ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KỌ́RÍŃTÌ 4-6
“A Kò Juwọ́ Sílẹ̀”
Ẹ fojú inú wo ìdílé méjì tó ń gbé nínú ilé àtijọ́ kan tó ti bà jẹ́. Ìdílé kan kárí sọ, inú wọn ò sì dùn, a ti mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ó yà wá lẹ́nu pé ńṣe ni inú ìdílé kejì ń dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìdílé kejì máa tó kó lọ sí ilé tuntun míì tó rẹwà gan-an.
Lóòótọ́ “gbogbo ìṣẹ̀dá jọ ń kérora nìṣó, wọ́n sì jọ wà nínú ìrora títí di báyìí,” àmọ́ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìrètí pé nǹkan ṣì máa dáa. (Ro 8:22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí àwọn ìṣòro ti ń bá wa fínra, àmọ́ a mọ̀ dáadáa pé ó “jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,” ó sì fúyẹ́ tá a bá fi wéra pẹ̀lú ìyè ayérayé nínú ayé tuntun. Tá a bá ń gbájú mọ́ àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ayọ̀, a ò sì ní juwọ́ sílẹ̀.