“Ẹ Ní Ìfẹ́ni Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Fún Ara Yín”
“Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—RÓÒMÙ 12:10.
1, 2. Irú àjọṣe wo ni míṣọ́nárì kan lóde òní àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn?
JÁLẸ̀ ọdún mẹ́tàlélógójì tí Don fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nárì ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ó fẹ́ràn àwọn tó lo ara rẹ̀ fún. Ní báyìí tó ń bá àìsàn kan tó máa gbẹ̀mí rẹ̀ yí, àwọn kan lára àwọn tí Don kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ rìnrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí àìsàn náà dá a gúnlẹ̀ sí kí wọ́n lè fi èdè Kòríà sọ fún un pé, “Kamsahamnida, kamsahamnida!”—“Ẹ ṣeun wa o, ẹ ṣe gan-an ni”! Ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Don ní fáwọn èèyàn yìí wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an.
2 Àpẹẹrẹ ti Don nìkan kọ́ ló wà. Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fáwọn tó lo ara rẹ̀ fún. Pọ́ọ̀lù forí ṣe ó fọrùn ṣe nítorí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé akíkanjú èèyàn ni, síbẹ̀ ó jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́ tó máa ń tọ́jú àwọn èèyàn “bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” Ó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tẹsalóníkà 2:7, 8) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ará Éfésù pé wọn ò ní rí òun mọ́, “ẹkún sísun tí kò mọ níwọ̀n bẹ́ sílẹ̀ láàárín gbogbo wọn, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” (Ìṣe 20:25, 37) Ó ṣe kedere pé àjọṣe tó wà láàárín Pọ́ọ̀lù àtàwọn arákùnrin rẹ̀ ju pé kéèyàn jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ. Wọ́n ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara wọn.
Ìfẹ́ni Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ìfẹ́
3. Báwo làwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tá a túmọ̀ sí ìfẹ́ni àti ìfẹ́ ṣe wọnú ara?
3 Nínú Ìwé Mímọ́, àwọn ànímọ́ bíi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ìgbatẹnirò àti ìyọ́nú wé mọ́ ànímọ́ Kristẹni tó dára jù lọ náà, ìfẹ́. (1 Tẹsalóníkà 2:8; 2 Pétérù 1:7) Gẹ́gẹ́ bí apá kọ̀ọ̀kan lára dáyámọ́ǹdì rírẹwà ṣe rí, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn ànímọ́ rere yìí jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀ téèyàn á fi ní ìwà rere. Kì í ṣe pé àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń mú káwọn Kristẹni túbọ̀ sún mọ́ ara wọn nìkan ni, àmọ́ ó tún ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Baba wọn tó wà lọ́run. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè. . . . Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 12:9, 10.
4. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” túmọ̀ sí?
4 Apá méjì ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” pín sí, apá àkọ́kọ́ túmọ̀ sí ìbádọ́rẹ̀ẹ́, apá kejì túmọ̀ sí ìfẹ́ téèyàn dìídì ní fún ẹnì kan. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan ṣe ṣàlàyé, èyí túmọ̀ sí pé “ohun tá a fi ń dá [àwọn Kristẹni] mọ̀ ni pé wọ́n ni ìfẹ́ àtọkànwá tó máa ń wà nínú ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n ṣọ̀kan, tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́.” Ṣé bó ṣe máa ń rí lára rẹ nìyẹn nígbà tó o bá wà láàárín àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ àtàwọn arábìnrin rẹ? Ńṣe ló yẹ kí ìjọ Kristẹni jẹ́ ibì kan tí ẹ̀mí ọ̀yàyà ti gbilẹ̀—ibì kan tí wọ́n ti mú ara wọn bí mọ̀lẹbí. (Gálátíà 6:10) Ìdí rèé tí Bíbélì The New Testament in Modern English, látọwọ́ J. B. Phillips, fi túmọ̀ Róòmù 12:10 pé: “Ẹ jẹ́ ká ní ìfẹ́ ọlọ́yàyà fún ara wa bí èyí tó wà láàárín ọmọ ìyà kan náà.” Bíbélì The Jerusalem Bible kà pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bó ṣe yẹ kí ọmọ ìyà kan náà ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tó mú káwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wọn kì í wulẹ̀ ṣe nítorí pé ó bọ́gbọ́n mu kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí nítorí pé ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ni. A ní láti fẹ́ràn ara wa “pẹ̀lú ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè,” ká “nífẹ̀ẹ́ ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì lọ́nà gbígbóná janjan láti inú ọkàn-àyà wá.”—1 Pétérù 1:22.
‘Ọlọ́run Ti Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Ara Wa’
5, 6. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe lo àpéjọ àgbáyé láti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìfẹ́ni Kristẹni? (b) Báwo làwọn ará ṣe máa túbọ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa bí wọ́n ṣe jọ wà pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ” ti di tútù nínú ayé yìí, síbẹ̀ Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.” (Mátíù 24:12; 1 Tẹsalóníkà 4:9) Àpéjọ àgbáyé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe jẹ́ àkókò kan tá a fi ń gba ẹ̀kọ́ yìí. Nígbà àpéjọ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lórílẹ̀-èdè tá a ti fẹ́ ṣe ìpàdé náà lọ máa ń pàdé àwọn tó ti ilẹ̀ ibòmíràn wá, ọ̀pọ̀ lára wọn á sì tún gba wọ́n sílé. Àwọn kan lára àwọn tó wá sí àpéjọ àgbáyé kan tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí wá láti orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn kì í máa ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Kristẹni kan tó wà lára àwọn tó ṣètò ilé fáwọn tó wá sí àpéjọ náà sọ pé: “ Ọkàn àwọn tó wá sípàdé náà ò balẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ dé, ojú sì máa ń tì wọ́n. Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ dágbére lẹ́yìn ọjọ́ kẹfà tí wọ́n lò, ńṣe làwọn ará yìí àtàwọn tó gbà wọ́n lálejò dì mọ́ra wọn, omi sì ń dà lójú wọn. Inú wọn dùn pé àwọn jàǹfààní ìfẹ́ Kristẹni tí wọn ò ní gbàgbé láé.” Ṣíṣe àwọn arákùnrin wa lálejò láìka irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ sí lè mú ká rí ànímọ́ rere tí onílé àti àlejò náà ní.—Róòmù 12:13.
6 Òótọ́ ni pé àwọn àpéjọ bí irú èyí máa ń mórí ẹni yá, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún tí àwọn Kristẹni ti jọ ń jọ́sìn Jèhófà máa ń jẹ́ kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn túbọ̀ dán mọ́rán. Tá a bá mọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa dáadáa, a ó túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ̀ rere tí wọ́n ní, ìyẹn ìṣòtítọ́ wọn, jíjẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, ìdúróṣinṣin wọn, inú rere wọn, ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wọn, ẹ̀mí ìgbatẹnirò wọn, ìyọ́nú wọn, àti ẹ̀mí àìmọtara ẹni nìkan tí wọ́n ní. (Sáàmù 15:3-5; Òwe 19:22) Mark, tó ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Tí àwa àtàwọn arákùnrin wa bá jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, a óò mọwọ́ ara wa débi pé kò ní sí nǹkan tó máa lè yà wá.”
7. Kí lohun tó yẹ ká ṣe ká lè gbádùn ìfẹ́ni Kristẹni nínú ìjọ?
7 Tá a bá fẹ́ kí àwa àtàwọn tá a jọ wá nínú ìjọ mọwọ́ ara wa dáadáa, ká sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, a ní láti sún mọ́ ara wa. Tá a bá ń wá sí ìpàdé Kristẹni déédéé, a óò mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa túbọ̀ lágbára sí i. Tá a bá ń wá sáwọn ìpàdé, tá à ń bá àwọn ará kẹ́gbẹ́ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, tá a sì ń kópa nínú ìpàdé, ńṣe là ń fún ara wa níṣìírí tá a sì ń ru ara sókè “sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Hébérù 10:24, 25) Alàgbà kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mo rántí dáadáa pé nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìdílé wa wà lára àwọn tó máa ń gbẹ̀yìn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, a máa ń tẹsẹ̀ dúró kí àwa àtàwọn ará tó kù lè jọ máa sọ̀rọ̀.”
Ǹjẹ́ Kò Yẹ Kó O “Gbòòrò Síwájú”?
8. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú”? (b) Kí la lè ṣe láti mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ nínú ìjọ?
8 Kí á lè lo irú ìfẹ́ yìí dáadáa, a ní láti mú ọkàn wa “gbòòrò síwájú.” Nínú ìwé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Ọkàn-àyà wa ti gbòòrò síwájú. Àyè kò há fún yín ní inú wa.” Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé kí àwọn náà “gbòòrò síwájú.” (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Ṣé ìwọ náà lè mú kí ìfẹ́ rẹ “gbòòrò síwájú”? Kò dìgbà tí àwọn ẹlòmíì bá wá bá ọ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, yàtọ̀ sí pé ó sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó tún rọ̀ wọ́n pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Ọ̀nà kan láti bọlá fáwọn ẹlòmíràn ni pé kó o kí wọn nípàdé dípò tí wàá fi máa retí pé kí wọ́n kọ́kọ́ wá kí ọ. O tún lè ní kí ìwọ àtàwọn jọ lọ sóde ẹ̀rí tàbí kẹ́ ẹ jọ múra sílẹ̀ fún ìpàdé. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kí ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ pọ̀ sí i.
9. Kí ni ohun tí àwọn kan ṣe kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwọn àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lè túbọ̀ jinlẹ̀? (Mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ tó o mọ̀ lágbègbè rẹ.)
9 Àwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ títí kan ẹnì kọ̀ọ̀kan lè “gbòòrò síwájú” nípa lílọ sílé ara wọn bóyá kí wọ́n tiẹ̀ jọ jẹun tàbí kí wọ́n jọ kópa nínú ìgbòkègbodò kan tó dára. (Lúùkù 10:42; 14:12-14) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Hakop máa ń ṣètò àsìkò ìgbádùn fún ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ kan. Ó sọ pé: “Tọmọdé tàgbà ló máa ń wà níbẹ̀ títí kan àwọn òbí anìkàntọ́mọ. Gbogbo wọn ni inú wọn máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá padà délé, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọwọ́ ara wọn dáadáa.” Ó yẹ kí àwa tá a jọ jẹ́ Kristẹni sapá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, kì í kàn án ṣe ká wulẹ̀ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nìkan.—3 Jòhánù 14.
10. Kí la lè ṣe nígbà tí àárín àwa àtàwọn arákùnrin wa kò bá gún régé?
10 Àmọ́ nígbà mìíràn, jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé lè máà jẹ́ kó rọrùn fún wa láti bá àwọn ẹlòmíràn ṣọ̀rẹ́ tàbí ká nífẹ̀ẹ́ wọn. Kí la lè ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a lè gbàdúrà pé kí àárín àwa àtàwọn arákùnrin wa gún régé. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn, yóò sì gbọ́ irú àdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀. (1 Jòhánù 4:20, 21; 5:14, 15) Ó tún yẹ ká ṣe nǹkan kan nípa ohun tá à ń gbàdúrà fún. Òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò kan tó ń jẹ́ Ric ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà sọ nípa arákùnrin kan tí ìwà rẹ̀ mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti bá a da nǹkan pọ̀. Ric sọ pé, “dípò tí màá fi yẹra fún arákùnrin náà, mo pinnu láti túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. Àṣé, èèyàn tó le ni bàbá tó bí i lọ́mọ. Lẹ́yìn tí mo sì ti rí akitiyan tí arákùnrin náà ti ṣe láti rí i pé òun borí ìṣòro yìí àti ìyípadà tó ti ní, ọkàn mi fà sí i. Bá a sì ṣe di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nìyẹn.”—1 Pétérù 4:8.
Máa Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀!
11. (a) Kí ló yẹ ká máa ṣe kí ìfẹ́ bàa lè gbilẹ̀ nínú ìjọ? (b) Kí nìdí tó fi léwu nípa tẹ̀mí pé kéèyàn má máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀?
11 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé ìgbé ayé wọn láìbá ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́. Ó má ṣe o! Àmọ́, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni. Kì í kàn án ṣe ká máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tàbí ká máa buyì fúnni tàbí ká máa bẹ́ mọ́ọ̀yàn káàkiri ló máa fi hàn pé a ní ìfẹ́ ará tòótọ́. Dípò ìyẹn, ó yẹ ká ṣe tán láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa ń ṣe sáwọn ará Kọ́ríńtì, ká sì jẹ́ káwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ mọ̀ pé lóòótọ́ ni ọ̀ràn wọn ká wa lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn kọ́ ló mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ tàbí tára wọn máa ń yá mọ́ọ̀yàn, síbẹ̀ ó léwu téèyàn bá lọ tutù jù. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.
12. Kí nìdí tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dán mọ́rán fi ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ara wa nínú ìjọ?
12 Bíbá ara wa sòótọ́ ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́. (Jòhánù 15:15) Gbogbo wa la nílò ọ̀rẹ́ tá a lè máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. Yàtọ̀ síyẹn, bá a bá ṣe dojúlùmọ̀ ara wa tó bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rọrùn tó láti bojú tó ọ̀ràn ara wa. Tá a bá jẹ́ kí ọrọ̀ àwọn ará jẹ́ wá lógún lọ́nà yìí, ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ á túbọ̀ gbilẹ̀ nínú ìjọ, a óò sì rí ìmúṣẹ òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35; Fílípì 2:1-4.
13. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa lóòótọ́?
13 Kí ìfẹ́ wa tó lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní tó pọ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi ìfẹ́ náà bá àwọn èèyàn lò. (Òwe 27:5) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la ní ìfẹ́, á hàn lójú wa, èyí sì lè mú káwọn ẹlòmíràn nífẹ̀ẹ́ àwa náà. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ìtànyòò ojú a máa mú kí ọkàn-àyà yọ̀.” (Òwe 15:30) Tá a bá ṣe ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní, èyí lè mú kí ìfẹ́ túbọ̀ gbilẹ̀ sí i. Òótọ́ ni pé a ò lè fowó ra ìfẹ́ tòótọ́, síbẹ̀ ẹ̀bùn tá a bá fún èèyàn látọkànwá ṣe pàtàkì. Káàdì ìkíni, lẹ́tà àti “ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́” jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀. (Òwe 25:11; 27:9) Nígbà tí àwa àtàwọn ẹlòmíràn bá ń ṣọ̀rẹ́, ó yẹ ká máa bá a lọ nípa lílo ìfẹ́ tí kò fi ìmọtara ẹni nìkan hàn. A ó fẹ́ láti ran àwọn ọ̀rẹ́ wa lọ́wọ́, àgàgà lákòókò ìṣòro. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
14. Kí lohun tá a lè ṣe tó bá dà bíi pé ẹnì kan tá a fi ìfẹ́ hàn sí kò fẹ́ fi ìfẹ́ hàn sí wa padà?
14 Ká sòótọ́, a ò lè retí pé kí àwa àti gbogbo àwọn ará ìjọ jọ máa ṣe wọléwọ̀de. Àá sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ. Nítorí náà, tó bá dà bí ẹni pé ẹnì kan ò sún mọ́ ọ tó bó o ṣe fẹ́, má ṣe yára da ara rẹ̀ lẹ́bi pé ìwọ lo níṣòro tàbí pé ẹ̀bi onítọ̀hún ni. Má sì ṣe sọ pé àfi dandan kó o bá onítọ̀hún ṣọ̀rẹ́. Tó o bá sún mọ́ ọn dé ìwọ̀n tó gbà ọ́ láyé dé, èyí lè mú kó ṣeé ṣe fún ìwọ àti onítọ̀hún láti túbọ̀ dọ̀rẹ́ lọ́jọ́ iwájú.
“Mo Ti Tẹ́wọ́ Gbà Ọ́”
15. Ipa wo ni ìgbóríyìn máa ń ní lórí àwọn èèyàn, ipa wo sí ni àìsí ìgbóríyìn máa ń ní lórí wọn?
15 Inú Jésù á mà dùn gan-an o lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi nígbà tó gbọ́ ohùn kan látọ̀run tó sọ pé: “Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́”! (Máàkù 1:11) Ó dájú pé gbólóhùn ìtẹ́wọ́gbà yìí á mú kó túbọ̀ dá Jésù lójú pé Baba rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 5:20) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan ò tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn bẹ́ẹ̀ rí lẹ́nu àwọn tí wọ́n buyì fún tí wọ́n sì fẹ́ràn. Ann sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bíi tèmi ló wà tí gbogbo àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wọn ò fara mọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni wọn. Ọ̀rọ̀ àríwísí ni irú àwa ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń gbọ́ nílé. Irú nǹkan báyìí sì máa ń bà wá nínú jẹ́.” Àmọ́ nígbà tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ, wọ́n wá rí ìfẹ́ àti àbójútó tí ìdílé nípa tẹ̀mí ń fún wọn, ìyẹn bàbá, màmá, ẹ̀gbọ́n àti àbúrò lọ́kùnrin lóbìnrin, nínú ìgbàgbọ́.—Máàkù 10:29, 30; Gálátíà 6:10.
16. Kí nìdí tí ṣíṣe àríwísí àwọn ẹlòmíràn kò fi dára?
16 Láwọn apá ibi kan láyé yìí, àwọn òbí, àtàwọn àgbàlagbà, títí kan àwọn olùkọ́ kì í sábà gbóríyìn fáwọn èwe nítorí wọ́n rò pé tí wọ́n bá ń yìn wọ́n, wọ́n ò ní máa kọbi ara sí nǹkan mọ́ tàbí pé wọ́n á máa gbéra ga. Irú èrò bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè ṣàkóbá fáwọn ìdílé Kristẹni àti ìjọ. Nígbà táwọn àgbàlagbà bá fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ tí ọ̀dọ́ kan ṣe nípàdé tàbí nǹkan mìíràn tó ṣe, wọ́n lè sọ pé: “Ó káre, àmọ́ ó lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ!” Wọ́n tiẹ̀ lè wá ṣe bíi pé inú àwọn ò dùn sí èwe kan làwọn ọ̀nà kan pàápàá. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ṣíṣe tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ yóò sún àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí láti máa fi gbogbo agbára wọn ṣe nǹkan dé ibi tí wọ́n bá lè ṣe é dé. Àmọ́ ibi tí irú ọ̀rọ̀ yìí sábà máa ń jà sí kì í dára nítorí pé àwọn èwe lè wá lọ́tìkọ̀ tàbí kí wọ́n rò pé àwọn ò lè kúnjú ìwọ̀n.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká wá ọ̀nà láti gbóríyìn fáwọn ẹlòmíràn?
17 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kó jẹ́ kìkì ìgbà tá a bá fẹ́ fún ẹnì kan nímọ̀ràn la máa tó yin onítọ̀hún. Gbígbóríyìn fúnni látọkànwá máa ń mú kí ìfẹ́ gbilẹ̀ láàárín ìdílé àti nínú ìjọ, èyí sì máa ń mú káwọn èwe fẹ́ láti lọ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ti pẹ́ nínú òtítọ́. Nítorí náà, dípò tá a máa fi jẹ́ kí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ pinnu ohun tá a máa ṣe sí ẹlòmíràn, ẹ jẹ́ ká “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” Máa gbóríyìn fáwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe máa ń ṣe.—Éfésù 4:24.
18. (a) Ẹ̀yin èwe, irú ojú wo ló yẹ kẹ́ ẹ máa fi wo ìmọ̀ràn táwọn àgbàlagbà bá fún yín? (b) Kí nìdí táwọn àgbàlagbà fi máa ń ronú dáadáa lórí ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fẹ́ fúnni?
18 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀yin ọ̀dọ́, táwọn àgbàlagbà bá gbà yín nímọ̀ràn, ẹ má ṣe rò pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ yín. (Oníwàásù 7:9) Wọ́n nífẹ̀ẹ́ yín o! Ó lè jẹ́ pé ọ̀ràn yín tó jẹ wọ́n lógún àti ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí wọ́n ní fún yín ló mú kí wọ́n máa fún yín nímọ̀ràn. Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni wọ́n á máa yọ ara wọn lẹ́nu sí pé àwọn ń bá yín sọ̀rọ̀? Nítorí pé àwọn àgbàlagbà—àgàgà àwọn alàgbà—mọ agbára tí ọ̀rọ̀ ní, ni wọ́n ṣe máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò ronú tí wọ́n á sì tún gbàdúrà kí wọ́n tó gbà yín nímọ̀ràn, torí pé ire yin ni wọ́n ń wá.—1 Pétérù 5:5.
“Jèhófà Jẹ́ Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Gidigidi Nínú Ìfẹ́ni”
19. Kí nìdí táwọn tó rí ìjákulẹ̀ fi lè máa wojú Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́?
19 Àwọn nǹkan tí kò bára dé tó ṣẹlẹ̀ sáwọn mìíràn ti lè mú kí wọ́n máa rò pé táwọn bá tún wá ń fi ìfẹ́ bá àwọn èèyàn lò, ìjákulẹ̀ ló máa já sí. Ó gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó lè sọ gbogbo ọ̀kan wọn fáwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́, kí wọ́n má ṣe gbàgbé pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” Jèhófà sọ fún wa pé ká sún mọ́ òun. (Ìṣe 17:27; Jákọ́bù 4:8) Ó tún mọ̀ pé a lè máa bẹ̀rù pé àwọn èèyàn á ṣe ohun tó máa dùn wá, ìyẹn ló mú kó ṣèlérí pé òun yóò dúró tì wá àti pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́. Onísáàmù náà Dáfídì mú kó dá wa lójú pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
20, 21. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé a lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà? b) Kí lohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà?
20 Àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ni àjọṣe tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè ní. Àmọ́, ṣé irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí àwọn ẹni ìgbàgbọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wa ọ̀run. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń túni lára tí wọ́n sọ wà lákọsílẹ̀ kí ọkàn wa lè balẹ̀ pé àwa náà lè sún mọ́ Jèhófà.—Sáàmù 23, 34, 139, Jòhánù 16:27; Róòmù 15:4.
21 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe ká bàa lè ní àjọse tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun kì í ṣe ohun tágbára wa ò lè ká. Dáfídì béèrè pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? . . . Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Sáàmù 15:1, 2; 25:14) Bá a ṣe rí i pé èrè púpọ̀ wà nínú sísin Ọlọ́run, èyí mú kó máa darí wa kó sì máa dáàbò bò wá, a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni.”—Jákọ́bù 5:11.
22. Irú àjọse wo ni Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn òun ní?
22 Ẹ ò rí pé ìbùkún ńlá gbáà ló jẹ́ pé Jèhófà ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú aráyé aláìpé! Ǹjẹ́ kò yẹ́ káwa náà máa nífẹ̀ẹ́ ara wa? Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, olúkúlùkù wa lè mú kí ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tá a fi mọ ẹgbẹ́ ará Kristẹni pọ̀ sí i, a sì lè jàǹfààní látinú ìfẹ́ ọ̀hún. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn títí láé.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo lo ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe sí ara wọn nínú ìjọ?
• Ọ̀nà wo ni olúkúlùkù wa lè gbà mú kí ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ pọ̀ sí i nínú ìjọ?
• Báwo ni ìgbóríyìn àtọkànwá ṣe lè mú kí ìfẹ́ Kristẹni pọ̀ sí i?
• Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ní gbà ń ràn wá lọ́wọ́, tó sì ń gbé wa ró?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìfẹ́ táwọn Kristẹni ní sí ara wọn kì í kàn án ṣe ọ̀ràn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe nìkan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ǹjẹ́ o lè mú ìfẹ́ rẹ “gbòòrò síwájú”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣé alárìíwísí ni ọ́ ni àbí ẹni tó ń fúnni ní ìṣírí?