‘A Óò Gbé Àwọn Òkú Dìde’
“Nítorí kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a ó sì yí wa padà.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 15:52.
1, 2. (a) Ìlérí tí ń tuni nínú wo ni a ṣe nípasẹ̀ wòlíì Hóséà? (b) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ láti mú àwọn òkú padà sí ìyè?
OHA ti pàdánù ẹnì kan tí ó sún mọ́ ọ nínú ikú rí bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, o mọ àròdùn tí ikú lè fà. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Kristẹni máa ń rí ìtùnú nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ wòlíì Hóséà, pé: “Èmi yóò tún wọn rà padà láti ọwọ́ Ṣìọ́ọ̀lù; èmi yóò mú wọn padà láti inú ikú. Ìwọ Ikú, ìtani rẹ dà? Ìwọ Ṣìọ́ọ̀lù, ìpanirun rẹ dà?”—Hóséà 13:14.
2 Èròǹgbà pé àwọn òkú yóò padà sí ìyè jọ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu lójú àwọn oníyèméjì. Ṣùgbọ́n ó dájú pé Ọlọ́run Olódùmarè ní agbára láti ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀! Kókó náà gan-an ni bóyá Jèhófà fẹ́ láti mú àwọn òkú padà sí ìyè. Ọkùnrin olódodo náà, Jóòbù, béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Lẹ́yìn náà, ó pèsè ìdáhùn tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:14, 15) Ọ̀rọ̀ náà “àfẹ́rí” tọ́ka sí ìyánhànhàn tàbí ìfẹ́ àtọkànwá. (Fi wé Sáàmù 84:2.) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń hára gàgà fún àjíǹde—ó ń ṣàárò àwọn olóòótọ́ tí ó ti kú, àwọn tí ó wà láàyè nínú ìrántí rẹ̀.—Mátíù 22:31, 32.
Jésù Tan Ìmọ́lẹ̀ Sórí Àjíǹde
3, 4. (a) Ìmọ́lẹ̀ wo ni Jésù tàn sórí ìrètí àjíǹde? (b) Èé ṣe tí a fi gbé Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí, tí kì í ṣe nínú ẹran ara?
3 Òye ráńpẹ́ ni àwọn olóòótọ́ ìgbàanì bí Jóòbù ní nípa àjíǹde. Jésù Kristi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ ní kíkún sórí ìrètí àgbàyanu yìí. Ó fi ipa pàtàkì tí òun alára kó hàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:36) Ibo ni a ó ti gbádùn ìyè náà? Fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó lo ìgbàgbọ́, yóò jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:11) Àmọ́ ṣá o, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.” (Lúùkù 12:32) Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti òkè ọ̀run. Fún ìdí yìí, ìlérí yìí túmọ̀ sí pé “agbo kékeré” kan yóò wà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. (Jòhánù 14:2, 3; 1 Pétérù 1:3, 4) Ìrètí ológo yìí mà ga o! Síwájú sí i, Jésù ṣí i payá fún àpọ́sítélì Jòhánù pé iye “agbo kékeré” yìí kò ní ju 144,000 lọ.—Ìṣípayá 14:1.
4 Ṣùgbọ́n báwo ni 144,000 yóò ṣe wọnú ògo ti òkè ọ̀run? Jésù “tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìyè àti àìdíbàjẹ́ nípasẹ̀ ìhìn rere.” Nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ “ọ̀nà tuntun àti ọ̀nà ààyè” sí ọ̀run. (2 Tímótì 1:10; Hébérù 10:19, 20) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó kú, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀. (Aísáyà 53:12) Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ti kéde, “Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde.” (Ìṣe 2:32) Àmọ́ ṣá o, a kò gbé Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Ó ti sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé: “Oúnjẹ tí èmi yóò fi fúnni ni ẹran ara mi nítorí ìyè ayé.” (Jòhánù 6:51) Gbígba ẹran ara yìí padà yóò ba ẹbọ yẹn jẹ́. Nítorí náà, Jésù ni a “fi ikú pa nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.” (1 Pétérù 3:18) Jésù tipa báyìí “gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa,” èyíinì ni fún “agbo kékeré.” (Hébérù 9:12) Ó gbé ìtóye ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn 144,000 sì ni ó kọ́kọ́ jàǹfààní nínú èyí.
5. Ìrètí wo ni a nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ọ̀rúndún kìíní?
5 Jésù nìkan kọ́ ni a óò jí dìde sí ìyè ti ọ̀run. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Róòmù pé a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n láti di ọmọ Ọlọ́run àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi bí wọ́n bá mú yíyàn tí a yàn wọ́n dájú nípa fífaradà á dé òpin. (Róòmù 8:16, 17) Pọ́ọ̀lù tún ṣàlàyé pé: “Bí a bá ti di sísopọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ ikú rẹ̀, dájúdájú, a ó so wá pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú.”—Róòmù 6:5.
Gbígbèjà Ìrètí Àjíǹde
6. Èé ṣe tí àtakò fi dìde sí ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ní Kọ́ríńtì, kí sì ni ìdáhùnpadà Pọ́ọ̀lù?
6 Àjíǹde jẹ́ ara “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́” ẹ̀sìn Kristẹni. (Hébérù 6:1, 2) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àtakò dìde sí ẹ̀kọ́ náà ní Kọ́ríńtì. Àwọn kan nínú ìjọ náà, tí ó jọ pé ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ti nípa lórí wọn, ń sọ pé: “Kò sí àjíǹde àwọn òkú.” (1 Kọ́ríńtì 15:12) Nígbà tí ìròyìn nípa èyí dé etí-ìgbọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó gbèjà ìrètí àjíǹde, pàápàá jù lọ ìrètí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì orí 15. Ìwọ yóò rí i pé ó ṣèrànwọ́ bí o ba ka orí náà jálẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti dámọ̀ràn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú.
7. (a) Ọ̀ràn pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù darí àfiyèsí sí? (b) Àwọn wo ni ó rí Jésù lẹ́yìn tí a jí i dìde?
7 Nínú ẹsẹ méjì àkọ́kọ́ nínú 1 Kọ́ríńtì orí 15, Pọ́ọ̀lù gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ó fẹ́ jíròrò kalẹ̀, ó ní: “Ẹ̀yin ará, mo sọ ìhìn rere náà di mímọ̀ fún yín, èyí tí mo polongo fún yín, tí ẹ̀yin pẹ̀lú gbà, nínú èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú dúró, nípasẹ̀ èyí tí a tún ń gbà yín là, . . . àyàfi bí ó bá jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, ẹ di onígbàgbọ́ lásán.” Bí àwọn ará Kọ́ríńtì bá kùnà láti dúró ṣinṣin nínú ìhìn rere, lásán ni wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “Mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.”—1 Kọ́ríńtì 15:3-8.
8, 9. (a) Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ti ṣe pàtàkì tó? (b) Ìgbà wo ni ó jọ pé Jésù fara han “èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará”?
8 Fún àwọn tí ó ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde Jésù kì í ṣe ọ̀ràn gbàá-bí-o-bá-fẹ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn ni ó wà láti jẹ́rìí sí i pé “Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa” àti pé a ti gbé e dìde. Kéfà, tí a mọ̀ sí Pétérù, jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Lẹ́yìn tí Pétérù sẹ́ Jésù ní òru tí a fi Jésù hàn, tí a sì mú un, fífi tí Jésù fara hàn án yóò tù ú nínú gan-an ni. Jésù tí a ti jí dìde tún bẹ “àwọn méjìlá” wò, èyíinì ni àwọn àpọ́sítélì gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan—ìrírí kan tí ó jẹ́ pé láìsí àní-àní, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù wọn, kí wọ́n sì di ẹlẹ́rìí aláìṣojo nípa àjíǹde Jésù—Jòhánù 20:19-23; Ìṣe 2:32.
9 Kristi tún fara han àwùjọ ńlá, “èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará.” Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Gálílì nìkan ni ó ti ní àwọn ọmọlẹ́yìn tó pọ̀ tó yẹn, èyí lè jẹ́ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ṣàlàyé nínú Mátíù 28:16-20, nígbà tí Jésù pàṣẹ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ wo ẹ̀rí lílágbára tí àwọn wọ̀nyí yóò jẹ́! Àwọn kan ṣì wà láàyè ní ọdún 55 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ yìí sí àwọn ará Kọ́ríńtì. Ṣùgbọ́n o, ṣàkíyèsí pé àwọn tí ó ti kú ni a sọ pé wọ́n “ti sùn nínú ikú.” Nígbà yẹn, a kò tíì jí wọn dìde láti gba èrè wọn ti òkè ọ̀run.
10. (a) Kí ni ìyọrísí ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gbẹ̀yìn? (b) Báwo ni Jésù ṣe fara han Pọ́ọ̀lù “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó”?
10 Ẹlẹ́rìí títayọ mìíràn sí àjíǹde Jésù ni Jákọ́bù, ọmọ Jósẹ́fù àti Màríà, ìyá Jésù. Ṣáájú àjíǹde náà, ó hàn gbangba pé Jákọ́bù kò tíì di onígbàgbọ́. (Jòhánù 7:5) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jésù fara han Jákọ́bù, ó di onígbàgbọ́, ó sì jọ pé ó kó ipa pàtàkì nínú yíyí àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ́kàn padà. (Ìṣe 1:13, 14) Nínú ìpàdé tí Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe gbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gòkè re ọ̀run, ó yanṣẹ́ fún wọn láti “jẹ́ ẹlẹ́rìí . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:6-11) Lẹ́yìn náà, ó fara han Sọ́ọ̀lù ará Tásù, ẹni tí ń ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni. (Ìṣe 22:6-8) Jésù fara han Sọ́ọ̀lù “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.” Ṣe ni ó dà bí pé a ti jí Sọ́ọ̀lù dìde sí ìyè ti ẹ̀mí ná, tí ó sì lè rí Olúwa ògo náà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kí àjíǹde àwọn ẹni àmì òróró tó bẹ̀rẹ̀. Ìrírí yìí bẹ́gi dínà àtakò oníkúpani tí Sọ́ọ̀lù ń ṣe sí ìjọ Kristẹni, ó sì mú ìyípadà ńláǹlà wá. (Ìṣe 9:3-9, 17-19) Sọ́ọ̀lù di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ọ̀kan lára àwọn òléwájú olùgbèjà ìgbàgbọ́ Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 15:9, 10.
Ìgbàgbọ́ Nínú Àjíǹde Ṣe Kókó
11. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe já àwọn tí ń sọ pé, “Kò sí àjíǹde” nírọ́?
11 Nítorí náà, òtítọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ àjíǹde Jésù. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Wàyí o, bí a bá ń wàásù Kristi pé a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, èé ti rí tí àwọn kan láàárín yín fi ń sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú?” (1 Kọ́ríńtì 15:12) Kì í ṣe kìkì pé irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ń ṣiyèméjì, tàbí tí ọkàn wọ́n ń ṣe kámi-kàmì-kámi nípa àjíǹde nìkan ni, ṣùgbọ́n wọn ń sọ ọ́ síta pé àwọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù tú ìrònú èké wọn fó. Ó sọ pé bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, a jẹ́ pé irọ́ ni ìhìn iṣẹ́ Kristẹni, àti pé àwọn tó jẹ́rìí sí àjíǹde Kristi jẹ́ “ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run.” Bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, a jẹ́ pé a kò tíì san ìràpadà fún Ọlọ́run; a jẹ́ pé àwọn Kristẹni ‘ṣì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’ (1 Kọ́ríńtì 15:13-19; Róòmù 3:23, 24; Hébérù 9:11-14) A jẹ́ pé àwọn Kristẹni tí ó ti “sùn nínú ikú,” tí àwọn kan nínú wọ́n kú gẹ́gẹ́ bí ajẹ́rìíkú, ti ṣègbé láìsí ìrètí gidi. Ká ní ìgbésí ayé yìí nìkan ni gbogbo ìrètí tí àwọn Kristẹni ní, ipò tí wọ́n wà ì bá mà ṣeni láàánú gan-an o! Ṣe ni wọ́n ì bá jìyà gbé.
12. (a) Kí ni pípè tí a pe Kristi ní “àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú” fi hàn? (b) Báwo ni Kristi ṣe mú kí àjíǹde ṣeé ṣe?
12 Àmọ́ ṣá o, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, òun ni “àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́ríńtì 15:20) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí Jèhófà nípa fífún un ní àkọ́so wọn, Jèhófà fi ìkórè wọ̀ǹtì-wọnti bù kún wọn. (Ẹ́kísódù 22:29, 30; 23:19; Òwe 3:9, 10) Nípa pípe Kristi ní “àkọ́so,” Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ni a óò gbé dìde láti inú òkú sí ìyè ti ọ̀run. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan. Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 15:21, 22) Jésù mú kí àjíǹde ṣeé ṣe nípa fífi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún títú aráyé sílẹ̀ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Gálátíà 1:4; 1 Pétérù 1:18, 19.a
13. (a) Ìgbà wo ni àjíǹde sí òkè ọ̀run ṣẹlẹ̀? (b) Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró kò “sùn nínú ikú”?
13 Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:23) A jí Kristi dìde ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró—“àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi”—ní láti dúró di kété lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín rẹ̀ bí ọba, èyí tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1914. (1 Tẹsalóníkà 4:14-16; Ìṣípayá 11:18) Àwọn tí ń bẹ láàyè nígbà wíwàníhìn-ín yẹn ńkọ́? Pọ́ọ̀lù wí pé: “Wò ó! Àṣírí ọlọ́wọ̀ ni mo ń sọ fún yín: Kì í ṣe gbogbo wa ni yóò sùn nínú ikú, ṣùgbọ́n a óò yí gbogbo wa padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn. Nítorí kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a ó sì yí wa padà.” (1 Kọ́ríńtì 15:51, 52) Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo ẹni àmì òróró ni ó sùn nínú sàréè ní dídúró de àjíǹde. Àwọn tí ó kú nígbà wíwàníhìn-ín Kristi ni a pa lára dà ní wàrà-ǹṣeṣà.—Ìṣípayá 14:13.
14. Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ni a “batisí fún ète jíjẹ́ òkú”?
14 Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ni àwọn tí a ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú yóò ṣe? Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá, èé ṣe tí a fi ń batisí wọn pẹ̀lú fún ète jíjẹ́ bẹ́ẹ̀? Èé ṣe tí àwa pẹ̀lú fi ń wà nínú ewu ní gbogbo wákàtí?” (1 Kọ́ríńtì 15:29, 30) Pọ́ọ̀lù kò sọ pé tìtorí àwọn òkú ni a ṣe batisí àwọn alààyè, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dà Bíbélì kan ti gbé e kalẹ̀. Ó ṣe tán, ìbatisí wé mọ́ jíjẹ́ tí Kristẹni kan jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, àwọn òkú ọkàn kò sì lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn. (Jòhánù 4:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni alààyè, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù alára, wọ́n wà “nínú ewu ní gbogbo wákàtí.” Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni a ti ‘batisí sínú ikú Kristi.’ (Róòmù 6:3) Láti ìgbà tí a ti fòróró yàn wọ́n, a ti “batisí” wọn sí ohun tí a lè pè ní ipa ọ̀nà tí yóò yọrí sí irú ikú tí Kristi kú. (Máàkù 10:35-40) Wọn yóò kú pẹ̀lú ìrètí àjíǹde ológo sí òkè ọ̀run.—1 Kọ́ríńtì 6:14; Fílípì 3:10, 11.
15. Àwọn ewu wo ni Pọ́ọ̀lù fojú winá rẹ̀, báwo sì ni ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ṣe kópa pàtàkì ní fífaradà wọ́n?
15 Wàyí o, Pọ́ọ̀lù wá ń ṣàlàyé pé òun náà ti dojú kọ ewu dé ìwọ̀n tí òun fi lè sọ pé: “Lójoojúmọ́ ni mo ń dojú kọ ikú.” Kí ó tó di pé àwọn kan sọ pé ó ń sọ àsọdùn, Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Èyí ni èmi ń kín lẹ́yìn nípasẹ̀ ayọ̀ ńláǹlà lórí yín, ẹ̀yin ará, èyí tí mo ní nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” The Jerusalem Bible túmọ̀ ẹsẹ náà báyìí: “Ẹ̀yin ará, ojoojúmọ́ ni mo ń dojú kọ ikú, mo sì lè fi ìyangàn tí mo ní nínú yín nínú Kristi Jésù Olúwa wa búra èyí.” Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ewu tí ó dojú kọ, ẹsẹ 32 sọ̀rọ̀ nípa ‘bíbá àwọn ẹranko ẹhànnà jà ní Éfésù.’ Àwọn ará Róòmù sábà máa ń pa àwọn ọ̀daràn nípa jíjù wọ́n sẹ́nu àwọn ẹranko ẹhànnà ní pápá ìṣeré. Bí Pọ́ọ̀lù bá fara da fífìjà pẹẹ́ta pẹ̀lú ẹranko ẹhànnà gidi, nípa ìrànlọ́wọ́ Jèhófà nìkan ni ó fi yè é. Ká ní kò sí ìrètí àjíǹde ni, yíyan ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó mú kí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu yóò jẹ́ ìwà òmùgọ̀ gbáà. Ká ní kò sí ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú ni, fífarada ìnira àti ìfara-ẹni-rúbọ tí ó wé mọ́ sísin Ọlọ́run kì bá ní ìtumọ̀ tí ó ṣe gúnmọ́. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Bí a kò bá ní gbé àwọn òkú dìde, ‘ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.’”—1 Kọ́ríńtì 15:31, 32; wo 2 Kọ́ríńtì 1:8, 9; 11:23-27.
16. (a) Ibo ni ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn náà “ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú” ti pilẹ̀ṣẹ̀? (b) Kí ni àwọn ewu tí ó wà nínú títẹ́wọ́gba ìrònú yìí?
16 Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 22:13 ni Pọ́ọ̀lù fà yọ, èyí tí ó ṣàpèjúwe ẹ̀mí ìgbékútà àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù aláìgbọràn. Tàbí kẹ̀, ó lè jẹ́ ohun tí ó ní lọ́kàn ni ìgbàgbọ́ àwọn Epikúréì, àwọn tí ń ṣáátá ìrètí èyíkéyìí nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, tí wọ́n sì gbà gbọ́ pé ayé jíjẹ ni èrè pàtàkì inú ìgbésí ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, èrò “kí a máa jẹ, kí a sì máa mu” kò bá ọ̀nà Ọlọ́run mu. Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Bíbá àwọn tí ó kọ àjíǹde kẹ́gbẹ́ lè ṣekú pani. Irú ìbákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ lè ti kó ipa kan nínú àwọn ìṣòro tí ó di dandan fún Pọ́ọ̀lù láti yanjú nínú ìjọ Kọ́ríńtì, àwọn ìṣòro bí ìṣekúṣe, ìyapa, pípe ara wọn lẹ́jọ́, àti àìbọ̀wọ̀ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.—1 Kọ́ríńtì 1:11; 5:1; 6:1; 11:20-22.
17 Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ pé: “Ẹ jí sí orí pípé lọ́nà òdodo, ẹ má sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí àwọn kan wà láìní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Mo ń sọ̀rọ̀ láti sún yín sí ìtìjú.” (1 Kọ́ríńtì 15:34) Ojú ìwòye òdì nípa àjíǹde ni ó ra àwọn kan níyè nípa tẹ̀mí, àfi bí ẹní mutí yó. Wọ́n ní láti jí, kí ojú wọ́n dá. Bákan náà lónìí, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí kámi-kàmì-kámi tí ó jẹ́ ti ayé ní ipa lórí wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ rọ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ìrètí wọn ti àjíǹde sókè ọ̀run. Ṣùgbọ́n àwọn ìbéèrè ṣì wà nílẹ̀—fún àwọn ará Kọ́ríńtì ìgbàanì àti fún àwa náà lónìí. Fún àpẹẹrẹ, irú ara wo ni 144,000 yóò gbé lọ sí ọ̀run? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ yòókù ńkọ́, àwọn tí ó ṣì wà nínú sàréè láìní ìrètí ti òkè ọ̀run? Kí ni àjíǹde yóò túmọ̀ sí fún irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? Nínú àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e, àwa yóò ṣàgbéyẹ̀wò ìyókù ìjíròrò Pọ́ọ̀lù nípa àjíǹde.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìtẹ̀jáde February 15, 1991, ti Ilé Ìṣọ́nà fún ìjíròrò ìràpadà.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ìmọ́lẹ̀ wo ni Jésù tàn sórí àjíǹde?
◻ Àwọn wo ni díẹ̀ lára àwọn tí ó jẹ́rìí sí àjíǹde Kristi?
◻ Èé ṣe tí àwọn kan fi pe ẹ̀kọ́ àjíǹde níjà, kí sì ni ìdáhùnpadà Pọ́ọ̀lù?
◻ Èé ṣe tí ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde fi ṣe kókó fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
17. (a) Ìyànjú wo ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kọ́ríńtì? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló kù tí a kò tíì dáhùn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọmọbìnrin Jáírù di ẹ̀rí pé àjíǹde ṣeé ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ká ní kò sí ìrètí àjíǹde ni, asán lórí asán ni ìjẹ́rìíkú àwọn Kristẹni olóòótọ́ ì bá jẹ́