Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìfẹ́ Tí Ń Soni Pọ̀
NÍ 1978, ìjì ńlá kan ní Àríwá Òkun Àtìláńtíìkì fọ́ ọkọ̀ afẹ́ ojú òkun náà Queen Elizabeth 2. Ìgbì òkun tí ó ga tó ilé alájà mẹ́wàá bì lu ọkọ̀ òkun náà, ó sì mú kí ó máa fẹ́ lẹ́ẹ́lẹ́ẹ́ kiri lójú omi bí èdídí onírọ́bà. Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ilé àti àwọn èrò ọkọ̀ náà fọ́n káàkiri nígbà tí ọkọ̀ náà forí sọlẹ̀. Ohun arabaríbí ibẹ̀ ni pé àwọn èrò ọkọ̀ tí iye wọ́n jẹ́ 1,200 wulẹ̀ fi ara pa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni. Ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbígbámúṣé, ẹ̀yà ara ọkọ̀ dáradára, àti bí wọ́n ti ṣe ọkọ̀ náà dáradára sí ni kò jẹ́ kí ọkọ̀ òkun náà fọ́ yáńgá.
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ìjì líle koko kan rọ́ lu ọkọ̀ òkun mìíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn ènìyàn 275 mìíràn wà nínú ọ̀kọ̀. Bí wọ́n ti ń bẹ̀rù pé bí ọwọ́ ìjì náà ṣe le tó yóò fọ́ ọkọ̀ òkun náà yáńgá, a rí í tí àwọn atukọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fa “àwọn ohun aṣèrànlọ́wọ́”—àwọn ṣéènì tàbí okùn—gba abẹ́ ọkọ̀ òkun náà láti ìhà kan sí ìhà kejì láti mú àwọn pákó tí wọ́n fi ṣe ara ọkọ̀ òkun oníṣòwò yìí pọ̀. Gbogbo àwọn èrò ọkọ̀ tó wà níbẹ̀ ló là á já, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ òkun náà kò lá á já.—Ìṣe, orí 27.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìdánwò nínú ìgbésí ayé lè mú kí a nímọ̀lára bíi pé a wà nínú ọkọ̀ òkun kan tí ó wà lórí òkun tí ń ru gùdù. Àwọn ìgbì hílàhílo, ìjákulẹ̀, àti ìsoríkọ́ lè pò wá rúurùu, ní dídán ìfẹ́ wa wò dé góńgó. Láti borí irú àwọn ìgbì bẹ́ẹ̀, kí a sì yẹra fún ìwópalẹ̀ túútúú, àwa pẹ̀lú nílò ìrànlọ́wọ́ díẹ̀.
Nígbà Tí Pákáǹleke Bá Ṣẹlẹ̀
Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti ìfaradà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sínú Bíbélì lọ́nà tí ó dára. Ó ṣe làálàá lórí àwọn ìjọ Kristẹni ìjímìjí. (Kọ́ríńtì Kejì 11:24-28) Àwọn àṣeyọrí rẹ̀ nínú iṣẹ́ Olúwa pèsè ẹ̀rí kedere nípa ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí ó ní fún àwọn aládùúgbò rẹ̀ àti ipò ìbátan lílágbára rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Síbẹ̀, ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù kò fi bẹ́ẹ̀ mìrìngìndìn. Lọ́nà olówuuru àti ti ìṣàpẹẹrẹ, àpọ́sítélì náà borí ọ̀pọ̀ pákáǹleke.
Ní ọjọ́ ayé Pọ́ọ̀lù, nígbà tí ọkọ̀ òkun kan kó sínú ìjì kan tí ń ru gùdù, lílà á já àwọn èrò ọkọ̀ àti ọkọ̀ òkun náà sinmi lórí òye iṣẹ́ agbo àwọn òṣìṣẹ́ inú ọkọ̀ náà àti lórí bí ọkọ̀ òkun náà ṣe níláti so pọ̀ gírígírí tó. Èyí rí bákan náà nígbà tí àpọ́sítélì yìí ṣalábàápàdé àwọn pákáǹleke lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti borí ìfiduni ti ara, ìfisẹ́wọ̀n, àti ìdálóró, pákáǹleke líle koko jù lọ tí ó pe ìdúródéédéé rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti èrò ìmọ̀lára àti agbára ìṣe rẹ̀ láti máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ níjà wá láti inú ìjọ Kristẹni.
Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù ṣe làálàá fún ọdún kan ààbọ̀ láìṣàárẹ̀ láti fìdí ìjọ tí ó wà ní ìlú ńlá Kọ́ríńtì múlẹ̀. Àwọn ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará Kọ́ríńtì mú kí ó ní ìmọ̀lára jẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún agbo náà. Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ sọ nípa ara rẹ̀ bíi pé òún jẹ́ bàbá fún wọn. (Kọ́ríńtì Kìíní 4:15) Síbẹ̀, láìka àkọsílẹ̀ ìfẹ́ àti iṣẹ́ àṣekára tí ó ń ṣe nítorí ìjọ sí, àwọn kan ní Kọ́ríńtì ń bú Pọ́ọ̀lù. (Kọ́ríńtì Kejì 10:10) Lójú gbogbo ohun tí ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfara-ẹni-rúbọ, ẹ wo bí ìyẹn ti ní láti bà á lọ́kàn jẹ́ tó!
Báwo ni àwọn tí wọ́n ti jàǹfààní ìfẹ́ Pọ́ọ̀lù fàlàlà ṣe lè ya ìkà, kí wọ́n sì jẹ́ olùtàbùkù bẹ́ẹ̀? Pọ́ọ̀lù gbọ́dọ̀ ti nímọ̀lára bíi pé a fa òun ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, bí ọkọ̀ òkun tí ìjì lílé kan rọ́ lù. Ẹ wo bí ìbá ti rọrùn tó fún un láti juwọ́ sílẹ̀, láti ronú pé àwọn ìsapá tí òún ti ṣe kọjá jẹ́ asán, tàbí kí ó bínú! Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe gírí? Kí ni kò jẹ́ kí ìjákulẹ̀ fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
Ìfẹ́ Tí Ó So Wá Pọ̀ Gírígírí
Pọ́ọ̀lù kò jẹ́ kí àwọn òǹkàwé rẹ̀ ṣiyè méjì nípa orísun ìpèsè okun àti ìsúnniṣe rẹ̀ tí kò dábọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:14) Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí orísun títayọ lọ́lá fún okun àti ìsúnniṣe. Ipá tí ó sọ ọ́ di ọ̀rànyàn náà ni “ìfẹ́ tí Kristi ní.” Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí pé: “Pọ́ọ̀lù kò sọ pé ìfẹ́ wa fún Kristi ló so wá pọ̀ gírígírí mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa . . . Ìyẹn yóò wulẹ̀ jẹ́ dídúró ní agbede méjì ọ̀nà. Ìfẹ́ wa fún Kristi ni a ń ru sókè, a sì ń ṣìkẹ́ rẹ̀ léraléra nípa ìfẹ́ rẹ̀ fún wa.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Ìfẹ́ tí Kristi fi hàn nípa jíjọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ikú aronilára lórí òpó igi oró—tí ó wá tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀mí ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ bí ìràpadà láti gba gbogbo aráyé onígbàgbọ́ là—sún Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́, sọ ọ́ di ọ̀rànyàn, ó sì kàn án nípá fún un láti máa bá a lọ láti ṣiṣẹ́ sìn pẹ̀lú ire Kristi àti ẹgbẹ́ àwọn ará lọ́kàn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ Kristi darí Pọ́ọ̀lù, ní ṣíṣàìjẹ́ kí ó ní ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan, ó sì fi ète rẹ̀ mọ sórí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀.
Láìṣeé sẹ́, orísun ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn ipa ọ̀nà ìgbésí ayé ìṣòtítọ́ Kristẹni ni ìfẹ́ Kristi. Nígbà tí a bá kojú àwọn ìdánwò tí ó lè ní ipa aṣèparun lórí wa ní ti ara ìyára, èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí, ipá tí ń sọ ọ́ di ọ̀ranyàn nínú ìfẹ́ Kristi yóò jẹ́ kí a lè lọ ré kọjá ibi tí ẹnì kan tí kò ní ìsúnniṣe tí ó tó yóò ti juwọ́ sílẹ̀. Ó ń fún wa ní okun láti fara dà á.
A kò lè gbíyè lé èrò ìmọ̀lára aláìpé wa fún ìtìlẹ́yìn àti ìsúniṣiṣẹ́. Èyí rí bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì nígbà tí ìdánwò wa bá ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìjákulẹ̀ àti hílàhílo. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìfẹ́ Kristi ní agbára láti sọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa di ọ̀ranyàn fún wa, láti ṣètìlẹ́yìn, kí ó sì sún wa ṣiṣẹ́, láìka ìdánwò wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sí. Ìfẹ́ Kristi ń jẹ́ kí Kristẹni kan lè lo ìfaradà tí ó ré kọjá ìfojúsọ́nà àwọn ẹlòmíràn, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó ré kọjá ìfojúsọ́nà òun fúnra rẹ̀ pàápàá.
Síwájú sí i, níwọ̀n bí ìfẹ́ Kristi ti jẹ́ èyí tí ó wà pẹ́ títí, ìyọrísí rẹ̀ kò lè lópin. Ipá ọ̀ranyàn tí kì í mì tàbí kí ó dín kù ló jẹ́. “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (Kọ́ríńtì Kìíní 13:8) Ó ń jẹ́ kí a lè máa fi ìdúróṣinṣin tẹ̀ lé e, láìtàrò ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.
Àwọn ìdánwò èrò ìmọ̀lára ń lo ipá kan tí ó lè fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a máa ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ tí Kristi fi hàn fún wa. Ìfẹ́ Kristi yóò so wá pọ̀ gírígírí. Ìfẹ́ rẹ̀ mú kí ó ṣeé ṣe láti má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa rì. (Tímótì Kìíní 1:14-19) Síwájú sí i, ìfẹ́ Kristi sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa láti ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti yin Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó mú kí ìfihàn ìfẹ́ Kristi ṣeé ṣe, lógo.—Róòmù 5:6-8.