-
‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’Ilé Ìṣọ́—2001 | November 1
-
-
“Ìfẹ́ A Máa Ní Ìpamọ́ra”
9. Kí nìdí tó lè mú kí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra”?
9 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìbátan àrà ọ̀tọ̀ kan wà láàárín ìfẹ́ àti ìpamọ́ra nígbà tó sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Albert Barnes sọ pé Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ èyí nítorí asọ̀ àti gbọ́nmi-si omi-ò-to tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 1:11, 12) Barnes là á mọ́lẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ tá a lò níhìn-ín [fún ìpamọ́ra] jẹ́ òdì kejì ṣíṣe nǹkan wàdùwàdù: ó jẹ́ òdì kejì ọ̀rọ̀ àti èrò ìbínú, àti ìkanra. Ó ń tọ́ka sí ọkàn tó lè RÍ ARA GBA NǸKAN FÚN ÌGBÀ PÍPẸ́ nígbà tí wọ́n bá ni ín lára, tí wọ́n bá sì mú un bínú.” Ìfẹ́ àti ìpamọ́ra tún ń fi kún àlàáfíà ìjọ Kristẹni lọ́nà tó ga.
10. (a) Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ gbà ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onípamọ́ra, ìmọ̀ràn wo sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nínú ọ̀ràn yìí? (b) Ọ̀rọ̀ wo ni ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ nípa ìpamọ́ra àti inú rere Ọlọ́run? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìfẹ́ ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onípamọ́ra.a (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ìfẹ́ ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa mú sùúrù fún ara wa ká sì máa rántí pé gbogbo wa ni aláìpé tá a ní àwọn àléébù àti kùdìẹ̀-kudiẹ. Ó dáa ká máa gba tẹni rò, ká sì máa dárí jini. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti máa rìn ‘pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ pátápátá ti èrò inú àti ìwà tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí a máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.’—Éfésù 4:1-3.
-
-
‘Ẹ Fi Ìpamọ́ra Wọ Ara Yín Láṣọ’Ilé Ìṣọ́—2001 | November 1
-
-
a Nígbà tí Gordon D. Fee tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń sọ èrò tirẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere,” ó kọ̀wé pé: “Nínú ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù, [ìpamọ́ra àti inú rere] jẹ́ ìhà méjèèjì tí Ọlọ́run kọ sí ìran ènìyàn (Róòmù 2:4). Ní apá kan, ìfaradà onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní ló jẹ́ kó fawọ́ ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹ̀dá sẹ́yìn; ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, inú rere rẹ̀ fara hàn nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀nà tó gbà ń fi àánú rẹ̀ hàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àpèjúwe ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe méjì yìí tó ṣe nípa Ọlọ́run, ẹni tó tipasẹ̀ Kristi fi hàn pé òun jẹ́ onísùúrù àti onínúure sí àwọn tí ìdájọ́ rẹ̀ tọ́ sí.”
-