-
Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Ìjọba Ọlọ́run Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso!Ilé Ìṣọ́—2015 | November 15
-
-
2. Àwọn mélòó ló ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù pàṣẹ tó wà nínú Mátíù 28:19, 20, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
2 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ló fara han àwọn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ lára àwọn tó wá pa dà di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn náà ló pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n lọ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún “àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.” Iṣẹ́ tí kò rọrùn lèyí jẹ́ nígbà yẹn!a Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n á máa ṣe iṣẹ́ ribiribi náà nìṣó títí di “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára àwọn tó ń wàásù ìhìn rere tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ.—Mát. 28:19, 20.
-
-
Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Ìjọba Ọlọ́run Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso!Ilé Ìṣọ́—2015 | November 15
-
-
a Ẹ̀rí fi hàn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó wà níbẹ̀ di Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì ó pè wọ́n ní “ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: ‘Púpọ̀ jù lọ nínú wọn ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú.’ Torí náà, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mọ ọ̀pọ̀ lára àwọn tí Jésù pàṣẹ náà fún ní tààràtà.
-