ORÍ KẸTA
Kọ́kọ́rọ́ Méjì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí
1, 2. (a) Báwo ni a ṣe pète kí ìgbéyàwó wà pẹ́ tó? (b) Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe?
NÍGBÀ tí Ọlọrun so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ nínú ìgbéyàwó, kò sí àmì tí ó fi hàn pé ìsopọ̀ náà yóò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. A pète pé kí Adamu àti Efa wà pọ̀ títí gbére. (Genesisi 2:24) Ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun fún ìgbéyàwó tí ó ní ọlá jẹ́ ìsopọ̀ ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Kìkì ìwà pálapàla bíburú jáì tí ọ̀kan tàbí àwọn méjèèjì lọ́wọ́ sí nìkan ni ó pèsè ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn.—Matteu 5:32.
2 Ó ha ṣeé ṣe fún ẹni méjì láti gbé pọ̀ tayọ̀tayọ̀ títí gbére bí? Bẹ́ẹ̀ ni, Bibeli sì fi kókó, tàbí kọ́kọ́rọ́, pàtàkì méjì tí ń ṣèrànwọ́ láti mú kí èyí ṣeé ṣe hàn. Bí ọkọ àti aya bá lo àwọn wọ̀nyí, wọn yóò ṣílẹ̀kùn ayọ̀ àti ọ̀pọ̀ ìbùkún. Kí ni àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyí?
KỌ́KỌ́RỌ́ ÀKỌ́KỌ́
3. Oríṣi ìfẹ́ mẹ́ta wo ni ó yẹ kí tọkọtaya mú dàgbà?
3 Ìfẹ́ ni kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́. Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, Bibeli fi hàn pé onírúurú ìfẹ́ ni ó wà. Ìfẹ́ni tímọ́tímọ́, ọlọ́yàyà, tí a ní fún ẹnì kan, irú ìfẹ́ tí ń wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, jẹ́ ọ̀kan. (Johannu 11:3) Ìfẹ́ tí ń gbèrú láàárín àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tún jẹ́ òmíràn. (Romu 12:10) Ìkẹta ni òòfà ìfẹ́ tí ẹnì kan lè ní fún mẹ́ḿbà ẹ̀yà kejì. (Owe 5:15-20) Dájúdájú, ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ mú gbogbo ìwọ̀nyí dàgbà. Ṣùgbọ́n, oríṣi ìfẹ́ kẹrin wà, tí ó ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ.
4. Kí ni oríṣi ìfẹ́ kẹrin?
4 Nínú èdè ìpìlẹ̀ tí a fi kọ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì, a·gaʹpe ni ọ̀rọ̀ tí a lò fún oríṣi ìfẹ́ kẹrin yìí. A lo ọ̀rọ̀ náà nínú 1 Johannu 4:8, níbi tí a ti sọ fún wa pé: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.” Ní tòótọ́, “awa nífẹ̀ẹ́, nitori [Ọlọrun] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Johannu 4:19) Kristian kan kọ́kọ́ ń mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà fún Jehofa Ọlọrun àti lẹ́yìn náà, fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. (Marku 12:29-31) A tún lo ọ̀rọ̀ náà, a·gaʹpe, nínú Efesu 5:2, tí ó sọ pé: “Ẹ . . . máa bá a lọ ní rírìn ninu ìfẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti nífẹ̀ẹ́ yín tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún yín.” Jesu sọ pé irú ìfẹ́ yìí ni a óò fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀: “Nipa èyí ni gbogbo ènìyàn yoo fi mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ [a·gaʹpe] láàárín ara yín.” (Johannu 13:35) Tún kíyè sí bí a ṣe lo a·gaʹpe nínú 1 Korinti 13:13 pé: “Awọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, awọn mẹ́ta wọnyi; ṣugbọn èyí tí ó tóbi jùlọ ninu iwọnyi ni ìfẹ́ [a·gaʹpe].”
5, 6. (a) Èé ṣe tí ìfẹ́ fi tóbi ju ìgbàgbọ́ àti ìrètí lọ? (b) Kí ni àwọn ìdí díẹ̀ tí ìfẹ́ yóò fi ṣèrànwọ́ láti mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí?
5 Kí ló mú kí ìfẹ́ a·gaʹpe yìí tóbi ju ìgbàgbọ́ àti ìrètí lọ? Àwọn ìlànà—àwọn ìlànà títọ́—tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ní ń ṣàkóso rẹ̀. (Orin Dafidi 119:105) Ó jẹ́ àníyàn aláìmọtara-ẹni-nìkan fún ṣíṣe ohun tí ó tọ́, tí ó sì dára lójú Ọlọrun, fún àwọn ẹlòmíràn, bóyá lójú wa, ẹni tí a ń ṣe é fún tọ́ sí i tàbí kò tọ́ sí i. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ń mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn tọkọtaya láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli náà: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti dáríjì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹlu máa ṣe.” (Kolosse 3:13) Àwọn tọkọtaya onífẹ̀ẹ́ ní “ìfẹ́ [a·gaʹpe] gbígbóná janjan fún [ara wọn],” wọ́n sì ń mú un dàgbà, “nitori ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Peteru 4:8) Kíyè sí i pé, ìfẹ́ ń bo àwọn àṣìṣe mọ́lẹ̀. Kì í mú wọn kúrò, níwọ̀n bí kò ti sí ènìyàn aláìpé kankan tí ó lè bọ́ lọ́wọ́ àṣìṣe.—Orin Dafidi 130:3, 4; Jakọbu 3:2.
6 Nígbà tí tọkọtaya bá mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Ọlọrun àti fún ara wọn dàgbà, ìgbéyàwó wọn yóò wà pẹ́ títí, yóò sì láyọ̀, nítorí “ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Korinti 13:8) Ìfẹ́ jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kolosse 3:14) Bí o bá ti ṣègbéyàwó, báwo ni ìwọ àti alábàáṣègbéyàwó rẹ ṣe lè mú irú ìfẹ́ yìí dàgbà? Ẹ jọ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pa pọ̀, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ ìfẹ́ Jesu, kí o sì gbìyànjú láti fara wé e, láti ronú àti láti hùwà bíi tirẹ̀. Ní àfikún sí i, lọ sí àwọn ìpàdé Kristian, níbi tí a ti ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kọ́ni. Sì gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun láti mú irú ìfẹ́ gíga lọ́lá yìí, tí ó jẹ́ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, dàgbà.—Owe 3:5, 6; Johannu 17:3; Galatia 5:22; Heberu 10:24, 25.
KỌ́KỌ́RỌ́ KEJÌ
7. Kí ni ọ̀wọ̀, ta sì ni ó yẹ kí ó fi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìgbéyàwó?
7 Bí àwọn méjì tí ó fẹ́ra wọn bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn ní tòótọ́, nígbà náà, wọn yóò ní ọ̀wọ̀ fún ara wọn pẹ̀lú, ọ̀wọ̀ sì ni kọ́kọ́rọ́ kejì sí ìgbéyàwó aláyọ̀. A túmọ̀ ọ̀wọ̀ sí “gbígba ti àwọn ẹlòmíràn rò, bíbọlá fún wọn.” Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gba gbogbo Kristian, títí kan ọkọ àti aya, nímọ̀ràn pé: “Ninu bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nìkínní kejì ẹ mú ipò iwájú.” (Romu 12:10) Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní bíbá [awọn aya yín] gbé ní irú-ọ̀nà kan naa ní ìbámu pẹlu ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun-ìlò aláìlerató, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” (1 Peteru 3:7) A gba aya nímọ̀ràn láti “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Efesu 5:33) Bí o bá fẹ́ẹ́ bọlá fún ẹnì kan, ìwọ yóò fi inú rere hàn sí ẹni náà, ìwọ yóò fi ọ̀wọ̀ hàn fún iyì ẹni náà àti ojú ìwòye rẹ̀, ìwọ yóò sì múra tán láti ṣe ohunkóhun tí ó bọ́gbọ́n mu tí ó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ.
8-10. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni ọ̀wọ̀ yóò gbà ṣèrànwọ́ láti fìdí ìdè ìgbéyàwó múlẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláyọ̀?
8 Àwọn tí wọ́n fẹ́ láti gbádùn ìgbéyàwó aláyọ̀ ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún alábàáṣègbéyàwó wọn nípa ṣíṣàìmáa “mójútó ire ara-ẹni ninu kìkì awọn ọ̀ràn ti ara [wọn] nìkan, ṣugbọn ire ara-ẹni ti awọn [alábàáṣègbéyàwó wọn] pẹlu.” (Filippi 2:4) Wọn kì í ronú nípa ohun tí ó dára fún ara wọn nìkan—èyí tí yóò já sí ìmọtara-ẹni-nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ronú nípa ohun tí ó dára jù lọ fún alábàáṣègbéyàwó wọn pẹ̀lú. Ní ti gidi, ìyẹn ló jẹ wọ́n lógún jù lọ.
9 Ọ̀wọ̀ yóò ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye yíyàtọ̀ síra tí wọ́n ní. Kò bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí àwọn ẹni méjì ní ojú ìwòye kan náà nínú ohun gbogbo. Ohun tí ó lè ṣe pàtàkì sí ọkọ lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì sí aya, ó sì lè máà jẹ́ ohun tí aya fẹ́ràn ni ọkọ fẹ́ràn. Ṣùgbọ́n, ẹnì kíní ní láti bọ̀wọ̀ fún ojú ìwòye àti yíyàn ẹnì kejì, níwọ̀n bí ìwọ̀nyí kò bá ti ré àwọn òfin àti ìlànà Jehofa kọjá. (1 Peteru 2:16; fi wé Filemoni 14.) Síwájú sí i, ẹnì kíní ní láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún iyì ẹnì kejì nípa ṣíṣàìbẹ̀tẹ́ lù ú tàbí fi ṣẹ̀sín, bóyá ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀.
10 Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ fún Ọlọrun àti fún ẹnì kíní kejì àti ọ̀wọ̀ àjùmọ̀ní jẹ́ kọ́kọ́rọ́ ṣíṣe kókó méjì sí ìgbéyàwó aláṣeyọrí. Báwo ni a ṣe lè lò wọ́n nínú àwọn àgbègbè ṣíṣe pàtàkì jù kan nínú ìgbéyàwó?
IPÒ ORÍ BÍI TI KRISTI
11. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́, ta ni olórí nínú ìgbéyàwó?
11 Bibeli sọ fún wa pé, a dá ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ànímọ́ tí yóò mú kí ó jẹ́ olórí ìdílé aláṣeyọrí. Nítorí èyí, ọkùnrin yóò jíhìn fún Jehofa fún ire tẹ̀mí àti tara ti ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀. Òun yóò ní láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó wà déédéé, tí ó gbé ìfẹ́ inú Jehofa yọ, ó sì ní láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere ti ìṣe oníwà-bí-Ọlọrun. “Kí awọn aya wà ní ìtẹríba fún awọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Oluwa, nitori pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti jẹ́ orí ìjọ.” (Efesu 5:22, 23) Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli sọ pé ọkọ pẹ̀lú ní orí, Ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ lórí rẹ̀. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀ orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀ orí Kristi ni Ọlọrun.” (1 Korinti 11:3) Ọlọgbọ́n ọkọ ń kọ́ bí a ṣe ń lo ipò orí nípa fífara wé orí tirẹ̀ fúnra rẹ̀, Kristi Jesu.
12. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni Jesu fi lélẹ̀ nínú fífi ìtẹríba hàn àti lílo ipò orí?
12 Jesu pẹ̀lú ní orí, Jehofa, ó sì wà ní ìtẹríba fún Un lọ́nà yíyẹ. Jesu wí pé: “Kì í ṣe ìfẹ́-inú ara mi ni mo ń wá, bíkòṣe ìfẹ́-inú ẹni tí ó rán mi.” (Johannu 5:30) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá tí ó jẹ́! Jesu ni “àkọ́bí ninu gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kolosse 1:15) Ó di Messia náà. Òun yóò di Orí ìjọ àwọn Kristian ẹni àmì òróró àti Ọba tí a yàn fún Ìjọba Ọlọrun, lékè gbogbo áńgẹ́lì. (Filippi 2:9-11; Heberu 1:4) Láìka irú ipò gíga fíofío, àti ìfojúsọ́nà ńlá bẹ́ẹ̀ sí, ọkùnrin náà, Jesu, kò le koko, kì í ṣe olórí kunkun, tàbí ẹni tí ń retí ìpé pérépéré lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Òun kì í ṣe òṣìkà olùṣàkóso, tí ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ létí léraléra pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí òun. Jesu jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú, ní pàtàkì sí àwọn tí a ń ni lára. Ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nitori onínú tútù ati ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni emi, ẹ̀yin yoo sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nitori àjàgà mi jẹ́ ti inúrere ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Matteu 11:28-30) Ohun ayọ̀ ni láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
13, 14. Báwo ni ọkọ onífẹ̀ẹ́ yóò ṣe lo ipò orí rẹ̀, ní fífara wé Jesu?
13 Ọkọ tí ń fọkàn fẹ́ ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ ṣe dáradára láti gbé àwọn ànímọ́ àtàtà Jesu yẹ̀ wò. Ọkọ rere kì í le koko, kì í sì í pàṣẹ wàá, ní ṣíṣi ipò orí rẹ̀ lò, gẹ́gẹ́ bíi kùmọ̀ láti fi tẹ ìyàwó rẹ̀ lórí ba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń bu ọlá fún un. Bí Jesu bá jẹ́ “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà,” ọkọ ní ìdí púpọ̀ sí i láti jẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí, láìdà bíi Jesu, ó ń ṣàṣìṣe. Nígbà tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń fẹ́ ìdáríjì aya rẹ̀. Nítorí náà, onírẹ̀lẹ̀ ọkọ máa ń gba àṣìṣe rẹ̀, bí ọ̀rọ̀ náà, “Máà bínú; ìwọ lo jàre,” tilẹ̀ nira láti sọ. Yóò rọrùn púpọ̀ fún aya kan láti bọ̀wọ̀ fún ipò orí ọkọ amẹ̀tọ́mọ̀wà àti onírẹ̀lẹ̀ ju ti onígbèéraga àti alágídí lọ. Bí ó ti yẹ, aya tí ó lọ́wọ̀ lára pẹ̀lú ń tọrọ àforíjì nígbà tí ó bá ṣàṣìṣe.
14 Ọlọrun dá àwọn ànímọ́ àtàtà mọ́ obìnrin, tí ó lè lò ní dídá kún ìgbéyàwó aláyọ̀. Ọlọgbọ́n ọkọ kan yóò mọ èyí, òun kì yóò sì dá a lọ́wọ́ kọ́. Ọ̀pọ̀ obìnrin túbọ̀ ń fi ìyọ́nú àti ìmọ̀lára hàn, àwọn ànímọ́ tí a nílò nínú bíbójú tó ìdílé àti mímú ipò ìbátan ènìyàn dàgbà sí i. Obìnrin sábà máa ń ní ọgbọ́n ọnà sísọ ilé di ibi tí ó gbádùn mọ́ni láti gbé. “Obìnrin oníwà rere,” tí a ṣàpèjúwe nínú Owe orí 31, ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ àgbàyanu àti ẹ̀bùn àbínibí títayọ lọ́lá, ìdílé rẹ̀ sì jàǹfààní kíkún láti inú wọn. Èé ṣe? Nítorí pé àyà ọkọ rẹ̀ “gbẹ́kẹ̀ lé” e.—Owe 31:10, 11.
15. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bíi ti Kristi hàn sí aya rẹ̀?
15 Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, a gbé ọlá àṣẹ ọkọ ga ju bí ó ti yẹ lọ, débi pé a ka bíbi í ní ìbéèrè sí àìlọ́wọ̀. Ó lè bá aya rẹ̀ lò lọ́nà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ ti ẹrú. Irú lílo ipò orí ní ìlòkulò bẹ́ẹ̀ ń yọrí sí ipò ìbátan tí kò dára, kì í ṣe pẹ̀lú aya rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú Ọlọrun pàápàá. (Fi wé 1 Johannu 4:20, 21.) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn ọkọ kan ń kọ̀ láti mú ipò iwájú, ní yíyọ̀ǹda fún àwọn aya wọn láti jẹ gàba lórí agbo ilé. Ọkọ tí ó tẹrí ba fún Kristi lọ́nà yíyẹ kì í kó aya rẹ̀ nífà tàbí dù ú ní iyì tí ó tọ́ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fara wé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ Jesu, ó sì ń ṣe bí Paulu ti gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ awọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Efesu 5:25) Kristi Jesu nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi kú fún wọn. Ọkọ rere kan yóò gbìyànjú láti fara wé ìwà àìmọtara-ẹni-nìkan yẹn, ní wíwá ire aya rẹ̀, dípò bíbèèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ ṣáá. Nígbà tí ọkọ kan bá tẹrí ba fún Kristi, tí ó sì fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bíi ti Kristi hàn, a óò sún aya rẹ̀ láti tẹrí ba fún un.—Efesu 5:28, 29, 33.
ÌTẸRÍBA AYA
16. Àwọn ànímọ́ wo ni ó yẹ kí aya kan fi hàn nínú ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀?
16 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí a ti ṣẹ̀dá Adamu, “Jehofa Ọlọrun ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa dá nìkan gbé. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’” (Genesisi 2:18, NW) Ọlọrun dá Efa gẹ́gẹ́ bí “àṣekún,” kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí abánidíje kan. A kò pète ìgbéyàwó láti dà bí ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ní àwọn ọ̀gá méjì, tí ń bára díje. Ọkọ ní láti lo ipò orí onífẹ̀ẹ́, aya sì ní láti fi ìfẹ́, ọ̀wọ̀, àti ìtẹríba àtọkànwá hàn.
17, 18. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni aya lè gbà jẹ́ olùrànlọ́wọ́ gidi fún ọkọ rẹ̀?
17 Ṣùgbọ́n, aya rere ń ṣe ju wíwulẹ̀ tẹrí ba lọ. Ó ń gbìyànjú láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ gidi, ní títi ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn nínú àwọn ìpinnu tí ó ń ṣe. Dájúdájú, èyí máa ń rọrùn fún un láti ṣe nígbà tí ó bá fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ìpinnu ọkọ rẹ̀. Àní nígbà tí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ìpinnu ọkọ rẹ̀ túbọ̀ yọrí sí rere.
18 Aya lè ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti jẹ́ orí rere ní àwọn ọ̀nà míràn. Ó lè sọ ìmọrírì rẹ̀ jáde fún àwọn ìsapá ọkọ rẹ̀ ní mímú ipò iwájú, dípò ṣíṣe lámèyítọ́ rẹ̀ tàbí mímú kí ó ronú pé kò lè tẹ́ ìfẹ́ ọkàn òun lọ́rùn rárá. Ní bíbá ọkọ rẹ̀ lò lọ́nà rere, ó yẹ kí ó rántí pé, “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ati ti ìwàtútù . . . ní ìníyelórí ńláǹlà ní ojú Ọlọrun,” kì í ṣe ní ojú ọkọ rẹ̀ nìkan. (1 Peteru 3:3, 4; Kolosse 3:12) Bí ọkọ náà kì í bá ṣe onígbàgbọ́ ńkọ́? Bóyá ó jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí kì í ṣe onígbàgbọ́, Ìwé Mímọ́ rọ àwọn aya “lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọkọ wọn, lati nífẹ̀ẹ́ awọn ọmọ wọn, lati jẹ́ ẹni tí ó yèkooro ní èrò-inú, oníwàmímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé, ẹni rere, tí ń fi ara wọn sábẹ́ awọn ọkọ tiwọn, kí ọ̀rọ̀ Ọlọrun má baà di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.” (Titu 2:4, 5) Bí ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn bá jẹ yọ, ó ṣeé ṣe kí aláìgbàgbọ́ ọkọ kan fi ọ̀wọ̀ hàn fún ipò tí aya rẹ̀ dì mú, bí ó bá gbé e kalẹ̀ pẹ̀lú “inú tútù ati ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” A ti jèrè àwọn aláìgbàgbọ́ ọkọ kan “láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà awọn aya wọn, nitori jíjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà mímọ́ [wọn] papọ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Peteru 3:1, 2, 15; 1 Korinti 7:13-16.
19. Bí ọkọ kan bá ní kí aya rẹ̀ rú òfin Ọlọrun ńkọ́?
19 Bí ọkọ kan bá ní kí aya rẹ̀ ṣe ohun tí Ọlọrun kà léèwọ̀ ńkọ́? Bí ìyẹ́n bá ṣẹlẹ̀, obìnrin náà ní láti rántí pé Ọlọrun ni Alákòóso rẹ̀ gíga jù lọ. Òun yóò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ohun tí àwọn aposteli ṣe, nígbà tí àwọn aláṣẹ ní kí wọ́n rú òfin Ọlọrun. Ìṣe 5:29 ròyìn pé: “Peteru ati awọn aposteli yòókù wí pé: ‘Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.’”
ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀PỌ̀ DÍDÁN MỌ́RÁN
20. Àgbègbè pàtàkì wo ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ti ṣe kókó?
20 Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tún ṣe kókó ní àgbègbè míràn nínú ìgbéyàwó—ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Ọkọ onífẹ̀ẹ́ yóò jíròrò ìgbòkègbodò, àwọn ìṣòro, àwọn ojú ìwòye ìyàwó rẹ̀ lórí onírúurú ọ̀ràn, pẹ̀lú rẹ̀. Obìnrin náà nílò èyí. Ọkọ tí ń wá àkókò láti bá ìyàwó rẹ̀ sọ̀rọ̀, tí ó sì ń tẹ́tí sílẹ̀ ní ti gidi sí ohun tí ìyàwó rẹ̀ ń sọ, ń fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí ó ní sí ìyàwó rẹ̀ hàn. (Jakọbu 1:19) Àwọn aya kan ṣàròyé pé àwọn ọkọ wọn kì í lo àkókò tí ó pọ̀ tó láti jíròrò pẹ̀lú wọn. Ìyẹ́n bani nínú jẹ́. Lóòótọ́, nínú ayé tí ọwọ́ há gádígádí yìí, ọkọ lè lo àkókò tí ó pọ̀ níta, nídìí iṣẹ́, ìṣúnná owó sì lè mú kí àwọn aya kan wá iṣẹ́ síta pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n tọkọtaya gbọ́dọ̀ wá àkókò láti jọ wà pọ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n lè wà ní dáńfó gedegbe sí ara wọn. Ó lè yọrí sí ìṣòro ńlá, bí a bá sún wọn láti wá ìbákẹ́gbẹ́ abánikẹ́dùn sóde ètò ìgbéyàwó.
21. Báwo ni ọ̀rọ̀ yíyẹ yóò ṣe ṣàǹfààní láti mú kí ìgbéyàwó jẹ́ aláyọ̀?
21 Ọ̀nà tí ọkọ àti aya gbà ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ ṣe pàtàkì. “Ọ̀rọ̀ dídùn . . . dùn mọ́ ọkàn, ó sì ṣe ìlera fún egungun.” (Owe 16:24) Bóyá alábàáṣègbéyàwó ẹni jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí kì í ṣe onígbàgbọ́, a lè lo ìmọ̀ràn Bibeli náà: “Nígbà gbogbo ẹ jẹ́ kí gbólóhùn àsọjáde yín máa jẹ́ pẹlu oore-ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn,” ìyẹn ni pé, kí ó dùn mọ́ni létí. (Kolosse 4:6) Nígbà tí ọjọ́ kan bá nira fún ẹnì kan, ọ̀rọ̀ jẹ̀lẹ́ńkẹ́, abánikẹ́dùn, tí ó wá láti ẹnu alábàáṣègbéyàwó rẹ̀, lè mú nǹkan sunwọ̀n sí i. “Bí èso igi wúrà nínú agbọ̀n fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò rẹ̀.” (Owe 25:11) Ohùn tí a fi sọ̀rọ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò ṣe pàtàkì gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀nà tí ń múnú bíni, tí ń dún bí àṣẹ, ẹnì kan lè sọ fún ẹnì kejì pé: “Tilẹ̀kùn yẹn!” Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ náà, “tí a fi iyọ̀ dùn,” tí a fi ohùn pẹ̀lẹ́, olóye sọ, “Jọ̀wọ́, ṣé o lè bá mi ti ilẹ̀kùn yẹn?” ti dùn tó!
22. Irú àwọn ìṣarasíhùwà wo ni tọkọtaya nílò láti lè pa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán mọ́?
22 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán máa ń gbèrú nígbà tí a bá rọra sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, tí a woni tìfẹ́tìfẹ́, tí a sì ṣàyẹ́sí ẹni, tí a fi inú rere, òye, àti jẹ̀lẹ́ńkẹ́ báni lo. Nípa ṣíṣiṣẹ́ kára láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán, ọkọ àti aya yóò lómìnira láti sọ àìní wọn jáde, wọ́n sì lè jẹ́ orísun ìtùnú àti ìrànwọ́ fún ara wọn nígbà ìjákulẹ̀ tàbí másùnmáwo. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọni láti “sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún awọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tessalonika 5:14) Àwọn àkókò yóò wà tí ọkọ yóò sorí kọ́, àwọn àkókò yóò sì wà tí aya yóò sorí kọ́. Wọ́n lè “sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún,” ní gbígbé ara wọn ró.—Romu 15:2.
23, 24. Báwo ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ yóò ṣe ṣèrànwọ́ nígbà tí àìfohùnṣọ̀kan bá wà? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.
23 Àwọn tọkọtaya tí ń fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn kì yóò rí gbogbo àìfohùnṣọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣòro ńlá kan. Wọn yóò ṣiṣẹ́ kára láti má ṣe “bínú” sí ara wọn “lọ́nà kíkorò.” (Kolosse 3:19) Àwọn méjèèjì ní láti rántí pé “ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà.” (Owe 15:1) Ṣọ́ra kí o má ṣe fojú tín-ínrín tàbí dẹ́bi fún alábàáṣègbéyàwó rẹ tí ó sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ka ìsọjáde náà sí àǹfààní kan láti lóye ojú ìwòye ẹnì kejì rẹ. Ẹ jùmọ̀ tiraka láti yanjú èdèkòyedè yín, kí ẹ sì jọ dórí ìpinnu tí ẹ fìmọ̀ ṣọ̀kan sí.
24 Rántí àkókò kan tí Sara dámọ̀ràn ojútùú sí ìṣòro kan báyìí fún ọkọ rẹ̀, Abrahamu, ṣùgbọ́n tí kò ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èrò ọkọ rẹ̀. Síbẹ̀, Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé: “Fetí sí ohùn rẹ̀.” (Genesisi 21:9-12) Abrahamu ṣe bẹ́ẹ̀, a sì bù kún un. Lọ́nà kan náà, bí aya bá dábàá ohun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọkọ rẹ̀ ní lọ́kàn, ó kéré tán, ọkọ náà gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀. Bákan náà, aya kò gbọdọ̀ jẹ gàba lórí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n, ó gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ohun tí ọkọ rẹ̀ ní láti sọ. (Owe 25:24) Fún ọkọ tàbí aya láti rin kinkin mọ́ ọ̀nà rẹ̀, ní gbogbo ìgbà, kò fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn.
25. Báwo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán yóò ṣe fi kún ayọ̀ nínú àwọn apá ṣíṣe tímọ́tímọ́ nínú ìgbéyàwó?
25 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ dídán mọ́rán tún ṣe pàtàkì nínú ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín tọkọtaya. Ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìlèkóra-ẹni-níjàánu lè ṣèpalára ńlá fún ipò ìbátan tímọ́tímọ́ jù lọ yìí nínú ìgbéyàwó. Àìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n-sọ àti sùúrù ṣe kókó. Nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá fi àìmọtara-ẹni-nìkan wá ire ẹnì kejì, ìbálòpọ̀ kì í sábà jẹ́ ìṣòro ńlá rárá. Nínú ọ̀ràn yìí, bí ó ti rí nínú àwọn ọ̀ràn míràn, “kí olúkúlùkù máṣe máa wá ire-àǹfààní ti ara rẹ̀, bíkòṣe ti ẹnìkejì.”—1 Korinti 7:3-5; 10:24.
26. Bí gbogbo ìgbéyàwó yóò tilẹ̀ ní dídùn àti kíkan tirẹ̀, báwo ni fífetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yóò ṣe ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti rí ayọ̀?
26 Ẹ wo irú ìmọ̀ràn àtàtà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnni! Ní tòótọ́, gbogbo ìgbéyàwó ni yóò ní dídùn àti kíkan tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí tọkọtaya bá tẹ́wọ́ gba ìrònú Jehofa, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣí i payá nínú Bibeli, tí wọ́n sì gbé ipò ìbátan wọn karí ìfẹ́ tí a gbé karí ìlànà àti ọ̀wọ̀, wọ́n lè ní ìdánilójú pé ìgbéyàwó wọn yóò láyọ̀, yóò sì wà pẹ́ títí. Nípa báyìí, kì í ṣe pé wọn yóò bu ọlá fún ara wọn nìkan ni, ṣùgbọ́n wọn yóò tún bu ọlá fún Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó, Jehofa Ọlọrun.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNA BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . TỌKỌTAYA KAN LÁTI GBÁDÙN ÌGBÉYÀWÓ ALÁYỌ̀, TÍ Ó WÀ PẸ́ TÍTÍ?
Àwọn Kristian tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn.—Johannu 13:35.
Àwọn Kristian máa ń ṣe tán láti dárí ji ara wọn.—Kolosse 3:13.
Ètò yíyẹ wà fún ipò orí.—1 Korinti 11:3.
Ó ṣe pàtàkì láti sọ ohun títọ́ ní ọ̀nà títọ́.—Owe 25:11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ àjùmọ̀ní ń ṣamọ̀nà sí ìgbéyàwó aláṣeyọrí