O Lè Sin Jèhófà Kó o Má Sì Kábàámọ̀
“Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.”—FÍLÍ. 3:13.
1-3. (a) Kí ni àbámọ̀? Kí ló lè mú ká kábàámọ̀? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe tó sì kábàámọ̀, kí la lè rí kọ́ lára rẹ̀?
AKÉWÌ kan sọ pé: “Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ téèyàn lè kọ sílẹ̀ àti èyí téèyàn lè sọ jáde lẹ́nu, ọ̀rọ̀ àbámọ̀ ló máa ń dunni jù lọ.” Àpẹẹrẹ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, ‘Ká ní mo mọ̀ ni.’ Torí náà, àbámọ̀ ni ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń báni nítorí ohun kan tí a ṣe ṣùgbọ́n tí kò yẹ ká ṣe, tàbí èyí tí a kò ṣe àmọ́ tó yẹ ká ṣe. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì máa ń gba omi lójú èèyàn nígbà míì. Gbogbo wa la máa ń kábàámọ̀ tá a bá rántí àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe lọ́nà tó yàtọ̀ sí bá a ṣe ṣe wọ́n. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó ò ń kábàámọ̀ rẹ̀?
2 Àwọn kan ti ṣe àṣìṣe tó lágbára gan-an, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni wọ́n dá. Àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé kì í ṣe pé wọ́n ṣe ohun tó burú, àmọ́ wọ́n ń ṣiyè méjì bóyá àwọn ìpinnu kan tí wọ́n ṣe kò dára tó. Àwọn kan gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn kan ò lè mọ́kàn kúrò nínú àwọn ìpinnu tó kù díẹ̀ káàtó tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n kábàámọ̀ pé: “Ká ní mo mọ̀ ni, mi ò bá má ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀!” (Sm. 51:3) Ìwọ ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ láti máa sin Ọlọ́run ní báyìí kó o má sì kábàámọ̀? Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ sọ fún wa nípa ẹni kan tó sin Jèhófà tí kò sì jẹ́ kí àwọn àṣìṣe tí òun ti ṣe ba òun nínú jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni ẹni náà.
3 Pọ́ọ̀lù ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe, àmọ́ ó tún ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ó kábàámọ̀ gan-an nítorí àwọn àṣìṣe tó ṣe, síbẹ̀ ó ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ̀ ká lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ lára rẹ̀.
IRÚ ÌGBÉSÍ AYÉ TÍ PỌ́Ọ̀LÙ GBÉ KÓ TÓ DI KRISTẸNI
4. Irú ìgbésí ayé wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbé kó tó di Kristẹni?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fi jẹ́ Farisí, ó ṣe àwọn nǹkan tó kábàámọ̀ rẹ̀ nígbà tó yá. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lọ́nà rírorò. Bíbélì sọ pé gbàrà tí àwọn tó ń ṣenúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti pa Sítéfánù, “Sọ́ọ̀lù [tá a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá] bẹ̀rẹ̀ sí hùwà sí ìjọ lọ́nà bíburú jáì. Ó ń gbógun ti ilé kan tẹ̀ lé òmíràn àti pé, ní wíwọ́ àti ọkùnrin àti obìnrin jáde, òun a fi wọ́n sẹ́wọ̀n.” (Ìṣe 8:3) Gẹ́gẹ́ bí Albert Barnes tó jẹ́ onímọ̀ nípa Bíbélì ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí ‘hùwà sí lọ́nà bíburú jáì’ fi hàn pé ńṣe ni Sọ́ọ̀lù ń gbéjà ko ìjọ Kristẹni “bí ẹranko ẹhànnà.” Júù tó ní ìtara ni Sọ́ọ̀lù, ó sì ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ kí òun pa ẹ̀sìn Kristẹni run. Torí náà, ó ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni lọ́nà tó lékenkà. Ó ń fi ikú dẹ́rù bà wọ́n. Ó fẹ́ láti pa gbogbo wọn run “àti ọkùnrin àti obìnrin.”—Ìṣe 9:1, 2; 22:4.a
5. Kí ló mú kí Sọ́ọ̀lù dáwọ́ inúnibíni dúró tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Kristi?
5 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù lọ sí Damásíkù. Ìdí tó fi lọ síbẹ̀ ni pé, ó fẹ́ lọ máa wọ́ àwọn Kristẹni jáde kúrò nínú ilé wọn. Ó fẹ́ fà wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù níbi tí wọ́n á ti fìyà jẹ wọ́n ní ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. Àmọ́, ọ̀nà kò gba ibi tó fojú sí, torí pé Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Kristẹni ò gbà fún un. (Éfé. 5:23) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń lọ sí Damásíkù, Jésù fara hàn án. Ìmọ́lẹ̀ kan kọ mànà láti ọ̀run, ó sì fọ́ ọ lójú. Lẹ́yìn náà, Jésù ní kó lọ sí Damásíkù níbi tí wọ́n ti máa sọ ohun tó máa ṣe fún un. (Ìṣe 9:3-9) Ìwé Ìṣe 9:10-22 sọ apá tó kù nínú ìtàn náà.
6, 7. Kí ló fi hàn pé Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun tí ṣe àṣìṣe tó burú jáì?
6 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó rí i pé kò tọ́ kí òun máa ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Torí náà, ó dáwọ́ inúnibíni dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Nígbà tó yá, ó sọ pé: “Dájúdájú, ẹ gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ rí nínú Ìsìn Àwọn Júù, pé títí dé àyè tí ó pọ̀ lápọ̀jù ni mo ń ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run, tí mo sì ń pa á run.” (Gál. 1:13) Nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì àti Fílípì àti èyí tó kọ sí Tímótì, ó sọ àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:9; Fílí. 3:6; 1 Tím. 1:13) Kì í ṣe pé inú Pọ́ọ̀lù dùn pé òun ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, kò fẹ́ díbọ́n pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò wáyé rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó mọ̀ pé òun ti ṣe àwọn àṣìṣe tó burú jáì.—Ìṣe 26:9-11.
7 Onímọ̀ nípa Bíbélì kan tó ń jẹ́ Frederic W. Farrar sọ̀rọ̀ nípa inúnibíni tí Pọ́ọ̀lù ṣe sí àwọn Kristẹni. Ó ní tá a bá fara balẹ̀ ronú lórí bí inúnibíni tí Pọ́ọ̀lù ṣe sí àwọn Kristẹni ṣe pọ̀ tó, kò ní ṣòro fún wa láti gbà pé àwọn èèyàn ti ní láti dá a lẹ́bi nítorí irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó ti ní láti kábàámọ̀ gidigidi pé òun ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni. Kódà ó ṣeé ṣe ká rí àwọn ará kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rí i fún ìgbà àkọ́kọ́, nínú àwọn ìjọ tó bẹ̀ wò tí wọ́n máa sọ ọ́ kò ó lójú pé: ‘Áà, ìwọ ni Pọ́ọ̀lù. Ìwọ lò ń ṣe inúnibíni sí wa!’—Ìṣe 9:21.
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù mọyì àánú àti ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí i? Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù?
8 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn sí òun ló sọ òun di òjíṣẹ́ ìhìn rere. Torí náà, ó mẹ́nu kan inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà ju àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yòókù lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà àádọ́rùn-ún [90] tó mẹ́nu kàn án nínú ìwé mẹ́rìnlá tó kọ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:10.) Pọ́ọ̀lù mọyì àánú tí Ọlọ́run fi hàn sí i. Ó sì fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lórí rẹ̀ má bàa já sásán. Ìyẹn ló mú kó “ṣe òpò púpọ̀ ju” gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ. Kí la lè rí kọ́ nínú èyí? Tá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tá a jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a ronú pìwà dà, tá ò sì hùwà búburú mọ́, Jèhófà lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá jì wá. Tá a bá rò pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti burú ju èyí tí Ọlọ́run lè dárí rẹ̀ jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Ọlọ́run dárí ji Pọ́ọ̀lù. (Ka 1 Tímótì 1:15, 16.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ṣe inúnibíni sí Jésù, ó sọ pé ọmọ Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún òun. (Ìṣe 9:5; Gál. 2:20) Pọ́ọ̀lù ti wá mọ̀ pé tí òun kò bá fẹ́ máa kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó kù díẹ̀ káàtó tí òun ti ṣe sẹ́yìn, àfi kí òun máa sa gbogbo ipá òun lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ṣé ìwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?
ǸJẸ́ Ò Ń KÁBÀÁMỌ̀ NÍTORÍ OHUNKÓHUN?
9, 10. (a) Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan fi máa ń kábàámọ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi dára pé ká máa ṣàníyàn nípa àṣìṣe tá a ti ṣe kọjá?
9 Ṣé o ti ṣe àwọn nǹkan kan rí tó o wá ń kábàámọ̀ rẹ̀ báyìí? Ṣé o ti lo okun àti agbára rẹ gan-an lórí ohun kan kó o tó wá rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ló yẹ kó o fi àkókò rẹ ṣe? Ǹjẹ́ o ti ṣe ohun kan tó pa ẹlòmíì lára rí? Àbí ohun kan wà tó o ronú pé ọ̀tọ̀ nibi tó yẹ kó o gbé e gbà. Tó o bá rí èyí tó kàn ẹ́ nínú àwọn ìbéèrè yìí, kí lo lè ṣe nípa rẹ̀?
10 Àwọn kan máa ń ṣàníyàn ní gbogbo ìgbà. Wọ́n á máa ro àròkàn nípa àwọn àṣìṣe wọn, ìyẹn sì máa ń mú kí inú wọn bà jẹ́. Ǹjẹ́ àníyàn lè yanjú ìṣòro? Rárá o! Ńṣe ni àníyàn ṣíṣe dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń pọnmi sínú apẹ̀rẹ̀ ajádìí. Irú apẹ̀rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ò lè gbomi dúró débi tó máa kún. Torí náà, ńṣe ni onítọ̀hún ń lo okun rẹ̀ dà nù! Dípò tí wàá fi máa ṣàníyàn, ńṣe ni kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé ńṣe lo ṣẹ ẹnì kan, tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀, kó o sì gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà jọba. Ronú nípa ohun tó mú kó o ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí onítọ̀hún, kó o má bàa tún ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé ńṣe ni wàá máa bá àbájáde àṣìṣe rẹ yí. Àmọ́, tó o bá ń ṣàníyàn nípa àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe, ńṣe ni wàá máa dá kún ìṣòro rẹ. Ìyẹn sì lè pa iṣẹ́ ìsìn rẹ lára.
11. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa kó sì fi àánú hàn sí wa? (b) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá ò fi ní máa dára wa lẹ́bi nítorí àṣìṣe tá a ti ṣe?
11 Àwọn kan máa ń rò pé àṣìṣe táwọn ṣe ti burú débi pé Ọlọ́run ò lè fi àánú hàn sí àwọn mọ́. Wọ́n lè rò pé àṣìṣe àwọn ti burú jù tàbí kó jẹ́ pé àwọn ti ń ṣe àṣìṣe lemọ́lemọ́ jù. Àmọ́, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ẹ̀ṣẹ̀ yòówù kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dá, wọ́n lè ronú pìwà dà, kí wọ́n yí pa dà, kí wọ́n sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 3:19) Jèhófà ti fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí ọ̀pọ̀ àwọn tó ronú pìwà dà, ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn náà. Jèhófà máa dárí ji ẹni tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó jẹ́ olóòótọ́, tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Bí àpẹẹrẹ, Jóòbù sọ pé òun “ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.” (Jóòbù 42:6) Ó ronú pìwà dà ní ti pé ó kẹ́dùn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Látàrí ìyẹn, Ọlọ́run dárí jì í. Bí àwa náà bá dẹ́ṣẹ̀, kí ló yẹ ká ṣe tá ò fi ní máa dá ara wa lẹ́bi? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13; Ják. 5:14-16) Torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Ọlọ́run, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá, ká má sì dá irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́. (2 Kọ́r. 7:10, 11) Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà máa fi àánú hàn sí wa torí pé ó máa ń dárí jini lọ́pọ̀lọpọ̀.—Aísá. 55:7.
12. (a) Bí ẹ̀rí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì? (b) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà “kẹ́dùn”? (Wo àpótí.) Báwo ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ṣe ràn wá lọ́wọ́?
12 Àdúrà lágbára gan-an ni. Tá a bá gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́. Nínú Sáàmù kan tó fani mọ́ra, Dáfídì sọ bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà rẹ̀. (Ka Sáàmù 32:1-5.) Kí Dáfídì tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dà á láàmú gan-an ni. Ó ṣàníyàn, ó ṣàìsàn, ó sì sorí kọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Ọlọ́run, tí Ọlọ́run sì ti dárí jì í, ló tó rí ìtura. Jèhófà dáhùn àdúrà Dáfídì. Ó fún un lókun. Okun tó rí gbà mú kó máa bá a nìṣó láti máa ṣe ohun tó dára. Bákan náà, bí o bá ń dààmú nítorí àwọn àṣìṣe kan tó o ti ṣe, gba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà pé kó dárí jì ẹ́. Sapá gidigidi láti ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ti gbọ́ àdúrà rẹ, ó sì ti dárí jì ẹ́.—Sm. 86:5.
MÁA RONÚ NÍPA ỌJỌ́ IWÁJÚ
13, 14. (a) Kí lohun tó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe báyìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló lè mú ká ronú nípa ohun tá à ń ṣe ní báyìí?
13 Òótọ́ ni pé a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe wa, àmọ́ kò yẹ ká máa ro àròjù nípa wọn, torí pé àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ùndá. Dípò tí a ó fi máa ro àròkàn nípa àwọn àṣìṣe wa, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká máa ronú nípa ohun tí à ń ṣe báyìí àti ọjọ́ iwájú wa. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ohun kan wà tí mò ń ṣe báyìí tí mo lè kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣé mi ò ní máa ronú pé ọ̀tọ̀ ni ọ̀nà tí mi ò bá gbé nǹkan gbà? Ṣé mò ń sin Ọlọ́run lọ́nà tí mi ò fi ní máa kábàámọ̀ tó bá yá?
14 Ìpọ́njú ńlá ti sún mọ́lé gan-an báyìí. Ó bọ́gbọ́n mu kó o bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Ǹjẹ́ mo lè gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà? Kí ló fà á ti mi ò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ǹjẹ́ mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n lè gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀? Ṣé irú ẹni tí Jèhófà ń fẹ́ nínú ayé tuntun ni mí?’ Dípò tí wàá fi máa ṣàníyàn nípa ohun tó yẹ kó o ṣe àmọ́ tí o kò tíì ṣe, máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe báyìí. Kó o sì rí i dájú pé ò ń fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́. Àwọn ìpinnu tó ò ní kábàámọ̀ lọ́jọ́ iwájú ni kó o máa ṣe nísinsìnyí.—2 Tím. 2:15.
MÁ ṢE KÁBÀÁMỌ̀ PÉ Ò Ń ṢE IṢẸ́ ÌSÌN MÍMỌ́
15, 16. (a) Àwọn nǹkan wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti yááfì kí wọ́n lè fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́? (b) Bí a bá ti yááfì ohunkóhun nítorí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ kábàámọ̀?
15 Ṣé o ti yááfì àwọn nǹkan kan kó o lè máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Bóyá ńṣe lo tiẹ̀ fi iṣẹ́ olówó ńlá sílẹ̀ kó o lè máa lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Tàbí kẹ̀, bóyá ńṣe lo yàn láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya kó o bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bó o bá sì ti ṣègbéyàwó, bóyá ńṣe lo yàn láti má ṣe bímọ kó o lè máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì, kó o lè máa ṣiṣẹ́ ìkọ́lé kárí ayé, kó o lè máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, alábòójútó àgbègbè tàbí míṣọ́nnárì. Nígbà tí ọjọ́ ogbó ti wá ń dé báyìí, ṣó yẹ kó o máa kábàámọ̀ àkókò tó o ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣó yẹ kó o máa ronú pé kò pọn dandan kó o yááfì gbogbo ohun tó o yááfì yẹn tàbí kó o máa ronú pé kò yẹ kó o ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn? Rárá o!
16 Ohun tó mú kó o ṣe àwọn ìpinnu yẹn ni pé o fẹ́ràn Jèhófà gan-an o sì fẹ́ ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sìn ín. Má ṣe rò pé ìgbésí ayé rẹ ì bá sàn ju bó ṣe rí nísinsìnyí lọ ká sọ pé o kò ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí ìpinnu tó o ṣe máa fún ẹ láyọ̀! Ọ̀nà tó o rò pé ó dára jù lọ fún ẹ láti sin Jèhófà lo yàn yẹn. Jèhófà ò sì ní gbàgbé gbogbo nǹkan tó o ti yááfì nítorí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Lẹ́yìn tó o bá ti ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun àti ara pípé, Jèhófà máa fi ọ̀pọ̀ ìbùkún tó fi gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ju àwọn ohun tó o ti yááfì lọ rọ́pò fún ẹ.—Sm. 145:16; 1 Tím. 6:19.
BÁ A ṢE LÈ MÁA SIN JÈHÓFÀ KÁ MÁ SÌ KÁBÀÁMỌ̀
17, 18. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tí kò fi máa bá a nìṣó láti ro àròkàn nípa àwọn àṣìṣe rẹ̀? (b) Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?
17 Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe tí kò fi máa bá a nìṣó láti ro àròkàn nípa àwọn àṣìṣe rẹ̀? Ó sọ pé òun gbàgbé àwọn ohun tó wà lẹ́yìn, òun sì ń nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú. (Ka Fílípì 3:13, 14.) Pọ́ọ̀lù ò kàn máa ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan búburú tó ti ṣe nígbà tó wà nínú ẹ̀sìn àwọn Júù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè jẹ́ olóòótọ́, kí ọwọ́ rẹ̀ sì lè tẹ ẹ̀bùn ìyè ayérayé.
18 Kí la lè rí kọ́ nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ? Dípò tí a ó fi máa ṣàníyàn torí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, ńṣe ló yẹ ká gbájú mọ́ bá a ṣe máa rí ìbùkún ọjọ́ iwájú gbà. Òótọ́ ni pé a kò lè gbàgbé àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe pátápátá, àmọ́ kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi torí wọn. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn máa bà wá nínú jẹ́. Ohun tó kù báyìí ni pé ká máa fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, ká sì máa ronú nípa ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu tó ń dúró dè wá!