“Ikú Ni A Ó Sọ Di Asán”
“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 15:26.
1, 2. (a) Ìrètí wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbé kalẹ̀ fún àwọn òkú? (b) Ìbéèrè wo nípa àjíǹde ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lé lórí?
“MO GBA . . . àjíǹde ara àti ìyè àìnípẹ̀kun gbọ́.” Báyìí ni Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Àwọn Àpọ́sítélì kà. Àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì kò fi kíkà á sórí ṣeré rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wọn tan mọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, ó sì jìnnà pátápátá sí ohun tí àwọn àpọ́sítélì gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn. Síbẹ̀, ó ní ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìwàláàyè ọjọ́ ọ̀la, ó sì kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Kí tilẹ̀ ni èyí túmọ̀ sí fún aráyé tí ikú ń pa?
2 Láti dáhùn, ẹ jẹ́ kí a padà sí ìjíròrò Pọ́ọ̀lù nípa àjíǹde, èyí tí a kọ sínú 1 Kọ́ríńtì orí 15. Ìwọ yóò rántí pé ní àwọn ẹsẹ tí ó bẹ̀rẹ̀, Pọ́ọ̀lù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àjíǹde jẹ́ apá pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ Kristẹni. Wàyí o, ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè kan pàtó: “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan yóò wí pé: ‘Báwo ni a ó ṣe gbé àwọn òkú dìde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?’”—1 Kọ́ríńtì 15:35.
Irú Ara Wo?
3. Èé ṣe tí àwọn kan fi kọ àjíǹde?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbé ìbéèrè yìí dìde, bóyá ṣe ni ó fẹ́ gbéjà ko ohun tí ìmọ̀ ọgbọ́n orí Plato ti dá sílẹ̀. Plato kọ́ni pé ènìyàn ní àìleèkú ọkàn tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú. Lójú ìwòye àwọn tí a fi irú èrò bẹ́ẹ̀ tọ́ dàgbà, ẹ̀kọ́ Kristẹni nípa àjíǹde kò wúlò rárá. Bí ọkàn bá ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú, kí ni ìdí fún àjíǹde? Síwájú sí i, ó jọ pé àjíǹde kò mọ́gbọ́n dání. Lẹ́yìn tí ara ti dà pọ̀ mọ́ erùpẹ̀, báwo ni àjíǹde ṣe lè wà? Heinrich Meyer, tí í ṣe alálàyé Bíbélì, sọ pé ó jọ pé àtakò tí àwọn ará Kọ́ríńtì kan ṣe ni wọ́n gbé ka “ìmọ̀ ọgbọ́n orí náà pé ìmúpadàbọ̀sípò àwọn apilẹ̀ ẹ̀yà ara kò ṣeé ṣe.”
4, 5. (a) Èé ṣe tí àtakò àwọn aláìnígbàgbọ́ fi jẹ́ aláìlọ́gbọ́n nínú? (b) Ṣàlàyé àpèjúwe Pọ́ọ̀lù nípa “èkìdá hóró.” (d) Irú ara wo ni Ọlọ́run fi fún àwọn ẹni àmì òróró tí a jí dìde?
4 Pọ́ọ̀lù fi àìbọ́gbọ́nmu ìrònú wọn hàn, ó ní: “Ìwọ aláìlọ́gbọ́n-nínú! Ohun tí o gbìn ni a kò sọ di ààyè láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ kú; àti ní ti ohun tí ìwọ gbìn, kì í ṣe ara tí yóò gbèrú ni ìwọ gbìn, bí kò ṣe èkìdá hóró, ó lè jẹ́, ti àlìkámà tàbí èyíkéyìí nínú àwọn ìyókù; ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún un ni ara gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú, àti fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ara tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 15:36-38) Kì í ṣe ara tí àwọn ènìyàn ní nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run yóò gbé dìde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìparadà yóò wà.
5 Pọ́ọ̀lù fi àjíǹde wé híhù hóró. Hóró àlìkámà bín-ín-tín àti igi tí yóò dàgbà láti inú rẹ̀ kò jọra rárá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, sọ pé: “Nígbà tí hóró kan bá bẹ̀rẹ̀ sí hù, yóò fa omi púpọ̀ mu. Omi náà máa ń fa ọ̀pọ̀ ìyípadà oníkẹ́míkà nínú hóró náà. Ó tún máa ń mú kí àwọn fọ́nrán inú hóró náà tóbi sí i, wọn a sì lu hóró náà já síta.” Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, hóró náà yóò kú gẹ́gẹ́ bí hóró kan, yóò sì di igi tí ń dàgbà bọ̀. “Ọlọ́run fún un ní ara,” ní ti pé ó lànà àwọn òfin tí ó bá sáyẹ́ǹsì mu, tí ń ṣàkóso ìdàgbà rẹ̀, hóró kọ̀ọ̀kan a sì gba ara tí ó jẹ́ irú tirẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:11) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró á kọ́kọ́ kú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Lẹ́yìn náà, ní àkókò tí Ọlọ́run yàn, òun yóò mú wọn padà bọ̀ sí ìyè nínú ara tuntun pèrépèré. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ fún àwọn ará Fílípì, “Jésù Kristi . . . yóò ṣàtúndá ara wa tí a ti tẹ́ lógo, kí ó lè bá ara ológo tirẹ̀ ṣe déédéé.” (Fílípì 3:20, 21; 2 Kọ́ríńtì 5:1, 2) A óò jí wọn dìde nínú ara tẹ̀mí, wọn yóò sì máa gbé ní àgbègbè àkóso tẹ̀mí.—1 Jòhánù 3:2.
6. Èé ṣe tí ó fi lọ́gbọ́n nínú láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lè fún àwọn tí a jí dìde ní ara tẹ̀mí yíyẹ?
6 Èyí ha nira jù láti gbà gbọ́ bí? Ó tì o. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé onírúurú ara ni àwọn ẹranko gbé wọ̀. Ní àfikún, ó fi ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín àwọn áńgẹ́lì òkè ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ran ara òun ẹ̀jẹ̀ hàn, ó wí pé: “Àwọn ara ti ọ̀run sì wà, àti àwọn ara ti ilẹ̀ ayé.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn ẹ̀dá aláìlẹ́mìí. Tipẹ́tipẹ́ kí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ṣàwárí àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run bí àwọn ìràwọ̀ aláwọ̀ aró, àwọn òmìrán pupa, àti àwọn ràrá funfun, ni Pọ́ọ̀lù ti sọ pé “ìràwọ̀ yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ní ògo.” Lójú ìwòye èyí, kò ha lọ́gbọ́n nínú pé Ọlọ́run lè pèsè ara tẹ̀mí yíyẹ fún àwọn ẹni àmì òróró tí a jí dìde?—1 Kọ́ríńtì 15:39-41.
7. Kí ni ìtumọ̀ àìdíbàjẹ́? àìleèkú?
7 Pọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni àjíǹde àwọn òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́, a sì gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:42) Ara ẹ̀dá ènìyàn, kódà nígbà tí ó jẹ́ pípé pàápàá, lè díbàjẹ́. Ó ṣeé pa. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí a jí Jésù dìde, a “yàn án tẹ́lẹ̀ pé kì yóò tún padà sínú ìdíbàjẹ́ mọ́.” (Ìṣe 13:34) Kì yóò tún padà láé sí ìyè nínú ara ẹ̀dá ènìyàn tí ó lè díbàjẹ́, bí ara ọ̀hún tilẹ̀ jẹ́ pípé. Ara tí Ọlọ́run fún àwọn ẹni àmì òróró tí a jí dìde jẹ́ aláìlèdíbàjẹ́—ikú kò lè rí i gbéṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò lè jẹrà. Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ pé: “A gbìn ín ní àbùkù, a gbé e dìde ní ògo. A gbìn ín ní àìlera, a gbé e dìde ní agbára. A gbìn ín ní ara ìyára, a gbé e dìde ní ara ti ẹ̀mí.” (1 Kọ́ríńtì 15:43, 44) Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.” Àìkú túmọ̀ sí ìwàláàyè àìlópin, tí kò ṣeé pa run. (1 Kọ́ríńtì 15:53; Hébérù 7:16) Lọ́nà yìí, àwọn tí a jí dìde yóò gbé “àwòrán ẹni ti ọ̀run” wọ̀, èyíinì ni Jésù, ẹni tí ó mú kí àjíǹde wọ́n ṣeé ṣe.—1 Kọ́ríńtì 15:45-49.
8. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé àwọn tí a jí dìde jẹ́ ẹni kan náà tí wọ́n jẹ́ nígbà tí wọ́n wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé? (b) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ni a mú ṣẹ nígbà tí àjíǹde bá ṣẹlẹ̀?
8 Láìka ìparadà yìí sí, àwọn tí a jí dìde ṣì jẹ́ ẹni náà tí wọ́n jẹ́ kí wọ́n tó kú. A óò gbé wọn dìde pẹ̀lú iyè kan náà àti àwọn ànímọ́ Kristẹni títayọ kan náà. (Málákì 3:3; Ìṣípayá 21:10, 18) Wọ́n fi èyí jọ Jésù Kristi. Ó para dà láti ẹ̀dá ẹ̀mí sí ẹ̀dá ènìyàn. Lẹ́yìn náà ni ó kú, tí a sì jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Síbẹ̀, “Jésù Kristi jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé.” (Hébérù 13:8) Àǹfààní ológo tí àwọn ẹni àmì òróró ní mà ga o! Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ṣùgbọ́n nígbà tí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí bá gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, tí èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí sì gbé àìkú wọ̀, nígbà náà ni àsọjáde náà yóò ṣẹ, èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘A ti gbé ikú mì títí láé.’ ‘Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?’”—1 Kọ́ríńtì 15:54, 55; Aísáyà 25:8; Hóséà 13:14.
Àjíǹde sí Orí Ilẹ̀ Ayé Kẹ̀?
9, 10. (a) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ 1 Kọ́ríńtì 15:24, kí ni “òpin” náà, kí sì ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bá a rìn? (b) Kí ni ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ kí a tó lè sọ ikú di asán?
9 Ọjọ́ ọ̀la kankan ha wà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí kò ní ìrètí ìyè àìleèkú tẹ̀mí sí òkè ọ̀run? Ó wà mọ̀nà! Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àjíǹde sí òkè ọ̀run yóò ṣẹlẹ̀ nígbà wíwàníhìn-ín Kristi, ó to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e lẹ́sẹẹsẹ, ó ní: “Lẹ́yìn náà, ni òpin, nígbà tí ó bá fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:23, 24.
10 “Òpin” náà ni òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí Jésù yóò fi Ìjọba náà lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìdúróṣinṣin. (Ìṣípayá 20:4) Ète Ọlọ́run “láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi” ni a ó ti mú ṣẹ. (Éfésù 1:9, 10) Àmọ́ ṣá o, Kristi yóò ti kọ́kọ́ run “gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára” tí ó tako ìfẹ́ Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ. Èyí kọjá ìparun tí yóò wáyé ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣípayá 16:16; 19:11-21) Pọ́ọ̀lù wí pé: “[Kristi] gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́ríńtì 15:25, 26) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ohun tí ó tan mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú Ádámù ni a óò ti mú kúrò. Ó dájú pé nígbà yẹn, Ọlọ́run yóò ti sọ “ibojì ìrántí” dòfìfo nípa mímú àwọn òkú padà bọ̀ sí ìyè.—Jòhánù 5:28.
11. (a) Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe àtúndá àwọn òkú ọkàn? (b) Irú ara wo ni a óò fún àwọn tí a óò jí dìde sórí ilẹ̀ ayé?
11 Èyí túmọ̀ sí ṣíṣe àtúndá àwọn ọkàn ẹ̀dá ènìyàn. Kò ṣeé ṣe kẹ̀? Ó ṣeé ṣe dáadáa, nítorí Sáàmù 104:29, 30, mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó kà pé: “Bí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn kúrò, wọn a gbẹ́mìí mì, wọn a sì padà lọ sínú ekuru wọn. Bí ìwọ bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a óò dá wọn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí a jí dìde yóò jẹ́ ẹni kan náà tí wọ́n jẹ́ ṣáájú ikú wọn, kò pọndandan kí wọ́n ní ara kan náà. Bí ó ti rí ní ti àwọn tí ó jíǹde lọ sí òkè ọ̀run, Ọlọ́run yóò fún wọn ní ara gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú. Láìsí àní-àní, ara tuntun tí wọ́n gbé wọ̀ yóò jí pépé, yóò sì jọ ara tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀, kí àwọn olólùfẹ́ wọn lè dá wọn mọ̀.
12. Ìgbà wo ni àjíǹde sórí ilẹ̀ ayé yóò ṣẹlẹ̀?
12 Ìgbà wo ni àjíǹde sí orí ilẹ̀ ayé yóò ṣẹlẹ̀? Màtá sọ nípa Lásárù, arákùnrin rẹ̀ tí ó kú, pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:24) Báwo ló ṣe mọ̀? Àjíǹde jẹ́ kókó àríyànjiyàn ní ọjọ́ rẹ̀, níwọ̀n bí àwọn Farisí ti gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n tí àwọn Sadusí kò gbà á gbọ́. (Ìṣe 23:8) Ìyẹn nìkan kọ́, Màtá á ti mọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́rìí tí ó wà ṣáájú àwọn Kristẹni tí ó ní ìrètí nínú àjíǹde. (Hébérù 11:35) Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó lè fòye mọ̀ láti inú Dáníẹ́lì 12:13 pé àjíǹde yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn. Ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Jésù alára ni ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí. (Jòhánù 6:39) “Ọjọ́ ìkẹyìn” yẹn bá Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ṣe kòńgẹ́. (Ìṣípayá 20:6) Sáà fojú inú wo irú ayọ̀ abara tín-ń-tín tí yóò wà ní “ọjọ́” yẹn nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kíkọyọyọ yìí bá bẹ̀rẹ̀!—Fi wé Lúùkù 24:41.
Àwọn Wo Ni Yóò Padà Bọ̀?
13. Kí ni ìran tí a kọ sílẹ̀ nípa àjíǹde nínú Ìṣípayá 20:12-14?
13 Inú Ìṣípayá 20:12-14 ni àkọsílẹ̀ ìran Jòhánù nípa àjíǹde sí orí ilẹ̀ ayé wà, tí ó kà pé: “Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.”
14. Àwọn wo ni yóò wà lára àwọn tí a óò jí dìde?
14 Àjíǹde yóò kan “ẹni ńlá àti ẹni kékeré,” àwọn gbajúmọ̀ àti gbáàtúù ènìyàn tó wà láàyè, tó sì ti kú. Họ́wù, àwọn ọmọdé jòjòló pàápàá yóò jíǹde! (Jeremáyà 31:15, 16) Nínú Ìṣe 24:15, a ṣí kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn tí ó ṣe pàtàkì payá, pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Gbajúmọ̀ lára “àwọn olódodo” wọnnì ni àwọn olóòótọ́ ìgbàanì, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, bí Ébẹ́lì, Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù, Sárà, àti Ráhábù. (Hébérù 11:1-40) Sáà fojú inú wo níní àǹfààní láti bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀, kí o sì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjímìjí inú Bíbélì láti ẹnu àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn! “Àwọn olódodo” yóò tún ní nínú, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí ó kú láìpẹ́, láìní ìrètí ti òkè ọ̀run. Ǹjẹ́ o ní mẹ́ńbà ìdílé tàbí olólùfẹ́ tí ó lè jẹ́ ara àwọn wọ̀nyí? Ẹ wo bí ó ti tuni nínú tó láti mọ̀ pé a lè rí wọn lẹ́ẹ̀kan sí i! Ṣùgbọ́n, àwọn wo ni “aláìṣòdodo” tí yóò padà bọ̀ pẹ̀lú? Wọ́n ní nínú àràádọ́ta ọ̀kẹ́, bóyá ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù, àwọn tí ó kú láìní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì, kí wọ́n sì mú un lò.
15. Kí ni ó túmọ̀ sí pé a óò “ṣèdájọ́” àwọn tí ń padà bọ̀ “láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà”?
15 Báwo ni a óò ṣe “ṣèdájọ́” àwọn tí yóò padà bọ̀ “láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn”? Àkájọ ìwé wọ̀nyí kì í ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe látẹ̀yìnwá; nígbà tí wọ́n kú, a dá wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ nígbà ayé wọn. (Róòmù 6:7, 23) Àmọ́ ṣá o, àwọn ènìyàn tí a jí dìde yóò ṣì wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àkájọ ìwé wọ̀nyí yóò lànà àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá sílẹ̀, tí gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé láti lè jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní láti inú ẹbọ Jésù Kristi. Bí a ti mú gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù kúrò, ‘a ó sọ ikú di asán’ pátápátá. Nígbà tí ó bá máa fi di òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Ọlọ́run yóò “jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.” (1 Kọ́ríǹtì 15:28) Àwọn ènìyàn kò tún ní nílò iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà tàbí Olùràpadà mọ́. Gbogbo aráyé ni a óò mú padà bọ̀ sípò ìjẹ́pípé tí Ádámù gbádùn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.
Àjíǹde Tí Ó Wà Létòlétò
16. (a) Èé ṣe tí ó fi lọ́gbọ́n nínú láti gbà gbọ́ pé àjíǹde yóò lọ létòlétò? (b) Àwọn wo ni ó ṣeé ṣe kí wọ́n wà lára àwọn tí yóò kọ́kọ́ padà wá láti inú òkú?
16 Níwọ̀n bí àjíǹde sí òkè ọ̀run ti wà létòlétò, “olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀,” ó ṣe kedere pé àjíǹde sí orí ilẹ̀ ayé kì yóò rọ́ àwọn ènìyàn kún orí ilẹ̀ ayé ní wọ̀ǹdùrùkù. (1 Kọ́ríńtì 15:23) Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, yóò pọndandan láti bójú tó àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ jí dìde. (Fi wé Lúùkù 8:55.) Wọn yóò nílò ohun ìgbẹ́mìíró nípa ti ara àti—jù bẹ́ẹ̀ lọ—ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí láti jèrè ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (Jòhánù 17:3) Bí gbogbo wọn bá padà bọ̀ sí ìyè lẹ́ẹ̀kan náà wìì, kò ní ṣeé ṣe láti tọ́jú wọn dáadáa. Ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé àjíǹde náà yóò ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó kú ní gẹ́rẹ́ ṣáájú òpin ètò Sátánì ni ó ṣeé ṣe kí wọ́n kọ́kọ́ jíǹde. A tún lè retí pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì tí yóò sìn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ aládé” yóò tètè jíǹde.—Sáàmù 45:16.
17. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Bíbélì kò mẹ́nu kàn nípa àjíǹde, èé sì ti ṣe tí kò fi yẹ kí àwọn Kristẹni dààmú púpọ̀ jù nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
17 Síbẹ̀síbẹ̀, kò yẹ kí a lérò pé kìkì ohun tí a sọ yìí labẹ gé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tí Bíbélì kò mẹ́nu kàn. Kò là á lẹ́sẹẹsẹ bí àjíǹde olúkúlùkù yóò ṣe ṣẹlẹ̀, ìgbà tí yóò ṣẹlẹ̀, tàbí ibi tí yóò ti ṣẹlẹ̀. Kò sọ fún wa nípa ètò tí a ṣe nípa ilé gbígbé, oúnjẹ, àti aṣọ fún àwọn tí ń padà bọ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni a kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú ètò tí Jèhófà yóò ṣe nípa àwọn ọ̀ràn bí títọ́ àti bíbójútó àwọn ọmọ tí a bá jí dìde tàbí bí òun yóò ṣe bójú tó àwọn ipò tí yóò kan àwọn ọ̀rẹ́ àti olólùfẹ́ wa. Ká sòótọ́, ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti máa ṣe kàyéfì nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n kò ní bọ́gbọ́n mu láti máa lo àkókò dànù lórí gbígbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè tí kò ṣeé dáhùn lọ́wọ́ tí a wà yìí. Ṣe ni ó yẹ kí a gbájú mọ́ fífi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà, kí a sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gbé ìrètí wọn ka àjíǹde ológo sí òkè ọ̀run. (2 Pétérù 1:10, 11) “Àwọn àgùntàn mìíràn” ní ìrètí láti gba ogún àìnípẹ̀kun ní ilẹ̀ àkóso orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:33, 34) Ní ti ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a kò tíì mọ̀ nípa àjíǹde, kí a sáà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ayọ̀ wa ọjọ́ iwájú wà láìyingin lọ́wọ́ Ẹni tí ó lè “tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16; Jeremáyà 17:7.
18. (a) Ìjagunmólú wo ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́? (b) Èé ṣe tí a fi gbé gbogbo ọkàn wa lé ìrètí àjíǹde?
18 Pọ́ọ̀lù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa pípòkìkí pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń fún wa ní ìjagunmólú nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!” (1 Kọ́ríńtì 15:57) Bẹ́ẹ̀ ni, a ṣẹ́gun ikú Ádámù nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” sì jùmọ̀ nípìn-ín nínú ìjagunmólú yìí. Ní tòótọ́, “àwọn àgùntàn mìíràn” tó wà láàyè lónìí ní ìrètí aláìlẹ́gbẹ́ nínú ìran yìí. Gẹ́gẹ́ bí ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń pọ̀ sí i, wọ́n lè la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já, kí wọ́n má sì kú láé! (Ìṣípayá 7:9, 14) Àmọ́ ṣá o, kódà àwọn tó kú nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” tàbí tí àwọn aṣojú Sátánì ṣekú pa lè gbọ́kàn lé ìrètí àjíǹde.—Oníwàásù 9:11.
19. Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni gbogbo Kristẹni lónìí gbọ́dọ̀ kọbi ara sí?
19 Nítorí náà, pẹ̀lú ìháragàgà ni a ń dúró de ọjọ́ ológo náà tí a ó sọ ikú di asán. Ìgbẹ́kẹ̀lé wa tí kò lè mì nínú ìlérí Jèhófà nípa àjíǹde jẹ́ kí a ní ojú ìwòye dídájú ṣáká. Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ìgbésí ayé yìí—bí a tilẹ̀ kú—kò sí nǹkan kan tí ó lè já èrè tí Jèhófà ti ṣèlérí gbà lọ́wọ́ wa. Fún ìdí yìí, ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn ará Kọ́ríńtì bá a mu wẹ́kú lónìí bí ó ti rí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, ó ní: “Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dáhùn ìbéèrè náà nípa irú ara tí àwọn ẹni àmì òróró yóò gbé wọ̀ nígbà àjíǹde?
◻ Báwo àti nígbà wo ni a ó sọ ikú di asán pátápátá?
◻ Àwọn wo ni yóò wà lára àwọn tí yóò jíǹde sórí ilẹ̀ ayé?
◻ Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nípa àwọn nǹkan tí Bíbélì kò mẹ́nu kàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Hóró kan “kú” nípa yíyípadà pátápátá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ ìgbàanì, bí Nóà, Ábúráhámù, Sárà, àti Ráhábù, yóò wà lára àwọn tí a óò jí dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àjíǹde yóò jẹ́ àkókò ayọ̀ abara tín-ń-tín!