Ìrètí Àjíǹde Dájú!
“Mo . . . ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde . . . yóò wà.”—ÌṢE 24:15.
1. Èé ṣe táa fi lè ní ìrètí nínú àjíǹde?
JÈHÓFÀ ti fún wa ní ìdí tí ó yè kooro láti ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. Ó ti ṣèlérí pé àwọn òkú yóò dìde, ìyẹn ni pé wọn ó dìde dúró láti wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì dájú pé ète rẹ̀ fún àwọn tó ń sùn nínú ikú yóò ní ìmúṣẹ. (Aísáyà 55:11; Lúùkù 18:27) Àní sẹ́, Ọlọ́run ti fi agbára rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde hàn tẹ́lẹ̀.
2. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè ṣàǹfààní fún wa?
2 Ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, lè gbé wa ró láwọn àkókò ìpọ́njú. Ìdánilójú ìrètí àjíǹde yìí tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ wa mọ́ sí Baba wa ọ̀run, kódà títí dójú ikú. Ó ṣeé ṣe kí ìrètí àjíǹde táa ní túbọ̀ lókun sí i báa ṣe ń gbé àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àwọn táa mú padà bọ̀ sí ìyè yẹ̀ wò. Gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí ni wọ́n ṣe láṣeyọrí nípasẹ̀ agbára tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ wá.
Wọ́n Rí Àwọn Òkú Wọn Gbà Nípa Àjíǹde
3. Kí la fún Èlíjà lágbára láti ṣe nígbà tí ọmọkùnrin opó Sáréfátì kú?
3 Nínú àtúnyẹ̀wò kan tó múni lọ́kàn yọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí àwọn ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ṣáájú àkókò Kristẹni fi hàn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde.” (Hébérù 11:35; 12:1) Ọ̀kan nínú irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ni tálákà opó kan ní Sáréfátì ìlú àwọn ará Fòníṣíà. Nítorí pé ó fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí Èlíjà, wòlíì Ọlọ́run, iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀ ní ti pé ìyẹ̀fun àti òróró rẹ̀ kò tán ní gbogbo àkókò ìyàn tí ì bá ti gbẹ̀mí òun àti ọmọkùnrin rẹ̀. Nígbà tí ọmọ náà wá kú lẹ́yìn ìgbà náà, Èlíjà gbé e sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú kan, ó gbàdúrà, ó na ara rẹ̀ sórí ọmọ náà nígbà mẹ́ta, ó sì bẹ̀bẹ̀ pé: “Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ọkàn ọmọ yìí padà wá sínú rẹ̀.” Ọlọ́run sì jẹ́ kí ọkàn tàbí ìwàláàyè náà padà sínú ọmọdékùnrin ọ̀hún. (1 Àwọn Ọba 17:8-24) Fojú inú wo bí inú opó yẹn yóò ṣe dùn tó nígbà tí a san èrè ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún un nípa àjíǹde àkọ́kọ́ nínú àkọsílẹ̀—ìyẹn, àjíǹde ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n!
4. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Èlíṣà ṣe ní Ṣúnémù?
4 Obìnrin mìíràn tó tún rí òkú tirẹ̀ gbà nípa àjíǹde ni obìnrin tó ń gbé ìlú Ṣúnémù. Ìyàwó baba arúgbó kan ni, ó fi inúure hàn sí wòlíì Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀. A sì fi ọmọkùnrin kan san èrè fún un. Àmọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, ó pe wòlíì náà kó wá wo òkú ọmọkùnrin ọ̀hún nínú ilé òun. Lẹ́yìn tí Èlíṣà gbàdúrà, tó sì gbé àwọn ìgbésẹ̀ bíi mélòó kan, “kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara ọmọ náà sì wá móoru.” Ó “bẹ̀rẹ̀ sí sín ní èyí tí ó tó ìgbà méje, lẹ́yìn èyí tí ọmọdékùnrin náà la ojú rẹ̀.” Kò sí àní-àní pé àjíǹde yẹn mú ayọ̀ ńlá wá fún tìyá tọmọ. (2 Àwọn Ọba 4:8-37; 8:1-6) Àmọ́ inú wọn yóò mà túbọ̀ dùn jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí wọ́n bá jí sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé nínú “àjíǹde tí ó sàn jù”—èyí tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún wọn láti wà láìní kú mọ́ láé! Èyí tọ́pẹ́, ó ju ọpẹ́ lọ, sí Jèhófà, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó ṣètò àjíǹde!—Hébérù 11:35.
5. Báwo ni Èlíṣà ṣe kópa nínú iṣẹ́ ìyanu kan kódà lẹ́yìn ikú rẹ̀ pàápàá?
5 Kódà lẹ́yìn tí Èlíṣà kú tí wọ́n sì sin ín, Ọlọ́run mú kí egungun rẹ̀ lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. A kà pé: “Bí [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan] ti ń sìnkú ọkùnrin kan, họ́wù, kíyè sí i, wọ́n rí [àwọn ọmọ Móábù kan tó jẹ́] ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí. Kíákíá, wọ́n sọ ọkùnrin náà sínú ibi ìsìnkú Èlíṣà, wọ́n sì lọ. Nígbà tí ọkùnrin [tó kú] náà fara kan egungun Èlíṣà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó wá sí ìyè, ó sì dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.” (2 Àwọn Ọba 13:20, 21) Ẹ wo bó ṣe máa jẹ́ ìyàlẹ́nu àti ìdùnnú ńlá tó fún ọkùnrin yẹn! Fojú inú wo ìdùnnú ńlá tí a óò ní nígbà tí a bá jí àwọn olólùfẹ́ wa dìde sí ìyè ní ìbámu pẹ̀lú ète Jèhófà Ọlọ́run tí kò lè kùnà!
Ọmọ Ọlọ́run Jí Òkú Dìde
6. Iṣẹ́ ìyanu wo ni Jésù ṣe nítòsí ìlú ńlá Náínì, báwo sì ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe lè nípa lórí wa?
6 Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ti fún wa ní ìdí yíyè kooro láti gbà gbọ́ pé àwọn òkú lè jíǹde, kí wọ́n sì ní àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ nítòsí ìlú ńlá Náínì lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbà pé irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe nípasẹ̀ agbára tí Ọlọ́run fúnni. Ní àkókò kan, Jésù pàdé àwọn aṣọ̀fọ̀ kan tí wọ́n ń gbé òkú ọ̀dọ́kùnrin kan jáde kúrò ní ìlú ńlá náà láti lọ sin. Ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí opó kan bí ni. Jésù sọ fún obìnrin náà pé: “Dẹ́kun sísunkún.” Ó wá fọwọ́ kan ohun tí a fi gbé òkú náà, ó sì wí pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!” Bó ṣe dìde nìyẹn tó ń sọ̀rọ̀. (Lúùkù 7:11-15) Dájúdájú, iṣẹ́ ìyanu yìí túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lókun pé ìrètí àjíǹde dájú.
7. Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn ọmọbìnrin Jáírù?
7 Tún gbé ìṣẹ̀lẹ̀ kan yẹ̀ wò, nípa Jáírù tó jẹ́ alága sínágọ́gù ní Kápánáúmù. Ó ní kí Jésù wá ran ọmọbìnrin òun ọ̀wọ́n, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá lọ́wọ́, nítorí pé ó sún mọ́ bèbè ikú. Kété lẹ́yìn náà ni wọ́n ròyìn pé ọmọbìnrin náà ti kú. Lẹ́yìn tí Jésù rọ Jáírù tí ìbànújẹ́ ti dorí rẹ̀ kodò láti lo ìgbàgbọ́, ó tẹ̀ lé e lọ sí ilé rẹ̀, níbi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń sunkún. Àwọn ènìyàn náà fi Jésù rẹ́rìn-ín nígbà tó sọ fún wọn pé: “Ọmọ kékeré náà kò tíì kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.” Ní ti tòótọ́, ó ti kú, àmọ́ Jésù fẹ́ fi hàn pé ó ṣeé ṣe láti jí ènìyàn sí ìyè gan-an gẹ́gẹ́ bó ti ṣeé ṣe láti jí ẹni tó ti sùn wọra kúrò lójú oorun. Ó wá di ọmọbìnrin náà lọ́wọ́ mú, ó sì wí pé: “Ọmọdébìnrin, dìde!” Ó sì dìde ní ìṣẹ́jú akàn, “àwọn òbí rẹ̀ kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe” nítorí ayọ̀ yẹn pọ̀. (Máàkù 5:35-43; Lúùkù 8:49-56) Dájúdájú, ayọ̀ yẹn á pọ̀ débi pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé kò ní “mọ ohun tí wọn ì bá ṣe” nígbà tí a bá jí àwọn olólùfẹ́ wọn tó ti kú dìde sí ìyè nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé.
8. Kí ni Jésù ṣe ní ibojì Lásárù?
8 Lásárù ti kú fún odindi ọjọ́ mẹ́rin nígbà tí Jésù dé ibojì rẹ̀ tó ní kí wọ́n gbé òkúta tó wà lẹ́nu ibojì náà kúrò. Lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà ní gbangba kí àwọn òǹwòran lè mọ̀ pé agbára tí Ọlọ́run fún òun lòún gbára lé, ó wí ní ohùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!” Bó ṣe jáde wá nìyẹn! Àwọn aṣọ ìdìkú tí wọ́n fi di ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣì wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ tí wọ́n fi yí ojú rẹ̀ ṣì wà níbẹ̀. Jésù ní: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.” Nígbà tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ láti tu Màríà àti Màtá, tí wọ́n jẹ́ arábìnrin Lásárù nínú, ló gba Jésù gbọ́. (Jòhánù 11:1-45) Ǹjẹ́ àkọsílẹ̀ yìí ò fún ọ ní ìrètí kíkún pé a lè jí àwọn olólùfẹ́ rẹ tó ti kú dìde sí ìyè nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run?
9. Èé ṣe tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jésù lè jí àwọn òkú dìde báyìí?
9 Nígbà tí Jòhánù Oníbatisí wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, Jésù fi ìròyìn tó fọkàn ẹni balẹ̀ yìí ránṣẹ́ sí i pé: “Àwọn afọ́jú ń padà ríran, . . . a sì ń gbé àwọn òkú dìde.” (Mátíù 11:4-6) Níwọ̀n ìgbà tí Jésù ti jí òkú dìde nígbà tó wà láyé, ó dájú pé ó tún lè ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tí Ọlọ́run fún ní agbára. Jésù ni “àjíǹde àti ìyè,” ẹ sì wá wo bó ṣe tuni nínú tó láti mọ̀ pé lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá”!—Jòhánù 5:28, 29; 11:25.
Àwọn Àjíǹde Mìíràn fún Ìrètí Wa Lókun
10. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe àjíǹde tí a kọ́kọ́ ròyìn pé ó ti ọwọ́ àpọ́sítélì kan ṣẹlẹ̀?
10 Nígbà tí Jésù rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí oníwàásù Ìjọba náà, ó sọ pé: “Ẹ gbé àwọn ẹni tí ó ti kú dìde.” ( Mátíù 10:5-8) Àmọ́ o, kí wọ́n tó lè ṣe èyí, wọ́n ní láti gbára lé agbára Ọlọ́run. Ní Jópà, ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, obìnrin oníwà bí Ọlọ́run nì, Dọ́káàsì (Tàbítà) sùn nínú ikú. Lára àwọn iṣẹ́ rere rẹ̀ ni pé ó máa ń hun aṣọ fún àwọn opó tó jẹ́ tálákà, àwọn opó wọ̀nyí sì sunkún gan-an nígbà tó kú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣètò rẹ̀ fún sínsin, wọ́n sì ránṣẹ́ sí Pétérù, bóyá kó lè wá tù wọ́n nínú. (Ìṣe 9:32-38) Ó ní kí gbogbo àwọn tí ó wà ní ìyẹ̀wù òkè jáde síta, ó gbàdúrà, ó sì wí pé: “Tàbítà, dìde!” Ó la ojú rẹ̀, ó dìde jókòó, ó di ọwọ́ Pétérù mú, òun náà sì gbé e dìde. Àjíǹde tí a kọ́kọ́ ròyìn pé ó ti ọwọ́ àpọ́sítélì kan ṣẹlẹ̀ yìí sọ ọ̀pọ̀ di onígbàgbọ́. (Ìṣe 9:39-42) Ó tún fi kún ìdí táa fi lè ní ìrètí nínú àjíǹde.
11. Àjíǹde wo ló kẹ́yìn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì?
11 Àjíǹde tó kẹ́yìn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì ni èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Tíróásì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, ó tẹsẹ̀ dúró níbẹ̀, ó sì fa àwíyé rẹ̀ gùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Bóyá nítorí rírẹ̀ tó rẹ̀ ẹ́, àti bóyá nítorí ooru tí ọ̀pọ̀ fìtílà tó wà níbẹ̀ fà àti híhá tí ibi ìpàdé náà há gádígádí, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yútíkọ́sì, sùn lọ, ó sì ré lulẹ̀ láti ojú fèrèsé àjà kẹta. Ńṣe ni wọ́n “gbé e ní òkú,” kì í ṣe pé ó kàn dákú lásán. Pọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ lé Yútíkọ́sì lórí, ó fi ọwọ́ gbá a mọ́ra, ó sì sọ fún àwọn tó ń wòran pé: “Ẹ dẹ́kun pípariwo gèè, nítorí pé ọkàn rẹ̀ wà nínú rẹ̀.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé a ti dá ìwàláàyè ọ̀dọ́kùnrin náà padà. “A sì tu” àwọn tó wà níbẹ̀ “nínú lọ́nà tí kò ṣeé díwọ̀n.” (Ìṣe 20:7-12) Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yóò jàǹfààní ìmúṣẹ ìrètí àjíǹde.
Àjíǹde—Ìrètí Tó Ti Wà Tipẹ́
12. Ọ̀rọ̀ ìdánilójú wo ni Pọ́ọ̀lù sọ nígbà tó wà níwájú Fẹ́líìsì, Gómìnà Róòmù?
12 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń jẹ́jọ́ níwájú Fẹ́líìsì, Gómìnà Róòmù, ó jẹ́rìí pé: “Mo . . . gba gbogbo ohun tí a là sílẹ̀ nínú Òfin gbọ́, tí a sì kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì; mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:14, 15) Báwo ni àwọn apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, irú bíi “Òfin” ṣe tọ́ka sí jíjí àwọn òkú dìde?
13. Èé ṣe táa fi lè sọ pé Ọlọ́run tọ́ka sí àjíǹde nígbà tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́?
13 Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tọ́ka sí àjíǹde nígbà tó sọ asọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ ní Édẹ́nì. Nígbà tí Ọlọ́run ń dájọ́ fún “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” Sátánì Èṣù, ó wí pé: “Èmi yóò . . . fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15) Pípa irú ọmọ obìnrin náà ní gìgísẹ̀ túmọ̀ sí pípa Jésù Kristi. Bí Irú-Ọmọ yẹn yóò bá pa ejò náà ní orí lẹ́yìn ìyẹn, a jẹ́ pé Kristi ní láti jí dìde kúrò nínú òkú nìyẹn.
14. Báwo ló ṣe jẹ́ pé Jèhófà “kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè”?
14 Jésù là á mọ́lẹ̀, ó ní: “Pé a gbé àwọn òkú dìde ni Mósè pàápàá sọ di mímọ̀, nínú ìròyìn nípa igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, nígbà tí ó pe Jèhófà ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:27, 37, 38; Ẹ́kísódù 3:6) Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ti kú ná, àmọ́ ète Ọlọ́run láti jí wọn dìde dájú pé yóò ní ìmúṣẹ débi pé lójú tirẹ̀, ṣe ló dá bíi pé wọ́n ṣì wà láàyè.
15. Èé ṣe tí Ábúráhámù fi ní ìdí láti gba àjíǹde gbọ́?
15 Ìdí wà fún Ábúráhámù láti ní ìrètí àjíǹde, nítorí pé nígbà tí òun àti Sárà aya rẹ̀ ti darúgbó gan-an, tí agbára wọn láti bímọ sì ti kú, Ọlọ́run mú agbára ìbímọ wọn padà bọ̀ sípò lọ́nà ìyanu. Bí àjíǹde lèyí rí. (Jẹ́nẹ́sísì 18:9-11; 21:1-3; Hébérù 11:11, 12) Nígbà tí Ísákì ọmọ wọn ń lọ sí nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kí ó fi ọmọ náà rúbọ. Àmọ́, bí Ábúráhámù ṣe fẹ́ dúńbú Ísákì gẹ́ẹ́ ni áńgẹ́lì Jèhófà dá ọwọ́ rẹ̀ dúró. Ábúráhámù ti “ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé [Ísákì] dìde, àní kúrò nínú òkú; láti ibẹ̀, ó sì tún rí i gbà lọ́nà àpèjúwe.”—Hébérù 11:17-19; Jẹ́nẹ́sísì 22:1-18.
16. Kí ni Ábúráhámù tó ń sùn nínú ikú báyìí ń dúró dè?
16 Ábúráhámù ní ìrètí nínú àjíǹde tí yóò wáyé lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà, Irú-Ọmọ tí a ṣèlérí náà. Láti ọ̀run, kó tó di pé Ọmọ Ọlọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ló ti kíyè sí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù. Nígbà tó di ènìyàn tí a mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Jésù Kristi, ó wá sọ fún àwọn Júù pé: “Ábúráhámù baba yín yọ̀ gidigidi nínú ìfojúsọ́nà fún rírí ọjọ́ mi.” (Jòhánù 8:56-58; Òwe 8:30, 31) Ábúráhámù ti ń sùn nínú ikú báyìí, ó ń dúró de àjíǹde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Mèsáyà náà.—Hébérù 11:8-10, 13.
Ẹ̀rí Láti Inú Òfin àti Sáàmù
17. Báwo ni “ohun tí a là sílẹ̀ nínú Òfin” ṣe tọ́ka sí àjíǹde Jésù Kristi?
17 Ìrètí àjíǹde tí Pọ́ọ̀lù ní wà ní ìbámu pẹ̀lú “ohun tí a là sílẹ̀ nínú Òfin.” Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ mú ìtí àkọ́so ìkórè yín wá sọ́dọ̀ àlùfáà. Kí ó sì fi ìtí náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà [ní Nísàn 16] láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún yín.” (Léfítíkù 23:9-14) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òfin yìí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ̀wé pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” Gẹ́gẹ́ bí “àkọ́so,” a jí Jésù dìde ní Nísàn 16, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn náà, ní àkókò wíwà níhìn-ín rẹ̀, àjíǹde ‘àwọn èso ìkẹyìn’ yóò wà—ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ̀mí tí a fi òróró yàn.—1 Kọ́ríńtì 15:20-23; 2 Kọ́ríńtì 1:21; 1 Jòhánù 2:20, 27.
18. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé a sọ àsọtẹ́lẹ̀ àjíǹde Jésù nínú Sáàmù?
18 Ìwé Sáàmù náà tún ti àjíǹde lẹ́yìn. Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Sáàmù kẹrìndínlógún, ẹsẹ ìkẹjọ sí ìkọkànlá, nígbà tó sọ pé: “Dáfídì sọ nípa [Kristi] pé, ‘Mo ní Jèhófà níwájú mi nígbà gbogbo; nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, kí a má bàa mì mí láé. Ní tìtorí èyí, ọkàn-àyà mi yá gágá, ahọ́n mi sì yọ̀ gidigidi. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹran ara mi pàápàá yóò máa gbé ní ìrètí; nítorí ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́.’” Pétérù fi kún un pé: “[Dáfídì] rí i ṣáájú, ó sì sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò ṣá a tì sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́. Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde.”—Ìṣe 2:25-32.
19, 20. Ìgbà wo ní Pétérù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 118:22, báwo ni èyí sì ṣe tan mọ́ ikú àti àjíǹde Jésù?
19 Ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, Pétérù dúró níwájú Sànhẹ́dírìn, ó sì tún ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí wọ́n béèrè bí àpọ́sítélì náà ṣe mú alágbe kan tó yarọ lára dá, ó sọ pé: “Kí ó di mímọ̀ fún gbogbo yín àti fún gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, pé ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì, ẹni tí ẹ̀yin kàn mọ́gi ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú, nípasẹ̀ ẹni yìí ni ọkùnrin yìí fi dúró níhìn-ín pẹ̀lú ara dídá níwájú yín. [Jésù] yìí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin akọ́lé hùwà sí bí aláìjámọ́ nǹkan kan tí ó ti di olórí igun ilé.’ Síwájú sí i, kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”—Ìṣe 4:10-12.
20 Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 118:22 ni Pétérù lò níhìn-ín, ó fi hàn pé ohun tó wà níbẹ̀ ń tọ́ka sí ikú àti àjíǹde Jésù. Oró tí àwọn aṣáájú ìsìn pọ̀ sí àwọn Júù nínú ló jẹ́ kí wọ́n kọ Jésù sílẹ̀. (Jòhánù 19:14-18; Ìṣe 3:14, 15) ‘Kíkọ̀ tí àwọn akọ́lé kọ òkúta náà sílẹ̀’ yọrí sí ikú Kristi, ṣùgbọ́n ‘pé òkúta náà di olórí igun ilé’ tọ́ka sí bí a ṣe jí i dìde sí ògo tẹ̀mí ní ọ̀run. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí onísáàmù náà sọ tẹ́lẹ̀, ‘ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀ ni èyí ti wá.’ (Sáàmù 118:23) Mímú kí “òkúta náà” di Olórí igun ilé ní í ṣe pẹ̀lú gbígbé e ga gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́la.—Éfésù 1:19, 20.
Ìrètí Àjíǹde Ń Gbéni Ró
21, 22. Ìrètí wo ni Jóòbù sọ jáde bó ṣe wà nínú ìwé Jóòbù 14:13-15, báwo sì ni èyí ṣe lè tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú lónìí?
21 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì fojú ara wa rí ẹnikẹ́ni tí a gbé dìde kúrò nínú òkú, a ti rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan tó mú kí àjíǹde dá wa lójú. Nítorí náà, a lè wá ní ìrètí tí Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ nì, sọ jáde. Nígbà tí ó ń jẹ ìrora, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ [Jèhófà] yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, . . . pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi! Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí? . . . Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:13-15) Ọlọ́run ‘yóò ṣàfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,’ yóò jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti jí Jóòbù dìde. Ìyẹn mà kúkú fún wa nírètí o!
22 Mẹ́ńbà ìdílé kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè máa ṣàìsàn líle koko, bíi ti Jóòbù, ó tiẹ̀ lè kú pàápàá. Àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí sun ẹkún ìbànújẹ́, àní bí Jésù pàápàá ṣe sunkún nítorí ikú Lásárù. (Jòhánù 11:35) Àmọ́, ẹ wá wò bó ṣe ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé Ọlọ́run yóò pe àwọn tó wà ní ìrántí rẹ̀, wọn ó sì dáhùn! Ńṣe ni yóò dà bí ẹni pé wọ́n padà dé láti ìrìn àjò kan—tí wọn ò ṣàìsàn tàbí kí wọ́n fara pa, àmọ́ tí ara wọn le koko.
23. Báwo ni àwọn kan ṣe sọ ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú ìrètí àjíǹde jáde?
23 Ikú Kristẹni àgbàlagbà kan tó jẹ́ olóòótọ́ mú kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kọ̀wé pé: “A bá yín kẹ́dùn gidigidi nítorí ikú ìyá yín. Kò ní pẹ́ rárá tí a ó fi kí i káàbọ̀—nínú ẹwà, tí ara rẹ̀ yóò sì yá gágá!” Àwọn òbí tí ọmọ wọn kú sọ pé: “A ń fojú sọ́nà gan-an de ọjọ́ tí Jason yóò jí dìde! Yóò wò yí ká, yóò sì rí Párádísè tó ti ń yàn hànhàn fún. . . . Yóò yá àwa táa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lórí láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú.” Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sì wá wò báa ṣe lè kún fún ọpẹ́ tó pé ìrètí àjíǹde dájú!
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde ṣe lè ṣàǹfààní fún wa?
• Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fún wa ní ìdí láti ní ìrètí àjíǹde?
• Èé ṣe táa fi lè sọ pé ìrètí tó ti wà tipẹ́ ni àjíǹde?
• Ìrètí tí ń gbéni ró wo la lè ní nípa àwọn òkú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Pẹ̀lú agbára látọ̀dọ̀ Jèhófà, Èlíjà dá ìwàláàyè ọmọdékùnrin opó kan padà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Nígbà tí Jésù jí ọmọbìnrin Jáírù dìde sí ìyè, àwọn òbí rẹ̀ kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe nítorí ayọ̀ yẹn pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù fi tìgboyàtìgboyà jẹ́rìí pé a ti jí Jésù dìde nínú òkú