-
Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
13. Kí ni iná tí Pọ́ọ̀lù lò nínú àkàwé rẹ̀ túmọ̀ sí, kí sì ni ó yẹ kí gbogbo Kristẹni mọ̀?
13 Iná kan wà tí gbogbo wa dojú kọ nínú ìgbésí ayé—ìdánwò ìgbàgbọ́ wa. (Jòhánù 15:20; Jákọ́bù 1:2, 3) Bí ti àwa pẹ̀lú lónìí, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni a óò dán wò. Bí a kò bá kọ́ wọn dáradára, àbájáde rẹ̀ lè bani nínú jẹ́. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó ti kọ́ sórí rẹ̀ bá wà síbẹ̀, òun yóò gba èrè; bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni bá jóná, òun yóò pàdánù, ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ ni a ó gbà là; síbẹ̀, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹní la iná já.”c—1 Kọ́ríńtì 3:14, 15.
14. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ṣe lè “pàdánù,” síbẹ̀, báwo ni a ṣe lè gbà wọ́n là bí ẹni la iná já? (b) Báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù?
14 Ọ̀rọ̀ tí ó gbàrònú jinlẹ̀ nìyí lóòótọ́! Ó máa ń dunni púpọ̀ láti sapá gidigidi láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, kìkì láti wá rí i pé ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìdánwò tàbí inúnibíni, tí ó sì wá fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ níkẹyìn. Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú gbà bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó fi sọ pé a pàdánù nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ìrírí náà máa ń dunni gan-an débi tí a fi ṣàpèjúwe ìgbàlà wa gẹ́gẹ́ bí “ẹni la iná já”—bí ẹnì kan tí ó pàdánù gbogbo ohun tí ó ní nínú iná, tí ó jẹ́ pé díẹ̀ báyìí ni òun alára fi rù ú là. Ní tiwa, báwo ni a ṣe lè dín ewu pípàdánù kù? Ẹ jẹ́ kí a fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí kọ́lé! Bí a bá kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ láti lè dé inú ọkàn-àyà wọn, tí a sún wọn láti mọyì àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣíṣeyebíye bí ọgbọ́n, ìfòyemọ̀, ìbẹ̀rù Jèhófà, àti ojúlówó ìgbàgbọ́, a jẹ́ pé a ń fi ohun èlò tí ó lè wà pẹ́ títí, tí kò lè gbiná kọ́lé. (Sáàmù 19:9, 10; Òwe 3:13-15; 1 Pétérù 1:6, 7) Àwọn tí wọ́n bá ní irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí yóò máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó; wọ́n ní ìrètí tí ó dájú láti wà láàyè títí láé. (1 Jòhánù 2:17) Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè fi àkàwé Pọ́ọ̀lù sílò? Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
-
-
Ṣé Iṣẹ́ Rẹ Yóò La Iná Já?Ilé Ìṣọ́—1998 | November 1
-
-
c Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù ń ṣiyèméjì nípa ìgbàlà kọ́lékọ́lé náà, ṣùgbọ́n ó ń ṣiyèméjì nípa ìgbàlà “iṣẹ́” rẹ̀. Bí The New English Bible ṣe túmọ̀ ẹsẹ náà nìyí: “Bí ilé tí ẹnì kan kọ́ bá dúró, a óò san èrè fún un; bí ó bá jóná, òun ni yóò pàdánù; síbẹ̀ yóò yè é bọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó la iná já.”
-