Ìrètí Àjíǹde Lágbára
“Èmi ti gba àdánù ohun gbogbo . . . láti lè mọ [Jésù Kristi] àti agbára àjíǹde rẹ̀.”—FÍLÍPÌ 3:8-10.
1, 2. (a) Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, báwo ni àlùfáà kan ṣe ṣàpèjúwe àjíǹde? (b) Báwo ni àjíǹde yóò ṣe rí?
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ àwọn ọdún 1890, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìwàásù kan tó ṣàjèjì tí àlùfáà kan ṣe ní Brooklyn, New York, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó sọ pé ohun tí àjíǹde ní nínú ni kíkó gbogbo egungun àti ẹran ara tó ti fìgbà kan para pọ̀ jẹ́ ara ènìyàn rí jọ, kí wọ́n sì mú wọn sọ jí, yálà àwọn èyí tí iná jó tàbí àwọn tí jàǹbá ọkọ̀ pa, èyí tí ẹranko búburú pa jẹ tàbí àwọn tó ti di ajílẹ̀. Oníwàásù náà là á mọ́lẹ̀ pé ní ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún kan, ibi gbogbo yóò kún tìrìgàngàn fún àwọn ọwọ́, apá, ẹsẹ̀, ìka, egungun, iṣan, àti awọ ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn òkú. Àwọn ẹ̀yà ara wọ̀nyí yóò máa wá àwọn ẹ̀yà tó kù tí wọ́n jọ jẹ́ ara kan náà kiri. Àwọn ọkàn yóò wáá wá láti ọ̀run rere àti ọ̀run àpáàdì láti kó wọnú àwọn ara tí a jí dìde wọ̀nyí.
2 Àjíǹde tí yóò ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ kíkó àwọn átọ́ọ̀mù ìpilẹ̀ṣẹ̀ jọ kò mọ́gbọ́n dání rárá, àwọn èèyàn ò sì ní ọkàn kan tí kò lè kú. (Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Jèhófà, Ọlọ́run àjíǹde, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní máa kó àwọn átọ́ọ̀mù tó ti fìgbà kan para pọ̀ jẹ́ ara ènìyàn jọ. Ó lè fún àwọn tó jí dìde ní ara tuntun. Jèhófà ti fún Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi ní agbára láti jí àwọn òkú dìde, àti pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 5:26) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:25, 26) Ìlérí amọ́kànyọ̀ mà lèyí o! Ó fún wa lókun láti fara da àdánwò àti láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà, àní dójú ikú.
3. Èé ṣe tí ó fi di dandan kí Pọ́ọ̀lù gbèjà àjíǹde?
3 Àjíǹde kò bá èrò pé àwọn ènìyàn ní ọkàn kan tí kò lè kú mu rárá—ìyẹn ni, èrò kan tí onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì nì, Plato, ní. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí fún àwọn lóókọlóókọ Gíríìkì tó wà ní Áréópágù ní Áténì, tó tọ́ka sí Jésù, tó sì sọ pé Ọlọ́run jí i dìde? Ìtàn náà sọ pé: “Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹlẹ́yà.” (Ìṣe 17:29-34) Láìka ìfiniṣẹ̀sín náà sí, ọ̀pọ̀ tó rí Jésù Kristi tí ó jíǹde náà ṣì wà láàyè nígbà yẹn, wọ́n sì jẹ́rìí sí i pé a ti jí i dìde kúrò nínú òkú. Àmọ́, àwọn olùkọ́ èké tó ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì sẹ́ àjíǹde náà. Pọ́ọ̀lù wá gbèjà ẹ̀kọ́ Kristẹni yìí lọ́nà tó lágbára nínú Kọ́ríńtì Kìíní, Orí Karùndínlógún. Táa bá fara balẹ̀ ka àwọn ìjiyàn rẹ̀, a óò rí i pé ó jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro nípa bí ìrètí àjíǹde ṣe dájú tó sì lágbára tó.
Ẹ̀rí Lílágbára Nípa Àjíǹde Jésù
4. Ẹ̀rí wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ nípa àwọn tó fojú rí àjíǹde Jésù?
4 Kíyè sí bí Pọ́ọ̀lù ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbèjà rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:1-11) Tí kì í bá ti ń ṣe pé àwọn ará Kọ́ríńtì kàn di onígbàgbọ́ lásán, ó yẹ kí wọ́n di ìhìn rere ìgbàlà mú ṣinṣin. Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, a sin ín, ó sì jí dìde. Ní ti tòótọ́, Jésù tó jíǹde náà fara han Kéfà (Pétérù), “lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà.” (Jòhánù 20:19-23) Àwọn bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn ló rí i, bóyá nígbà tó ń pàṣẹ pé: ‘Ẹ lọ máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mátíù 28:19, 20) Jákọ́bù rí i, bí gbogbo àpọ́sítélì tòótọ́ ṣe rí i. (Ìṣe 1:6-11) Nítòsí Damásíkù, Jésù fara han Sọ́ọ̀lù “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó”—bí ẹni pé a ti jí i dìde sí ìyè ti ẹ̀mí. (Ìṣe 9:1-9) Àwọn ará Kọ́ríńtì di onígbàgbọ́ nítorí pé Pọ́ọ̀lù wàásù fún wọn, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà.
5. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà ronú gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú 1 Kọ́ríńtì 15:12-19?
5 Kíyè sí ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà ronú. (1 Kọ́ríńtì 15:12-19) Níwọ̀n ìgbà tí àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn ti wàásù pé Kristi jíǹde, báwo làwọn kan ṣe lè wá máa sọ pé kò sí àjíǹde? Bí Jésù kò bá jí dìde kúrò nínú òkú, a jẹ́ pé asán ni ìwàásù àti ìgbàgbọ́ wa, a jẹ́ pé òpùrọ́ ni wá, tó ń jẹ́rìí irọ́ mọ́ Ọlọ́run pé ó jí Kristi dìde. Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, ‘a ṣì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa,’ àwọn tó sì kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ti ṣègbé. Láfikún sí i, “bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.”
6. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ láti fìdí àjíǹde Jésù múlẹ̀? (b) Kí ni “ọ̀tá ìkẹyìn,” báwo la ó sì ṣe sọ ọ́ di asán?
6 Pọ́ọ̀lù fìdí àjíǹde Jésù múlẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:20-28) Nígbà tó ti jẹ́ pé Kristi ni “àkọ́so” nínú gbogbo àwọn tó sùn nínú ikú, àwọn tó kù náà yóò ní àjíǹde. Níwọ̀n bí ikú ti wá láti inú àìgbọ́ràn ọkùnrin náà, Ádámù, àjíǹde jẹ́ nípasẹ̀ ọkùnrin kan—Jésù. A óò jí àwọn tó jẹ́ tirẹ̀ dìde nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀. Kristi sọ “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán,” gbogbo àwọn tó lòdì sí ipò ọba-aláṣẹ ti Ọlọ́run, ó sì ń ṣàkóso bí Ọba títí Jèhófà yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Kódà “ọ̀tá ìkẹyìn”—ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù—ni a ó sọ di asán nípasẹ̀ ìtóye ẹbọ Jésù. Nígbà náà ni Kristi yóò wá dá Ìjọba náà padà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀, nípa fífi ara rẹ̀ sábẹ́ “Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”
Batisí fún Òkú Kẹ̀?
7. Àwọn wo la “ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú,” kí ni èyí sì túmọ̀ sí fún wọn?
7 A béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣòdì sí àjíǹde pé: “Kí ni àwọn tí a ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú yóò ṣe?” (1 Kọ́ríńtì 15:29) Kì í ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé kí a batisí àwọn alààyè nítorí àwọn òkú, nítorí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ fúnra wọn kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n gbà gbọ́, kí wọ́n sì ṣe batisí. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 2:41) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni a “ń batisí fún ète jíjẹ́ òkú” nípa ríri ara wọn bọ ọ̀nà ìgbésí ayé kan tí yóò yọrí sí ikú àti àjíǹde. Irú ìbatisí yìí máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá fi ìrètí òkè ọ̀run sí wọn lọ́kàn, á sì dópin nígbà tí a bá jí wọn kúrò nínú ikú sínú ìyè àìleèkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run.—Róòmù 6:3-5; 8:16, 17; 1 Kọ́ríńtì 6:14.
8. Kí ló yẹ kó dá àwọn Kristẹni lójú, kódà bí Sátánì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tilẹ̀ pa wọ́n?
8 Bí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, ìrètí àjíǹde ló ń mú kí àwọn Kristẹni lè fara dà á, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu ń wu wọ́n láti wákàtí dé wákàtí, tí ikú sì ń fẹjú mọ́ wọn lójoojúmọ́ nítorí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí wọ́n ń ṣe. (1 Kọ́ríńtì 15:30, 31) Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà lè jí wọn dìde tó bá fàyè gba Sátánì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n. Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè pa ọkàn, ìyẹn, ìwàláàyè wọn run ní Gẹ̀hẹ́nà, tó túmọ̀ sí ìparun ayérayé.—Lúùkù 12:5.
A Gbọ́dọ̀ Wà Lójúfò
9. Bí ìrètí àjíǹde bá máa gbé ẹ̀mí wa ró, kí la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
9 Ìrètí àjíǹde gbé Pọ́ọ̀lù ró. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti jù ú sínú pápá ìṣeré láti bá àwọn ẹranko búburú jà nígbà tó wà ní Éfésù. (1 Kọ́ríńtì 15:32) Tíyẹn bá ti ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé bí a ṣe gba Dáníẹ́lì kúrò lọ́wọ́ kìnnìún la ṣe gba òun náà. (Dáníẹ́lì 6:16-22; Hébérù 11:32, 33) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù ní ìrètí àjíǹde, kò ní ìṣarasíhùwà tí àwọn apẹ̀yìndà Júdà ní ní ọjọ́ Aísáyà. Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (Aísáyà 22:13 Septuagint) Bí ìrètí àjíǹde bá máa gbé ẹ̀mí wa ró bó ṣe gbé ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù ró, a gbọ́dọ̀ yẹra fún níní irú ẹ̀mí burúkú bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àmọ́ ṣá o, onírúurú apá ìgbésí ayé ni ìlànà yìí kàn.
10. Báwo ni ìrètí àjíǹde táa ní ṣe lè dúró sán-ún lọ́kàn wa?
10 Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tó ń ṣe iyèméjì nípa àjíǹde pé: “Ẹ jí sí orí pípé lọ́nà òdodo, ẹ má sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, nítorí àwọn kan wà láìní ìmọ̀ nípa Ọlọ́run. Mo ń sọ̀rọ̀ láti sún yín sí ìtìjú.” (1 Kọ́ríńtì 15:34) Ní “àkókò òpin” yìí, a ní láti gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípé nípa Ọlọ́run àti nípa Kristi. (Dáníẹ́lì 12:4; Jòhánù 17:3) Èyí ni yóò jẹ́ kí ìrètí àjíǹde dúró sán-ún lọ́kàn wa.
Àjíǹde Pẹ̀lú Ara Wo?
11. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?
11 Pọ́ọ̀lù wá gbé àwọn ìbéèrè bíi mélòó kan yẹ̀ wò tẹ̀ lé e. (1 Kọ́ríńtì 15:35-41) Bóyá nítorí àtigbé iyèméjì dìde nípa àjíǹde, ẹnì kan lè máa wádìí pé: “Báwo ni a ó ṣe gbé àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?” Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn, irúgbìn tí a gbìn sínú ilẹ̀ kọ́kọ́ máa ń kú bí ó ti ń para dà láti di èéhù. Bákan náà, ẹnì kan tí a fi ẹ̀mí bí gbọ́dọ̀ kú. Gan-an gẹ́gẹ́ bí irúgbìn ṣe máa ń para dà di ohun ọ̀gbìn tó ní ara tuntun, bẹ́ẹ̀ náà ni ara àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a jíǹde ṣe yàtọ̀ sí ẹran ara ẹ̀dá ènìyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní bátànì ìwàláàyè tó ní kó tó kú, síbẹ̀, a jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá tuntun pẹ̀lú ara tẹ̀mí, tí ó lè gbé ní ọ̀run. Báa ṣe lè retí, àwọn tí yóò jíǹde sórí ilẹ̀ ayé yóò ní ara ẹ̀dá ènìyàn.
12. Kí ni gbólóhùn náà “àwọn ara ti ọ̀run” àti “àwọn ara ti ilẹ̀ ayé” túmọ̀ sí?
12 Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ, ẹran ara ènìyàn yàtọ̀ sí ti ẹranko. Kódà ẹran ara ẹranko yàtọ̀ síra láti irú kan sí irú mìíràn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:20-25) “Àwọn ara ti ọ̀run” yàtọ̀ ní ògo sí “àwọn ara ti ilẹ̀ ayé” tó jẹ́ ẹlẹ́ran ara. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyàtọ̀ tún wà nínú ògo ti oòrùn, òṣùpá, àti ti àwọn ìràwọ̀. Àmọ́ àwọn ẹni àmì òróró tí a jí dìde ní ògo tó ga gan-an ju ìwọ̀nyí lọ.
13. Ní ìbámu pẹ̀lú 1 Kọ́ríńtì 15:42-44, kí la gbìn, kí la sì gbé dìde?
13 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀, ó fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni àjíǹde àwọn òkú.” (1 Kọ́ríńtì 15:42-44) Ó sọ pé: “A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́, a sì gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.” Ó lè jẹ́ àwọn ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn níhìn-ín. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́ nígbà tí ó kú, a gbé e dìde sí àìdíbàjẹ́, tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ta á lábùkù, a gbé e dìde sí ìyè ti ọ̀run, a sì fí i hàn kedere pẹ̀lú Kristi nínú ògo. (Ìṣe 5:41; Kólósè 3:4) Nígbà tí ó kú, a gbìn ín ní “ara ìyára,” a sì gbé e dìde ní “ara ti ẹ̀mí.” Níwọ̀n bí èyí tí ṣeé ṣe nínú ọ̀ràn ti àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí bí, a lè ní ìdánilójú pé a lè gbé àwọn mìíràn náà dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé.
14. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín Kristi àti Ádámù hàn?
14 Pọ́ọ̀lù wá fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín Kristi àti Ádámù hàn. (1 Kọ́ríńtì 15:45-49) Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, “di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) “Ádámù ìkẹyìn”—Jésù—“di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.” Ó fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà, fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró lákọ̀ọ́kọ́. (Máàkù 10:45) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n “gbé àwòrán ẹni tí a fi ekuru dá wọ̀,” àmọ́ nígbà tí wọ́n bá jíǹde, wọ́n á wá dà bí Ádámù ìkẹyìn. Àmọ́ ṣá o, ẹbọ Jésù yóò ṣàǹfààní fún gbogbo ìran ènìyàn onígbọràn, títí kan àwọn tí a óò jí dìde sórí ilẹ̀ ayé.—1 Jòhánù 2:1, 2.
15. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò fi ní jíǹde sínú ẹran ara, báwo ni wọ́n sì ṣe dìde ní àkókò wíwàníhìn-ín Jésù?
15 Nígbà tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá kú, wọn ò ní jí dìde bí ẹlẹ́ran ara. (1 Kọ́ríńtì 15:50-53) Ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ tí ó ti díbàjẹ́ kò lè jogún àìdíbàjẹ́ àti Ìjọba ọ̀run. Àwọn ẹni àmì òróró kan kò ní sùn pẹ́ nínú oorun ikú. Bí wọ́n bá ṣe ń fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò wíwàníhìn-ín Jésù ni wọ́n máa “yí . . . padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́.” Wọn ó dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí ìyè ti ẹ̀mí nínú àìdíbàjẹ́ àti ògo. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, “aya” Kristi ti ọ̀run yóò pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì.—Ìṣípayá 14:1; 19:7-9; 21:9; 1 Tẹsalóníkà 4:15-17.
Ìṣẹ́gun Lórí Ikú!
16. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn wòlíì ìṣáájú sọ, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀?
16 Tayọ̀tayọ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi polongo pé a óò gbé ikú mì títí láé. (1 Kọ́ríńtì 15:54-57) Nígbà tí ara ìdíbàjẹ́ àti kíkú bá gbé àìdíbàjẹ́ àti àìkú wọ̀, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí yóò wá ní ìmúṣẹ pé: “A ti gbé ikú mì títí láé.” “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?” (Aísáyà 25:8; Hóséà 13:14) Ìtani tí ń fa ikú ni ẹ̀ṣẹ̀, agbára ẹ̀ṣẹ̀ sì ni Òfin, tí ń mú kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ̀bi ikú. Ṣùgbọ́n nítorí ẹbọ àti àjíǹde Jésù, ikú tí a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kò ní jẹ́ aṣẹ́gun mọ́.—Róòmù 5:12; 6:23.
17. Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ inú 1 Kọ́ríńtì 15:58 kàn lóde òní?
17 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kan àwọn ìyókù ẹni àmì òróró àtàwọn tó jẹ́ “àgùntàn mìíràn” ti Jésù, kódà bí wọ́n tilẹ̀ kú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. (Jòhánù 10:16) Òpò wọn gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà kì í ṣe asán, nítorí pé àjíǹde ń dúró dè wọ́n. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú ṣíṣe iṣẹ́ Olúwa báa ti ń dúró de ọjọ́ tí a ó fayọ̀ ké jáde pé: “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà?”
Ìrètí Àjíǹde Nímùúṣẹ!
18. Báwo ni ìrètí Pọ́ọ̀lù nínú àjíǹde ṣe lágbára tó?
18 Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù táa kọ́ sínú Kọ́ríńtì Kìíní, Orí Kẹẹ̀ẹ́dógún mú un ṣe kedere pé ìrètí àjíǹde lágbára nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó dá a lójú hán-únhán-ún pé a jí Jésù dìde kúrò nínú òkú, àti pé a ó jọ̀wọ́ àwọn òkú yòókù kúrò nínú sàréè gbogbo aráyé. Ǹjẹ́ o ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù ka gbogbo èrè onímọtara ẹni nìkan sí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí,” ó sì “gba àdánù ohun gbogbo” kí ó lè ‘mọ Kristi àti agbára àjíǹde rẹ̀.’ Àpọ́sítélì náà ṣe tán láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún irú ikú tí Kristi kú pẹ̀lú ìrètí àtirí “àjíǹde àkọ́kọ́.” A tún pè é ní “àjíǹde èkíní,” èyí tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù ní. Dájúdájú, a óò gbé wọn dìde sí ìyè ti ẹ̀mí ní ọ̀run, nígbà tó jẹ́ pé “ìyókù àwọn òkú” ni a óò jí dìde sórí ilẹ̀ ayé.—Fílípì 3:8-11; Ìṣípayá 7:4; 20:5, 6.
19, 20. (a) Àwọn wo ló wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì tí a óò jí dìde sí ìyè lórí ilẹ́ ayé? (b) Àjíǹde àwọn wo lò ń fojú sọ́nà fún?
19 Ìrètí àjíǹde ti ní ìmúṣẹ ológo fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ títí dé ojú ikú. (Róòmù 8:18; 1 Tẹsalóníkà 4:15-18; Ìṣípayá 2:10) Àwọn tó bá la “ìpọ́njú ńlá náà” já yóò rí ìmúṣẹ ìrètí àjíǹde lórí ilẹ̀ ayé bí ‘òkun tí ń jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, tí ikú àti Hédíìsì sì ń jọ̀wọ́ àwọn tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.’ (Ìṣípayá 7:9, 13, 14; 20:13) Jóòbù, tó fojú winá ikú ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta, yóò wà lára àwọn tí a óò jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó láti kí wọn káàbọ̀—àti bí inú àwọn náà yóò ṣe dùn tó pé àwọn ti ní arákùnrin méje àti arábìnrin rírẹwà mẹ́ta mìíràn sí i!—Jóòbù 1:1, 2, 18, 19; 42:12-15.
20 Ẹ wo ìbùkún ńláǹlà tí yóò jẹ́, nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà, Ísákì àti Rèbékà—àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn mìíràn, títí kan “gbogbo àwọn wòlíì”—bá jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé! (Lúùkù 13:28) Ọ̀kan lára irú àwọn wòlíì bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì, tí a ṣèlérí fún pé yóò jíǹde lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà. Láti nǹkan bí ẹgbàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [2,500] ni Dáníẹ́lì ti ń sinmi nínú sàréè, àmọ́ nípa agbára àjíǹde, kò ní pẹ́ tí ‘yóò fi dìde fún ìpín rẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn “olórí ní gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Dáníẹ́lì 12:13; Sáàmù 45:16) Ẹ wo irú ìdùnnú ńlá tí yóò jẹ́ láti kí àwọn tó ti kú káàbọ̀, kì í ṣe kìkì àwọn olóòótọ́ ìgbàanì nìkan o, àmọ́ wàá tún kí baba tìrẹ, ìyá tìrẹ, ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, tàbí àwọn olólùfẹ́ rẹ mìíràn káàbọ̀ pẹ̀lú, àwọn tí ikú tó jẹ́ ọ̀tá ti gbà mọ́ ọ lọ́wọ́!
21. Èé ṣe tí a kò fi ní láti jáfara ní ṣíṣe ohun rere fún àwọn ẹlòmíràn?
21 Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn olólùfẹ́ wa ti lè sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, kí wọ́n sì ti di arúgbó. Ọjọ́ ogbó lè mú kí ó ṣòro fún wọn láti kojú àwọn ìpèníjà ìgbésí ayé. Ì bá mà dára o, táa bá lè ṣe ohunkóhun tí apá wa bá ká nísinsìnyí láti ràn wọ́n lọ́wọ́! Tí a bá ṣe èyí, a ò ní kábàámọ̀ pé a ò ṣe àwọn ojúṣe kan tó yẹ kí a ṣe fún wọn tó bá ṣẹlẹ̀ pé ikú mú wọn lọ. (Oníwàásù 9:11; 12:1-7; 1 Tímótì 5:3, 8) A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà kò ní gbàgbé àwọn ohun rere táa ṣe fún àwọn ẹlòmíràn, láìka ọjọ́ orí tàbí ipò tí wọ́n wà sí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gálátíà 6:10; Hébérù 6:10.
22. Títí di ìgbà tí ìrètí àjíǹde yóò nímùúṣẹ, kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?
22 Jèhófà ni “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń tù wá nínú, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìrètí àjíǹde tó lágbára tu àwọn mìíràn nínú. Títí di ìgbà tí a ó fi rí ìmúṣẹ ìrètí yẹn nígbà tí a bá jí àwọn òkú dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé, ẹ jẹ́ kí a dà bíi Pọ́ọ̀lù, ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde. Ǹjẹ́ kí a fara wé Jésù ní pàtàkì, ẹni tó rí ìmúṣẹ ìrètí tó ní nínú agbára Ọlọ́run láti jí i dìde. Àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn Kristi láìpẹ́, wọn ó sì jáde wá. Ǹjẹ́ kí èyí fún wa ní ìtùnú àti ayọ̀. Àmọ́ ṣá o, lékè gbogbo rẹ̀, ǹjẹ́ kí a kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà, ẹni tí ó mú kí ìṣẹ́gun lórí ikú ṣeé ṣe nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Ẹ̀rí wo ni Pọ́ọ̀lù fún wa nípa àwọn tí àjíǹde Jésù ṣojú wọn?
• Kí ni “ọ̀tá ìkẹyìn,” báwo ni a ó sì ṣe sọ ọ́ di asán?
• Ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, kí la gbìn, kí la sì gbé dìde?
• Àwọn wo ni wàá fẹ́ rí lára àwọn tó wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nígbà táa bá jí wọn dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbèjà àjíǹde lọ́nà tó lágbára
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àjíǹde Jóòbù, ti ìdílé rẹ̀, àti ti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn yóò mú ìdùnnú ńlá wá!