Ìwọ Ha Ń gbé Ìgbésí Ayé Fún Òní Tàbí Fún Ọjọ́ Ọ̀la Ayérayé?
“A gbà wá là nínú ìrètí yìí.”—RÓÒMÙ 8:24.
1. Kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Epikúréì fi ń kọ́ni, báwo sì ni irú ọgbọ́n èrò orí bẹ́ẹ̀ ṣe nípa lórí àwọn Kristẹni kan?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí ń gbé ní Kọ́ríńtì pé: “Èé ti rí tí àwọn kan láàárín yín fi ń wí pé kò sí àjíǹde àwọn òkú?” (Kọ́ríńtì Kíní 15:12) Ó ṣe kedere pé, ọgbọ́n èrò orí aṣekúpani ti Epikúréì, amòye Gíríìkì náà, ti wọ àárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù pé àfiyèsí sí ẹ̀kọ́ Epikúréì náà pé: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ kí á sì máa mu, nítorí ní ọ̀la àwa yóò kú.” (Kọ́ríńtì Kíní 15:32) Ní fífojú ẹ̀gàn wo ìrètí èyíkéyìí nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, àwọn ọmọlẹ́yìn ọlọ́gbọ́n èrò orí náà gbà gbọ́ pé ìgbádùn ara ẹni ni àǹfààní kan ṣoṣo tàbí olórí àǹfààní nínú ìgbésí ayé. (Ìṣe 17:18, 32) Ọgbọ́n èrò orí Epikúréì jẹ́ ti anìkànjọpọ́n, afòfíntótó ṣàríwísí, àti èyí tí ń bani jẹ́ pátápátá.
2. (a) Èé ṣe tí ó fi léwu púpọ̀ láti sọ pé kò sí àjíǹde? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì lókun?
2 Àìgbàgbọ́ nínú àjíǹde yìí ní ìyọrísí tí ó burú gan-an. Pọ́ọ̀lù ronú pé: “Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tí ì gbé Kristi dìde. Ṣùgbọ́n bí a kò bá tí ì gbé Kristi dìde, dájúdájú asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa. . . . Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni a ní láti káàánú fún jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.” (Kọ́ríńtì Kíní 15:13-19) Bẹ́ẹ̀ ni, láìsí ìrètí ọjọ́ ọ̀la ayérayé, ẹ̀sìn Kristẹni yóò jẹ́ “asán.” Kì yóò ní ète kankan. Abájọ nígbà náà tí ìjọ Kọ́ríńtì fi di ibi tí ìṣòro ti ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, lábẹ́ agbára èrò abọ̀rìṣà yí. (Kọ́ríńtì Kíní 1:11; 5:1; 6:1; 11:20-22) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù ní in lọ́kàn láti fún ìgbàgbọ́ wọn nínú àjíǹde lókun. Ní lílo ìrònú lílágbára, àwọn àyọlò inú Ìwé Mímọ́, àti àwọn àkàwé, ó fẹ̀rí hàn láìsí iyè méjì èyíkéyìí pé ìrètí àjíǹde kì í ṣe àròsọ bí kò ṣe òtítọ́ gidi tí yóò nímùúṣẹ dájúdájú. Lórí ìpìlẹ̀ yí, ó ṣeé ṣe fún un láti rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—Kọ́ríńtì Kíní 15:20-58.
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”
3, 4. (a) Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ti sọ, ẹ̀mí ìrònú eléwu wo ni àwọn kan yóò ní ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? (b) Kí ni ó yẹ kí a máa rán ara wa létí nígbà gbogbo?
3 Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ẹ̀mí ìrònú tibitire-la-dálé-ayé, ti màá-jayé-òní. (Éfésù 2:2) Bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an ni ó rí. Ó sọ nípa ‘àwọn olùyọṣùtì pẹ̀lú ìyọṣùtì wọn, tí wọ́n ń wí pé: “Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí náà dà? Họ́wù, láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá wa ti sùn nínú ikú, ohun gbogbo ń bá a lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá.”’ (Pétérù Kejì 3:3, 4) Bí àwọn olùjọsìn tòótọ́ bá gbà pẹ̀lú irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀, wọ́n lè di “aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso.” (Pétérù Kejì 1:8) Ó dùn mọ́ni pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí.
4 Kò sí ohun tí ó burú láti nífẹ̀ẹ́ sí òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí tí ń bọ̀. Rántí ọkàn ìfẹ́ tí àwọn àpọ́sítélì Jésù gan-an fi hàn: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba pa dà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yìí bí?” Jésù fèsì pé: “Kì í ṣe tiyín láti mọ àwọn àkókò tàbí àsìkò tí Bàbá ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:6, 7) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gbé kókó pàtàkì ìhìn iṣẹ́ tí ó sọ ní orí Òkè Ólífì jáde pé: “Ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. . . . Ní wákàtí tí ẹ̀yin kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọkùnrin ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:42, 44) Ó ṣe pàtàkì pé kí a máa rán ara wa létí ìmọ̀ràn yẹn! A lè fi ẹ̀mí ìrònú náà pé, ‘Bóyá kí n tilẹ̀ rẹ̀ ẹ́ lẹ̀ díẹ̀ ná, kí n má fi nǹkan ni ara mi lára,’ dẹ àwọn kan wò. Ẹ wo irú àṣìṣe ńlá tí èyí yóò jẹ́! Ronú nípa Jákọ́bù àti Jòhánù, “àwọn Ọmọkùnrin Ààrá.”—Máàkù 3:17.
5, 6. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni a lè rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Jákọ́bù àti Jòhánù?
5 A mọ̀ pé Jákọ́bù jẹ́ àpọ́sítélì onítara gidigidi. (Lúùkù 9:51-55) Ó ti ní láti kó ipa aláápọn ní gbàrà tí a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jákọ́bù kò tí ì dàgbà púpọ̀, Hẹ́rọ́dù Ágírípà I ṣekú pa á. (Ìṣe 12:1-3) A ha rò pé, bí Jákọ́bù ti ń rí i tí ẹ̀mí rẹ̀ fẹ́ pin láìròtẹ́lẹ̀, yóò banú jẹ́ pé òun ti jẹ́ onítara, pé òun ti tiraka gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí? Rárá o! Dájúdájú, inú rẹ̀ dùn pé òun ti lo èyí tí ó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé òun tí kò gùn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nísinsìnyí, kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ó lè mọ̀ bóyá ìgbésí ayé wa yóò dópin láìròtẹ́lẹ̀. (Oníwàásù 9:11; fi wé Lúùkù 12:20, 21.) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa bá ìtara gbígbóná janjan àti ìgbòkègbodò wa lọ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ní ọ̀nà yí, a óò lè pa orúkọ rere tí a ti ṣe pẹ̀lú rẹ̀ mọ́, a óò sì lè máa bá ìgbésí ayé wa lọ pẹ̀lú ọjọ́ ọ̀la wa ayérayé lọ́kàn.—Oníwàásù 7:1.
6 A lè rí ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ó jọra kọ́ nínú ọ̀ràn àpọ́sítélì Jòhánù, tí ó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù rọni lọ́nà gbígbóná janjan pé, “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mátíù 25:13; Máàkù 13:37; Lúùkù 21:34-36) Jòhánù fi ìmọ̀ràn náà sọ́kàn, ní fífi ìtara ṣiṣẹ́ sìn fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Ní ti gidi, ó jọ bíi pé ó pẹ́ láyé ju gbogbo àwọn àpọ́sítélì yòó kù lọ. Nígbà tí Jòhánù ti darúgbó, tí ó ṣeé ṣe fún un láti bojú wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ìgbòkègbodò àfòtítọ́ṣe rẹ̀, ó ha kà á sí àṣìṣe, ìgbésí ayé tí a kò lò lọ́nà rere tàbí tí kò wà déédéé bí? Rárá o! Ó ṣì ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún ọjọ́ iwájú. Nígbà tí Jésù tí a jí dìde sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni; mo ń bọ̀ kíákíá,” Jòhánù fèsì kíákíá pé, “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” (Ìṣípayá 22:20) Dájúdájú, Jòhánù kò gbé ìgbésí ayé fún òní, ní yíyán hànhàn fún ‘ìgbésí ayé tí ó sẹ́lẹ́ńkẹ́jọ̀’ onígbẹdẹmukẹ, oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ó ti pinnu láti máa bá a lọ ní fífi gbogbo ìgbésí ayé àti okun rẹ̀ sìn, títí dìgbà tí Olúwa yóò fi dé. Àwa ńkọ́?
Ìpìlẹ̀ fún Gbígbàgbọ́ Nínú Ìyè Àìnípẹ̀kun
7. (a) Báwo ni a ṣe “ṣèlérí” ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun “ṣáájú àwọn àkókò pípẹ́ títí”? (b) Báwo ni Jésù ṣe tànmọ́lẹ̀ sórí ìrètí ìyè ayérayé?
7 Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun kì í ṣe àlá tí ẹnì kan lá tàbí èrò tí ẹnì kan gbé kalẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Títù 1:2 ti sọ, a gbé ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run tí a ní karí “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí ṣáájú àwọn àkókò pípẹ́ títí.” Ó jẹ́ ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn láti wà láàyè títí láé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Kò sí ohunkóhun tí ó lè sojú ète yìí dé, kì í tilẹ̀ ṣe ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, lójú ẹsẹ̀ ni Ọlọ́run ṣèlérí “irú-ọmọ” kan tí yóò ṣàtúnṣe gbogbo ìpalára tí a ti mú wá bá aráyé. Nígbà tí “irú-ọmọ” tàbí Mèsáyà náà, Jésù, dé, ó sọ ìrètí ìyè ayérayé di ọ̀kan lára òpó ẹ̀kọ́ rẹ̀. (Jòhánù 3:16; 6:47, 51; 10:28; 17:3) Nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà, Kristi gba ẹ̀tọ́ òfin láti fi ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí aráyé. (Mátíù 20:28) Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 144,000 lápapọ̀, yóò gbé títí láé nínú àwọn ọ̀run. (Ìṣípayá 14:1-4) Nípa báyìí, àwọn kan tí wọ́n ti jẹ́ àwọn ènìyàn kíkú tẹ́lẹ̀ yóò “gbé àìkú wọ̀”!—Kọ́ríńtì Kíní 15:53.
8. (a) Kí ni “àìkú,” èé sì ti ṣe tí Jèhófà fi jíǹkí àwọn 144,000? (b) Ìrètí wo ni Jésù nawọ́ rẹ̀ jáde sí “àwọn àgùntàn míràn”?
8 “Àìkú” ju ṣíṣàìkú láé lọ. Ó ní í ṣe pẹ̀lú “agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run.” (Hébérù 7:16; fi wé Ìṣípayá 20:6.) Ṣùgbọ́n, kí ni Ọlọ́run ṣàṣepé rẹ̀ nípa fífúnni ní irú ẹ̀bùn gígọntiọ bẹ́ẹ̀? Rántí ìpèníjà Sátánì pé, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀dá Ọlọ́run tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Nípa fífún 144,000 ní àìkú, Ọlọ́run fi hàn pé òun ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú ẹgbẹ́ yìí, tí ó ti pèsè ìdáhùn títayọ lọ́lá sí ìpèníjà Sátánì. Ṣùgbọ́n, aráyé yòó kù ńkọ́? Jésù sọ fún àwọn mẹ́ńbà àkọ́kọ́ “agbo kékeré” ti àjògún Ìjọba yìí pé, wọn yóò “jókòó lórí àwọn ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 12:32; 22:30) Èyí dọ́gbọ́n fi hàn pé àwọn mìíràn yóò gba ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀. Bí a kò tilẹ̀ fún “àwọn àgùntàn míràn” wọ̀nyí ní àìkú, wọ́n gba “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:46) Nípa báyìí, ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ìrètí gbogbo Kristẹni. Kì í ṣe àlá asán bí kò ṣe ohun kan tí “Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́” ti ṣèlérí lọ́nà tí ń fini lọ́kàn balẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀jẹ̀ iyebíye Jésù rà.—Títù 1:2.
Ní Ọjọ́ Iwájú Jíjìnnà Ha Ni Bí?
9, 10. Àwọn ẹ̀rí tí ó ṣe kedere wo ni ó wà pé a ti sún mọ́ òpin?
9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ pé “àwọn àkókò líle koko tí ó nira láti bá lò” yóò fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” láìṣeéjá ní koro. Bí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó yí wa ká ti ń ṣubú sínú ipò àìnífẹ̀ẹ́, ìwọra, ìtẹ́fẹ̀ẹ́-ọkàn-ẹni-lọ́rùn, àti àìníwà-bí-Ọlọ́run, àwa kò ha mọ̀ pé ọjọ́ tí Jèhófà yóò mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ètò ìgbékalẹ̀ ayé búburú yìí ti ń yára sún mọ́lé? Bí ìwà ipá àti ìkórìíra ti ń gbilẹ̀ sí i, a kò ha rí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ síwájú sí i pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù” láyìíká wa bí? (Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Àwọn kan lè pariwo “Àlàáfíà àti ààbò,” lọ́nà tí ń fi hàn pé wọ́n ń fojú sọ́nà fún rere, ṣùgbọ́n gbogbo ìrètí fún àlàáfíà yóò pòórá, nítorí “ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìrora gógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yóò sì yè bọ́ lọ́nàkọnà.” A kò fi wá sínú òkùnkùn nípa ìtumọ̀ ọjọ́ wa. Nítorí náà, “ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò kí a sì pa agbára ìmòye wa mọ́.”—Tẹsalóníkà Kíní 5:1-6.
10 Síwájú sí i, Bíbélì fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn jẹ́ “sáà àkókò kúkúrú.” (Ìṣípayá 12:12; fi wé 17:10.) Ó ṣe kedere pé èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú “àkókò kúkúrú” náà ti kọjá. Fún àpẹẹrẹ, àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì ṣàpèjúwe ìforígbárí tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù,” tí ó ti nasẹ̀ dé ọ̀rúndún yìí lọ́nà pípéye. (Dáníẹ́lì 11:5, 6) Ìkọlù àṣekágbá tí “ọba àríwá” yóò ṣe, tí a ṣàpèjúwe nínú Dáníẹ́lì 11:44, 45, ni ohun tí ó kù láti ní ìmúṣẹ.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà July 1, 1987, àti November 1, 1993, fún ìjíròrò lórí àsọtẹ́lẹ̀ yí.
11. (a) Ìwọ̀n wo ni Mátíù 24:14 ti nímùúṣẹ dé? (b) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù 10:23 fi hàn?
11 Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù pé “a óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé,” tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Mátíù 24:14) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ wọn ní ilẹ̀, erékùṣù, àti ìpínlẹ̀ 233. Òtítọ́ ni pé àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò tí ì ṣiṣẹ́ nínú wọn ṣì ń bẹ, bóyá tí ó bá sì tó àkókò lójú Jèhófà, ilẹ̀kùn àǹfààní yóò ṣí sílẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 16:9) Síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù 10:23 pé: “Ẹ kì yóò parí àlọyíká àwọn ìlú ńlá Ísírẹ́lì lọ́nàkọnà títí Ọmọkùnrin ènìyàn yóò fi dé,” ń múni ronú jinlẹ̀. Bí ó tilẹ̀ dájú pé a óò kéde ìhìn rere jákèjádò ayé, a kò ní fúnra wa mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé kí Jésù tó “dé” gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ.
12. (a) “Èdìdì” wo ni a tọ́ka sí nínú Ìṣípayá 7:3? (b) Kí ni ìjẹ́pàtàkì dídín tí iye àwọn ẹni àmì òróró ń dín kù lórí ilẹ̀ ayé?
12 Ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú Ìṣípayá 7:1, 3, tí ó sọ pé, a sé “ẹ̀fúùfù mẹ́rin” aṣèparun mọ́ “títí di ẹ̀yìn ìgbà tí a bá fi èdìdì di àwọn ẹrú Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn.” Èyí kò tọ́ka sí èdìdì àkọ́kọ́, tí ó wáyé nígbà tí àwọn 144,000 gba ìpè wọn ti ọ̀run. (Éfésù 1:13) Ó ń tọ́ka sí èdìdì ìkẹyìn, nígbà tí a mọ̀ wọ́n pátápátá sí “ẹrú Ọlọ́run wa,” tí a ti dán wò, tí wọ́n sì dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́. Iye ojúlówó ọmọkùnrin Ọlọ́run tí a fòróró yàn, tí ó ṣì wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, túbọ̀ ń dín kù sí i gidigidi. Síwájú sí i, Bíbélì sọ ní kedere pé, ó jẹ́ “ní tìtorí àwọn àyànfẹ́” ni a óò ṣe ké apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá “kúrú.” (Mátíù 24:21, 22) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ẹni àmì òróró jẹ́ arúgbó. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èyí kò ha fi hàn pé òpin ti sún mọ́lé bí?
Olùṣòtítọ́ Olùṣọ́
13, 14. Kí ni ẹrù iṣẹ́ ẹgbẹ́ olùṣọ́?
13 Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, yóò dára bí a bá kọbi ara sí ìtọ́sọ́nà tí ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ ń pèsè fún wa. (Mátíù 24:45) Fún èyí tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún, “ẹrú” òde òní náà ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “olùṣọ́.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 3:17-21) Ile-Iṣọ Naa ti July 1, 1984, ṣàlàyé pé: “Oluṣọ yii nkiyesi i bi awọn iṣẹlẹ ṣe nlọ lori ilẹ aye ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli, o kilọ nipa ìkùsi-dẹ̀dẹ̀ ‘ipọnju nla kan ti a ko ti i ri iru rẹ̀ ri lati igba ti aye ti ṣẹ̀’ ti o si nkede ‘ihinrere nipa ohun rere.’”—Mátíù 24:21; Aísáyà 52:7.
14 Rántí pé: Iṣẹ́ olùṣọ́ ni láti kéde “ohun tí ó rí.” (Aísáyà 21:6-8) Ní àkókò tí a kọ Bíbélì, olùṣọ́ máa ń ṣe ìkìlọ̀ àní nígbà tí òun kò tí ì rí ohun tó jọ bí ewu náà dáradára, tí ó ṣì jìnnà réré. (Àwọn Ọba Kejì 9:17, 18) Dájúdájú, wọ́n máa ń ṣe ìkìlọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún. Ṣùgbọ́n olùṣọ́ tí ó mọṣẹ́ níṣẹ́ kì yóò lọ́ tìkọ̀ láti ṣèkìlọ̀ nítorí ìbẹ̀rù ojútì. Bí ilé rẹ bá ń jó, báwo ni ìwọ yóò ṣe nímọ̀lára bí àwọn panápaná bá kọ̀ láti yọjú nítorí wọ́n rò pé, ó lè jẹ́ igbe ìkìlọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni? Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, a retí pé kí àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ dáhùn pa dà kánmọ́kánmọ́ sí àmì ewu èyíkéyìí! Ní ọ̀nà kan náà, ẹgbẹ́ olùṣọ́ ti sọ̀rọ̀ jáde nígbà tí àyíká ipò jọ bí èyí tí ó béèrè pé kí ó ṣe bẹ́ẹ̀.
15, 16. (a) Èé ṣe tí a fi ń ṣe àtúnṣe nínú òye tí a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀? (b) Kí ni a lè rí kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n ṣi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan lóye?
15 Ṣùgbọ́n bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń jẹyọ, òye tí a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ ti túbọ̀ ṣe kedere sí i. Ìtàn fi hàn pé, ó máa ń ṣọ̀wọ́n, bí ó bá tilẹ̀ wáyé rí, pé kí a lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá ní kíkún kí ó tó di pé wọ́n ní ìmúṣẹ. Ọlọ́run sọ fún Ábúrámù iye ọdún gan-an tí irú-ọmọ rẹ̀ yóò fi ṣe “àlejò ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn,” ìyẹn ni, fún 400 ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 15:13) Ṣùgbọ́n Mósè fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí olùdáǹdè láìpọ́jọ́.—Ìṣe 7:23-30.
16 Tún ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà. Ní ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá, ó jọ bíi pé ó ṣe kedere gan-an pé a sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú àti àjíǹde Mèsáyà. (Aísáyà 53:8-10) Síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gan-an kùnà láti lóye òtítọ́ yìí. (Mátíù 16:21-23) Wọn kò rí i pé Dáníẹ́lì 7:13, 14 yóò nímùúṣẹ nígbà pa·rou·siʹa, tàbí “wíwàníhìn-ín” Kristi lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 24:3) Nítorí náà, wọ́n fi ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún sáré síwájú nínú ìṣirò wọn, nígbà tí wọ́n bi Jésù pé: “Olúwa, ìwọ ha ń mú ìjọba pa dà bọ̀ sípò fún Ísírẹ́lì ní àkókò yí bí?” (Ìṣe 1:6) Àní lẹ́yìn ìgbà tí ìjọ Kristẹni ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin pàápàá, èrò tí ń ṣini lọ́nà àti ìfojúsọ́nà asán ń bá a lọ láti yọjú. (Tẹsalóníkà Kejì 2:1, 2) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan ń ní ojú ìwòye tí kò tọ̀nà, láìṣeé já ní koro, Jèhófà bù kún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn onígbàgbọ́ ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyẹn!
17. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àwọn àtúnṣe tí a ń ṣe nípa òye wa lórí Ìwé Mímọ́?
17 Lónìí bákan náà, ẹgbẹ́ olùṣọ́ ti ní láti mú kí ojú ìwòye rẹ̀ túbọ̀ ṣe kedere sí i lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n, ẹnikẹ́ni ha lè ṣiyè méjì pé Jèhófà ti bù kún ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà bí? Ìyẹn nìkan kọ́, bí a bá gbé e yẹ̀ wò láti inú àyíká ipò, àwọn àtúnṣe tí a ti ṣe kò ha kéré ní ìfiwéra bí? Pàtàkì òye wa nípa Bíbélì kò tí ì yí pa dà. Ìdánilójú tí a ni pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lágbára ju ti ìgbàkígbà rí lọ!
Gbígbé Ìgbésí Ayé fún Ọjọ́ Ọ̀la Ayérayé
18. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a yẹra fún gbígbé ìgbésí ayé fún òní nìkan?
18 Ayé lè sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a jẹ, kí a sì mu, nítorí a óò kú lọ́la,’ ṣùgbọ́n kò yẹ kí a ní irú ìṣarasíhùwà yí. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi làkàkà lórí asán láti jẹ gbogbo ìgbádùn tí o lè jẹ nínú ayé nísinsìnyí nígbà tí o lè ṣiṣẹ́ láti jèrè ọjọ́ ọ̀la ayérayé kan? Ìrètí yẹn, yálà ìyè àìkú nínú ọ̀run tàbí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, kì í ṣe àlá, kì í ṣe èrò tí ẹnì kan gbé kalẹ̀. Òtítọ́ gidi ni, tí Ọlọ́run “tí kò lè purọ́” ṣèlérí. (Títù 1:2) Ẹ̀rí pọ̀ jaburata pé ìmúṣẹ ìrètí wa ti sún mọ́lé! “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ti dín kù.”—Kọ́ríńtì Kíní 7:29.
19, 20. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìrúbọ ti a ti ṣe fún ire Ìjọba? (b) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a gbé ìgbésí ayé ní níní ayérayé lọ́kàn?
19 Òtítọ́ ni pé ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí ti pẹ́ ju bí ọ̀pọ̀ ti rò lọ. Àwọn díẹ̀ lè ronú nísinsìnyí pé, ká ní àwọn ti mọ̀ pé bí yóò ti pẹ́ tó nìyí, àwọn ì bá tí ṣe àwọn ìrúbọ kan tí àwọn ṣe. Ṣùgbọ́n, kò yẹ ki ẹnì kan kábàámọ̀ ṣíṣe tí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, ṣíṣe ìrúbọ jẹ́ apá pàtàkì jíjẹ́ Kristẹni. Àwọn Kristẹni máa ‘ń sẹ́ níní ara wọn.’ (Mátíù 16:24) A kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé àwọn ìsapá tí a ṣe láti wu Ọlọ́run ti já sí asán. Jésù ṣèlérí pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí bàbá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí . . . àti nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Máàkù 10:29, 30) Ní ẹgbẹ̀rún ọdún sí ìgbà tí a wà yí, báwo ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ, ilé rẹ, tàbí owó tí o ní ní báǹkì yóò ti wúlò tó? Síbẹ̀, àwọn ìrúbọ tí o ti ṣe fún Jèhófà yóò nítumọ̀ ní mílíọ̀nù ọdún sí ìgbà tí a wà yí—àní ní bílíọ̀nù ọdún sí ìgbà tí a wà yí pàápàá! “Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín.”—Hébérù 6:10.
20 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésí ayé ní níní ayérayé lọ́kàn, láìtẹ ojú wa “mọ́ àwọn ohun tí a ń rí, bí kò ṣe àwọn ohun tí a kò rí. Nítorí àwọn ohun tí a ń rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:18) Wòlíì Hábákúkù kọ̀wé pé: “Ìran náà ṣì jẹ́ fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, ó sì ń sáré lọ ní mímí hẹlẹhẹlẹ sí òpin, kì yóò sì purọ́. Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3, NW) Báwo ni ‘bíbá a nìṣó ní fífojú sọ́nà’ fún òpin ṣe kan ọ̀nà tí a ń gbà ṣe ojúṣe ara ẹni àti ti ìdílé wa? Àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí.
Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni jíjọ tí ó jọ pé òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí ń jáfara ṣe nípa lórí àwọn kan lónìí?
◻ Kí ni ìpìlẹ̀ tí a ní fún ìrètí ìyè ayérayé wa?
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àwọn ìrúbọ tí a ti ṣe fún ire Ìjọba?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A gbọ́dọ̀ ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé kí òpin tó dé