Ṣíṣàjọpín Ìtùnú Tí Jèhófà Ń Pèsè
“Ìrètí wa fún yín dúró láìmì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní tòótọ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti jẹ́ alájọpín àwọn ìjìyà náà, ní ọ̀nà kan náà ni ẹ̀yin yóò ṣàjọpín ìtùnú pẹ̀lú.”—KỌ́RÍŃTÌ KEJÌ 1:7.
1, 2. Kí ni ó ti jẹ́ ìrírí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ti di Kristẹni lónìí?
Ọ̀PỌ̀ àwọn tí ń ka Ilé Ìṣọ́ nísinsìnyí dàgbà láìní ìmọ̀ nípa òtítọ́ Ọlọ́run. Bóyá bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn tìrẹ ṣe rí. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ronú padà sẹ́yìn nípa bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí nígbà tí ojú inú rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí o kọ́kọ́ lóye pé àwọn òkú kì í jìyà, ṣùgbọ́n pé wọn kò mọ ohunkóhun, ara kò ha tù ọ́ bí? Nígbà tí o sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí tí ó wà fún àwọn òkú, pé a óò jí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù padà sí ìyè nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a kò ha tù ọ́ nínú bí?—Oníwàásù 9:5, 10; Jòhánù 5:28, 29.
2 Ìlérí Ọlọ́run láti fòpin sí ìwà ibi àti láti sọ ilẹ̀ ayé yìí di párádísè kan ńkọ́? Nígbà tí o kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí, kò ha tù ọ́ nínú, kò ha sì mú ọ ní ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà bí? Báwo ni ìmọ̀lára rẹ ti rí nígbà tí o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ṣíṣeé ṣe náà láti má ṣe kú láé ṣùgbọ́n láti là á já sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ yẹn? Dájúdájú, ó mú orí rẹ yá gágá. Bẹ́ẹ̀ ni, o ti rí ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run tí ń tuni nínú gbà, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ nísinsìnyí jákèjádò ayé.—Orin Dáfídì 37:9-11, 29; Jòhánù 11:26; Ìṣípayá 21:3-5.
3. Èé ṣe tí ìpọ́njú fi ń dé bá àwọn tí ń ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run tí ń tuni nínú pẹ̀lú?
3 Ṣùgbọ́n, nígbà tí o gbìyànjú láti ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ìwọ pẹ̀lú wá mọ̀ pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (Tẹsalóníkà Kejì 3:2) Ó ṣeé ṣe pé díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tẹ́lẹ̀ rí fi ọ́ ṣẹlẹ́yà nítorí fífi ìgbàgbọ́ hàn nínú àwọn ìlérí Bíbélì. O tilẹ̀ ti lè jìyà inúnibíni nítorí bíbá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àtakò náà ti lè gbóná janjan bí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìyípadà láti mú ìgbésí ayé rẹ bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. O bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí ìpọ́njú tí Sátánì àti ayé rẹ̀ ń mú wá sórí gbogbo àwọn tí ó bá tẹ́wọ́ gba ìtùnú Ọlọ́run.
4. Ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi ìfẹ́ hàn fi lè hùwà padà sí ìpọ́njú?
4 Ó bani nínú jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, ìpọ́njú ń mú kí àwọn kan kọsẹ̀, kí wọ́n sì dá ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn pẹ̀lú ìjọ Kristẹni dúró. (Mátíù 13:5, 6, 20, 21) Àwọn mìíràn fara da ìpọ́njú nípa pípa ọkàn wọn pọ̀ sórí àwọn ìlérí tí ń tuni nínú tí wọ́n ń kọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. (Mátíù 28:19, 20; Máàkù 8:34) Àmọ́ ṣáá o, ìpọ́njú kì í dáwọ́ dúró nígbà tí Kristẹni kan bá ṣe batisí. Fún àpẹẹrẹ, wíwà láìlábàwọ́n lè jẹ́ ìjàkadì líle koko fún ẹnì kan tí ó ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla látilẹ̀wá. Àwọn mìíràn ní láti dojú kọ àtakò àtìgbàdégbà láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí kò gbà gbọ́. Ohun yòó wù kí ìpọ́njú náà jẹ́, gbogbo àwọn tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ lépa ìgbésí ayé oníyàsímímọ́ sí Ọlọ́run lè ní ìdánilójú ohun kan. Ní ọ̀nà kan tí ó jẹ́ tí ara ẹni gan-an, wọn yóò rí ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà.
“Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
5. Ní àfikún sí ọ̀pọ̀ ìpọ́njú tí ó dé bá Pọ́ọ̀lù, kí ni ó tún nírìírí rẹ̀?
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹnì kan tí ó ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún ìtùnú tí Ọlọ́run ń pèsè. Lẹ́yìn àkókò àdánwò ńlá ní Éṣíà àti ní Makedóníà, ara tù ú gidigidi nígbà tí ó gbọ́ pé ìjọ Kọ́ríńtì ti dáhùn padà lọ́nà rere sí lẹ́tà tí ó fi bá wọn wí. Èyí sún un láti kọ lẹ́tà kejì sí wọn, tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Bàbá Olúwa wa Jésù Kristi, Bàbá àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4.
6. Kí ni a rí kọ́ láti inú àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4?
6 Ọ̀rọ́ pọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí a fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bá sọ̀rọ̀ ìyìn tàbí dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, tàbí tí ó bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀ nínú lẹ́tà rẹ̀, a sábà máa ń rí i pé ó máa ń fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún Jésù, Orí ìjọ Kristẹni. (Róòmù 1:8; 7:25; Éfésù 1:3; Hébérù 13:20, 21) Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìyìn yìí fún “Ọlọ́run àti Bàbá Olúwa wa Jésù Kristi.” Lẹ́yìn náà, fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú àwọn ìwé rẹ̀, ó lo ọ̀rọ̀ orúkọ èdè Gíríìkì kan tí a túmọ̀ sí “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Ọ̀rọ̀ orúkọ yìí wá láti inú ọ̀rọ̀ kan tí a ń lò láti fi ìbànújẹ́ hàn nígbà tí ẹlòmíràn bá ń jìyà. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti Ọlọ́run fún èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ olùṣòtítọ́ tí ń jìyà ìpọ́njú—ìmọ̀lára oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí ó ń sún Ọlọ́run láti gbégbèésẹ̀ tàánútàánú nítorí wọn. Ní paríparí rẹ̀, Pọ́ọ̀lù wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí orísun ànímọ́ fífani mọ́ra yìí nípa pípè é ní “Bàbá àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.”
7. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo”?
7 “Àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ti Ọlọ́run ń mú ìtura wá fún ẹni tí ìpọ́njú dé bá. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù tẹ̀ síwájú láti ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” Nípa báyìí, ìtùnú yòó wù tí a lè rí gbà láti ara inú rere ti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, a lè wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí orísun rẹ̀. Kò sí ìtùnú gidi, tí ó wà pẹ́ títí, tí kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Síwájú sí i, òun ni ó dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, tí ó tipa báyìí mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ olùtùnú. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì ni ó ń sún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fi àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí àwọn tí ó nílò ìtùnú.
A Kọ́ Wa Láti Jẹ́ Olùtùnú
8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ni orísun àwọn àdánwò wa, ipa ṣíṣàǹfààní wo ni ìfaradà wa lè ní lórí wa?
8 Bí Jèhófà Ọlọ́run tilẹ̀ fàyè gba onírúurú àdánwò tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́, òun kò fìgbà kan rí jẹ́ orísun irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 1:13) Ṣùgbọ́n, ìtùnú tí òun ń pèsè nígbà tí a bá ń fara da ìpọ́njú lè kọ́ wa láti túbọ̀ wà lójúfò sí àìní àwọn ẹlòmíràn. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Kí àwa lè tu àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” (Kọ́ríńtì Kejì 1:4) Nípa báyìí, Jèhófà ń kọ́ wa láti jẹ́ ẹní tí ń ṣàjọpín ìtùnú rẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa àti pẹ̀lú àwọn tí a ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bí a ti ń fara wé Kristi, tí a sì “ń tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—Aísáyà 61:2; Mátíù 5:4.
9. (a) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìjìyà? (b) Báwo ni a ṣe ń tu àwọn ẹlòmíràn nínú nígbà tí a bá fi ìṣòtítọ́ fara da ìpọ́njú?
9 Pọ́ọ̀lù fara da ọ̀pọ̀ ìjìyà, ọpẹ́lọpẹ́ ọ̀pọ̀ jaburata ìtùnú tí ó rí gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. (Kọ́ríńtì Kejì 1:5) Àwa pẹ̀lú lè rí ọ̀pọ̀ jaburata ìtùnú gbà nípa ṣíṣàṣàrò nípa àwọn ìlérí ṣíṣeyebíye ti Ọlọ́run, nípa gbígbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti nípa rírí ìdáhùn Ọlọ́run gbà sí àwọn àdúrà wa. Nípa báyìí, a óò fún wa lókun láti máa bá a nìṣó ní gbígbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ, kí a sì máa fi Èṣù hàn ní òpùrọ́. (Jóòbù 2:4; Òwe 27:11) Nígbà tí a bá ti fi ìṣòtítọ́ fara da irú ìpọ́njú èyíkéyìí, gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, a gbọ́dọ̀ fi gbogbo ògo rẹ̀ fún Jèhófà, ẹni tí ìtùnú rẹ̀ ń mú kí àwọn Kristẹni dúró ní olùṣòtítọ́ lábẹ́ àdánwò. Ìfaradà àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ ní agbára ìdarí tí ń tuni nínú lórí ẹgbẹ́ àwọn ará, ní mímú kí àwọn ẹlòmíràn pinnu láti “fara da àwọn ìjìyà kan náà.”—Kọ́ríńtì Kejì 1:6.
10, 11. (a) Kí ni àwọn nǹkan díẹ̀ tí ó fa ìpọ́njú fún ìjọ Kọ́ríńtì ìgbàanì? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tu ìjọ Kọ́ríńtì nínú, ìrètí wo ni ó sì sọ jáde?
10 Àwọn ará Kọ́ríńtì ní ìpín tiwọn lára ìjìyà tí ń wá sórí gbogbo Kristẹni tòótọ́. Ní àfikún sí i, wọ́n nílò ìmọ̀ràn láti yọ alágbèrè tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. (Kọ́ríńtì Kìíní 5:1, 2, 11, 13) Ìkùnà láti gbé ìgbésẹ̀ yìí àti láti fòpin sí gbọ́nmisi-omi-ò-to àti ìpínyà ti mú ìtìjú wá sórí ìjọ. Ṣùgbọ́n, wọ́n lo ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n sì fi ojúlówó ìrònúpìwàdà hàn. Fún ìdí èyí, ó fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà gbóríyìn fún wọn, ó sì sọ pé ìhùwàpadà lọ́nà rere wọn sí lẹ́tà òun ti tu òun nínú. (Kọ́ríńtì Kejì 7:8, 10, 11, 13) Ní kedere, ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ náà ti ronú pìwà dà pẹ̀lú. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n nímọ̀ràn láti ‘dárí jì í kí wọ́n sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má baà gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì.’—Kọ́ríńtì Kejì 2:7.
11 Ó dájú pé, lẹ́tà kejì ti Pọ́ọ̀lù ti gbọ́dọ̀ tu ìjọ Kọ́ríńtì nínú. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ète tí ó ní lọ́kàn. Ó ṣàlàyé pé: “Ìrètí wa fún yín dúró láìmì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní tòótọ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jẹ́ alájọpín àwọn ìjìyà náà, ní ọ̀nà kan náà ni ẹ̀yin yóò ṣàjọpín ìtùnú pẹ̀lú.” (Kọ́ríńtì Kejì 1:7) Ní ìparí lẹ́tà rẹ̀, Pọ́ọ̀lù rọni pé: “Ẹ máa bá a lọ . . . láti máa gba ìtùnú, . . . Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.”—Kọ́ríńtì Kejì 13:11.
12. Kí ni àìní tí gbogbo Kristẹni ní?
12 Ẹ wo ẹ̀kọ́ pàtàkì tí a lè rí kọ́ láti inú èyí! Gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ Kristẹni ní láti “ṣàjọpín ìtùnú” tí Ọlọ́run ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ pàápàá lè nílò ìtùnú bí wọ́n bá ti ronú pìwà dà, tí wọ́n sì ti ṣàtúnṣe ọ̀nà àìtọ́ wọn. Nípa báyìí, “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ti gbé ìpèsè aláàánú kan kalẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwọn alàgbà méjì lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn kan tí a yọ lẹ́gbẹ́. Àwọn wọ̀nyí lè máà tún fi ìwà ọlọ̀tẹ̀ hàn mọ́ tàbí wọ́n lè máà tún lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mọ́, wọ́n sì lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ pípọn dandan láti lè gbà wọ́n padà.—Mátíù 24:45; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:16.
Ìpọ́njú Pọ́ọ̀lù ní Éṣíà
13, 14. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe àkókò ìpọ́njú líle koko tí ó nírìírí rẹ̀ ní Éṣíà? (b) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù ti lè ní lọ́kàn?
13 A kò lè fi irú ìyà tí ìjọ Kọ́ríńtì jẹ títí di àkókò yìí wé ọ̀pọ̀ ìpọ́njú tí Pọ́ọ̀lù ní láti fara dà. Nípa báyìí, ó lè rán wọn létí pé: “Àwa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀, ẹ̀yin ará, nípa ìpọ́njú tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa ní àgbègbè Éṣíà, pé àwa wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ dé góńgó ré kọjá okun wa, tó bẹ́ẹ̀ tí a kò ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè wa pàápàá. Ní ti tòótọ́, a nímọ̀lára nínú ara wa pé a ti gba ìdájọ́ ìkú. Èyí jẹ́ kí a má baà ní ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú ara wa, bí kò ṣe nínú Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde. Láti inú irúfẹ́ ohun ńlá kan bẹ́ẹ̀ bí ikú ni òun ti gbà wá sílẹ̀ tí òun yóò sì gbà wá sílẹ̀; ìrètí wa sì wà nínú rẹ̀ pé òun yóò gbà wá sílẹ̀ síwájú sí i pẹ̀lú.”—Kọ́ríńtì Kejì 1:8-10.
14 Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bíbélì mélòó kan gbà gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí rúkèrúdò tí ó ṣẹlẹ̀ ní Éfésù, tí ì bá ti gba ìwàláàyè Pọ́ọ̀lù àti ti àwọn ará Makedóníà méjì tí ń bá a rìnrìn àjò, Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì. A fipá mú àwọn Kristẹni méjì yìí lọ sí gbọ̀ngàn ìwòran tí àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn kún fọ́fọ́, tí wọ́n ń “kígbe fún nǹkan bíi wákàtí méjì pé: ‘Títóbi ni Átẹ́mísì [abo ọlọ́run] ti àwọn ará Éfésù!’” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìjòyè ìlú kan kẹ́sẹ járí ní pípa àwùjọ náà lẹ́nu mọ́. Ewu tí ó wu ìwàláàyè Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì yìí gbọ́dọ̀ ti dààmú Pọ́ọ̀lù gidigidi. Ní tòótọ́, ó fẹ́ wọlé lọ, kí ó sì bá àgbájọ àwọn ènìyànkénìyàn agbawèrèmẹ́sìn náà sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n a dá a dúró láti má ṣe fi ìwàláàyè rẹ̀ wewu lọ́nà yìí.—Ìṣe 19:26-41.
15. Ipò tí ó légbá kan wo ni ó lè jẹ́ pé a ṣàpèjúwe nínú Kọ́ríńtì Kìíní 15:32?
15 Ṣùgbọ́n, ó lè jẹ́ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe ré kọjá ìṣẹ̀lẹ̀ tí a mẹ́nu kàn tán yìí fíìfíì. Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, bí mo bá ti bá àwọn ẹranko ẹhànnà jà ní Éfésù, ire kí ni ó jẹ́ fún mi?” (Kọ́ríńtì Kìíní 15:32) Èyí lè túmọ̀ sí pé kì í ṣe àwọn ènìyàn oníwà ẹranko nìkan ni ó wu ìwàláàyè Pọ́ọ̀lù léwu, ṣùgbọ́n àwọn ẹranko ẹhànnà ní ti gidi nínú pápá ìṣeré Éfésù wu ú léwu pẹ̀lú. Nígbà míràn, a máa ń jẹ àwọn ọ̀daràn níyà nípa fífipá mú wọn láti bá àwọn ẹranko ẹhànnà jà, nígbà tí àwọn àwùjọ tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ yóò sì máa wòran. Bí Pọ́ọ̀lù bá ní in lọ́kàn pé òun kojú àwọn ẹranko ẹhànnà ní ti gidi, ó ti ní láti jẹ́ pé nígbà tí ọ̀ràn náà dójú ọ̀gbagadè, ọ̀nà ìyanu ni a fi gbà á sílẹ̀, kúrò lọ́wọ́ ikú òǹrorò, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti dáàbò bo Dáníẹ́lì kúrò lẹ́nu àwọn kìnnìún ní ti gidi.—Dáníẹ́lì 6:22.
Àwọn Àpẹẹrẹ Òde Òní
16. (a) Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí fi lè lóye àwọn ìpọ́njú tí ó dé bá Pọ́ọ̀lù? (b) Kí ni ó lè dá wa lójú nípa àwọn tí wọ́n kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn? (c) Kí ni ipa rere tí yíyè bọ́ tí àwọn Kristẹni yè bọ́ lọ́wọ́ ikú ti ní?
16 Ọ̀pọ̀ Kristẹni lónìí lè lóye irú àwọn ìpọ́njú tí ó dé bá Pọ́ọ̀lù. (Kọ́ríńtì Kejì 11:23-27) Lónìí, pẹ̀lú, àwọn Kristẹni ti wà “lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ dé góńgó ré kọjá okun [wọn],” ọ̀pọ̀ sì ti kojú àwọn ipò nínú èyí tí wọn ‘kò ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè wọn.’ (Kọ́ríńtì Kejì 1:8) Àwọn òṣìkàpànìyàn àti àwọn òǹrorò onínúnibíni ti pa àwọn kan. A lè ní ìdánilójú pé agbára Ọlọ́run tí ń tuni nínú mú kí wọn lè fara dà àti pé wọ́n kú pẹ̀lú ọkàn-àyà àti èrò inú tí ó dúró gbọn-in-gbọn-in lórí ìmúṣẹ ìrètí wọn, yálà ìrètí ti ọ̀run tàbí ti orí ilẹ̀ ayé. (Kọ́ríńtì Kìíní 10:13; Fílípì 4:13; Ìṣípayá 2:10) Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, Jèhófà ti fọgbọ́n darí àwọn nǹkan, a sì ti gba àwọn ará wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Dájúdájú, àwọn ti wọ́n ti rí ìgbàlà lọ́nà bẹ́ẹ̀ ti mú ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó pọ̀ sí i dàgbà “nínú Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde.” (Kọ́ríńtì Kejì 1:9) Lẹ́yìn náà, wọ́n lè sọ̀rọ̀ àní pẹ̀lú ìdánilójú gidigidi bí wọ́n ti ń ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run tí ń tuni nínú pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 24:14.
17-19. Ìrírí wo ni ó fi hàn pé àwọn ará wa ní Rwanda ti jẹ́ olùṣàjọpín nínú ìtùnú Ọlọ́run?
17 Láìpẹ́ yìí, àwọn ará wa ní Rwanda la inú ìrírí tí ó jọ ti Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kọjá. Ọ̀pọ̀ pàdánù ẹ̀mí wọn, ṣùgbọ́n ìsapá Sátánì kùnà láti pa ìgbàgbọ́ wọn run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè yìí ti rí ìtùnú Ọlọ́run gbà ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ara ẹni. Nígbà ìpalápatán ẹ̀yà ti Tutsi àti Hutu tí wọ́n ń gbé ní Rwanda, àwọn Hutu wà tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wewu láti dáàbò bo àwọn Tutsi àti àwọn Tutsi tí wọ́n dáàbò bo àwọn Hutu. Àwọn aláṣerégèé pa àwọn kan nítorí pé wọ́n ń dáàbò bo àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Fún àpẹẹrẹ, a pa Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ Hutu tí ń jẹ́ Gahizi, lẹ́yìn tí ó fi arábìnrin kan tí ó jẹ́ Tutsi tí ń jẹ́ Chantal pa mọ́. Arábìnrin kan tí ó jẹ́ Hutu tí ń jẹ́ Charlotte fi ọkọ Chantal, Jean, tí ó jẹ́ Tutsi, pa mọ́ sí ibòmíràn. Fún 40 ọjọ́, Jean àti arákùnrin mìíràn tí ó jẹ́ Tutsi sá pa mọ́ sínú ọwọ̀n tí èéfín ń gbà jáde, wọ́n sì máa ń jáde síta fún ìgbà díẹ̀ kìkì ní òru. Ní gbogbo àkókò wọ̀nyí, Charlotte pèsè oúnjẹ àti ààbò fún wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó ń gbé nítòsí àgọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hutu. Lójú ìwé yìí, ẹ lè rí àwòrán Jean àti Chantal, tí wọ́n ti tún padà wà pa pọ̀, tí wọ́n ń dúpẹ́ pé àwọn olùjọ́sìn ẹlẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ Hutu, “fi ọrùn ara wọn wewu,” gan-an gẹ́gẹ́ bí Pírísíkà àti Ákúílà ti ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—Róòmù 16:3, 4.
18 Ìwé agbéròyìnjáde náà, Intaremara, kan sáárá sí Ẹlẹ́rìí mìíràn tí ó jẹ́ Hutu, Rwakabubu, fún dídáàbò bo àwọn Tutsi tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.a Ó wí pé: “Rwakabubu tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹni tí ó ń bá a nìṣó láti máa fi àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ arákùnrin rẹ̀ (bí àwọn onígbàgbọ́ kan náà ṣe ń pe ẹnì kíní kejì nìyẹn) pa mọ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ ni ó fi máa ń gbé oúnjẹ àti omi mímu lọ fún wọn bí òún tilẹ̀ jẹ́ ẹni tí ikọ́ fée ń yọ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún un ní agbára àrà ọ̀tọ̀.”
19 Tún ronú nípa tọkọtaya olùfìfẹ́hàn kan tí wọ́n jẹ́ Hutu tí wọ́n ń jẹ́ Nicodeme àti Athanasie. Kí ìpalápatán ẹ̀yà náà tó bẹ́ sílẹ̀, àwọn tọkọtaya yìí ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ Tutsi, tí ń jẹ́ Alphonse. Ní fífi ẹ̀mí wọn wewu, wọ́n fi Alphonse pamọ́ sílé wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n rí i pé ilé náà kì í ṣe ibi tí ó láàbò nítorí àwọn aládùúgbò wọn tí wọ́n jẹ́ Hutu mọ̀ nípa ọ̀rẹ́ wọn tí ó jẹ́ Tutsi. Nítorí náà, Nicodeme àti Athanasie fi Alphonse pa mọ́ sínú ihò kan lágbàlá wọn. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó dára nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni àwọn aládùúgbò máa ń wá Alphonse wá. Nígbà tí ó fi dùbúlẹ̀ sínú ihò yìí fún ọjọ́ 28, Alphonse ṣàṣàrò lórí àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì bíi èyí tí ó sọ nípa Ráhábù, tí ó fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì pa mọ́ sórí òrùlé ilé rẹ̀ ní Jẹ́ríkò. (Jóṣúà 6:17) Lónìí, Alphonse ń bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó ní Rwanda gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìn rere, ní dídúpẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Hutu fi ẹ̀mí wọn wewu nítorí rẹ̀. Nicodeme àti Athanasie ńkọ́? Nísinsìnyí, wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó ti ṣe batisí, wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó ju 20 lọ pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn.
20. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà tu àwọn ará wa nínú ní Rwanda, ṣùgbọ́n àìní wo tí ń bá a nìṣó ni ọ̀pọ̀ lára wọn ní?
20 Ní àkókò tí ìpalápatán ẹ̀yà bẹ̀rẹ̀ ní Rwanda, àwọn olùpòkìkí ìhìn rere 2,500 ní ń bẹ ní orílẹ̀-èdè náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún sọ ìwàláàyè wọn nù, tàbí tí a fi agbára mú wọn láti sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, iye àwọn Ẹlẹ́rìí ti lọ sókè sí ohun tí ó ju 3,000 lọ. Ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí pé ní tòótọ́, Ọlọ́run tu àwọn ará wa nínú. Ọ̀pọ̀ ọmọ òrukàn àti àwọn opó tí ń bẹ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ńkọ́? Lọ́nà ti ẹ̀dá, ìpọ́njú ṣì ń dé bá àwọn wọ̀nyí, wọ́n sì nílò ìtùnú tí ń bá a nìṣó. (Jákọ́bù 1:27) A óò nu omijé wọn nù pátápátá kìkì nígbà tí àjíǹde bá wáyé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànwọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn ará wọn àti nítorí pé wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” wọ́n lè kojú ìgbésí ayé.
21. (a) Ibòmíràn wo ni àwọn ará wa ti tún nílò ìtùnú Ọlọ́run gidigidi, kí sì ni ọ̀nà kan tí gbogbo wa ti lè ṣèrànlọ́wọ́? (Wo àpótí “Ìtùnú Láàárín Ọdún Mẹ́rin Tí Ogun Fi Jà.”) (b) Nígbà wo ní a óò tẹ́ àìní wa fún ìtùnú lọ́rùn pátápátá?
21 Ní ọ̀pọ̀ ibòmíràn, irú bíi Eritrea, Singapore, àti Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, àwọn ará wa ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ sin Jèhófà láìka ìpọ́njú sí. Ǹjẹ́ kí a máa ran irú àwọn ará bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ nípa rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ déédéé pé kí wọ́n lè rí ìtùnú gbà. (Kọ́ríńtì Kejì 1:11) Ǹjẹ́ kí a sì máa fi ìṣòtítọ́ fara dà á títí di ìgbà náà nígbà tí Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi “yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa]” ní èrò ìtumọ̀ kíkún. Nígbà náà a óò rí ìtùnú tí Jèhófà yóò pèsè nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀ gbà dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.—Ìṣípayá 7:17; 21:4; Pétérù Kejì 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1995, ojú ìwé 26, sọ ìrírí ọmọbìnrin Rwakabubu, Deborah, ẹni tí àdúrà rẹ̀ wọ àwọn sójà kan tí wọ́n jẹ́ Hutu lọ́kàn, tí ó sì dáàbò bo ìdílé rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ pípa wọ́n.
Ìwọ́ Ha Mọ̀ Bí?
◻ Èé ṣe tí a fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo”?
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ìpọ́njú?
◻ Ta ni a lè bá ṣàjọpín ìtùnú?
◻ Báwo ni a óò ṣe tẹ́ àìní wa fún ìtùnú lọ́rùn pátápátá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jean àti Chantal, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ Tutsi, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ Hutu fi wọ́n pa mọ́ ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà ìpalápatán ẹ̀yà ní Rwanda
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run tí ń tuni nínú pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn ní Rwanda