‘Gbà Lọ Soke Lati Pade oluwa’—Bawo?
APA ipari opin eto-igbekalẹ buburu ti isinsinyi ń baa lọ laiṣeeyipada. Pẹlu ikọjalọ gbogbo wakati, gbogbo iṣẹju, gbogbo iṣẹju-aaya kọọkan, a ń sunmọ awọn iṣẹlẹ amúnitakìjí ti a sọtẹlẹ lati ìgbà pipẹ wá. Ìgbàlọsókè ha jẹ ọ̀kan ninu iwọnyi bi? Bi o bá jẹ bẹẹ, nigba wo ati bawo ni yoo ṣe ṣẹlẹ?
Ọ̀rọ̀ naa “ìgbàlọsókè” [rapture] kò farahan ninu Bibeli. Ṣugbọn awọn ti wọn gbagbọ ninu rẹ̀ tọkasi ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ni 1 Tessalonika 4:17 gẹgẹ bi ipilẹ fun igbagbọ wọn. Ẹ jẹ ki a ṣayẹwo ẹsẹ iwe mimọ yii ninu ayika ọ̀rọ̀ rẹ̀. Paulu kọwe pe:
“Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹyin ki o jẹ́ òpè, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti. Nitori bi awa bá gbagbọ pe Jesu ti kú, o sì ti jinde, gẹgẹ bẹẹ ni Ọlọrun yoo mú awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu araarẹ̀. Nitori eyiyii ni awa ń wi fun yin nipa ọ̀rọ̀ Oluwa, pe awa ti o walaaye, ti a sì kù lẹhin de [wíwàníhìn-ín, NW] Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yoo ṣaaju awọn ti o sùn. Nitori Oluwa tikaraarẹ yoo sọkalẹ lati ọrun wá ti oun ti ariwo, pẹlu ohùn olórí awọn angẹli, ati pẹlu ìpè Ọlọrun; awọn òkú ninu Kristi ni yoo si kọ jinde: Nigba naa ni a o si gba awa ti o walaaye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa ni oju ọrun: bẹẹ ni awa ó si maa wà titi lae lọdọ Oluwa. Nitori naa, ẹ maa fi ọ̀rọ̀ wọnyi tu araayin ninu.”—1 Tessalonika 4:13-18.
Ijọ ti o wà ni Tessalonika ni o fẹrẹẹ jẹ titun nigba ti Paulu kọ lẹta rẹ̀ akọkọ si awọn Kristian nibẹ ni nǹkan bii 50 C.E. Awọn mẹmba ijọ naa ni a kó idaamu bá pe diẹ ninu iye wọn ‘ń sun ninu ikú.’ Bi o ti wu ki o ri, ohun ti Paulu kọwe rẹ̀ tu awọn ará Tessalonika ninu pẹlu ireti ajinde.
“Wíwàníhìn-ín” Kristi
Nigba ti o ń fidi rẹ̀ mulẹ pe awọn Kristian olododo ti o kú nigba naa ni a o ji dide, Paulu sọ bakan naa pe: “Awa ti o walaaye, ti a si kù lẹhin de [wíwàníhìn-ín, NW] Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yoo ṣaaju awọn ti o sùn.” (Ẹsẹ 15) Ohun ti o yẹ fun afiyesi niti gidi, ni itọkasi aposteli si “wíwàníhìn-ín” Oluwa. Nibi yii ọ̀rọ̀ ẹsẹ iwe ede-ipilẹṣẹ lo ọ̀rọ̀ Griki naa pa·rou·siʹan, eyi ti o tumọ niti gidi si “wíwà ni ìhà ẹ̀gbẹ́.”
Nigba ti olori Orilẹ-ede ilẹ okeere kan ba ṣe ibẹwo si orilẹ-ede kan, ọjọ wíwà nibẹ rẹ̀ ni a sábà maa ń kede. Eyi ni o ti jẹ́ otitọ nipa wíwàníhìn-ín Jesu Kristi Oluwa. Ilé-Ìṣọ́nà ti fi iṣedeedee gbé ẹ̀rí kalẹ fun awọn akẹkọọ asọtẹlẹ Bibeli alailabosi-ọkan pe wíwàníhìn-ín Jesu ninu agbara Ijọba ti ọrun bẹrẹ ni 1914. Awọn iṣẹlẹ lati ọdun yẹn wá jẹrii si wíwàníhìn-ín Jesu alaiṣeefojuri. (Matteu 24:3-14) Nitori naa nipa sisọ pe awọn Kristian pato kan ti wọn ń gbe lakooko wíwàníhìn-ín Oluwa ni a o “gbà . . . soke . . . lati pade Oluwa ni oju ọrun,” Paulu ní i lọ́kàn pe awọn olulaaja wọnyẹn yoo pade Kristi, kìí ṣe ninu ofuurufu ilẹ̀-ayé, ṣugbọn ni ilẹ ọba alaiṣeefojuri ti ọrun nibi ti Jesu ti jokoo ni ọwọ́ ọtun Ọlọrun. (Heberu 1:1-3) Ṣugbọn awọn wo ni?
“Israeli Ọlọrun”
Iwe Mimọ sọ pupọ nipa awọn ọmọ Israeli nipa ti ara ó sì tun sọrọ pẹlu nipa “Israeli Ọlọrun” nipa ti ẹmi. Awọn onigbagbọ Ju ati ti orilẹ-ede Keferi ni wọn yoo parapọ jẹ ẹkunrẹrẹ iye ẹgbẹ́ awujọ yii eyi ti a fàmì òróró yàn nipasẹ ẹmi mimọ Ọlọrun, tabi ipá agbekankanṣiṣẹ. (Galatia 6:16; Romu 11:25, 26; 1 Johannu 2:20, 27) Iwe Ìfihàn ṣipaya pe apapọ iye awọn Israeli ti ẹmi jẹ́ 144,000, gbogbo awọn ti a fihàn pẹlu Ọdọ-agutan naa, Jesu Kristi, lori Oke Sioni ti ọrun. Papọ pẹlu Kristi, wọn yoo jẹ ọba ati alufaa ni ọrun. (Ìfihàn 7:1-8; 14:1-4; 20:6) Awọn ti wọn yoo ní ninu ni awọn eniyan lẹnikọọkan ti wọn ti ń darapọ mọ awọn ijọ ti o wà ni Tessalonika ati nibomiran, ohun yoowu ti ipilẹṣẹ wọn nipa ti ẹ̀yà ati orilẹ-ede ìbáà jẹ́.—Iṣe 10:34, 35.
Ṣaaju ki awọn mẹmba oluṣotitọ eyikeyii lara Israeli tẹmi tó lè rí èrè ti ọrun gbà, wọn yoo nilati nipin-in ninu iriri pato kan. Gẹgẹ bi iku Jesu lori opo-igi idaloro ṣe ṣaaju ajinde rẹ̀ si ìyè ninu awọn ọrun, nitori naa awọn Kristian ti wọn ní ireti ti ọrun gbọdọ kú ṣaaju ki wọn tó lè rí ère wọn gbà. (1 Korinti 15:35, 36) Iyẹn yoo jẹ otitọ nipa awọn mẹmba Israeli tẹmi ti wọn gbé ni ọrundun kìn-ín-ní C.E. ati nipa iru awọn eniyan bẹẹ lẹnikọọkan ti wọn walaaye lonii.
Lẹhin mimẹnukan “wíwàníhìn-ín Oluwa” (NW), Paulu tọkasi akoko naa nigba ti awọn Israeli tẹmi oluṣotitọ ti wọn ti kú yoo gba èrè ti ọrun wọn. O kọwe pe: “Oluwa tikaraarẹ yoo sọkalẹ lati ọrun wá ti oun ti ariwo, pẹlu ohùn olórí awọn angẹli, ati pẹlu ìpè Ọlọrun; awọn òkú ninu Kristi ni yoo sì kọ́ jinde.” (Ẹsẹ 16) Nitori naa, gbàrà ti wíwàníhìn-ín Jesu gẹgẹ bi Ọba ti bẹrẹ, a o reti ki ajinde ti ọrun bẹrẹ, ni bibẹrẹ pẹlu awọn wọnni wọn jẹ ti Israeli tẹmi ti wọn ti ku tẹlẹ gẹgẹ bi olupawatitọ mọ. (1 Korinti 15:23) Wọn ń ṣiṣẹsin nisinsinyi ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu Jesu ni ọrun. Ṣugbọn ki ni nipa ti awọn Kristian ẹni-ami-ororo kéréje ni ifiwera ti wọn ń gbe sibẹ lori ilẹ̀-ayé? Wọn ha ń duro de ìgbàlọsókè bi?
‘Gbà Lọ Soke’—Bawo?
Lẹhin titọka si awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti wọn ti kú, Paulu fikun un pe: “Nigba naa ni a ó sì gba awa ti ó walaaye ti ó sì kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanmọ, lati pade Oluwa ni oju ọrun: bẹẹ ni awa ó sì maa wà titi lae.” (Ẹsẹ 17) ‘Awọn ti o walaaye’ yoo jẹ awọn wọnni ti wọn walaaye lakooko wíwàníhìn-ín Kristi. A o ‘gbà wọn lọ soke’ lati pade Jesu Oluwa. Gẹgẹ bi o ṣe ri ninu ọ̀ràn awọn Kristian akọkọbẹrẹ ti wọn jẹ́ oluṣotitọ, iku pọndandan fun wọn gẹgẹ bi ẹ̀dá eniyan lati lè jẹ́ ẹni ti a sopọ ṣọkan pẹlu Kristi ni ọrun.—Romu 8:17, 35-39.
Ni kikọwe si awọn Kristian ni Korinti, Paulu sọ ni kedere pe: “Ará, ǹjẹ́ eyi ni mo wi pe, ara oun ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ijọba Ọlọrun; bẹẹ ni idibajẹ kò lè jogún aidibajẹ. Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun yin; gbogbo wa ki yoo sùn, ṣugbọn gbogbo wa ni a o palarada, lọ́gán, ni iṣẹju, nigba ìpè ikẹhin: nitori ìpè yoo dún, a o si ji awọn òkú dide ni aidibajẹ, a o sì pa wa larada.” (1 Korinti 15:50-52) Lẹhin kiku ninu iṣotitọ nigba wíwàníhìn-ín Kristi, ọkọọkan ninu awọn aṣẹku Israeli tẹmi rí èrè rẹ̀ ti ọrun gbà lọgan. “Ni iṣẹju,” oun ni a ji dide gẹgẹ bi ẹda ẹmi ti a si ‘gbà lọ soke’ lati pade Jesu ati lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alajumọṣakoso ninu Ijọba ti awọn ọrun. Ṣugbọn ki ni nipa ti gbogbo awọn miiran ti wọn ṣẹku ti wọn ń jọsin Jehofa? Bi opin eto-igbekalẹ buburu yii ti ń sunmọle, awọn pẹlu ni a o ha gbà lọ soke ọrun bi?
Lilaaja—Ṣugbọn Kìí Ṣe Nipasẹ Ìgbàlọsókè
Niwọn bi o ti jẹ pe wíwàníhìn-ín ọlọ́ba Jesu bẹrẹ ni 1914, a ti rìn jinna wọnu “ìgbà ikẹhin” ayé yii. (Danieli 12:4) Paulu kilọ pe: “Ṣugbọn niti akoko ati ìgbà wọnni, ará, ẹyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si yin, nitori pe ẹyin tikaraayin mọ dajudaju pe, ọjọ Oluwa ń bọ̀wá gẹgẹ bi olè ni oru. Nigba ti wọn ba ń wi pe, alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun ojiji yoo de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o loyun; wọn kì yoo sì lè sálà.” (1 Tessalonika 5:1-3) Ṣugbọn awọn Kristian ti wọn wa lojufo yoo yèbọ́. Bawo?
Igbe “alaafia ati ailewu” jẹ ohun ti yoo kọ́kọ́ wáyé ṣaaju akoko ti Jesu pe ni “ipọnju nla.” Ni ṣiṣapejuwe “ogunlọgọ nla” ti awọn oluṣotitọ ti wọn ni ireti gbigbe titilae ninu paradise ori ilẹ̀-ayé kan, iwe Ìfihàn sọ pe: “Awọn wọnyi ni o jade lati inu ipọnju nla, wọn si fọ aṣọ wọn, wọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọdọ-Agutan naa.” (Ìfihàn 7:9, 14; Luku 23:43) Bẹẹkọ, ireti wọn kìí ṣe ti ìgbàlọsókè kan. Kaka bẹẹ, wọn ni ireti lilaaja nihin-in gan-an lori ilẹ̀-ayé. Lati murasilẹ fun un, wọn gbọdọ maa baa lọ lati jikalẹ nipa tẹmi. Bawo ni iwọ ṣe lè ṣe eyi ki o si la opin eto-igbekalẹ yii ja?
Iwọ nilati ‘maa wa ni airekọja, ki o si maa gbé ìgbàyà igbagbọ ati ifẹ wọ; ati ireti igbala fun aṣibori.’ (1 Tessalonika 5:6-8) Nisinsinyi ni akoko naa lati kọbiara si Ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ti Ọlọrun, Bibeli. Bi akoko ti ń kọjalọ titi di opin eto-igbekalẹ yii, kọbiara si imọran Paulu pe: “Ẹ maṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ maa wadii ohun gbogbo daju; ẹ di eyi ti o dara mu ṣinṣin.” (1 Tessalonika 5:20, 21) Nipa bẹẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ki ọ kaabọ si Gbọngan Ijọba wọn, nibi ti o ti lè ṣajọpin pẹlu wọn ninu kikẹkọọ awọn asọtẹlẹ Bibeli ati awọn apa ẹka Ọ̀rọ̀ onimiisi Ọlọrun miiran.
Bi o ṣe ń dagba ninu ìmọ̀ pípéye ati igbagbọ, iwọ yoo lóye iṣiṣẹyọri ète Jehofa Ọlọrun lati gba ilẹ̀-ayé yii silẹ kuro lọwọ awọn ọ̀tá rẹ̀ ki o si sọ ori ilẹ̀-ayé di paradise. Nipa lilo igbagbọ, iwọ lè wà lara awọn olula ipọnju nla naa já pẹlu, ki o si lanfaani lati kí araadọta-ọkẹ awọn wọnni ti a o ji dide si iwalaaye lori ilẹ̀-ayé kaabọ. Ẹ sì wo bi yoo ti jẹ ohun ayọ tó lati gbé labẹ Ijọba Ọlọrun ni ọwọ́ Jesu Kristi ati awọn alajumọṣakoso rẹ̀, awọn ti a o ti ‘gbà lọ soke lati pade Oluwa’ nipa jiji wọn dide si ìyè ninu ilẹ-ọba ti ọrun!
Fun gbogbo eniyan onigbọran lapapọ, nigba naa, ki ni ireti tootọ ti o ba Iwe Mimọ mu? Kìí ṣe ìgbàlọsókè kan. Kaka bẹẹ, o jẹ ìyè ayeraye lori ilẹ̀-ayé labẹẹ iṣakoso Ijọba Ọlọrun.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn olula ipọnju nla já yoo ki awọn ti a ji dide si ìyè lori paradise ilẹ̀-ayé kaabọ labẹ iṣakoso Jesu ati awọn ti a ‘gbà lọ soke’ ọ̀run