Ó Ń Rẹ̀ Wá Àmọ́ A Kì í Ṣàárẹ̀
“Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, . . . ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.”—AÍSÁYÀ 40:28, 29.
1, 2. (a) Ọ̀nà tó fani mọ́ra wo la gbà pe gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣe ìsìn mímọ́? (b) Kí ló lè jẹ́ ewu ńlá fún ipò wa nípa tẹ̀mí?
GẸ́GẸ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù, a mọ ọ̀nà fífanimọ́ra tó gbà pè wá nígbà tó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. . . . Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28-30) A tún fún àwọn Kristẹni láǹfààní àtirí “àwọn àsìkò títunilára . . . láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:19) Dájúdájú, ìwọ fúnra rẹ á ti rí ìtura téèyàn máa ń ní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, níní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára, àti fífi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nínú ìgbésí ayé rẹ.
2 Síbẹ̀, àwọn kan lára àwọn olùjọsìn Jèhófà máa ń bára wọn nínú wàhálà lọ́pọ̀ ìgbà. Ìgbà mìíràn wà tí àwọn àkókò ìrẹ̀wẹ̀sì yìí lè jẹ́ fúngbà díẹ̀. Ìgbà mìíràn sì wà tí irú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ kì í lọ bọ̀rọ̀. Bí àkókò ṣe ń lọ, àwọn kan lè wá máa ronú pé ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ti di ẹrù ìnira dípò kó jẹ́ ẹrù tó ń tuni lára gẹ́gẹ́ bí ìlérí Jésù. Irú èrò òdì bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ewu ńlá fún àjọṣe tó wà láàárín Kristẹni kan àti Jèhófà.
3. Kí nìdí tí Jésù fi fúnni ní ìmọ̀ràn tó wà nínú Jòhánù 14:1?
3 Kété ṣáájú ìgbà tí wọ́n mú Jésù tí wọ́n sì pa á, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú. Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:1) Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé àwọn àpọ́sítélì náà máa rí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú máa ṣẹlẹ̀ sáwọn láìpẹ́ sí àkókò yẹn. Inúnibíni líle koko ló sì máa tẹ̀ lé èyí. Jésù sì mọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú káwọn àpọ́sítélì òun kọsẹ̀. (Jòhánù 16:1) Tí kò bá sì wá nǹkan ṣe sí i, ìbànújẹ́ lè sọ wọn di aláìlágbára nípa tẹ̀mí, èyí sì lè mú kí wọ́n pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú Jèhófà. Bákan náà ló rí fún àwọn Kristẹni lónìí. Ìrẹ̀wẹ̀sì téèyàn bá ní fún àkókò pípẹ́ lè mú kéèyàn ní ìrora ọkàn, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọkàn wa di èyí tí a dẹ́rù pa. (Jeremáyà 8:18) Gbogbo nǹkan lè tojú sú wa. Nínú irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fúnni láti ronú dáadáa, ká sì wá rẹ̀wẹ̀sì pátápátá nípa tẹ̀mí, kódà a lè sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́ pàápàá.
4. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní jẹ́ kí ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa ṣàárẹ̀?
4 Ìmọ̀ràn Bíbélì yẹn bá a mú gẹ́ẹ́, tó sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa, kó máa bàa rẹ̀wẹ̀sì kó sì ṣàárẹ̀ nípa tẹ̀mí. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tó ń jẹ́ kó rẹ̀ wá gan-an.
Jíjẹ́ Kristẹni Kì Í Níni Lára
5. Kí ló dà bíi pé ó ta kora nínú ọ̀ràn jíjẹ́ Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn?
5 Lóòótọ́, jíjẹ́ Kristẹni gba pé kéèyàn lo ara rẹ̀ tokuntokun. (Lúùkù 13:24) Kódà Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí kò bá sì máa gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn kò lè jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Lúùkù 14:27) Tá a bá wo ọ̀rọ̀ yìí lóréfèé, ó dà bíi pé ó ta ko ohun tí Jésù sọ nípa ẹrù rẹ̀ tó fúyẹ́ tó sì tuni lára, àmọ́ ní ti gidi, wọn ò ta kora.
6, 7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀nà tá a gbà ń jọ́sìn kì í ṣe èyí tó ń kó àárẹ̀ báni?
6 Lílo ara wa tokuntokun àti ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára lè jẹ́ kó rẹ̀ wá nípa tara, àmọ́ ó tún lè fini lọ́kàn balẹ̀ kó sì tuni lára tó bá jẹ́ pé ohun tó dáa ló ń sún wa ṣe é. (Oníwàásù 3:13, 22) Kí sì ni ohun tó tún lè dára jù pé ká lọ sọ àgbàyanu òtítọ́ Bíbélì fún àwọn aládùúgbò wa? Àti pe gbogbo akitiyan wa láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà ìwà rere tí Ọlọ́run là kalẹ̀ kéré gan-an lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní tá a máa rí níbẹ̀. (Òwe 2:10-20) Kódà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, a kà á sí nǹkan iyì láti jìyà nítorí Ìjọba Ọlọ́run.—1 Pétérù 4:14.
7 Ẹrù Jésù tuni lára ní tòótọ́, àgàgà tá a bá fi wé bí àwọn tí kò kúrò lábẹ́ àjàgà ìsìn èké ṣe wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí wa kò sì béèrè ohun tí agbára wa ò ká lọ́wọ́ wa. “Àwọn àṣẹ” Jèhófà “kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Ìsìn Kristẹni tòótọ́, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́, kì í nini lára. Ó ṣe kedere pé ọ̀nà tá a gbà ń jọ́sìn kì í ṣe èyí tó ń kó àárẹ̀ àti ìrẹ̀wẹ̀sì báni.
Ẹ “Mú Gbogbo Ẹrù Wíwúwo Kúrò”
8. Kí ló sábà máa ń fa àárẹ̀ nípa tẹ̀mí?
8 Ohun tó sábà máa ń fa àárẹ̀ èyíkéyìí nípa tẹ̀mí ni ìnira tí ètò àwọn nǹkan tó ti díbàjẹ́ yìí máa ń kó bá wa. Nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” àwọn ipa búburú tó lè mú kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu kó sì fa ọwọ́ aago wa sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ló yí wa ká. (1 Jòhánù 5:19) Àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì lè dabarú àwọn ohun tí à ń ṣe déédéé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Àwọn ìnira tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i yìí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, kódà ó lè paná ẹ̀mí wa kú pátápátá. Abájọ tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé ká “mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò.”—Hébérù 12:1-3.
9. Báwo ni lílépa ohun tí ara ṣe lè dẹ́rù pa wa?
9 Bí àpẹẹrẹ, òkìkí, owó, eré ìnàjú, ìrìn àjò afẹ́, àti àwọn nǹkan tara mìíràn táwọn èèyàn ń lépa nínú ayé lè nípa tí kò dára lórí èrò inú wa. (1 Jòhánù 2:15-17) Àwọn kan tó lépa ọrọ̀ lára àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sọ ìgbésí ayé wọn di èyí tí kò rọrùn rárá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.
10. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa ọrọ̀ látinú àkàwé tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn?
10 Nígbà tó bá ń rẹ̀ wá tá a sì ń rẹ̀wẹ̀sì nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, ṣé kì í ṣe pé àwọn ohun tara tá à ń lépa ló ń nípa lórí ipò tẹ̀mí wa yẹn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó fà á gan-an nìyẹn gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn fi hàn. Jésù fi “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù” wé ẹ̀gún tó “gbógun wọlé,” tó sì “fún [irúgbìn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lọ́kàn wá] pa.” (Máàkù 4:18, 19) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”—Hébérù 13:5.
11. Báwo la ṣe lè mú àwọn ohun tó lè dẹ́rù pa wá kúrò?
11 Àwọn ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé kì í ṣe lílépa àwọn nǹkan púpọ̀ sí i ló ń mú kí ìgbésí ayé nira, bí kò ṣe ohun tá a ń fi àwọn ohun tá a ní ṣe. Àwọn kan lè ní àárẹ̀ ọkàn nítorí àìsàn tó ń ṣe wọ́n, nítorí èèyàn wọn tó kú, tàbí nítorí àwọn ìṣòro mìíràn tó ń fa ìrora ọkàn. Wọ́n ti rí i pé ó yẹ káwọn máa ṣàtúnṣe látìgbàdégbà. Àwọn tọkọtaya kan pinnu láti pa díẹ̀ tì lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tọ́wọ́ bá dilẹ̀ àtàwọn ìwéwèé mìíràn tí kò ṣe pàtàkì. Wọ́n dìídì yẹ gbogbo ẹrù wọn wò, wọ́n sì kó àwọn ohun tí wọ́n máa ń lò fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò nílé. Àwa náà lè máa yẹ àwọn ohun tá à ń ṣe àtàwọn ohun ìní wa wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ká sì kó gbogbo àwọn ohun tí kò pọn dandan kúrò nílé kí ó mà bàa rẹ̀ wa nípa tẹ̀mí ká sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wa.
Ìfòyebánilò àti Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Ṣe Pàtàkì
12. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa àwọn àṣìṣe tiwa fúnra wa?
12 Àwọn àṣìṣe tiwa fúnra wa, kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké pàápàá lè máa mú kí ìgbésí ayé nira fún wa. Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ pé: “Àwọn ìṣìnà mi ti gba orí mi kọjá; bí ẹrù wíwúwo, wọ́n wúwo jù fún mi.” (Sáàmù 38:4) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àtúnṣe díẹ̀ ló máa yọ àwọn ẹrù wíwúwo kúrò lọ́rùn wa.
13. Báwo ni lílo òye ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dára nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
13 Bíbélì gbà wa níyànjú pé ká ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.” (Òwe 3:21, 22) Bíbélì sọ pé, “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye bani lò.” (Jákọ́bù 3:17) Àwọn kan dìídì fẹ́ ṣe tó àwọn ẹlòmíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Àmọ́, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn. Nítorí olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:4, 5) Lóòótọ́, àpẹẹrẹ rere àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lè jẹ́ ìṣírí láti fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà, àmọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti lílo òye yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa lé kìkì àwọn ohun tá a lè lé bá níbàámu pẹ̀lú ipò wa.
14, 15. Báwo la ṣe lè lo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ láti bójú tó ohun tá a nílò nípa tara àti ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa?
14 Tá a bá ń lo òye lórí àwọn ohun tó dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì pàápàá, àá lè dènà ṣíṣe àárẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a ní ohun tá a máa ń ṣe déédéé tí yóò mú kí ara wa le? Gbé àpẹẹrẹ àwọn tọkọtaya kan yẹ̀ wò, wọ́n ń sìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti rí ìjẹ́pàtàkì lílo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ láti dènà àárẹ̀. Èyí ìyàwó sọ pé: “Bó ti wu kíṣẹ́ tá à ń ṣe pọ̀ tó, a máa ń gbìyànjú láti rí i pé àkókò tá à ń sùn lálaalẹ́ kò yí padà. A tún máa ń ṣe eré ìmárale déédéé. Èyí ti ràn wá lọ́wọ́ gan-an. A mọ ibi tí agbára wa mọ, a ò sì ṣe àwọn ohun tó ju agbára wa lọ. A gbìyànjú láti rí i pé a ò fi ara wa wé àwọn tó ní agbára tó pọ̀.” Ǹjẹ́ a máa ń jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore tá a sì ń sinmi dáadáa? Fífi ọgbọ́n kíyè sí ìlera wa lè dín àárẹ̀ nípa tara àti àárẹ̀ nípa tẹ̀mí kù.
15 Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pátápátá làwọn kan lára wa nílò. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti sìn láwọn ibi mélòó kan tí kò rọrùn fún un. Oríṣiríṣi àìsàn ló ti ṣe é, títí kan àrùn jẹjẹrẹ. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò tí kò bára dé yìí? Arábìnrin náà sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí ń dá nìkan wà kí ẹnikẹ́ni má sì bá mi sọ̀rọ̀. Bí ìdààmú ọkàn náà ṣe ń pọ̀ sí i ló ń ṣe mi bíi pé kí n ráyè wà níbi tó pa rọ́rọ́ tí mo ti lè kàwé kí n sì sinmi.” Ọgbọ́n tó gbẹ́ṣẹ́ àti agbára láti ronú ń jẹ́ ká mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa nílò ká sì ṣe wọ́n, kí ó má bàa rẹ̀ wá nípa tẹ̀mí.
Jèhófà Ọlọ́run Ń fún Wa Lágbára
16, 17. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an láti tọ́jú ara wa nípa tẹ̀mí? (b) Kí ló yẹ ká fi kún àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́?
16 Bíbójútó ìlera wa nípa tẹ̀mí ṣe pàtàkì gan-an. Tí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run bá gún régé, bó tiẹ̀ rẹ̀ wá nípa tara, ìjọsìn rẹ̀ kò ní sú wa láé. Jèhófà ni ẹni tí “ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.” (Aísáyà 40:28, 29) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí òun fúnra rẹ̀ rí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kọ̀wé pé: “Àwa kò juwọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, dájúdájú, ẹni tí àwa jẹ́ ní inú ni a ń sọ dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—2 Kọ́ríńtì 4:16.
17 Kíyè sí gbólóhùn yẹn “láti ọjọ́ dé ọjọ́.” Èyí túmọ̀ sí pé ká lo àǹfààní ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa lójoojúmọ́. Obìnrin míṣọ́nnárì kan tó ti fi òtítọ́ sìn fún ọdún mẹ́tàlélógójì kojú àwọn àkókò kan tó rẹ̀ ẹ́ nípa tara tó sì tún rẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú. Àmọ́ kò ṣàárẹ̀ nípa tẹ̀mí. Obìnrin náà sọ pé: “Mo ti sọ ọ́ dàṣà mi láti máa tètè jí kí n lè gbàdúrà sí Jèhófà kí n sì ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ èyíkéyìí tí mo bá fẹ́ ṣe. Ohun tí mo ń ṣe lójoojúmọ́ yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa fara da ipò tí kò rọgbọ títí di ìsinsìnyí.” A lè gbára lé agbára tí Jèhófà fi ń gbéni ró tá a bá ń gbàdúrà sí i “láti ọjọ́ dé ọjọ́” tá a sì ń ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ gíga rẹ̀ àtàwọn ìlérí rẹ̀ déédéé.
18. Ìtùnú wo ni Bíbélì fún àwọn olóòótọ́ tí wọ́n ti darúgbó tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn?
18 Èyí ṣe pàtàkì gan-an, àgàgà fáwọn tó rẹ̀wẹ̀sì nítorí ọjọ́ ogbó àti àìsàn. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí bọkàn jẹ́, ohun tó sì fa èyí lè máà jẹ́ nítorí pé wọ́n ń fi ara wọn wé àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ kó jẹ́ nítorí pé wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ń ṣe nísinsìnyí wé ohun tí wọ́n máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìtùnú ńlá ló mà jẹ́ o, láti mọ̀ pé Jèhófà mọyì àwọn arúgbó! Bíbélì sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, ó sì mọyì ìjọsìn tá a fi gbogbo ọkàn wa ṣe láìfi àìlera wa pè. Àwọn iṣẹ́ rere tá a ṣe sì ti wà nínú àkọsílẹ̀ tí kò ṣeé pa rẹ́ nínú ìrántí Ọlọ́run. Ìwé Mímọ́ mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Hébérù 6:10) Inú wa mà dùn gan-an o, pé àwọn kan wà láàárín wa tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún!
Ẹ Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀
19. Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú ṣíṣe ohun rere ní gbogbo ìgbà?
19 Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé fífi gbogbo okun ṣe eré ìdárayá déédéé lè dín àárẹ̀ kù. Bákan náà ni ṣíṣe àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí déédéé lè ṣèrànwọ́ láti dín àárẹ̀ tẹ̀mí kù. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀. Ní ti gidi, nígbà náà, níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:9, 10) Kíyè sí àwọn gbólóhùn tó sọ pé “ṣíṣe ohun tí ó dára” àti “ṣe ohun rere.” Èyí túmọ̀ sí pé ká ṣe nǹkan kan. Ṣíṣe ohun rere fáwọn ẹlòmíràn kò ní jẹ́ ká ṣàárẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.
20. Tá a bá fẹ́ gbógun ti ìrẹ̀wẹ̀sì, àwọn wo la ò gbọ́dọ̀ bá kẹ́gbẹ́?
20 Àmọ́, bíbá àwọn tó fojú di òfin Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ àti bíbá wọn ṣe wọléwọ̀de lè di ohun ìnira tó ń múni ṣàárẹ̀. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ìwúwo òkúta àti ẹrù iyanrìn—ṣùgbọ́n ìbínú láti ọ̀dọ̀ òmùgọ̀ wúwo ju àwọn méjèèjì lọ.” (Òwe 27:3) Tá a bá fẹ́ gbógun ti ìrẹ̀wẹ̀sì àti àárẹ̀ nípa tẹ̀mí, a ò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tó ní èrò òdì kẹ́gbẹ́, tí wọ́n máa ń wá ẹ̀sùn síni lẹ́sẹ̀, tí wọ́n sì máa ń ṣe àríwísí àwọn ẹlòmíràn.
21. Báwo la ṣe lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn ẹlòmíràn láwọn ìpàdé Kristẹni?
21 Àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ ọ̀nà kan tí Jèhófà máa ń gbà fún wa ní agbára nípa tẹ̀mí. Ibẹ̀ la ti ní àǹfààní tó pọ̀ láti fi àwọn ìtọ́ni tó ń tuni lára àti ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin gba ara wa níyànjú. (Hébérù 10:25) Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ sapá láti máa gbéni ró nígbà tí wọ́n bá ń dáhùn láwọn ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n bá níṣẹ́ lórí pèpéle. Àwọn tó ń mú ipò iwájú gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ló ṣe pàtàkì fún jù lọ láti máa gba àwọn ará níyànjú. (Aísáyà 32:1, 2) Kódà nígbà tó bá yẹ láti gbani níyànjú tàbí láti báni wí, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń báni wí gbọ́dọ̀ tuni lára. (Gálátíà 6:1, 2) Láìsí àní-àní, ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ẹlòmíràn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti sìn Jèhófà láìṣàárẹ̀.—Sáàmù 133:1; Jòhánù 13:35.
22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ẹ̀dá la jẹ́, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà gidi gan-an?
22 Jíjọ́sìn Jèhófà ní àkókò òpin yìí gba iṣẹ́. Àwọn Kristẹni náà máa ń ní àárẹ̀ ọpọlọ, ìrora, àti másùnmáwo. Ẹ̀dá aláìpé tá a jẹ́ ti mú ká dà bí ohun ẹlẹgẹ́, bí ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Dájúdájú, yóò rẹ̀ wa, àmọ́ ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣàárẹ̀ tàbí ká juwọ́ sílẹ̀ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká jẹ́ “onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi.’”—Hébérù 13:6.
Àtúnyẹ̀wò Ráńpẹ́
• Kí làwọn ohun to ń dẹ́rù pani tá a lè pa tì?
• Báwo la ṣe lè kópa nínú ṣíṣe “ohun rere” fáwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tó bá rẹ̀ wá tàbí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Jésù mọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì tó wà fúngbà pípẹ́ lè kó ìdààmú bá àwọn àpọ́sítélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn kan ti pa ohun tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tọ́wọ́ bá dilẹ̀ tì, títí kan àwọn ìwéwèé tí kò ṣe pàtàkì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó níbi tágbára wá mọ, síbẹ̀ Jèhófà mọyì ìjọsìn tá a ń fi gbogbo ọkàn ṣe