ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 50
“Báwo Ni Àwọn Òkú Ṣe Máa Jíǹde?”
“Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?”—1 KỌ́R. 15:55.
ORIN 141 Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni mọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run?
ÈYÍ tó pọ̀ jù lára àwa tá à ń sin Jèhófà báyìí ló ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Àmọ́, àwọn tó kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìrètí àtilọ sí ọ̀run. Ó máa ń wu àwọn ẹni àmì òróró yìí láti mọ bí ìgbésí ayé wọn ṣe máa rí tí wọ́n bá dé ọ̀run. Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe kan àwọn tó nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé? Bá a ṣe máa rí i, àjíǹde ti ọ̀run máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fáwọn tó nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Torí náà, yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé yìí la máa wà, gbogbo wa pátá ló yẹ ká mọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run.
2 Ọlọ́run mí sí mélòó kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láti sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti ọ̀run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “A ti wá di ọmọ Ọlọ́run, àmọ́ a ò tíì fi ohun tí a máa jẹ́ hàn kedere. A mọ̀ pé nígbà tí a bá fi í hàn kedere a máa dà bíi rẹ̀.” (1 Jòh. 3:2) Torí náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ò mọ báwọn ṣe máa rí gan-an nígbà tí Ọlọ́run bá jí àwọn dìde sí ọ̀run pẹ̀lú ara ti ẹ̀mí. Àmọ́, wọ́n máa rí Jèhófà lójúkojú nígbà tí wọ́n bá gba èrè wọn ní ọ̀run. Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àjíǹde ti ọ̀run, àmọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan díẹ̀ nípa ẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró máa wà pẹ̀lú Kristi nígbà tó bá “sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán,” títí kan “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jésù àtàwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso á fi ara wọn àti ohun gbogbo sábẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 15:24-28) Ó dájú pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an!b
3. Bí 1 Kọ́ríńtì 15:30-32 ṣe sọ, kí ni ìrètí àjíǹde tí Pọ́ọ̀lù ní mú kó ṣe?
3 Ìrètí àjíǹde tí Pọ́ọ̀lù ní mú kó lè fara da onírúurú àdánwò. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:30-32.) Ó sọ fún àwọn ará ní Kọ́ríńtì pé: “Ojoojúmọ́ ni mò ń dojú kọ ikú.” Ó tún sọ pé: “Mo ti bá àwọn ẹranko jà ní Éfésù.” Ó lè jẹ́ ìgbà tó bá àwọn ẹranko gidi jà ní gbọ̀ngàn ìwòran tó wà ní Éfésù ló ní lọ́kàn. (2 Kọ́r. 1:8; 4:10; 11:23) Ó sì lè jẹ́ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn Júù àtàwọn míì tó ń hùwà bí “ẹranko” ló ní lọ́kàn. (Ìṣe 19:26-34; 1 Kọ́r. 16:9) Èyí ó wù ó jẹ́, ó ṣe kedere pé ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù wà nínú ewu. Síbẹ̀ ó gbà pé tóun bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí òun dìde.—2 Kọ́r. 4:16-18.
4. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe ń fún àwa Kristẹni lókun lónìí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
4 Àsìkò tá à ń gbé yìí léwu gan-an, àwọn ará wa kan ń gbé láwọn ilẹ̀ tí ìwà ọ̀daràn ti gbilẹ̀, ojú wọn sì máa ń rí màbo. Àwọn míì ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti ń jagun, ọ̀pọ̀ ìgbà sì lẹ̀mí wọn máa ń wà nínú ewu. Bákan náà, àwọn ará wa kan ń gbé láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Síbẹ̀, wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà nìṣó bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n pa wọ́n. Láìka ipò táwọn ará yìí dojú kọ, wọn ò dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà, àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n sì jẹ́ fún wa. Ọkàn wọn balẹ̀ torí wọ́n mọ̀ pé tí àwọn bá tiẹ̀ kú nísinsìnyí, Jèhófà máa jí àwọn dìde lọ́jọ́ iwájú, á sì san àwọn lẹ́san.
5. Èrò tí kò tọ́ wo ló lè mú kí ìrètí àjíǹde má dá wa lójú mọ́?
5 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì pé kí wọ́n ṣọ́ra fún èrò tí kò tọ́ tí àwọn kan ní, pé: “Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, ‘ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.’ ” Kódà, ṣáájú ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù làwọn èèyàn ti nírú èrò tí kò tọ́ yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò tí kò tọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní bó ṣe wà nínú Àìsáyà 22:13 ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí. Dípò káwọn ọmọ Ísírẹ́lì sún mọ́ Ọlọ́run, bí wọ́n á ṣe jayé orí wọn ló gbà wọ́n lọ́kàn. Ká kúkú sọ pé, ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ń sọ ni pé “màá jayé òní, mi ò mọ ẹ̀yìn ọ̀la,” irú èrò tó sì wọ́pọ̀ lóde òní nìyẹn. Àmọ́ ohun tó máa ń gbẹ̀yìn irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í dáa, bó sì ṣe rí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà nìyẹn. Kódà, Jèhófà rí i dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì.—2 Kíró. 36:15-20.
6. Tá a bá fẹ́ kí ìrètí àjíǹde túbọ̀ dá wa lójú, àwọn wo la ò ní bá kẹ́gbẹ́?
6 Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, àwọn kan wà tá ò gbọ́dọ̀ bá kẹ́gbẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn tí kò gbà gbọ́ pé àwọn òkú máa jíǹde. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa: Kò sí àǹfààní kankan tá a máa rí tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ò mọ̀ ju bí wọ́n ṣe máa jayé orí wọn lọ. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè mú kí Kristẹni kan ní èrò tí kò tọ́, wọ́n sì lè ba ìwà rere ẹ̀ jẹ́. Kódà, wọ́n lè mú kí Kristẹni náà máa ṣe ohun tí Jèhófà kórìíra. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí orí yín pé lọ́nà òdodo, ẹ má sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà.”—1 Kọ́r. 15:33, 34.
IRÚ ARA WO NI WỌ́N MÁA NÍ?
7. Àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe káwọn kan béèrè nípa àjíǹde bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:35-38?
7 Ka 1 Kọ́ríńtì 15:35-38. Ẹnì kan tí ò gbà pé àjíǹde máa wáyé lè béèrè pé: “Báwo ni àwọn òkú ṣe máa jíǹde?” Á dáa ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ torí pé onírúurú èrò làwọn èèyàn ní nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Àmọ́ kí ni Bíbélì sọ?
8. Àpèjúwe wo ló lè jẹ́ ká lóye bí àjíǹde ti ọ̀run ṣe máa rí?
8 Tẹ́nì kan bá kú, ara ẹ̀ máa jẹrà. Àmọ́, Ẹni tó dá ayé àtọ̀run lè jí ẹni náà dìde kó sì fún un ní ara tuntun. (Jẹ́n. 1:1; 2:7) Pọ́ọ̀lù lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ara tó ti jẹrà yẹn ni Ọlọ́run máa fún ẹni náà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ “hóró” ọkà kan péré téèyàn gbìn. Tá a bá gbin hóró ọkà, á kọ́kọ́ jẹrà, lẹ́yìn náà á mú irúgbìn tuntun jáde. Irúgbìn tuntun yìí máa yàtọ̀ sí hóró kékeré tá a gbìn tẹ́lẹ̀. Àpèjúwe yìí ni Pọ́ọ̀lù lò láti jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa fún ẹni tó jíǹde náà ní “ara bí ó ṣe wù ú.”
9. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 15:39-41 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé onírúurú ara ló wà?
9 Ka 1 Kọ́ríńtì 15:39-41. Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ohun tí Jèhófà dá yàtọ̀ síra wọn. Bí àpẹẹrẹ, màlúù yàtọ̀ sí ẹyẹ, ẹyẹ sì yàtọ̀ sí ẹja, bẹ́ẹ̀ sì lẹran ara wọn ò rí bákan náà. Ó ní tá a bá gbójú wòkè, àá rí i pé oòrùn yàtọ̀ sí òṣùpá, kódà “ògo ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fi ojú lásán rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ìràwọ̀, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sọ pé onírúurú ìràwọ̀ ló wà. Àwọn kan tóbi, àwọn kan kéré, àwọn kan pọ́n yòò, àwọn kan sì funfun, bẹ́ẹ̀ sì làwọn míì yẹ́lò bí oòrùn wa yìí. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé “àwọn ohun tó wà ní ọ̀run ní ara tiwọn, àwọn tó wà ní ayé sì ní tiwọn.” Kí ló ní lọ́kàn? Ara tó ṣeé fojú rí làwa tí à ń gbé láyé ní, àmọ́ ara ti ẹ̀mí làwọn tó wà lọ́run ní bíi tàwọn áńgẹ́lì.
10. Irú ara wo làwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run máa ní?
10 Ẹ kíyè sí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí pẹ̀lú àjíǹde àwọn òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.” Lóòótọ́, téèyàn bá kú, ara ẹ̀ á jẹrà, á sì pa dà di erùpẹ̀. (Jẹ́n. 3:19) Kí ló wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run gbé ara ẹnì kan “dìde ní àìdíbàjẹ́”? Kì í ṣe àwọn tó jíǹde pa dà sáyé, irú àwọn tí Èlíjà, Èlíṣà àti Jésù jí dìde ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde sí ọ̀run pẹ̀lú “ara tẹ̀mí” ni Pọ́ọ̀lù ń sọ—1 Kọ́r. 15:42-44.
11-12. Irú ara wo ni Jésù ní nígbà tí Ọlọ́run jí i dìde, báwo ni àjíǹde àwọn ẹni àmì òróró sì ṣe máa jọra pẹ̀lú ti Jésù?
11 Nígbà tí Jésù wà láyé, irú ara tá a ní yìí lòun náà ní. Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run jí i dìde, ó “di ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè” ó sì pa dà sí ọ̀run. Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró náà máa di ẹ̀dá ẹ̀mí lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí a ṣe gbé àwòrán ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá wọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni a máa gbé àwòrán ẹni ti ọ̀run wọ̀.”—1 Kọ́r. 15:45-49.
12 Ó ṣe pàtàkì ká fi sọ́kàn pé nígbà tí Jèhófà jí Jésù dìde, ara ti ẹ̀mí ló fún un. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń parí ìjíròrò rẹ̀ nípa àjíǹde, ó ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run” ní ọ̀run. (1 Kọ́r. 15:50) Èyí fi hàn pé nígbà tí Jèhófà bá jí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ẹni àmì òróró yòókù dìde, wọn ò ní gbé ara tó ń díbàjẹ́ yìí àti ẹ̀jẹ̀ lọ sí ọ̀run. Ìgbà wo ni Ọlọ́run máa jí wọn dìde? Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọjọ́ iwájú lèyí máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn ni pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá kú ni wọ́n máa jíǹde. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sáwọn ará ní Kọ́ríńtì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan bí àpọ́sítélì Jémíìsì “ti sùn nínú ikú.” (Ìṣe 12:1, 2) Àwọn àpọ́sítélì tó kù àtàwọn ẹni àmì òróró ṣì máa “sùn nínú ikú.”—1 Kọ́r. 15:6.
WỌ́N ṢẸ́GUN IKÚ
13. Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ táá fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín?
13 Jésù àti Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ni ìgbà tí Kristi máa wà níhìn-ín. Lára àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn ni ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú míì táá máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Àtọdún 1914 làwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí ti ń nímùúṣẹ. Ohun pàtàkì míì wà tó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn. Jésù sọ pé a máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mát. 24:3, 7-14) Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere pé “ìgbà tí Olúwa bá wà níhìn-ín” yẹn kan náà ni Jèhófà máa jí àwọn ẹni àmì òróró tó ti “sùn nínú ikú” dìde.—1 Tẹs. 4:14-16; 1 Kọ́r. 15:23.
14. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró tó bá kú nígbà tí Kristi bá wà níhìn-ín?
14 Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró tó wà láyé báyìí bá kú ni wọ́n máa jíǹde lọ sọ́run. Pọ́ọ̀lù fìdí èyí múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní 1 Kọ́ríńtì 15:51, 52, ó ní: “Kì í ṣe gbogbo wa ló máa sùn nínú ikú, àmọ́ a máa yí gbogbo wa pa dà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.” Ó dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ti ń nímùúṣẹ! Àwọn arákùnrin Kristi yìí máa láyọ̀ gan-an lẹ́yìn tí wọ́n bá jíǹde torí pé wọ́n máa “wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.”—1 Tẹs. 4:17.
15. Iṣẹ́ wo làwọn tó máa yí pa dà “ní ìpajúpẹ́” máa ṣe?
15 Bíbélì sọ iṣẹ́ tí àwọn tó máa yí pa dà “ní ìpajúpẹ́” máa ṣe ní ọ̀run. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn, kó lè fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, bí mo ṣe gbà á lọ́wọ́ Baba mi gẹ́lẹ́.” (Ìfi. 2:26, 27) Wọ́n máa wà pẹ̀lú Ọ̀gá wọn, wọ́n á sì jọ fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè.—Ìfi. 19:11-15.
16. Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ṣẹ́gun ikú?
16 Kò sí àní-àní pé àwọn ẹni àmì òróró máa ṣẹ́gun ikú. (1 Kọ́r. 15:54-57) Torí pé ọ̀run ni Jèhófà jí wọn dìde sí, wọ́n á wà pẹ̀lú Jésù nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì láti fòpin sí ìwà ibi tó kárí ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa “wá látinú ìpọ́njú ńlá náà,” wọ́n á sì fẹsẹ̀ rìn wọnú ayé tuntun. (Ìfi. 7:14) Àwọn tó la ìpọ́njú ńlá náà já máa tún rí ìṣẹ́gun míì lórí ikú, ìyẹn nígbà tí Jèhófà bá jí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ti kú dìde. Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n bá jíǹde! (Ìṣe 24:15) Àwọn tó bá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ máa ṣẹ́gun ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.
17. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 15:58 rọ̀ wá pé ká máa ṣe báyìí?
17 Ó yẹ kí inú gbogbo àwa Kristẹni tá a wà láàyè báyìí máa dùn torí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nípa àjíǹde tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì. Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé ká ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí “nínú iṣẹ́ Olúwa.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ yìí, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin, a máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Ohun tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú yìí á kọjá àfẹnusọ, á sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé làálàá wa kò já sí asán nínú Olúwa.
ORIN 140 Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-Gbẹ́yín!
a Apá kejì 1 Kọ́ríńtì orí 15 ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àjíǹde, pàápàá àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Síbẹ̀, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ máa ṣe àwọn àgùntàn mìíràn náà láǹfààní. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àá rí bí ìrètí àjíǹde ṣe jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbé ayé wa nísinsìnyí ká sì máa fayọ̀ retí ọjọ́ iwájú.
b “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:29.