùn pé a ní àwọn àgbàlagbà láàárín wa. Àwọn ìjọ kan ní àwọn àgbàlagbà tó ti wà nínú ètò Jèhófà tipẹ́tipẹ́. Àwọn àgbàlagbà míì sì wà tó jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú òtítọ́ ni. Èyí ó wù ó jẹ́, wọ́n lè ní àwọn àìlera kan tí wọ́n ń bá yí, ìyẹn sì lè mú kó nira fún wọn láti ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń lo gbogbo okun wọn láti fún àwọn míì níṣìírí, kí wọ́n sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní ń ṣe wá láǹfààní. Inú Jèhófà ń dùn sí wọn gan-an, àwa náà sì mọyì wọn.—Òwe 16:31.
11-12. Kí làwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ yín ń ṣe tó wú ẹ lórí?
11 Àwọn míì tó tún wà nínú ìjọ ni àwọn ọ̀dọ́. Inú ayé tí Sátánì ń darí tó sì kún fún èrò àti ìwà tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń gbé, síbẹ̀ wọn ò jẹ́ kó kéèràn ràn wọ́n. (1 Jòh. 5:19) Ó máa ń wú wa lórí gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ọ̀dọ́ yìí ń dáhùn nípàdé, tí wọ́n ń lọ sóde ẹ̀rí, tí wọ́n sì ń fìgboyà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ wúlò nínú ìjọ, a sì mọyì yín gan-an!—Sm. 8:2.
12 Síbẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń ronú pé àwọn ò wúlò, àwọn ò sì já mọ́ nǹkan kan nínú ìjọ. Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lójú pé a wúlò nínú ìjọ? Ẹ jẹ́ ká jíròrò kókó yìí.
JẸ́ KÓ DÁ Ẹ LÓJÚ PÉ O WÚLÒ NÍNÚ ÌJỌ
13-14. Kí ló lè mú káwọn kan ronú pé àwọn ò wúlò nínú ìjọ?
13 Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ kejì tá a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò. Ó sọ ìṣòro kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ní lónìí. Ọ̀pọ̀ máa ń ronú pé àwọn ò wúlò nínú ìjọ rárá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí ẹsẹ̀ bá sọ pé, ‘Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,’ ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. Tí etí bá sì sọ pé, ‘Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,’ ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara.” (1 Kọ́r. 12:15, 16) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?
14 Tó o bá ń fi ara ẹ wé àwọn míì nínú ìjọ, o lè máa ronú pé o ò já mọ́ nǹkan kan. Òótọ́ ni pé àwọn kan lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa, àwọn míì lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan gan-an, káwọn míì sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ó ṣeé ṣe kó o ronú pé o ò lè ṣe bíi tiwọn láé. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, èyí fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, o sì mọ̀wọ̀n ara ẹ. (Fílí. 2:3) Àmọ́, ó tún yẹ kó o kíyè sára. Tó o bá ń fi ara ẹ wé àwọn míì nígbà gbogbo, inú ẹ ò ní dùn. Kódà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò wúlò nínú ìjọ rárá bó ṣe wà nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò. Kí lá jẹ́ kó o borí irú èrò bẹ́ẹ̀?
15. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 12:4-11, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní?
15 Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Jèhófà fún àwọn mélòó kan lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní àwọn ẹ̀bùn kan, àmọ́ kì í ṣe ẹ̀bùn kan náà ló fún gbogbo wọn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 12:4-11.) Ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ohun tí wọ́n lè ṣe sì yàtọ̀ síra, síbẹ̀ kò sí èyí tí kò wúlò. Lónìí, àwa ò ní irú àwọn ẹ̀bùn àgbàyanu bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìlànà ibẹ̀ ni pé bí ẹ̀bùn tá a ní bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra, gbogbo wa pátá la wúlò fún Jèhófà.
16. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá?
16 Dípò ká máa fi ara wa wé àwọn míì, ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá sílò pé: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”—Gál. 6:4.
17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò?
17 Tá a bá fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, tá a sì ń kíyè sí àwọn ohun tá a lè ṣe, àá rí i pé àwa náà ní ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, alàgbà kan lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ lórí pèpéle, àmọ́ kó mọ béèyàn ṣe ń wàásù dáadáa kó sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ bá a ṣe ń ṣètò nǹkan bíi tàwọn alàgbà míì, àmọ́ ó máa ń yá àwọn akéde lára láti lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé ìmọ̀ràn Bíbélì ló máa fún àwọn. Ó sì lè jẹ́ ẹni táwọn èèyàn mọ̀ pé ó máa ń ṣàlejò gan-an. (Héb. 13:2, 16) Tá a bá mọyì ẹ̀bùn tá a ní àtohun tá a lè ṣe, ọkàn wa á balẹ̀ pé àwa náà wúlò nínú ìjọ. A ò sì ní máa jowú àwọn ará tó lẹ́bùn táwa ò ní.
18. Báwo la ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú àwọn ohun tá a lè ṣe?
18 Ẹ̀bùn yòówù ká ní tàbí ohun yòówù ká lè ṣe, gbogbo wa ló yẹ ká máa sapá láti sunwọ̀n sí i. Ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń gba àwọn ìtọ́ni àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé tá à ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ èyí táá jẹ́ ká sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé ò ń fi àwọn ìtọ́ni yìí sílò nínú gbogbo apá tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí?
19. Kí lo lè ṣe kó o bàa lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run?
19 Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀ míì tí Jèhófà ṣètò ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó lè lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sí márùnlélọ́gọ́ta (65). Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé irú ẹ kọ́ ni wọ́n ń wá nílé ẹ̀kọ́ náà. Dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn ìdí tí o ò fi ní lè lọ, ṣe ni kó o ronú nípa àwọn ìdí tó fi yẹ kó o lọ. Lẹ́yìn náà, ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o kúnjú ìwọ̀n láti lọ. Tó o bá sapá, tó o sì bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, wẹ́rẹ́ lọwọ́ ẹ á tẹ ohun tó o rò pé o ò ní lè ṣe láé.
LO Ẹ̀BÙN RẸ LÁTI FI GBÉ ÌJỌ RÓ
20. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó wà ní Róòmù 12:6-8?
20 Ẹ̀kọ́ kẹta tá a rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò wà nínú Róòmù 12:6-8. (Kà á.) Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ní. Àmọ́ ní báyìí, ó gbà wá níyànjú pé ká lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tá a ní láti gbé ìjọ ró, ká sì fún àwọn ará lókun.
21-22. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Arákùnrin Robert àti Arákùnrin Felice?
21 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Robert.c Lẹ́yìn tó ti sìn ní ilẹ̀ òkèèrè, ètò Ọlọ́run ní kó máa lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Lóòótọ́ léraléra ni wọ́n fi dá a lójú pé kì í ṣe torí pé kò ṣe dáadáa tó ni wọ́n fi dá a pa dà, síbẹ̀ ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni mo fi ń ronú pé bóyá torí pé mo ṣe nǹkan kan ni wọ́n fi dá mi pa dà, ó sì ń ṣe mí bíi pé mo ti kùnà. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ń ṣe mí bíi pé kí n fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀.” Kí ló mú kó pa dà máa láyọ̀? Alàgbà kan rán an létí pé ṣe ni Jèhófà máa ń fi àwọn iṣẹ́ tá a ṣe sẹ́yìn dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ kúnjú ìwọ̀n fún èyí tá à ń ṣe lọ́wọ́. Arákùnrin Robert wá rí i pé kò yẹ kóun tún máa wakọ̀ sẹ́yìn mọ́, àfi kóun máa tẹ̀ síwájú, kóun sì gbájú mọ́ ohun tóun ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́.
22 Irú ìṣòro yìí náà ni Arákùnrin Felice Episcopo kojú. Ọdún 1956 lòun àtìyàwó ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì, wọ́n sì ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Nígbà tó dọdún 1964, wọ́n bímọ. Arákùnrin Felice sọ pé: “Ìpèníjà ńlá ni torí òun ló jẹ́ ká fi iṣẹ́ àyànfúnni tá a kà sóhun iyebíye sílẹ̀. Kí n sòótọ́, nǹkan bí ọdún kan ni mo fi káàánú ara mi. Àfìgbà tí mo rí i pé èrò tí mo ní kò tọ́, àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo sọ pé, o jẹ́ yá gbé ìyẹn kúrò lọ́kàn, bá ò kú ìṣe ò tán.” Ṣé ó ti ṣe ẹ́ bíi ti Robert àti Felice rí? Ṣé inú ẹ kì í dùn torí pé o ò láǹfààní láti ṣe ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o yí èrò ẹ pa dà, kó o sì pọkàn pọ̀ sórí ohun tó o lè ṣe báyìí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà dípò tí wàá fi máa wakọ̀ sẹ́yìn. Jẹ́ kọ́wọ́ rẹ dí bó o ṣe ń lo ẹ̀bùn àti okun rẹ láti ran àwọn míì lọ́wọ́, tó o sì ń fún ìjọ lókun. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀.
23. Kí ló yẹ ká ṣe, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
23 Gbogbo wa la ṣeyebíye lójú Jèhófà. Inú ẹ̀ máa ń dùn pé a wà lára ìdílé òun. Tá a bá fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a lè ṣe ká lè gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ró, tá a sì ń sapá gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa ronú pé a ò wúlò nínú ìjọ. Àmọ́ ojú wo la fi ń wo àwọn míì nínú ìjọ? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì wọn? Kókó pàtàkì yìí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà
a Gbogbo wa la fẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé a ṣeyebíye lójú ẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò wúlò fún un. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé gbogbo wa pátá la wúlò nínú ìjọ.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Oníkálukú wa ló ní àyè tàbí ojúṣe tiẹ̀ tó bá di pé ká gbé ìjọ ró, kó sì wà níṣọ̀kan. Kì í ṣe ibi téèyàn ti wá, ẹ̀yà rẹ̀, bó ṣe lówó lọ́wọ́ tó, bó ṣe kàwé tó, bó ṣe gbayì tó tàbí àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀ ló ń pinnu ojúṣe téèyàn ní nínú ìjọ.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà
d ÀWÒRÁN: Fọ́tò mẹ́ta yìí jẹ́ ká rí ohun táwọn ará ṣe kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ àti lẹ́yìn tó parí. Àwòrán 1: Alàgbà kan ń kí ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé, arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń ṣètò makirofóònù tí wọ́n máa lò nípàdé, arábìnrin kan sì ń bá arábìnrin àgbàlagbà kan sọ̀rọ̀. Àwòrán 2: Àwọn ará lọ́mọdé àti lágbà ń nawọ́ kí wọ́n lè dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àwòrán 3: Tọkọtaya kan ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. Ìyá kan mú ọmọ ẹ̀ lọ sídìí àpótí kó lè fowó sínú ẹ̀. Arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń bójú tó ìwé, arákùnrin kan sì ń fún arábìnrin àgbàlagbà kan níṣìírí.