-
Bá A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
3. (a) Ojú wo ni Jésù fi wo ètò òṣèlú nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tá a fẹ̀mí yàn ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀? (Fi àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kún un.)
3 Dípò kí Jésù bá wọn dá sí ètò òṣèlú nígbà tó wà láyé, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, ìyẹn Ìjọba tí Ọlọ́run máa gbé kalẹ̀ lókè ọ̀run èyí tí Jésù máa ṣàkóso lé lórí gẹ́gẹ́ bí Ọba. (Dáníẹ́lì 7:13, 14; Lúùkù 4:43; 17:20, 21) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n mú Jésù lọ síwájú Gómìnà Róòmù náà, Pọ́ńtíù Pílátù, ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa fífi hàn pé Kristi àti Ìjọba rẹ̀ làwọn fara mọ́, tí wọ́n sì ń kéde Ìjọba náà fún gbogbo ayé. (Mátíù 24:14) Ìyẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Nítorí náà, àwa jẹ́ ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi . . . gẹ́gẹ́ bí àwọn adípò fún Kristi, àwa bẹ̀bẹ̀ pé: ‘Ẹ padà bá Ọlọ́run rẹ́.’”a—2 Kọ́ríńtì 5:20.
4. Ọ̀nà wo ni gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbà fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run làwọn fara mọ́? (Wo Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Tí Wọn Ò Dá Sí Ọ̀ràn Òṣèlú.)
4 Nítorí pé àwọn ikọ̀ máa ń ṣojú fún ọba tàbí orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ òkèèrè, wọn kì í dá sí ọ̀ràn abẹ́lé tó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá rán wọn lọ; ohun tí wọ́n bá bá lọ ni wọ́n máa ń gbájú mọ́. Àmọ́, àwọn ikọ̀ máa ń gbẹnu sọ fún orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń ṣojú fún. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tá a fẹ̀mí yàn, tí ‘ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aráàlú ń bẹ ní ọ̀run’ náà ṣe rí nìyẹn. (Fílípì 3:20) Kódà, ọpẹ́lọpẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ń fìtara ṣe, ìyẹn ló ti mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” Kristi lọ́wọ́ láti “padà bá Ọlọ́run rẹ́.” (Jòhánù 10:16; Mátíù 25:31-40) Àwọn tí wọ́n ràn lọ́wọ́ yìí ló wá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú ikọ̀ fún Kristi, ní ti pé wọ́n ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn arákùnrin Jésù tá a fẹ̀mí yàn. Gẹ́gẹ́ bí agbo kan tó ń fi ìṣọ̀kan gbẹnu sọ fún Ìjọba Mèsáyà náà, àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì kì í lọ́wọ́ sí ètò òṣèlú lọ́nà èyíkéyìí.—Ka Aísáyà 2:2-4.
-
-
Bá A Ṣe Lè Ya Ara Wa Sọ́tọ̀ Kúrò Nínú Ayé‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
a Látìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì, lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí múlẹ̀, ni Kristi ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tá a fẹ̀mí yàn, tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. (Kólósè 1:13) Nígbà tó di ọdún 1914, Ọlọ́run gbé àṣẹ lé Kristi lọ́wọ́ láti máa ṣàkóso lórí “ìjọba ayé.” Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn pẹ̀lú ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ tí ń ṣojú fún Ìjọba Mèsáyà.—Ìṣípayá 11:15.
-