ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26
Ṣé Ìwọ Náà Lè Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn?
“Ọlọ́run . . . ń mú kó wù yín láti gbé ìgbésẹ̀, ó sì ń fún yín ní agbára láti ṣe é.”—FÍLÍ. 2:13.
ORIN 64 À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ?
BÁWO lo ṣe di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n wàásù fún ẹ. Ó lè jẹ́ àwọn òbí ẹ tàbí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Ó sì lè jẹ́ ọmọ ilé ìwé ẹ tàbí Ẹlẹ́rìí kan tó ń wàásù láti ilé dé ilé ló sọ “ìhìn rere” fún ẹ. (Máàkù 13:10) Lẹ́yìn náà, wọ́n lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, o rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, ìyẹn sì mú kíwọ náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ní báyìí tí Jèhófà ti fà ẹ́ sínú òtítọ́, tó o sì ti di ọmọlẹ́yìn Jésù, o nírètí láti gbé títí láé. (Jòh. 6:44) Kò sí àní-àní pé o mọyì bí Jèhófà ṣe lo ẹnì kan láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tó sì jẹ́ kó o di ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Òun.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ní báyìí tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìwọ náà láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè nírètí àtiwà láàyè títí láé. Ó lè rọrùn fún àwọn kan lára wa láti máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ kó ṣòro fún wọn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. A máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń mú ká máa sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí àwọn ohun tó lè mú kó ṣòro fún wa láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ dípò ká kàn máa wàásù nìkan.
JÉSÙ PÀṢẸ PÉ KÁ MÁA WÀÁSÙ KÁ SÌ MÁA KỌ́NI
3. Kí nìdí tá a fi ń wàásù?
3 Nígbà tí Jésù wà láyé, iṣẹ́ alápá méjì ló fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó ní kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì sọ bí wọ́n ṣe máa ṣe é. (Mát. 10:7; Lúùkù 8:1) Lára ohun tí Jésù sọ fún wọn ni pé àwọn kan á tẹ́tí sí wọn, àwọn míì ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 9:2-5) Kódà, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí iṣẹ́ náà ṣe máa gbòòrò tó, ó sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jẹ́rìí “fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14; Ìṣe 1:8) Yálà àwọn èèyàn ṣe tán àtidi ọmọ ẹ̀yìn àbí wọn ò ṣe tán, a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ìjọba náà máa ṣe.
4. Kí ni Mátíù 28:18-20 sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe láfikún sí wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?
4 Kí ni iṣẹ́ kejì tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n ṣe? Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn tó máa di ọmọlẹ́yìn òun láti máa pa gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún wọn mọ́. Àmọ́, ṣé ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nìkan ni wọ́n máa wàásù tí wọ́n sì máa kọ́ni bí àwọn kan ṣe sọ? Rárá o. Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà máa tẹ̀ síwájú títí di ọjọ́ wa yìí, àní “títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Ka Mátíù 28:18-20.) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Jésù ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ló gbé iṣẹ́ yìí fún wọn. (1 Kọ́r. 15:6) Bákan náà, nínú ìran tí Jésù fi han Jòhánù, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn òun ló yẹ kó máa kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà.—Ìfi. 22:17.
5. Àfiwé wo ni Pọ́ọ̀lù lò nínú 1 Kọ́ríńtì 3:6-9 tó jẹ́ ká rí bí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ṣe so kọ́ra?
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn wé iṣẹ́ táwọn àgbẹ̀ máa ń ṣe, tó fi hàn pé iṣẹ́ wa kọjá ká kàn fúnrúgbìn. Ó sọ fún àwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin . . . Ẹ̀yin jẹ́ pápá Ọlọ́run tí à ń ro lọ́wọ́.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6-9.) Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú “pápá Ọlọ́run,” kì í ṣe pé ká kàn fúnrúgbìn, a tún gbọ́dọ̀ máa bomi rin ín, ká sì máa kíyè sí bó ṣe ń dàgbà. (Jòh. 4:35) Síbẹ̀, ká máa rántí pé Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà.
6. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn, kí la gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe?
6 “Àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” là ń wá. (Ìṣe 13:48) Ká tó lè sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn, a gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ (1) láti lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, (2) kí wọ́n gba ohun tí wọ́n ń kọ́ gbọ́, (3) kí wọ́n sì máa fi í sílò. (Jòh. 17:3; Kól. 2:6, 7; 1 Tẹs. 2:13) Gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ la lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn, tá a sì ń jẹ́ kí ara tù wọ́n nígbà tí wọ́n bá wá sípàdé. (Jòh. 13:35) Ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa lo ọ̀pọ̀ àkókò, á sì sapá gan-an láti ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè borí “àwọn nǹkan tó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,” ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àwọn ìwà tí ò dáa tó ti mọ́ ọn lára. (2 Kọ́r. 10:4, 5) Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù ká tó lè ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kó sì ṣèrìbọmi, àmọ́ ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
ÌFẸ́ LÓ Ń MÚ KÁ SỌ ÀWỌN ÈÈYÀN DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN
7. Kí ló ń mú ká máa wàásù, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?
7 Kí nìdí tá a fi ń wàásù, tá a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Àkọ́kọ́, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Tó o bá ń sapá láti pa àṣẹ Jésù mọ́ tó ní ká wàásù ká sì sọni dọmọ ẹ̀yìn, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (1 Jòh. 5:3) Wò ó báyìí ná: Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló mú kó o máa wàásù láti ilé dé ilé, àmọ́ ṣó rọrùn? Kò dájú. Ṣé ẹ̀rù bà ẹ́ nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù láti ilé dé ilé? Kò sí àní-àní pé ẹ̀rù bà ẹ́. Àmọ́ torí pé o mọ̀ pé iṣẹ́ tí Jésù fẹ́ kó o ṣe nìyẹn, o ṣe bẹ́ẹ̀, o ò sì jẹ́ kó sú ẹ. Bọ́jọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́, ó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti máa wàásù. Àmọ́ tó bá di pé kó o máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? Ṣé ìyẹn náà máa ń bà ẹ́ lẹ́rù? Ó ṣeé ṣe. Àmọ́, tó o bá bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o borí ìbẹ̀rù ẹ kó o sì ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Jèhófà máa mú kó wù ẹ́ láti máa sọni dọmọ ẹ̀yìn.
8. Bó ṣe wà nínú Máàkù 6:34, kí ni nǹkan kejì tó ń mú ká máa kọ́ni?
8 Ìkejì, ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn ló ń mú ká máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìgbà kan wà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wàásù gan-an, ó sì ti rẹ̀ wọ́n. Nígbà tí wọ́n máa dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ sinmi, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ tó ń dúró dè wọ́n. Torí náà, àánú wọn ṣe Jésù ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní “ọ̀pọ̀ nǹkan.” (Ka Máàkù 6:34.) Kí nìdí tí Jésù fi tiraka láti kọ́ àwọn èèyàn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́ lásìkò yẹn? Jésù fira ẹ̀ sípò àwọn èèyàn yẹn. Ó mọ̀ pé wọ́n ń jìyà, wọ́n nílò ìtùnú, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Bọ́rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ó lè jọ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún wọn, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n níṣòro, wọ́n sì nílò ìtùnú. Kódà, ṣe ni wọ́n dà bí àgùntàn tí ò ní olùṣọ́ àgùntàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọ Ọlọ́run, wọn ò sì nírètí. (Éfé. 2:12) Yàtọ̀ síyẹn, ojú ọ̀nà “tó lọ sí ìparun” ni wọ́n wà. (Mát. 7:13) Tá a bá ronú nípa bí ìgbésí ayé àwọn tí ò mọ Ọlọ́run ṣe rí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ìfẹ́ àti àánú tá a ní sí wọn á mú ká ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀nà tó dáa jù tá a sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
9. Kí ni Fílípì 2:13 sọ pé Jèhófà máa ṣe fún wa?
9 Ó lè má yá ẹ lára láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí o mọ̀ pé ó máa gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára ẹ nìyẹn, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wàá máa darí. (Ka Fílípì 2:13.) Àpọ́sítélì Jòhánù fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ń dáhùn àwọn àdúrà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (1 Jòh. 5:14, 15) Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa jẹ́ kó wù ẹ́ láti máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO MÍÌ
10-11. Kí ló lè mú kó má yá wa lára láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
10 A mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa kọ́ni, àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìṣòro yìí àti bá a ṣe lè borí wọn.
11 Tó ò bá lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn akéde kan ti dàgbà, àwọn míì sì ń ṣàìsàn. Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ látinú bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù lásìkò àrùn Corona. A ti rí i pé a lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí fóònù, torí náà, o lè wàásù fẹ́nì kan kó o sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ̀ látinú ilé ẹ! Nǹkan míì ni pé àwọn míì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ wọn kì í sí nílé lásìkò tá a máa ń jáde òde ẹ̀rí. Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ráyè láàárọ̀ kùtù tàbí lọ́wọ́ alẹ́. Ṣé o lè ṣètò àkókò ẹ láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lásìkò tí wọ́n máa ráyè? Ó ṣe tán alẹ́ ni Jésù kọ́ Nikodémù lẹ́kọ̀ọ́ torí àsìkò tí Nikodémù ráyè nìyẹn.—Jòh. 3:1, 2.
12. Àwọn nǹkan wo ló mú kó dá wa lójú pé àwa náà lè di olùkọ́ tó já fáfá?
12 Ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò ní lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A lè ronú pé òye wa ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó débi tá a fi máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára ẹ nìyẹn, jẹ́ ká wo àwọn nǹkan mẹ́ta táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ náà lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àkọ́kọ́, Jèhófà mọ̀ pé o tóótun láti kọ́ àwọn míì. (2 Kọ́r. 3:5) Ìkejì, Jésù tó ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé” ló pàṣẹ pé kó o máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Mát. 28:18) Ìkẹta, àwọn míì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, kó sì kọ́ òun ní ohun tí òun máa sọ, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòh. 8:28; 12:49) Yàtọ̀ síyẹn, o lè ní kí alábòójútó àwùjọ rẹ, aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí akéde kan tó nírìírí ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára ohun táá jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó o bá wọn ṣiṣẹ́ kó o sì kíyè sí bí wọ́n ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
13. Kí nìdí tó fi yẹ ká mú ara wa bá àyípadà tó ń dé bá iṣẹ́ ìwàásù mu?
13 Ó lè má rọrùn fún wa láti máa lo àwọn ọ̀nà tuntun tá a gbà ń wàásù báyìí. Bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti yí pa dà. Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tá à ń lò báyìí gba pé kó o múra sílẹ̀ dáadáa, kó o sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tó yàtọ̀ sí bá a ṣe máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, ìpínrọ̀ díẹ̀ la máa ń kà, ìjíròrò ló sì máa ń pọ̀ jù nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń kọ́ni, a máa ń lo ọ̀pọ̀ fídíò àtàwọn ìtẹ̀jáde tó wà lórí ìkànnì àti lórí JW Library®. Tí ò bá rọrùn fún ẹ láti máa lo àwọn nǹkan yìí, o lè sọ fún ẹnì kan pé kó kọ́ ẹ. Ohun kan ni pé ó máa ń pẹ́ kí nǹkan tuntun tó mọ́ àwa èèyàn lára. Àmọ́ lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà àtàwọn ará, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, wàá sì máa gbádùn ẹ̀. Aṣáájú-ọ̀nà kan tiẹ̀ sọ pé: “Àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ló ń gbádùn ọ̀nà tuntun tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ báyìí.”
14. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, báwo sì ni ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7 ṣe lè fún wa níṣìírí?
14 Ó lè ṣòro láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Àwọn èèyàn lè má nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ta kò wá. Kí ni ò ní jẹ́ kó sú wa tá a bá ń wàásù nírú agbègbè yìí? Ká rántí pé inú ayé tó kún fún ìṣòro là ń gbé, ipò àwọn èèyàn sì máa ń yí pa dà. Torí náà àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa lónìí lè nífẹ̀ẹ́ sí i nígbà míì. (Mát. 5:3) Àwọn kan tí ò kì í gbàwé wa tẹ́lẹ̀ ti wá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni Ọ̀gá ìkórè náà. (Mát. 9:38) Ó fẹ́ ká máa fúnrúgbìn ká sì máa bomi rin ín, àmọ́ Òun ló ń mú kó dàgbà. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá tiẹ̀ lẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀. Ìdí ni pé kì í ṣe iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ló máa mú kí Jèhófà bù kún wa, ìsapá wa ló máa ń wò!b
WÀÁ LÁYỌ̀ TÓ O BÁ Ń SỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN
15. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tẹ́nì kan bá gbà ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń fi ohun tó ń kọ́ sílò?
15 Inú Jèhófà máa ń dùn tí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. (Òwe 23:15, 16) Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn gan-an bó ṣe ń rí i táwa èèyàn ẹ̀ ń fìtara wàásù tá a sì ń kọ́ni lónìí! Bí àpẹẹrẹ, láìka bí àrùn Corona ṣe gbalẹ̀ gbòde lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́jọ (7,705,765) la darí, ìyẹn mú kí àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (241,994) ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn yìí náà máa kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á sì sọ wọ́n dọmọ ẹ̀yìn. (Lúùkù 6:40) Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí i tá à ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
16. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?
16 Kò rọrùn láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ẹni tuntun kí wọ́n lè wá jọ́sìn Òun. Torí náà, ṣé o lè pinnu pé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ó kéré tán? Tó o bá ń lo gbogbo àǹfààní tó o ní láti wàásù, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu pé wàá rí àwọn tó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapá ẹ.
17. Báwo ló ṣe máa rí lára wa tá a bá lẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
17 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa wàásù ká sì máa kọ́ni ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Iṣẹ́ yìí ń fún wa láyọ̀ gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti dọmọ ẹ̀yìn nílùú Tẹsalóníkà sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, ó ní: “Kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni? Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.” (1 Tẹs. 2:19, 20; Ìṣe 17:1-4) Bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ lónìí náà nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Stéphanie tóun àti ọkọ ẹ̀ kọ́ àwọn mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi sọ pé: “Kò sóhun tó ń fúnni láyọ̀ tó pé kéèyàn ran àwọn míì lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n á sì ṣèrìbọmi.”
ORIN 57 Máa Wàásù fún Onírúurú Èèyàn
a Jèhófà ti fún wa láǹfààní láti máa wàásù fáwọn èèyàn. Àmọ́ kò mọ síbẹ̀ o, ó tún ní ká máa kọ́ wọn pé kí wọ́n pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́. Kí ló ń mú kó máa wù wá láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́? Àwọn ìṣòro wo là ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? Kí la sì lè ṣe láti borí àwọn ìṣòro yìí? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bí gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ kan lọ́wọ́ títí táá fi ṣèrìbọmi, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bí Gbogbo Ìjọ Ṣe Lè Mú Kí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Tẹ̀ Síwájú Kó sì Ṣèrìbọmi” nínú Ilé Ìṣọ́ March 2021.
c ÀWÒRÁN: Wo bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè tún ayé ẹnì kan ṣe: Níbẹ̀rẹ̀, ọkùnrin yìí ò láyọ̀, ìgbésí ayé ẹ̀ ò sì nítumọ̀ torí pé kò mọ Jèhófà. Lẹ́yìn náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún un, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, torí náà, ó ya ara ẹ̀ sí mímọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. Níkẹyìn, gbogbo wọn ń gbádùn nínú Párádísè.