Ori 20
Idile Eniyan Alayọ Labẹ Ipò-Jíjẹ́ Baba Titun Kan
1. Eeṣe ti ọ̀rọ̀ ipò-jíjẹ́ baba titun kan fi jẹ́ ihinrere tobẹẹ fun idile eniyan?
LẸHIN Armageddoni, ipò-jíjẹ́ baba keji kan ń duro de gbogbo iran eniyan. Iyẹn nitootọ jẹ́ irohin rere! Ipò-jíjẹ́ baba titun naa mu ki iye ayeraye ninu ijẹpipe eniyan ninu paradise kan kárí-ayé ṣeeṣe, nitori Baba titun idile eniyan naa fúnraarẹ̀ jẹ́ alaileeku. O ní agbara lati fi iwalaaye pipe jinki gbogbo awọn wọnni ti oun ba gbà bí awọn ọmọ rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé.
2. Eeṣe ti a fi nilo ipò-jíjẹ́ baba titun kan?
2 A nilo ipò-jíjẹ́ baba titun kan nitori pe iran eniyan ti padanu ipò-jíjẹ́ baba ipilẹṣẹ rẹ̀, ipò-jíjẹ́ baba ti Ẹlẹ́dàá eniyan. Ila-iran ti ó ṣàn lati ọdọ Jesu padasẹhin sọdọ ọkunrin akọkọ, Adamu, dopin pẹlu fifunni ní itolẹsẹẹsẹ yii: “Kainani, tii ṣe ọmọ Enosi, tii ṣe ọmọ Seti, tii ṣe ọmọ Adamu, tii ṣe ọmọ Ọlọrun.”—Luku 3:37, 38.
3. Bawo ni ipadanu ipò-jíjẹ́ ti Jehofa Ọlọrun jẹ́ baba ṣe jẹ́ ibanujẹ tó fun gbogbo araye?
3 Ipadanu ipò-jíjẹ́ ti Jehofa Ọlọrun jẹ́ baba ní abayọri bibaninujẹ fun gbogbo iran eniyan. Awọn iran àtẹ̀lé Adamu jogun idalẹbi iku. A ṣalaye ọ̀rọ̀ naa kedere ninu Romu 5:12 pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti ti ipa ọdọ eniyan kan wọ ayé, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹ ni iku si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.” “Eniyan kan” yẹn ni Adamu, ati nitori ẹṣẹ àmọ̀ọ́mọ̀dá rẹ̀, ó padanu ipò-jíjẹ́ ti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ Jehofa jẹ́ baba.
4. Abẹ́ ipò-jíjẹ́ baba wo ni Adamu ati iran eniyan wá bọ si?
4 Abẹ́ ipò-jíjẹ́ baba wo ni Adamu wá bọ si nigba naa? Abẹ́ ipò-jíjẹ́ baba wo ni o wá mu ayé iran eniyan wá? Yoo jẹ́ ipò-jíjẹ́ baba ti ẹni naa ti ó yi i lọkan pada lati jade kuro ninu idile gbogbo awọn ọmọkunrin Ọlọrun onigbọran ní ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé. O jẹ́ ipò-jíjẹ́ baba ti ẹni naa ti ó pa irọ akọkọ, Satani Eṣu. Bawo ni alatako Jehofa yii ṣe mu ki eyi ri bẹẹ?
5. (a) Ikọ̀ wo ni Satani Eṣu lò lati tan aya Adamu jẹ sinu ṣiṣaigbọran si Ọlọrun? (b) Eeṣe ati bawo ni Adamu ṣe wá sabẹ itẹwọgba ẹkunrẹrẹ ẹbi fun ipa ọna rẹ̀?
5 Ninu 2 Korinti 11:3 aposteli Paulu tudii ọran naa, ní kikọwe pe: “Ejo ti tan Efa jẹ́ nipasẹ arekereke rẹ̀.” Lọna arekereke, Satani lo ejo kan ní Edeni lati jíṣẹ́ irọ akọkọ fun Efa alaifura, ni fifi ẹ̀sùn irọ pipa kan Jehofa Ọlọrun. (Genesisi 3:1-7; Johannu 8:44) Adamu kò ṣatunṣe oju iwoye aya rẹ̀. Ko kọ̀ lati jẹ́ eso naa pẹlu rẹ̀ ki o si mu ipò naa tọ́. Mímọ̀ọ́mọ̀ ṣiwahu rẹ̀ kó o sọwọ Ejo naa. Ní gbigbe ẹbi naa ka ibi ti ó yẹ, 1 Timoteu 2:14 wi pe: “A kò si tan Adamu jẹ, ṣugbọn obinrin naa, nigba ti a tàn án, o ṣubu sinu ẹṣẹ.”
Ẹni Ti Ipò-Jíjẹ́ Baba Yẹ Fun
6, 7. Iru ipò-jíjẹ́ baba wo ni Jesu fihan pe a lè fi lé oun lọwọ, bawo si ni asọtẹlẹ Bibeli ṣe sọ eyi ní kedere?
6 Ní kíkọ̀ lati jọsin “ọlọrun ayé yii,” Jesu fihan pe oun ni Ẹni naa ti a lè fi ipò-jíjẹ́ baba keji fun idile eniyan lé lọwọ. (2 Korinti 4:4; Matteu 4:1-11; Luku 4:1-13) Lati ìgbà ibi rẹ̀ bi eniyan ní 2 B.C.E., oun ni Ẹni naa ti asọtẹlẹ Isaiah 9:6 tọkasi pe:
7 “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkunrin kan fun wa: ijọba yoo si wà ní ejika rẹ̀: a o si maa pe orukọ rẹ̀ ní Iyanu, Oludamọran, Ọlọrun Alagbara, Baba Ayeraye, Ọmọ-Aládé Alaafia.” Nitori naa “Ọmọ-Aládé Alaafia” ní ipa pataki miiran lati ko fun iran eniyan—eyiini ni ti jíjẹ́ “Baba Ayeraye.”
8. Eeṣe ti o fi ṣeeṣe fun Jesu lati gbe igbesẹ lati di “Baba Ayeraye” fun iran eniyan, bawo si ni aposteli Paulu ṣe jẹrii sí eyi?
8 Ọmọkunrin Ọlọrun ni yoo wá di “Baba Ayeraye” fun idile eniyan yii, awọn ẹni ti oun ti fi iwalaaye eniyan pipe rẹ̀ lelẹ fun ní irubọ. Ṣe ni ó ri gan-an gẹgẹ bi aposteli Paulu ti kọwe rẹ̀ pe: “Nitori bi nipa ẹṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ ku, meloomeloo ni oore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹbun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ. Njẹ bi nipa ẹṣẹ kan idajọ de bá gbogbo eniyan si idalẹbi; gẹgẹ bẹẹ ni nipa iwa ododo kan, ẹbun ọfẹ de sori gbogbo eniyan fun idalare si iye.”—Romu 5:15, 18.
9. Bawo ni Jesu ṣe di Adamu keji fun iran eniyan, ṣugbọn lati inu ilẹ-ọba wo ni oun ti ń ṣiṣẹ bii Baba iran eniyan?
9 Nipa bayii, awọn ọran pataki wọnyi ni a mu wà deedee ní pipe perepere. Ẹni ti ó da “ẹṣẹ kan” yẹn ni ọkunrin akọkọ lori ilẹ̀-ayé, Adamu. “Iwa ododo kan” yẹn ni a hù lati ọwọ ọkunrin pipe kanṣoṣo miiran naa, Jesu. Eyi fun un laaye lati di “Baba Ayeraye” awọn ọmọ iran àtẹ̀lé Adamu ti ó ṣẹ̀ naa. Ní ọna yii o di Adamu ikeji fun idile eniyan. Fifi iwalaaye eniyan pipe rẹ̀ rubọ ati gbigbe ẹtọ iwalaaye yẹn kalẹ niwaju Onidaajọ Nla naa ní ọ̀run kò jẹ ki o ṣeeṣe fun un lati ṣiṣẹsin nihin-in lori ilẹ̀-ayé bii baba ayeraye kan fun iran eniyan. Nigba ti a ji i dide kuro ninu oku, ó pada si ilẹ-ọba ẹmi a si gbe e ga si ọwọ ọtun Ẹni ti ó ji i dide. Nitori bẹẹ a ṣalaye pe: “Bẹẹ ni a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaaju, alaaye ọkan ni a da a; Adamu ikẹhin ẹmi ìsọnidààyè.” (1 Korinti 15:45) Àgbàfiṣe Baba titun ti iran eniyan naa yoo fun un ní ibẹrẹ igbesi-aye didara julọ ti ó ṣeeṣe.
Awọn Ẹ̀dá Eniyan Akọkọ Ti Yoo Ṣe Baba Fun
10. Awọn wo ni ẹda eniyan akọkọ ti àgbàfiṣe Baba yii yoo di baba fun?
10 “Baba Ayeraye” naa, Jesu Kristi Ọba, yoo ṣaṣefihan awọn ti oun yoo kọkọ jẹ́ baba fun. Bawo? Nipa pipa iwalaaye araadọta ọkẹ awọn olufọkansin ti wọn walaaye nisinsinyi mọ́ la “ipọnju nla” naa já. Awọn ni “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran.”—Ìfihàn 7:9, 14.
11. Anfaani ti ori ilẹ̀-ayé wo ni ó wà niwaju awọn ẹni bi agutan olula “ipọnju nla” já?
11 Anfaani ti ori ilẹ̀-ayé ti a gbekalẹ niwaju “ogunlọgọ nla” lẹhin “ipọnju nla” kò ní ibaadọgba. Bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ bi apakan “ami ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsiyi, awọn ewurẹ iṣapẹẹrẹ inu owe Jesu ni a o ke kuro ninu iwalaaye lori ilẹ̀-ayé yii, eyi ti yoo si tumọsi iparun ayeraye fun wọn. Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ fun “ogunlọgọ nla” awọn ẹni bi agutan ti wọn fi tifẹtifẹ ati pẹlu iduroṣinṣin ṣe rere fun àṣẹ́kù “awọn arakunrin” Kristi tẹmi ti wọn ṣì wà lori ilẹ̀-ayé sibẹ. (Matteu 25:31-46) Pipa iru “awọn agutan” bẹẹ mọ́ bọ́ si odikeji “ipọnju nla” ati sinu Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ti a ti sọtẹlẹ yoo mu ki o ṣeeṣe fun awọn olulaaja wọnyi lati wọnú awọn ibukun ilẹ-ọba Ijọba naa. Awọn ni yoo jẹ́ ọmọ-abẹ ti ori ilẹ̀-ayé fun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa.
12. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wo nipa ajinde ni ó fihan pe iwalaaye ailopin ni a gbeka iwaju awọn wọnni ti wọn wọnú ilẹ-ọba Ijọba naa ti ori ilẹ̀-ayé?
12 Ní akoko yẹn awọn ọ̀rọ̀ ti Jesu sọ ṣaaju ki ó to ji Lasaru dide kuro ninu oku ni a o muṣẹ lara awọn wọnni ti wọn ba wọ ilẹ-ọba Ijọba naa ti ori ilẹ̀-ayé. Oun wi pe: “Emi ni ajinde, ati iye: ẹni ti ó bá gbà mi gbọ́, bi o tilẹ ku, yoo yè. Ẹnikẹni ti ó ń bẹ laaye, ti ó si gbà mi gbọ, ki yoo ku laelae.” (Johannu 11:25, 26) Nitori igbọran wọn si i, ọwọ́ wọn yoo tẹ ijẹpipe iwalaaye eniyan ninu ilẹ-ọba Ọba naa ti ori ilẹ̀-ayé. Ani oluṣe buburu abanikẹdun naa paapaa ti ó kú lẹgbẹẹ Jesu ní Kalfari ni a o ṣojurere si pẹlu anfaani lati wọnú Paradise naa. (Luku 23:43) Jesu yoo ṣe ojuṣe gbogbo ohun ti orukọ rẹ̀ “Baba Ayeraye” duro fun.
Ifojusọna Alayọ fun Awọn Oku
13. Ajinde oku eniyan yoo mu ki ó ṣeeṣe lati ri awọn ẹni gbigbajumọ akoko igbaani wo ninu ilẹ-ọba Ijọba naa ti ori ilẹ̀-ayé?
13 Jesu, atọmọdọmọ Abrahamu ti ó gba iwaju julọ, sọ wi pe babanla yii, ọmọkunrin rẹ̀ Isaaki, ati ọmọ ọmọkunrin rẹ̀ Jakọbu ni a o ri ninu ilẹ-ọba Ijọba Ọlọrun ti ori ilẹ̀-ayé. (Matteu 22:31, 32) Eyi ni a o mu ki o ṣeeṣe nipasẹ ajinde. Bi Jesu ti wi, gbogbo awọn oku eniyan ti wọn wà ninu iboji iranti ní yoo gbọ́ ohùn Ọmọkunrin Ọlọrun ti wọn yoo si jade wa. Ọjọ iwaju wọn lẹhin naa yoo sinmi lori ipa ọna ti wọn ba tọ̀.—Johannu 5:28, 29; Ìfihàn 20:12-15.
14. Ki ni a nilati kọkọ ṣe ṣaaju fun awọn wọnni ti wọn wà ní ìlà fun ajinde ti ori ilẹ̀-ayé, awọn wo ni yoo si kọ́kọ́ nipin-in ninu awọn imurasilẹ wọnyi?
14 Awọn imurasilẹ bibuaya ni a nilati ṣe fun apakan iran eniyan ti a o mu jade wá lati inu isa-oku si iwalaaye lori ilẹ̀-ayé labẹ Ijọba “Baba Ayeraye” naa. Awọn olula “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” já ní Armageddoni ni yoo kọkọ dáwọ́lé awọn imurasilẹ wọnyi. (Ìfihàn 16:14, 16) Bi iye “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa yoo ti pọ to nigba naa ni a ko mọ nisinsinyi, ṣugbọn wọn yoo pọ̀ tó fun ẹru-iṣẹ naa.
15. Ọpọ yoo ṣiṣẹsin ninu akanṣe ipo wo labẹ àgbàfiṣe Baba iran eniyan?
15 A dari Orin Dafidi 45 si “Ọmọ-Aládé Alaafia” yii bi Ọba, ati niwọn bi oun yoo ti di “Baba Ayeraye” fun iran eniyan, orin yii wi fun un pe: “Ní ipò awọn baba nla rẹ ni awọn ọmọkunrin rẹ yoo wà, awọn ẹni ti iwọ yoo yàn gẹgẹ bi ọmọ-alade ni gbogbo ilẹ̀-ayé.” (Orin Dafidi 45:16, NW) Ṣugbọn ṣaaju ajinde “awọn baba nla” oluṣotitọ wọnyẹn paapaa, awọn ọkunrin laaarin “ogunlọgọ nla” ti olula Armageddoni já ni a o ti yàn si iru awọn ipò ọmọ-alade bẹẹ. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn olufojusọna fun lila Armageddoni já wọnyi ni wọn ti ń ṣiṣẹsin lọwọlọwọ gẹgẹ bi awọn alagba ninu ohun ti ó ju 73,000 ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti wọn ń ṣabojuto awọn ire tẹmi awọn ijọ wọn lọ́kankòjọ̀kan.
16. (a) Labẹ idari awọn ọmọ-alade, awọn olula Armageddoni já yoo ṣiṣẹsin ninu igbokegbodo wo? (b) Awọn ibeere wo ni o dide niti itotẹlera bi awọn oku yoo ṣe pada wa?
16 Labẹ abojuto ọmọ-alade, awọn olula Armageddoni já yoo ṣiṣẹsin pẹlu ifọwọsowọpọ alaapọn. Iru itọni gan-an tí awọn “ọmọ-alade ni gbogbo ilẹ̀-ayé” yoo ri gbà lati ọdọ “Ọmọ-Aládé Alaafia” ti ọ̀run naa ni a kò tii mọ̀, eyi ti yoo pese iriri amoriyagaga fun gbogbo awọn ẹlẹgbẹ wọn olula Armageddoni já. Wulẹ ronu wo lori gbogbo aṣọ ti a o nilati ran lati fi wọ awọn oku ti wọn ń padabọ pẹlu awọn ẹwu ti wọn ṣe deedee! Ronu nipa gbogbo ipese ounjẹ ti a gbọdọ pese tabi kó pamọ! A gbọdọ ti mura awọn ile gbigbe silẹ. Ẹ wo iru akoko amarayagaga ti eyi yoo jẹ́ fun gbogbo awọn wọnni ti yoo lọwọ ninu iṣẹ imurasilẹ yii! Awọn wo ni yoo kọkọ pada wa? Wọn yoo ha pada wá ní itotẹlera ẹni ikẹhin si ẹni akọkọ bi wọn ṣe sọkalẹ lọ sinu iboji iranti bi? A o ha ji Abeli ajẹriiku ati Enoku, ti Ọlọrun mu lọ, ati bakan naa Noa, Abrahamu, Isaaki, Jakọbu, ati gbogbo awọn wolii oluṣotitọ wọnni dide lakọọkọ na gẹgẹ bi ere akanṣe kan bi?
17. Ta ni yoo pinnu itotẹlera bi awọn oku yoo ṣe pada si iye lori ilẹ̀-ayé, orukọ oyè wo ti a ti sọtẹlẹ nipa rẹ̀ ni o fi agbara rẹ̀ lati bojuto awọn ẹru-iṣẹ rẹ̀ hàn?
17 “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa mọ̀ yoo si pinnu eyi. Yoo si tootun lẹkun-unrẹrẹ fun awọn ẹru-iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Baba titun ti iran eniyan ti a ti rà pada. Omiran ninu awọn orukọ oyè rẹ̀ ti a ti sọtẹlẹ ni “Ọlọrun Alagbara.” Eyi tọka pe oun yoo jẹ́ Ẹni alagbara kan, ti ó kun fun agbara. Aṣefihan jíjẹ́ ọlọrun rẹ̀ yoo jẹ́ alagbara niti pe oun yoo ji gbogbo awọn oku ti a ti rà pada dide, ní riranti orukọ ati akopọ animọ wọn lẹnikọọkan. (Johannu 5:28, 29; Iṣe 10:42) Oun ní agbara iṣe pipe perepere lati ṣe atunṣe awọn ibajẹ ti Satani Eṣu ti ṣe laaarin 6,000 ọdun iwalaaye eniyan ti ó ti kọja.
18. (a) Bawo ni a ṣe mu aini naa fun Adamu lati di babanla Jesu Kristi kuro? (b) Bawo ni a ṣe mu ki o ṣeeṣe fun Jesu lati di baba keji fun awọn ọmọ-inu Adamu?
18 Adamu akọkọ fi ogun ìní idalẹbi iku silẹ fun awọn ọmọ-inu rẹ̀. Adamu ha di babanla fun ọkunrin naa Jesu Kristi bi? Bẹẹkọ, Jesu kò ní baba eniyan kankan ṣugbọn a bi i lati ọwọ́ wundia kan ti ó loyun pẹlu agbara iwalaaye rẹ̀ ti Ọlọrun ta atare rẹ̀ lati ilẹ-ọba ẹmi. Nitori naa ẹlẹṣẹ naa Adamu kò di babanla fun Ọmọkunrin Ọlọrun ti ori ilẹ̀-ayé yẹn. Bi o ti wu ki o ri, Adamu ikeji ti di ẹmi ìsọnidààyè. Ninu ipò rẹ̀ yii oun lè mu asọtẹlẹ Isaiah ṣẹ ki ó sì di “Baba Ayeraye” fun awọn ọmọ-inu Adamu akọkọ, awọn ẹni ti oun rapada ti ó si gbà ṣọmọ pẹlu ete fifi iye eniyan pipe jinki wọn ninu paradise ori ilẹ̀-ayé.
19. Sinu ipo ibatan titun wo si iran eniyan ni Jehofa Ọlọrun yoo wá, ipetepero Satani Eṣu wo ni oun yoo tipa bẹẹ doju rẹ̀ bolẹ̀?
19 Ní iru ọna bayii Baba Jesu Kristi ní ọ̀run yoo wa di Baba Nla ti ọ̀run fun idile eniyan ti a mupadabọsipo. Fun idi yii idile eniyan yoo wọnú ibatan titun kan pẹlu Ẹlẹ́dàá ọ̀run oun ayé. Kò tii si igba kan ri lae ti ṣiṣeeṣe ti ó kere julọ wà pe Jehofa yoo kuna ní mimu ète rẹ̀ atetekọṣe ṣẹ. Nipa bayii Jehofa yoo ti doju ipetepero buburu ati alaiwa-bi-Ọlọrun ti Satani Eṣu bolẹ̀. Gbogbo idile eniyan ti a ti tun rapada ni a o mu loye otitọ yii. Ẹ wo iru ọjọ agbayanu ti eyi yoo jẹ́ nigba ti Jesu Kristi bá tẹwọgba ipò-jíjẹ́ baba idile eniyan ki o baa lè tọ́ iran eniyan dagba ninu Paradise ti a ti dá pada sori ilẹ̀-ayé!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 164, 165]
Kristi, ninu agbara ọba, di “Baba Ayeraye” fun gbogbo awọn ti ó gbà ṣọmọ