ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 1-3
Jèhófà—“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
Ìjọ Kristẹni jẹ́ ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń tù wá nínú. Kí làwọn nǹkan tá a lè ṣe láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?
Tẹ́tí sí wọn, má dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu
“Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”—Ro 12:15
O lè kọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró sínú káàdì, kó o sì fún wọn, o sì lè fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà.—w17.07 15, àpótí
Gbàdúrà fún wọn, kó o sì gbàdúrà pẹ̀lú wọn